Jèhófà ni Ààbò àti Okun Mi
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà ni Ààbò àti Okun Mi
GẸ́GẸ́ BÍ MARCEL FILTEAU ṢE SỌ Ọ́
“Tóo bá fẹ́ ẹ, kò sí bóò ṣe ní ṣẹ̀wọ̀n.” Ohun tí àwọn èèyàn sọ fún ọmọbìnrin tí mo fẹ́ fẹ́ nìyẹn. Ẹ jẹ́ kí ń ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fí ń sọ irú ọ̀rọ̀ báyẹn.
NÍGBÀ tí wọ́n bí mi ní ọdún 1927, ẹkùn Quebec ti Kánádà jẹ́ ibi tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ti fìdí múlẹ̀ gan-an nígbà yẹn. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, Cécile Dufour, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sílé wa ní ìlú Montreal. Nítorí ìdí èyí, àwọn aládùúgbò wa kì í jẹ́ kó gbádùn. Àní, wọ́n tiẹ̀ fi ọlọ́pàá mú un, tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà fún wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Bíbélì. Kò pẹ́ táa fi lóye òtítọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.”—Mátíù 24:9.
Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ ló gbà pé kò ṣeé gbọ́ sétí rárá kí ìdílé ará Kánádà kan tó ń sọ èdè Faransé fi ẹ̀sìn Kátólíìkì sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi kò fìgbà kan di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi, síbẹ̀ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbà pé àwọn ẹ̀kọ́ tí Ìjọ Kátólíìkì fi ń kọ́ni kò bá Bíbélì mu. Nítorí náà, wọ́n gba àwọn ọmọ wọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ níyànjú láti máa ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún àwa tí a tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì.
Mímú Ìdúró Láwọn Àkókò Ìṣòro
Ìgbà tí mo ṣì wà nílé ìwé ní ọdún 1942 ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ojúlówó ìfẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà yẹn ní wọ́n fòfin de ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ìjímìjí, wọn ò sì lọ́wọ́ nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè. (Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52) Wọ́n fi Roland, ẹ̀gbọ́n mi àgbà pátápátá sí àgọ́ tí wọ́n ti ń fiṣẹ́ páni lórí nítorí pé ó kọ̀ láti gbébọn lákòókò tí ogun àgbáyé ń jà lọ́wọ́.
a Ó wá ń wù mí kí wọ́n ka èmi náà mọ́ irú àwọn tó ní àpẹẹrẹ ìgboyà fún ìwà títọ́ bẹ́ẹ̀, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń ṣe láwọn ilé àdáni nìyẹn. Kò pẹ́ tí wọ́n fi pè mí láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bí mo ṣe ń tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí ni mo ti mọ̀ dájú pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè fi ọlọ́pàá mú mi, kí wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n.
Àárín àkókò yìí ni Baba fún mi ní ìwé kan lédè Faransé tó ṣàpèjúwe ìyà tó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Jámánì nígbà tí wọ́n kọ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ogun tí Adolph Hitler ń jà.Lẹ́yìn tí mo gbàdúrà fún okun, mo kan ilẹ̀kùn tí mo máa kọ́kọ́ kàn pàá láti wàásù. Obìnrin onínúure kan dáhùn, lẹ́yìn ti mo sọ ẹni tí mo jẹ́ fún un, mo ka àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Tímótì 3:16 fún un pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.”
Mo wá béèrè pé: “Ṣe wàá fẹ́ láti túbọ̀ kọ́ nípa Bíbélì sí i?”
Obìnrin náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Mo wá sọ fún un pé màá mú ọ̀rẹ́ kan tó mọ Bíbélì jù mí lọ wá, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn ìrírí mi àkọ́kọ́ yẹn, mo wá ní ìgboyà sí i, mo sì wá rí i pé kì í ṣe okun tiwa fúnra wa la fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, ìrànlọ́wọ́ Jèhófà la fi ń ṣe é. Ẹ wò ó, ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé ‘agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá jẹ́ ti Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.’—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Lẹ́yìn ìyẹn, iṣẹ́ ìwàásù wá di apá kan ìgbésí ayé mi, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfàṣẹ ọba múni àti ṣíṣẹ̀wọ̀n di apá kan rẹ̀ pẹ̀lú. Abájọ tí wọ́n fi sọ fún ìyàwó tí mo fẹ́ fẹ́ pé, “Tóo bá fẹ́ ẹ, kò sí bóò ṣe ní ṣẹ̀wọ̀n”! Síbẹ̀, irú àwọn ìrírí wọ̀nyẹn kì í ṣe ohun tó kọjá ìfaradà. Lẹ́yìn táa bá ti sun oorun ọjọ́ kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, a óò rí Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa kan tó máa dúró fún wa.
Àwọn Ìpinnu Pàtàkì
Ní April 1943, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ní August 1944, mo lọ sí àpéjọpọ̀ ńlá tó jẹ́ àkọ́kọ́ fún mi, ní Buffalo, New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó wà nítòsí ibodè Kánádà. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] ènìyàn ló wá sí àpéjọpọ̀ náà, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sì mú kí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wù mí í ṣe, ìyẹn ni ohun tí a ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. May 1945 ni wọ́n mú òfin tí wọ́n fi dé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà kúrò, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lóṣù tó tẹ̀ lé e.
Àmọ́, bí mo ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sí i tó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀wọ̀n tí mo fi ń jura ń pọ̀ sí i. Ìgbà kan wà tí wọ́n fi èmi àti Mike Miller sínú yàrá kan náà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, olóòótọ́ èèyàn lọ́kùnrin yìí, ó sì ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láti ọjọ́ tó ti pẹ́. La bá jókòó sórí ilẹ̀ onísìmẹ́ǹtì, a sì sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀. Ìjíròrò wa tó Gálátíà 5:15.
ń gbéni ró nípa tẹ̀mí yẹn fún mi lókun gan-an ni. Àmọ́, lẹ́yìn náà ni ìbéèrè kan wá sí mi lọ́kàn pé, ‘Tó bá wá jẹ́ pé a ti ní gbọ́nmisi-omi-ò-to kan láàárín ara wa tẹ́lẹ̀, tí a kì í sì í bára wa sọ̀rọ̀ ńkọ́?’ Àkókò tí mo lò pẹ̀lú arákùnrin yìí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ dídára jù lọ kan nínú ìgbésí ayé mi—òun ni pé a nílò àwọn arákùnrin wa, nítorí náà a ní láti máa dárí ji ara wa, ká sì máa ṣoore fúnra wa. Bí a ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tí à ń ṣe ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọwé nípa rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní bíbu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín ní àjẹrun, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín rẹ́ ráúráú lẹ́nì kìíní-kejì.”—Ní September 1945, wọ́n pè mí láti wá sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society ní Toronto, Kánádà, ìyẹn níbi tí a ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó wà níbẹ̀ ń gbéni ró gan-an ni, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ lókun. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni wọ́n yàn mí láti lọ ṣiṣẹ́ ní oko Bẹ́tẹ́lì, tó wà ní nǹkan bí ogójì kìlómítà sí ìhà àríwá ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà. Bí èmi àti omidan Anne Wolynec ṣe ń ṣa èso strawberry ni mo ṣàkíyèsí pé yàtọ̀ sí pé ó rẹwà, ó tún ní ìfẹ́ àti ìtara fún Jèhófà. Báa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wa sọ́nà nìyẹn, a sì ṣègbéyàwó ní January 1947.
Ní ọdún méjì ààbọ̀ tó tẹ̀ lé e, a ṣe aṣáájú ọ̀nà ní London, Ontario, lẹ́yìn ìyẹn la wá lọ sí Erékùsù Cape Breton, níbi táa ti ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ kan sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní 1949, wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹrìnlá ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, níbi táa ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì.
Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì ni Quebec
Wọ́n ti yan àwọn ará Kánádà tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege láwọn kíláàsì tó ṣáájú tiwa ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní Quebec. Ní 1950, àwa àti àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n míì láti kíláàsì kẹrìnlá tó jẹ́ tiwa tún dara pọ̀ mọ́ wọn. Pípọ̀ tí ìgbòkègbodò míṣọ́nnárì ń pọ̀ sí i tún mú inúnibíni líle koko wá, ó sì tún mú kí àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí èèyàn kọ lù wá, àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀sì Roman Kátólíìkì ló sì ṣokùnfà rẹ̀.
Ọjọ́ méjì lẹ́yìn táa dé ibi tí a kọ́kọ́ yàn wá sí fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ìlú ńlá Rouyn ni àwọn ọlọ́pàá wá gbé Anne, tí wọ́n sì jù ú sí ẹ̀yìn ọkọ̀ wọn. Irú èyí ò ṣẹlẹ̀ sí i rí, nítorí pé abúlé kékeré kan ní ẹkùn Manitoba, Kánádà ló ti wá, níbi tó jẹ́ pé kì í ti í sábà rí ọlọ́pàá. Ìdí nìyẹn tẹ́rù fi bà á, ó wá rántí ọ̀rọ̀ náà pé, “Tóo bá fẹ́ ẹ, kò sí bóo ṣe ní ṣẹ̀wọ̀n.” Àmọ́, kí wọ́n tó máa lọ, àwọn ọlọ́pàá náà rí mi, wọ́n sì gbé èmi náà sínú ọkọ̀ tí Anne wà. Ó kígbe pé: “Ìwọ ni mo tún rí yìí, inú mi mà dùn o! Síbẹ̀, ó rọ wọ́jọ́ lọ́nà kan tó yani lẹ́nu, ó wá sọ pé, “Kò burú, irú ohun kan náà kúkú ṣẹlẹ̀ sí àwọn àpọ́sítélì nítorí pé wọ́n ń wàásù nípa Jésù.” (Ìṣe 4:1-3; 5:17, 18) Nígbà tó ṣe díẹ̀ lọ́jọ́ kan náà yẹn wọ́n dá wa sílẹ̀ nígbà táà rẹ́ni dúró fún wa.
Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, nígbà táa wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé ní ìpínlẹ̀ wa tuntun ní Montreal, mo gbọ́ tí rúkèrúdò kan ń lọ lójú pópó, mo sì rí àwọn ẹhànnà tínú ń bí tí wọ́n ń ju òkò. Bí mo ṣe ní kí n lọ ran Anne àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́ làwọn ọlọ́pàá débẹ̀. Dípò tí wọn ì bá fi kó àwọn èèyànkéèyàn náà, Anne àti ẹnì kejì rẹ̀ làwọn ọlọ́pàá mà kó o! Nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, Anne rán ẹnì kejì rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí létí pé òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù làwọn ń nírìírí rẹ̀ yìí, nígbà tó sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.”—Mátíù 10:22.
Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] ẹjọ́ tí wọ́n pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà nílẹ̀ ní Quebec. Ní gbogbo gbòò, ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá ni pé à ń pín ìwé ọ̀tẹ̀ kiri tàbí pé a ń pín ìwé kiri láìgbàṣẹ. Nítorí ìdí yìí, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin Ní Ọ́fíìsì Watch Tower Society, pe ìjọba ilẹ̀ Quebec lẹ́jọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táa fi ṣẹjọ́, Jèhófà jẹ́ ká borí nígbà méjì lọ́nà tó lágbára ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti ilẹ̀ Kánádà. Ní December 1950 la dá wa láre pé àwọn ìwé wa kì í ṣe ìwé ọ̀tẹ̀, nígbà tó sì di October 1953, ilé ẹjọ́ fàyè gbà wá pé a lè máa pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa kiri láìgba ìwé àṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, a wá rí i ní kedere bí Jèhófà ṣe jẹ́ ibi “ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.”—Sáàmù 46:1.
Lọ́nà tó gbàfiyèsí, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Quebec ti lọ sókè gan-an o, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ọdún 1945, ọ̀ọ́dúnrún lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [356] làwọn tó wà níbẹ̀, àmọ́ lónìí, wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000]! Ní Aísáyà 54:17.
ti tòótọ́, bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí nígbà tó wí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi.”—Iṣẹ́ Wa Nílẹ̀ Faransé
Ní September 1959, wọ́n pe èmi àti Anne ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Paris, ní ilẹ̀ Faransé, níbi tí wọ́n ti yàn mi gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìwé títẹ̀. Títí dìgbà táa fi dé ní January 1960 yẹn, ilé iṣẹ́ okòwò kan ló ń bá wọn tẹ̀wé. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé wọ́n ti fòfin de Ilé Ìṣọ́ nílẹ̀ Faransé, ńṣe la máa ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde bí ìwé kékeré olójú ewé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lóṣooṣù. Orúkọ táa fún ìwé náà ni The Interior Bulletin of Jehovah’s Witnesses, ó sì máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ táa máa kà nínú ìjọ lóṣù yẹn nínú. Láàárín ọdún 1960 sí 1967, iye àwọn tó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Faransé lọ sókè láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé irínwó àti mọ́kàndínlógójì [15,439] sí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ó lé igba àti àádọ́ta [26,250].
Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a yan àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyẹn sí ibòmíràn, a yan àwọn kan sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ní Áfíríkà, àwọn mìíràn sì padà sí Quebec. A padà sí Quebec nítorí pé ara Anne ò yá, ó sì nílò iṣẹ́ abẹ. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí Anne fi gba ìtọ́jú, ara rẹ̀ yá. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n wá yàn mí sí iṣẹ́ alábòójútó àyíká, kí n máa bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí.
Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì ní Áfíríkà
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní 1981, inú wa dùn láti gba iṣẹ́ tuntun gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Zaire, táa wá ń pè ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Congo báyìí. Àwọn ènìyàn ibẹ̀ ò lówó lọ́wọ́, ìyà tó sì ǹ jẹ wọ́n ò kéré. Nígbà táa débẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàléláàádọ́ta [25,753], àmọ́ lónìí, wọ́n ti di ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́fà [113,000], àwọn tó sì wá síbi Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọdún 1999 lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta, ọ̀ọ́dúnrún àti méjìlélọ́gọ́ta[446,362]!
Ní 1984, a gba ilẹ̀ kan tó ń lọ sí nǹkan bí igba hẹ́kítà lọ́dọ̀ ìjọba kí a lè fi kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun. Lẹ́yìn náà ní December 1985, a ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Kinshasa, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, iye àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000], wọ́n wá láti apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn àlùfáà wá bẹ̀rẹ̀ sí í súnná sí àtakò tó da iṣẹ́ wa rú ní Zaire. Nígbà tó di March 12, 1986, wọ́n kọ lẹ́tà kan sí àwọn lóókọ-lóókọ lára àwọn arákùnrin, lẹ́tà náà sọ pé ìjọba kò fọwọ́ sí ẹgbẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ilẹ̀ Zaire. Ẹni tó fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe fòfin de gbogbo ìgbòkègbodò wa nígbà yẹn ni olórí orílẹ̀-èdè náà, Mobutu Sese Seko, tó ti di olóògbé báyìí.
Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣàdédé yọjú wọ̀nyẹn, a ní láti fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì yẹn sílò, tó sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) A wá ọ̀nà láti rí bébà, yíǹkì, fíìmù, àwo ìtẹ̀wé, àti kẹ́míkà gbà láti orílẹ̀-èdè mìíràn kí a lè fi tẹ̀wé ní Kinshasa. A tún dọ́gbọ́n ọ̀nà tí a ó máa gbà pín wọn kiri fúnra wa. Nígbà tí ètò wa ti fìdí múlẹ̀ tán, ọ̀nà tí a ń gbà pín ìwé wa tún wá gbéṣẹ́ ju ti ilé ìfìwéránṣẹ́ tó jẹ́ ti ìjọba lọ!
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí làwọn ọlọ́pàá mú, ọ̀pọ̀ ni wọ́n sì dá lóró burúkú. Síbẹ̀, táa bá yọwọ́ àwọn díẹ̀ tó juwọ́ sílẹ̀, àwọn ará fara da irú ìjìyà bẹ́ẹ̀, wọ́n sì di ìṣòtítọ́ wọn mú. Wọ́n mú èmi náà, mo sì fojú ara mi rí nǹkan burúkú tí wọ́n ń fojú àwọn arákùnrin rí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àtàwọn aláṣẹ ń há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n Jèhófà máa ń ṣe ọ̀nà àbájáde fún wa.—2 Kọ́ríńtì 4:8.
A ti kó nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pa mọ́ sí ibi tí oníṣòwò kan máa ń kó ẹrù pa mọ́ sí. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lọ ṣòfófó fún àwọn ọlọ́pàá, wọ́n sì mú oníṣòwò náà. Bí wọ́n ṣe ń lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ṣèèṣì bá mi pàdé níbi tí mo ti ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi lọ. Ní ọkùnrin oníṣòwò náà bá sọ fún wọn pé èmi ni mo kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa mọ́ sọ́dọ̀ òun. Bí àwọn ọlọ́pàá náà ṣe dá mi dúró nìyẹn tí wọ́n ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi nípa rẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mo kó àwọn ìwé tó lòdì sófin pa mọ́ síbi tí ọkùnrin yìí ń kẹ́rù sí.
Mo bi wọ́n pé: “Ǹjẹ́ ẹ ní ọ̀kan lára àwọn ìwé náà?”
Wọ́n dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Mo ní: “Ǹjẹ́ mo lè rí i?”
Wọ́n fún mi ní ẹ̀dà kan, bí mo ṣe ṣí i nìyẹn tí mo sì fi ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ hàn wọ́n pé: “A tẹ̀ ẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti ọwọ́ Watch Tower Bible & Tract Society.”
Mo wá rán wọn létí pé: “Ẹrù Amẹ́ríkà ló wà lọ́wọ́ yín yẹn kì í ṣe ti Zaire. Ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Zaire ni ìjọba yín gbẹ́sẹ̀ lé, wọn ò gbẹ́sẹ̀ lé Watch Tower Bible & Tract Society ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tẹ́ẹ fẹ́ fi àwọn ìwé wọ̀nyẹn ṣe o.”
Bí wọ́n ṣe fi mí sílẹ̀ nìyẹn nítorí pé wọn ò ní àṣẹ ilé ẹjọ́ kankan tí wọ́n lè fi mú mi. Òru ọjọ́ yẹn la mú ọkọ̀ akẹ́rù méjì lọ síbi ìkẹ́rùsí náà táa sì palẹ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́ kúrò níbẹ̀. Inú bí àwọn aláṣẹ gan-an ni nígbà tí wọ́n débẹ̀ lọ́jọ́ kejì tí wọn ò bá ohunkóhun níbẹ̀ mọ́. Ìgbà yẹn ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wá mi kiri, nítorí pé wọn ti gba àṣẹ tí wọ́n lè fi mú mi nílé ẹjọ́. Wọ́n rí mi, àmọ́ nítorí pé wọn ò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bí mo ṣe wa ara mí lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nìyẹn o! Ẹlẹ́rìí mìíràn tẹ̀ lé mi kó lè bá mi gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi padà kí wọ́n to gbẹ́sẹ̀ lé e.
Lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò fún odindi wákàtí mẹ́jọ, wọ́n pinnu pé àwọn óò lé mi kúrò nílùú. Ṣùgbọ́n mo fi ẹ̀dà lẹ́tà tí mo gbà lọ́dọ̀ ìjọba hàn wọ́n, ìyẹn lẹ́tà tó fi hàn pé wọ́n ti yàn mí láti ṣírò iye owó tí ohun ìní ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fòfin dè ní Zaire tó. Nítorí èyí wọ́n gbà pé kí n máa bá iṣẹ́ mi ní Bẹ́tẹ́lì lọ.
Lẹ́yìn tí mo ti fi ọdún mẹ́rin sìn lábẹ́ pákáǹleke iṣẹ́ wa tí wọ́n fòfin dè ní Zaire, mo wá ní ọgbẹ́ inú tó ń ṣẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì lè ṣekú pani. Ohun táa wá pinnu ni pé kí n lọ gba ìtọ́jú ni Gúúsù Áfíríkà, níbi tí ẹ̀ka tó wà níbẹ̀ ti bójú tó mi dáradára, ara mi sì yá. Lẹ́yìn táa ti fi ọdún mẹ́jọ sìn ní Zaire, táa sì ní àwọn ìrírí mánigbàgbé, tí wọ́n mu wa láyọ̀, a kó lọ sí ẹ̀ka ti Gúúsù Áfíríkà ní 1989. Ọdún 1998 la padà sí ìlú wa, àtìgbà yẹn la sì tún ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Kánádà.
Mo Dúpẹ́ Pé Mo Sin Jèhófà
Nígbà tí mo bá bojú wẹ̀yìn wo ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta tí mo ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo máa ń dúpẹ́ pé mo lo ìgbà èwe mi nínú iṣẹ́ ìsìn ṣíṣeyebíye ti Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ipò líle koko ni Anne ti fara dà, síbẹ̀ kò ráhùn rí, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú mi nínú gbogbo ìgbòkègbodò wa. Àwa méjèèjì ti ní àǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, àwọn bíi mélòó kan lára wọn wà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún báyìí. Nǹkan ayọ̀ ńlá ló mà jẹ́ o, láti rí i tí àwọn kan lára àwọn ọmọ wọn àtàwọn ọmọ-ọmọ wọn pàápàá ń sin Jèhófà, Ọlọ́run wa atóbilọ́lá!
Ó dá mi lójú pé kò sí ohun ti ayé yìí lè fún wa táa lè fi wé àwọn àǹfààní àti ìbùkún tí Jèhófà ti fún wa. Lóòótọ́, a ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò, àmọ́ gbogbo wọ́n ló ti gbé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà ró. Ní ti gidi, Jèhófà ti jẹ́ ilé gogoro tí okun wa ti wá, òun ni ibi ìsádi wa, àti ìrànlọ́wọ́ tí a máa ń rí nígbà ìpọ́njú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ ìwé yìí jáde lákọ̀ọ́kọ́ pàá ní èdè Jámánì, Kreuzzug gegen das Christentum (Ogun Lòdì sí Ìsìn Kristẹni). A wá túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Faransé àti ti Polish, àmọ́, a kò tú u sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
A jọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní 1947; èmi àti Anne lónìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn èèyàn táa bá pàdé ní Zaire nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì