Báwo Ni Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù Fún Àwọn Olubi Ti Pọ̀ Tó?
Báwo Ni Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù Fún Àwọn Olubi Ti Pọ̀ Tó?
“Èé ṣe . . . tí o [Jèhófà] fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì?”—HÁBÁKÚKÙ 1:13.
1. Ìgbà wo ni ayé yóò kún fún ìmọ̀ nípa ògo Jèhófà?
ṢÉ ỌLỌ́RUN máa pa àwọn olubi run lóòótọ́? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbà wo la ó dúró dà? Jákèjádò ayé làwọn èèyàn ti ń béèrè irú ìbéèrè báwọ̀nyí. Níbo la ti lè rí ìdáhùn? Inú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò tó ti yàn. Wọ́n mú un dá wa lójú pé láìpẹ́ Jèhófà yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí gbogbo àwọn ẹni ibi. Ìgbà yẹn nìkan ni ayé tó lè “kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Ìyẹn ni ìlérí tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ táa rí nínú Ọ̀rọ̀ Mímọ́ Ọlọ́run, èyí tó wà nínú ìwé Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹrìnlá.
2. Àwọn ìdájọ́ àtọ̀runwá mẹ́ta wo ló wà nínú ìwé Hábákúkù?
2 Ìwé tí Hábákúkù kọ ní nǹkan bí ọdún 628 ṣááju Sànmánì Tiwa ní ọ̀wọ́ ìdájọ́ mẹ́ta tí Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ṣẹ. Méjì lára ìdájọ́ yẹn ti nímùúṣẹ. Èyí àkọ́kọ́ ni ìdájọ́ Jèhófà lórí orílẹ̀-èdè alágídí yẹn, ìyẹn ni Júdà ìgbàanì. Èkejì ńkọ́? Ìyẹn ni ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Bábílónì agbonimọ́lẹ̀. Dájúdájú, kò yẹ ká mikàn rárá pé ìkẹta nínú ìdájọ́ àtọ̀runwá yìí yóò ní ìmúṣẹ. Àní, a lè máa retí ìmúṣẹ rẹ̀ láìpẹ́ jọjọ. Tìtorí àwọn adúróṣánṣán tí ń bẹ lọ́jọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí gbogbo àwọn olubi èèyàn. Ẹni tó bá ṣẹ́ kù nínú wọn yóò kàgbákò tirẹ̀ nínú “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” tó ń bọ̀ kánkán yìí.—Ìṣípayá 16:14, 16.
3. Kí ló dájú pé yóò dé sórí àwọn ẹni burúkú tó wà ní àkókò tiwa?
3 Ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run ń sún mọ́lé gírígírí. Bó ṣe dá wa lójú pé ìdájọ́ Jèhófà dé sórí Júdà àti Bábílónì lọ́jọ́sí, bẹ́ẹ̀ náà ló dá wa lójú pé ìdájọ́ Ọlọ́run yóò dé sórí àwọn olubi ní àkókò tiwa yìí. Ṣùgbọ́n, ní báyìí, o ò ṣe kúkú gbà pé a wà ní Júdà nígbà ayé Hábákúkù? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà?
Ilẹ̀ tí Rúkèrúdò Bá
4. Ìròyìn amúnigbọ̀nrìrì wo ni Hábákúkù gbọ́?
4 Fojú inú wò ó pé o rí Hábákúkù, wòlíì Jèhófà tó jókòó sórí òkè ilé rẹ̀, tó ń gbádùn atẹ́gùn tó ń fẹ́ lóló lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ohun èlò orin kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ níbẹ̀. (Hábákúkù 1:1; 3:19, ìsọfúnni àkọkẹ́yìn) Àmọ́ Hábákúkù gbọ́ ìròyìn amúnigbọ̀nrìrì kan. Jèhóákímù, Ọba Júdà ti pa Úríjà, ó sì gbé òkú wòlíì náà lọ sínú itẹ́ òkú àwọn gbáàtúù èèyàn. (Jeremáyà 26:23) Ká sọ tòótọ́, Úríjà ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n jìnnìjìnnì, tó sì torí ẹ̀ sá lọ sí Íjíbítì. Síbẹ̀, Hábákúkù mọ̀ pé kì í ṣe ìfẹ́ láti gbé ògo Jèhófà ga ló mú kí Jèhóákímù hùwà ipá tó hù yìí. Èyí hàn gbangba nínú ẹ̀mí àìbìkítà burúkú tí ọba náà ní sí òfin Ọlọ́run àti ìkórìíra tó ní sí wòlíì Jeremáyà àti àwọn mìíràn tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà.
5. Báwo ní ipò tẹ̀mí ti rí ní Júdà, báwo ló sì ṣe rí lọ́kàn Hábákúkù?
5 Hábákúkù rí èéfín tùràrí tí ń rú túú lórí àwọn òrùlé tí ń bẹ nítòsí ilé rẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ń sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jèhófà o. Ṣe ni wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké tí Ọba burúkú nì, tí wọ́n ń pè ní Jèhóákímù, tó jọba lórí Júdà, gbé kalẹ̀. Ẹ̀gbin gbùn-ún-ùn! Omijé lé ròrò lójú Hábákúkù, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ? Nítorí náà, òfin kú tipiri, ìdájọ́ òdodo kò sì jáde lọ rárá. Nítorí pé ẹni burúkú yí olódodo ká, nítorí ìdí yẹn ni ìdájọ́ òdodo fi jáde lọ ní wíwọ́.”—Hábákúkù 1:2-4.
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí òfin àti ìdájọ́ òdodo ní Júdà?
6 Bẹ́ẹ̀ ni, fífini ṣèjẹ àti ìwà ipá pọ̀ káàkiri. Ibikíbi tí Hábákúkù bá yíjú sí ló ti ń rí rògbòdìyàn, aáwọ̀, àti gbọ́nmi-si-omi-ò-to. “Òfin ti kú tipiri,” ìyẹn ni pé, òfin ò gbéṣẹ́ mọ́. Ìdájọ́ òdodo ńkọ́? Ẹẹ̀, ‘kò jáde lọ rárá’ lọ́nà tí yóò fi ṣe ohun tó yẹ kó ṣe! Wọn ò jẹ́ ó gbérí rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘àwọn ẹni burúkú ló yí àwọn olódodo ká,’ tí wọ́n sì ń sọ òfin táa dìídì gbé kalẹ̀ láti dáàbò bo àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́. Ká sòótọ́, “ìdájọ́ òdodo . . . jáde lọ ní wíwọ́.” Wọ́n ti gbé e gbòdì. Ẹ ò ri pé ipò yìí burú jáì!
7. Kí ni Hábákúkù pinnu láti ṣe?
7 Hábákúkù sinmẹ̀dọ̀, ó ń ronú lórí ọ̀ràn yìí. Ṣé ó jọ̀gọ̀ nù ni? Rárá o! Lẹ́yìn tó ti ronú lórí gbogbo inúnibíni tí wọ́n ti ṣe sí àwọn tó ti fi ọkàn tòótọ́ sin Ọlọ́run, ọkùnrin adúróṣinṣin yìí túnra mú, ó lóun ò ní yẹsẹ̀ lórí ìpinnu òun láti jẹ́ wòlíì Jèhófà tó dúró gbọn-in. Hábákúkù kò ní yéé polongo iṣẹ́ Ọlọ́run—kódà bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tilẹ̀ máa yọrí sí ikú.
Jèhófà Ṣe “Ìgbòkègbodò” Àràmàǹdà
8, 9. “Ìgbòkègbodò” àràmàǹdà wo ni Jèhófà fẹ́ ṣe?
8 Nínú ìran, Hábákúkù rí àwọn onísìn èké, tí wọ́n tàbùkù Ọlọ́run. Ẹ gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ fún wọn, ó ní: “Ẹ wo inú àwọn orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì máa wò, kí ẹ sì wo ara yín sùn-ùn lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú kàyéfì.” Ó ṣeé ṣe kí Hábákúkù ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi ń bá àwọn olubi wọ̀nyẹn sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà ló wá gbọ́ tí Jèhófà ń sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣe kàyéfì; nítorí ìgbòkègbodò kan wà tí ẹnì kan ń ṣe ní àwọn ọjọ́ yín, èyí tí ẹ kì yóò gbà gbọ́ bí a tilẹ̀ ṣèròyìn rẹ̀.” (Hábákúkù 1:5) Dájúdájú, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń ṣe ìgbòkègbodò àràmàǹdà yìí. Ṣùgbọ́n, kí ni ìgbòkègbodò náà?
9 Hábákúkù fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run tún bá a sọ, èyí tó wà nínú Hábákúkù orí kìíní, ẹsẹ ìkẹfà sí ìkọkànlá. Iṣẹ́ tí Jèhófà rán an nìyí, kò sì sí ọlọ́run èké kankan tàbí òkú òrìṣàkórìṣà tó lè ní kó má ṣẹ: “Èmi yóò gbé àwọn ará Kálídíà dìde, orílẹ̀-èdè tí ó korò, tí ó sì ní inú fùfù, èyí tí ń lọ sí àwọn ibi fífẹ̀ gbayawu ilẹ̀ ayé kí ó bàa lè gba àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tirẹ̀. Ó jẹ́ adajìnnìjìnnì-boni àti amúnikún-fún-ẹ̀rù. Láti ọ̀dọ̀ òun fúnra rẹ̀ ni ìdájọ́ òdodo tirẹ̀ àti iyì tirẹ̀ ti ń jáde lọ. Àwọn ẹṣin rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí ó yára ju àmọ̀tẹ́kùn, wọ́n sì jẹ́ òǹrorò ju ìkookò ìrọ̀lẹ́. Àwọn ẹṣin ogun rẹ̀ sì ti fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀, ibi jíjìnnàréré sì ni àwọn ẹṣin ogun rẹ̀ ti wá. Wọ́n ń fò bí idì tí ń yára kánkán lọ jẹ nǹkan. Látòkè délẹ̀, kìkì ìwà ipá ni ó wá fún. Ìpéjọ ojú wọ́n dà bí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn, ó sì ń kó àwọn òǹdè jọpọ̀ bí iyanrìn. Ní tirẹ̀, ó ń fi àwọn ọba pàápàá ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì jẹ́ ohun apanilẹ́rìn-ín fún un. Ní tirẹ̀, ó ń fi gbogbo ibi olódi pàápàá rẹ́rìn-ín, ó sì ń kó ekuru jọ pelemọ, ó sì ń gbà á. Ní àkókò yẹn, dájúdájú, òun yóò lọ síwájú bí ẹ̀fúùfù, yóò sì kọjá lọ, yóò sì jẹ̀bi ní ti tòótọ́. Agbára rẹ̀ yìí wá láti ọwọ́ ọlọ́run rẹ̀.”
10. Ta ni Jèhófà gbé dìde?
10 Ìkìlọ̀ ńlá mà lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọ̀gá Ògo o! Jèhófà fẹ́ gbé àwọn ará Kálídíà dìde, orílẹ̀-èdè Bábílónì tó burú ju èèmọ̀ lọ. Bó bá ṣe ń la ‘àwọn ibi fífẹ̀ gbayawu ilẹ̀ ayé’ já, yóò ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ jaburata ibùgbé. Èyí mà tún jáni láyà o! Àwọn ará Kálídíà tóó “da jìnnìjìnnì boni, wọ́n tóó múni kún fún ẹ̀rù,” wọn rorò, àkòtagìrì ni wọ́n. Fúnra orílẹ̀-èdè náà ló ń gbé àwọn òfin rẹ̀ tó le koko kalẹ̀. ‘Láti inú ara rẹ̀ ní ìdájọ́ òdodo rẹ̀ sì ti ń jáde lọ.’
11. Báwo ni o ṣe lè ṣàpèjúwe bí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ṣe kọlu Júdà?
11 Ẹṣin àwọn ará Bábílónì lè sáré ju àwọn àmọ̀tẹ́kùn eléré àsápajúdé lọ. Àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ rorò ju àwọn ìkookò arebipa, tí ń ṣọdẹ lóru. Bí wọ́n ti ń hára gàgà láti lọ, ‘àwọn ẹṣin ogun rẹ̀ fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀’ kùràkùrà. Láti iyàn-níyàn Bábílónì ni wọ́n ti forí lé Júdà. Bí idì tó ń fò bọ̀ láti wá ki oúnjẹ tó fẹ́ràn mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kálídíà yóò ṣe ki ẹran ọdẹ wọn mọ́lẹ̀ láìpẹ́. Ṣé àwọn ọmọ ogun díẹ̀ ló kàn ń gbé sùnmọ̀mí bọ̀ ni, tí wọ́n kàn fẹ́ wá kẹ́rù lọ? Rárá o! “Látòkè délẹ̀, kìkì ìwà ipá ni ó wá fún,” bí ọ̀pọ̀ yanturu ọmọ ogun tó rọ́ wá láti wá ṣeni bí ọṣẹ́ ti ń ṣojú. Híhá tí wọ́n ń hára gàgà mú kí wọ́n ranjú kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gẹṣin lọ sí ìwọ̀ oòrùn Júdà àti Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì ń sáré tete bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn. Àwọn èèyàn tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì kó lẹ́rú pọ̀ débi pé ṣe ni wọ́n ‘ń kó àwọn òǹdè bí iyanrìn.’
12. Kí nìwà àwọn ará Bábílónì, kí sì ni ọ̀tá tí ń páni láyà yìí ‘jẹ̀bi rẹ̀ ní ti tòótọ́’?
12 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kálídíà fi àwọn ọba ṣẹ̀sín, wọ́n sì fi àwọn ìjòyè ńláńlá rẹ́rìn-ín, kò sì síkankan nínú wọn tó lè dá wọn dúró, bí wọ́n ti ń já bọ̀ ṣòòròṣò. Ó ‘ń fi gbogbo ibi olódi rẹ́rìn-ín’ nítorí pé gbogbo ibi táwọn ara Júdà fi ṣe odi agbára ló wó lulẹ̀ nígbà tí àwọn ará Bábílónì “kó ekuru jọ pelemọ,” nípa mímọ òkìtì, tí wọ́n sì ń tibẹ̀ bá wọn jà. Nígbà tí àkókò tí Jèhófà yàn bá tó, àwọn ọ̀tá tí ń páni láyà wọ̀nyí “yóò lọ síwájú bí ẹ̀fúùfù.” Nítorí tí ó bá Júdà àti Jerúsálẹ́mù jà, ‘yóò jẹ̀bi ní ti tòótọ́’ fún ṣíṣe àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́ṣẹ́. Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wàrà-ǹ-ṣeṣà yìí, ọ̀gágun àwọn ará Kálídíà yóò bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pé: ‘Agbára yìí wá láti ọwọ́ ọlọ́run wa.’ Ó mà ṣe o, kò tí ì mọ nǹkan kan!
Ìdí Tó Múná Dóko Táa Fi Lè Ní Ìrètí
13. Èé ṣe tí Hábákúkù fi kún fún ìrètí, tó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún?
13 Bí Hábákúkù ṣe túbọ̀ ń lóye ète Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún tó ní yìí, ó júbà Jèhófà. Gẹ́gẹ́ báa ti kíyè sí i nínú Hábákúkù orí kìíní, ẹsẹ ìkejìlá, wòlíì náà wí pé: “Kì í ha ṣe láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti wà, Jèhófà? Ìwọ Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.” Òdodo ọ̀rọ̀ ni, Jèhófà ni Ọlọ́run “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin”—ìyẹn ni títí láé.—Sáàmù 90:1, 2.
14. Ìwà wo làwọn apẹ̀yìndà tó wà ní Júdà ń hù?
14 Bó ṣe ń ronú lórí ìran tí Ọlọ́run fi hàn án, tó sì ń yọ̀ nítorí òye jíjinlẹ̀ tó fún un, wòlíì náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jèhófà, ìwọ ti gbé e kalẹ̀ fún ìdájọ́; ìwọ Àpáta sì ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún ìfìbáwítọ́sọ́nà.” Ọlọ́run ti dá àwọn apẹ̀yìndà tó wà ní Júdà lẹ́bi, Jèhófà yóò bá wọn wí gidigidi, yóò sì fìyà tó tó ìyà jẹ wọ́n. Òun ló yẹ kí wọ́n máa wò gẹ́gẹ́ bí Àpáta wọn, ojúlówó odi agbára wọn, ibi ìsádi wọn, àti Orísun ìgbàlà wọn. (Sáàmù 62:7; 94:22; 95:1) Síbẹ̀, àwọn apẹ̀yìndà tó jẹ́ aṣáájú Júdà kò sún mọ́ Ọlọ́run rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn olùjọsìn Jèhófà, tí wọn ò ṣe ẹnikẹ́ni níbi, ni wọ́n ń ni lára ṣáá.
15. Lọ́nà wo ni “ojú [Jèhófà fi] mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú”?
15 Ipò yìí kó ìdààmú ńlá bá wòlíì Jèhófà. Ló bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní: “Ojú rẹ ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú; ìwọ kò sì lè wo ìdààmú.” (Hábákúkù 1:13) Bẹ́ẹ̀ ni, “ojú [Jèhófà] ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú,” ìyẹn ni pé, láti fàyè gba ìwà àìtọ́.
16. Báwo lo ṣe lè ṣàkópọ̀ àkọsílẹ̀ Hábákúkù 1:13-17?
16 Nítorí náà, Hábákúkù ní àwọn ìbéèrè mélòó kan lọ́kàn, èyí tó lè múni ronú jinlẹ̀. Ó béèrè pé: “Èé ṣe tí o fi ń wo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, tí o fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì? Èé sì ti ṣe tí ìwọ fi ṣe ará ayé bí àwọn ẹja òkun, bí àwọn ohun tí ń rákò, tí kò sí ẹni tí ń ṣàkóso lórí wọn? Gbogbo ìwọ̀nyí ni ó ti fi ìwọ̀ ẹja lásán-làsàn mú gòkè wá; ó wọ́ wọn lọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀, ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ìpẹja rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń yọ̀, tí ó sì kún fún ìdùnnú. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń rú ẹbọ sí àwọ̀n ńlá rẹ̀, tí ó sì ń rú èéfín ẹbọ sí àwọ̀n ìpẹja rẹ̀; nítorí nípasẹ̀ wọn, ìpín rẹ̀ ni a fi òróró dùn dáadáa, oúnjẹ rẹ̀ sì jẹ́ afúnni-nílera. Ṣé ìdí nìyẹn tí yóò fi sọ àwọ̀n ńlá rẹ̀ di òfìfo, ó ha sì ní láti máa pa àwọn orílẹ̀-èdè nígbà gbogbo, nígbà tí kò fi ìyọ́nú hàn?”—Hábákúkù 1:13-17.
17. (a) Nípa kíkọjú ìjà sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, báwo ni àwọn ará Bábílónì ṣe mú ète Ọlọ́run ṣẹ? (b) Kí ni Jèhófà yóò fi han Hábákúkù?
17 Nígbà tí àwọn ará Bábílónì bá dojú ìjà kọ àwọn ará Júdà àti olú ìlú wọn, ìyẹn Jerúsálẹ́mù, ohun tí ń bẹ lọ́kàn wọn ni wọn yóò ṣe. Wọn ò ní mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń lò wọ́n láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn aláìṣòótọ́ ènìyàn. Ó rọrùn láti rí ìdí tó fi ṣòro gidigidi fún Hábákúkù láti lóye pé Ọlọ́run yóò lo àwọn olubi ará Bábílónì láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Àwọn ìkà ènìyàn, àwọn ará Kálídíà wọ̀nyí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà o. Ojú tí wọ́n fi ń wo ‘ẹja àti àwọn ohun tí ń rákò’ ni wọ́n fi ń wo ènìyàn, wọ́n ka èèyàn sí ohun tí wọ́n lè kó lẹ́rú, kí wọ́n sì jọba lé lórí. Àmọ́ ṣá o, ìdààmú tó dé bá Hábákúkù yìí kò ní wà pẹ́ títí. Láìpẹ́, Jèhófà yóò fi han wòlíì rẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì kò ní lọ láìjìyà, nítorí ẹ̀mí ìwọra tí wọ́n fi ń kóni ní ìkógun àti nítorí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n jẹ lọ́nà tó bùáyà.—Hábákúkù 2:8.
Gbára Dì fún Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Jèhófà Tún Fẹ́ Sọ
18. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìwà Hábákúkù, gẹ́gẹ́ bí Hábákúkù 2:1 ti fi hàn?
18 Wàyí o, Hábákúkù ń retí láti gbọ́ ohun tí Jèhófà tún fẹ́ bá a sọ. Wòlíì náà fi tìpinnu-tìpinnu sọ pé: “Ibi ìṣọ́ mi ni èmi yóò dúró sí, èmi yóò sì mú ìdúró mi lórí odi ààbò; èmi yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́, láti rí ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ mi, àti ohun tí èmi yóò fi fèsì nígbà tí a bá fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà.” (Hábákúkù 2:1) Pẹ̀lú ìháragàgà ni Hábákúkù fẹ́ mọ ohun tí Ọlọ́run yóò tún gba ẹnu rẹ̀ sọ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà pé, ó jẹ́ Ọlọ́run tí kì í fàyè gba ohun burúkú, mú kó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ìwà ibi fi ń gbilẹ̀ sí i, àmọ́ ṣá o, ó ṣe tán láti jẹ́ kí èrò ọkàn òun yí padà. Tóò, àwa náà ńkọ́? Báa bá tiẹ̀ ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn nǹkan kan tí kò dára, ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní pé ó jẹ́ Ọlọ́run òdodo yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá ìdúróṣinṣin wa nìṣó, ká sì dúró dè é.—Sáàmù 42: 5, 11.
19. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Hábákúkù, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn Júù alágídí?
19 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún Hábákúkù gẹ́lẹ́, ó mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí orílẹ̀-èdè Júù alágídí yẹn, nípa jíjẹ́ kí àwọn ará Bábílónì dó ti Júdà. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, bí wọ́n ti ń pa arúgbó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pa ọmọdé, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú. (2 Kíróníkà 36:17-20) Lẹ́yìn tí ìyókù àwọn Júù olóòótọ́ wọ̀nyí ti wà nígbèkùn fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n padà sí ilẹ̀ wọn, ní àsẹ̀yìnwà-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn èyí, àwọn Júù tún di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà—àgàgà nígbà tí wọ́n wá kọ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.
20. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo Hábákúkù orí kìíní ẹsẹ ìkarùn-ún nípa báwọn èèyàn yóò ṣe kọ Jésù sílẹ̀?
20 Gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 13:38-41 ti sọ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí àwọn Júù tó wà ní Áńtíókù mọ ohun tó túmọ̀ sí láti kọ Jésù sílẹ̀, kí á sì tipa bẹ́ẹ̀ gan ẹbọ ìràpadà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé Hábákúkù 1:5, tí a bá kà á nínú ẹ̀dà ti Septuagint lédè Gíríìkì, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ rí i pé ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì kò wá sórí yín, ‘Ẹ kíyè sí i, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ó ṣe yín ní kàyéfì, kí ẹ sì pòórá dànù, nítorí pé èmi ń ṣe iṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ yín, iṣẹ́ kan tí ẹ kì yóò gbà gbọ́ lọ́nàkọnà bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ṣèròyìn rẹ̀ fún yín ní kúlẹ̀kúlẹ̀.’” Gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fà yọ, Hábákúkù orí kìíní ẹsẹ ìkarùn-ún nímùúṣẹ ní ìgbà kejì, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.
21. Ojú wo ni àwọn Júù ọjọ́ Hábákúkù fi wo “iṣẹ́” tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, ìyẹn ni lílo àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run?
21 Lójú àwọn Júù ọjọ́ Hábákúkù, “iṣẹ́” tí Ọlọ́run yóò ṣe, ìyẹn ni lílo àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run, dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ láé, nítorí ìlú yìí ni ibùjókòó ìjọsìn Jèhófà, ibẹ̀ sì ni ọba rẹ̀ tó fi òróró yàn ti gorí ìtẹ́. (Sáàmù 132:11-18) Irú ìparun bẹ́ẹ̀ ò sì tí ì ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù rí. Kò sẹ́ni tó sọ iná sí tẹ́ńpìlì rẹ̀ rí. A ò gbàjọba lọ́wọ́ ìdílé ọba Dáfídì rí. Wọn ò gbà pé Jèhófà lè yọ̀ǹda kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ láé. Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ Hábákúkù, Ọlọ́run pèsè ìkìlọ̀ tó tó, ó sọ fún wọn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnigbọ̀nrìrì wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Ìtàn sì jẹ́rìí sí i pé gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wí.
“Iṣẹ́” Àrà tí Ọlọ́run Fẹ́ Ṣe Ní Ọjọ́ Wa
22. “Iṣẹ́” àrà wo ni Jèhófà yóò ṣe ní ọjọ́ tiwa yìí?
22 Ǹjẹ́ Jèhófà ń bọ̀ wá ṣe “iṣẹ́” àrà kan ní ọjọ́ tiwa? Mọ̀ dájú pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú àwọn oníyèméjì ó dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, iṣẹ́ àrà tí Jèhófà fẹ́ ṣe ni pípa Kirisẹ́ńdọ̀mù run. Gẹ́gẹ́ bíi Júdà ìgbàanì, ó ń sọ pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n, ó ti bà jẹ́ pátápátá. Jèhófà yóò rí i dájú pé gbogbo ẹ̀ka ètò ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù la pa run láìpẹ́ jọjọ, bẹ́ẹ̀ náà la ó sì pa “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé run pẹ̀lú.—Ìṣípayá 18:1-24.
23. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run sún Hábákúkù láti ṣe?
23 Jèhófà ṣì ní iṣẹ́ púpọ̀ fún Hábákúkù láti ṣe ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Kí ni Ọlọ́run tún fẹ́ sọ fún wòlíì rẹ̀. Họ́wù, Hábákúkù máa tó gbọ́ ohun tí yóò sún un gbé ohun èlò ìkọrin rẹ̀, tí yóò sì fi àdúrà kọrin arò sí Jèhófà. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀mí Ọlọ́run yóò kọ́kọ́ sún wòlíì náà láti kéde àwọn ègbé amúnigbọ̀nrìrì. Dájúdájú, a ó mọrírì níní òye ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ tí irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní fún àkókò tí Ọlọ́run ti yàn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ gbé àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù yẹ̀ wò.
Ṣé O Rántí?
• Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Júdà nígbà ayé Hábákúkù?
• “Ìgbòkègbodò” àràmàǹdà wo ni Jèhófà ṣe ní àkókò Hábákúkù?
• Kí ló jẹ́ kí Hábákúkù ní ìrètí?
• “Iṣẹ́” àrà wo ni Ọlọ́run fẹ́ ṣe ní ọjọ́ tiwa yìí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Hábákúkù ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí ìwà ibi máa gbilẹ̀ sí i. Ìwọ ńkọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Hábákúkù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àjálù yóò ṣe dé sórí ilẹ̀ Júdà látọwọ́ àwọn ará Bábílónì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ògiri àlàpà táa wú jáde ní Jerúsálẹ́mù nìyí, ìlú tí wọ́n pa run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa