Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Àṣírí Àṣeyọrí?

Kí Ni Àṣírí Àṣeyọrí?

Kí Ni Àṣírí Àṣeyọrí?

ÀWỌN ọ̀dọ́mọkùnrin méjì, tí wọ́n jẹ́ alákíkanjú rọra ń fọgbọ́n ṣe ẹ̀rọ àràmàǹdà kan tí wọ́n fẹ́ lò fún ìwádìí pàtàkì kan. Lójijì ni ẹ̀fúùfù líle kọlu ẹ̀rọ ẹlẹgẹ́ tí wọ́n ti tò jọ yìí, bátẹ́gùn ṣe gbé e nìyẹn, tó ká a róbótó, ló bá bọ́ lulẹ̀ ló fọ́ yángá. Ni ìbànújẹ́ bá dorí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kodò, ni wọ́n bá ń wò duu láìlèfọhùn. Bí gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí wọn ti fọgbọ́n ṣe ṣe wá di àwókù igi àti irin gèlètè nìyẹn.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Orville àti Wilbur Wright ní October ọdún 1900 yẹn kọ́ ni ìṣòro àkọ́kọ́ tí wọ́n ní níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú àtiṣe ẹ̀rọ tó wúwo ju afẹ́fẹ́ lọ, ìyẹn ẹ̀rọ tó lè fò lófuurufú. Wọ́n sì ti lo ọdún bíi mélòó kan lórí rẹ̀, owó tí wọ́n sì ti ná sórí ìwádìí náà kì í ṣe kékeré.

Àmọ́ ṣá o, wọ́n jèrè ìforítì wọn níkẹyìn. Nígbà tó di December 17, 1903, ní Kitty Hawk, Àríwá Carolina, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Wright méjì yìí láǹfààní láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú tó fò fún ìṣẹ́jú àáyá méjìlá, lóòótọ́ èyí kéré jọjọ sí àkókò tí ọkọ̀ òfuurufú fi ń fò ní òde òní, àmọ́ ìyẹn tó láti yí ayé padà títí láé!

Ṣíṣàṣeyọrí nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí a bá dáwọ́ lé sinmi lórí ìforítì tó gba sùúrù. Yálà a fẹ́ kọ́ èdè tuntun ni o, bóyá a fẹ́ kọ́ṣẹ́ ọwọ́ ni o, tàbí ká tiẹ̀ fẹ́ bá ẹni kan dọ́rẹ̀ẹ́ pàápàá, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn nǹkan tó níye lórí ló gba ìsapá gidigidi kọ́wọ́ wa tó lè tẹ̀ wọ́n. Òǹkọ̀wé nì, Charles Templeton sọ pé: “Ìgbà mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ló jẹ́ pé ohun kan tó máa ń mú àṣeyọrí wá ni iṣẹ́ àṣekára.” Leonard Pitts Kékeré tó jẹ́ òǹkọ̀wé ìròyìn sọ pé: “A máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn àbínibí, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì í yé sọ̀rọ̀ nípa oríire, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń gbójú fo ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ dá. Ìyẹn ni iṣẹ́ àṣekára àti ọ̀pọ̀ àṣedànù. Ara ẹ̀ náà sì ni bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní kùtùkùtù kí a sì ṣiṣẹ́ dòru.”

Èyí fìdí ohun tí Bíbélì ti sọ tipẹ́tipẹ́ múlẹ̀ pé: “Ọwọ́ àwọn ẹni aláápọn ni yóò ṣàkóso.” (Òwe 12:24) Jíjẹ́ aláápọn túmọ̀ sí pé kí a ní ìforítì nínú ohun táa bá ń ṣe. Èyí pọndandan bí a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú ohun táa bá dáwọ́ lé. Kí ni ìforítì? Báwo la ṣe lè ní ìforítì nínú lílé góńgó wa bá, inú kí ló sì ti yẹ ká máa ní ìforítì? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí la óò dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò U.S. National Archives