Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa

Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa

Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa

“Èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—HÁBÁKÚKÙ 3:18.

1. Ìran wo ni Dáníẹ́lì rí ṣáájú ìṣubú Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa?

 ÓLÉ lọ́dún mẹ́wàá ṣáájú ìṣubú Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Dáníẹ́lì, wòlíì arúgbó náà rí ìran kan tó mú un gbọ̀n rìrì. Ìran náà sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí ogun àjàkẹ́yìn tí yóò wáyé láàárín àwọn ọ̀tá Jèhófà àti Ọba tó yàn, Jésù Kristi. Kí ni ìṣarasíhùwà Dáníẹ́lì? Ó wí pé: “Okun mi tán, . . . ara mi kú tipiri ní tìtorí ohun tí mo rí.”—Dáníẹ́lì 8:27.

2. Ìjà wo ní Dáníẹ́lì rí nínú ìran, kí sì ni ìṣarasíhùwà rẹ nípa bó ti sún mọ́lé tó?

2 Àwa náà ńkọ́? Áà, àkókò ti lọ tán o! Kí ni ìṣarasíhùwà wa nígbà táa mọ̀ pé ìjà tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran, ìyẹn ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dónì, ti sún mọ́lé gírígírí? Kí ni ìṣarasíhùwà wa nígbà táa rí i pé ìwà ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù ṣí sójútáyé ti wá gbilẹ̀ débi pé, ó di dandan kí ìparun dé sórí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run? Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀lára wa jọ ti Hábákúkù fúnra rẹ̀, bó ṣe ṣàpèjúwe wọn nínú orí kẹta ìwé rẹ̀ tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀.

Hábákúkù Gbàdúrà fún Àánú Ọlọ́run

3. Ta ni Hábákúkù gbàdúrà fún, báwo sì ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe lè nípa lórí wa?

3 Àdúrà ló wà nínú Hábákúkù orí kẹta. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ ìkíní ti sọ, ègè la fi kọ ọ́, ìyẹn ni orin arò tàbí orin ọ̀fọ̀. Wòlíì náà gba àdúrà ọ̀hún bí ẹni pé ara rẹ̀ ló gbà á fún. Ṣùgbọ́n, ní gidi, nítorí orílẹ̀-èdè tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run ni Hábákúkù ṣe ń gbàdúrà. Lóde òní, àdúrà rẹ̀ ní ìtumọ̀ pàtàkì fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Táa bá ní èyí lọ́kàn báa ṣe ń ka Hábákúkù orí kẹta, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ká mọ̀ pé gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná, ṣùgbọ́n, wọ́n tún mú inú wa dùn. Àdúrà Hábákúkù tàbí orin arò tó kọ, fún wa ní ìdí tó múná dóko láti máa kún fún ìdùnnú nínú Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà wa.

4. Èé ṣe tí Hábákúkù fi ń bẹ̀rù, ọ̀nà wo ló sì dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò gbà lo agbára rẹ̀?

4 Gẹ́gẹ́ báa ṣe gbọ́ nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì tó ṣáájú, ipò nǹkan burú bàlùmọ̀ nílẹ̀ Júdà nígbà ayé Hábákúkù. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ní gbà kí nǹkan máa bá a lọ báyìí. Jèhófà yóò gbégbèésẹ̀, bó ti ṣe nígbà àtijọ́. Abájọ tí wòlíì náà fi kígbe lóhùn rara pé: “Jèhófà, mo ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ. Jèhófà mo ti fòyà ìgbòkègbodò rẹ”! Kí ló ní lọ́kàn? ‘Ìròyìn nípa Jèhófà’ ni àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ti ṣe, irú èyí tó ṣe ní Òkun Pupa, nínú aginjù, àti ní Jẹ́ríkò. Hábákúkù mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí dáadáa, wọ́n sì já a láyà, nítorí ó mọ̀ pé Jèhófà yóò tún lo agbára ńlá rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá rẹ̀. Báa ṣe ń rí ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù lónìí, àwa náà mọ̀ pé Jèhófà yóò gbégbèésẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ti ṣe láyé ọjọ́hun. Ìyẹn ha ń mú ká bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni! Síbẹ̀, a ń fi àìṣojo gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí Hábákúkù ti ṣe, ó ní: “Ní àárín àwọn ọdún, mú un wá [sí] ìyè! Ní àárín àwọn ọdún, kí o sọ ọ́ di mímọ̀. Nígbà ṣìbáṣìbo, kí o rántí láti fi àánú hàn.” (Hábákúkù 3:2) Nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, “ní àárín àwọn ọdún,” kí Ọlọ́run jọ̀wọ́ tún padà lo agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Nígbà yẹn, kí Ọlọ́run jọ̀wọ́ rántí láti ṣíjú àánú wo àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀!

Jèhófà Ti Ń Yan Bọ̀!

5. Báwo ni ‘Ọlọ́run ṣe ń bọ̀ láti Témánì,’ kí sì ni èyí fi hàn nípa Amágẹ́dónì?

5 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá gbọ́ àdúrà yìí, pé kó ṣíjú àánú wo wá? A rí èsì rẹ̀ nínú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹta àti ìkẹrin. Lákọ̀ọ́kọ́, wòlíì náà sọ pé: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń bọ̀ láti Témánì, àní Ẹni Mímọ́ láti Òkè Ńlá Páránì.” Nígbà ayé wòlíì Mósè, Témánì àti Páránì wà lójú ọ̀nà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà la aginjù kọjá lọ síhà Kénáánì. Bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó tóbi yìí ti ń bá ìrìn wọn lọ, ńṣe ló dà bí ẹni pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ wà lórí ìrìn, tí kò sì sí ohun tó lè dá a dúró. Kété kí Mósè tó kú, ó wí pé: “Jèhófà-Sínáì ni ó ti wá, Ó sì kọ mànà láti Séírì sára wọn. Ó tàn yanran wá láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Páránì, Àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún [áńgẹ́lì] mímọ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Diutarónómì 33:2) Nígbà tí Jèhófà bá kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Amágẹ́dónì, yóò tún fi irú agbára ńlá rẹ̀ kan náà tí kò ṣeé kò lójú hàn.

6. Yàtọ̀ sí ògo Ọlọ́run, kí làwọn Kristẹni tó ń fòye mọ nǹkan ń rí?

6 Hábákúkù tún sọ pé: “Iyì [Jèhófà] bo ọ̀run; ilẹ̀ ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀. Ní ti ìtànyòò rẹ̀, ó wá dà bí ìmọ́lẹ̀.” Ìran ńlá mà lèyí o! Lóòótọ́, èèyàn ò lè rí Jèhófà Ọlọ́run sójú kó wà láàyè. (Ẹ́kísódù 33:20) Ṣùgbọ́n o, ńṣe lojú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń tàn yanran nígbà tí wọ́n bá ń ronú nípa ọlá ńlá rẹ̀. (Éfésù 1:18) Àwọn Kristẹni tí wọ́n ń fòye mọ nǹkan máa ń rí ohun mìíràn tó tún yàtọ̀ sí ògo Jèhófà. Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrin parí ọ̀rọ̀ náà pé: “Ó ní ìtànṣán méjì tí ń jáde láti ọwọ́ rẹ̀, ibẹ̀ sì ni ibi ìpamọ́ okun rẹ̀ wà.” Bẹ́ẹ̀ ni, a rí i pé Jèhófà ti ṣe tán láti jà, yóò sì lo ọwọ́ ọ̀tún okun àti agbára rẹ̀.

7. Kí ni yíyan tí Ọlọ́run yóò yan gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun yóò yọrí sí fún àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí i?

7 Yíyan tí Ọlọ́run yóò yan bí aṣẹ́gun yóò yọrí sí ìjábá fún àwọn tó ń dìtẹ̀ mọ́ ọn. Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkarùn-ún sọ pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀, ibà amáragbóná fòfò a sì máa jáde lọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀.” Lọ́dún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sún mọ́ ààlà Ilẹ̀ Ìlérí tán, púpọ̀ nínú wọn ṣọ̀tẹ̀, wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà. Nítorí èyí, àjàkálẹ̀ àrùn tí Ọlọ́run rán ṣekú pa àwọn ènìyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ kan. (Númérì 25:1-9) Láìpẹ́ sígbà táa wà yí, nígbà tí Jèhófà bá yan lọ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” bákan náà làwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí i yóò ṣe jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àjàkálẹ̀ àrùn tilẹ̀ lè pa àwọn kan.—Ìṣípayá 16:14, 16.

8. Gẹ́gẹ́ bí Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹfà ti wí, kí ló ń dúró de àwọn ọ̀tá Ọlọ́run?

8 Wàyí o, wá gbọ́ àpèjúwe wíwọnilọ́kàn tí wòlíì náà ṣe nípa itú tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun pa. Nínú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹfà, a kà pé: “Ó [Jèhófà Ọlọ́run] dúró jẹ́ẹ́, kí ó bàa lè gbọn ilẹ̀ ayé jìgìjìgì. Ó wò, ó sì wá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè fò sókè. Àwọn òkè ńlá ayérayé sì wá fọ́ túútúú; àwọn òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tẹrí ba. Àwọn ìrìn àtọjọ́mọ́jọ́ jẹ́ tirẹ̀.” Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà “dúró jẹ́ẹ́,” bí ọ̀gágun tí ń yẹ pápá ogun wò. Ni ìbẹ̀rù bá mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Nígbà tí wọ́n rí ẹni tí wọ́n fẹ́ bá jà, jìnnìjìnnì bò wọ́n, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fò sókè làìlàì, nítorí ṣìbáṣìbo tó bá wọn. Jésù sọ nípa àkókò kan, nígbà tí “gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò.” (Mátíù 24:30) Yóò ti pẹ́ jù kí wọ́n tó mọ̀ pé kò sí ẹnì kankan tó tóó ko Jèhófà lójú. Àwọn ètò tí ènìyàn gbé kalẹ̀—kódà àwọn tó dà bí pé mìmì kan ò lè mì wọ́n bí “àwọn òkè ńlá ayérayé” àti “àwọn òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” pàápàá—yóò wó palẹ̀ bẹẹrẹ. Yóò wá dà bí ‘ìrìn àtọjọ́mọ́jọ́ tí Ọlọ́run rìn,’ bó ṣe ṣe láyé ọjọ́sí.

9, 10. Kí ni Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkeje sí ìkọkànlá rán wa létí rẹ̀?

9 ‘Ìbínú Jèhófà ti wá gbóná’ mọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun ìjà wo ni yóò fi jagun náà? Fetí sílẹ̀ bí wòlíì náà ṣe ṣàpèjúwe wọn, ó wí pé: “Ọrun rẹ di títú síta ní ìhòòhò rẹ̀. Ìbúra tí àwọn ẹ̀yà ṣe ni ohun tí a wí. O tẹ̀ síwájú láti fi àwọn odò pín ilẹ̀ ayé níyà. Àwọn òkè ńlá rí ọ; wọ́n wá wà nínú ìrora mímúná. Ìjì ààrá ti omi kọjá lọ. Ibú omi mú ìró rẹ̀ jáde. Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ibi gíga lókè. Oòrùn—òṣùpá—dúró jẹ́ẹ́, ní ibùjókòó gíga fíofío lọ́hùn-ún. Bí ìmọ́lẹ̀ ni àwọn ọfà rẹ ń lọ ṣáá. Mànàmáná ọ̀kọ̀ rẹ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìtànyòò.”—Hábákúkù 3:7-11.

10 Lọ́jọ́ Jóṣúà, Jèhófà mú kí oòrùn àti òṣùpá dúró jẹ́ẹ́, nígbà tó ń fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tó kọyọyọ. (Jóṣúà 10:12-14) Àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù rán wa létí pé Jèhófà yóò lo agbára kan náà yìí ní Amágẹ́dónì. Lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà fi hàn pé òun lè darí ibú omi ilẹ̀ ayé nígbà tó fi Òkun Pupa pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò run. Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, odò Jọ́dánì tó kún dẹ́múdẹ́mú kò dí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti yan g̣ẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Jóṣúà 3:15-17) Nígbà ayé wòlíì Dèbórà, ọ̀gbàrá òjò gbá àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà, ọ̀tá Ísírẹ́lì lọ. (Onídàájọ́ 5:21) Àwọn ìkún omi kan náà wọ̀nyí, òjò ọlọ́gbàrá, àti ibú omi yóò wà fún Jèhófà láti lò ní Amágẹ́dónì. Ààrá àti mànàmáná pẹ̀lú wà lọ́wọ́ rẹ̀, bí ẹní mú ọ̀kọ̀ àti apó tó kún fún ọfà dání.

11. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá tú agbára ńlá rẹ̀ jáde?

11 Ká sòótọ́, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá tú agbára ńlá rẹ̀ jáde. Ọ̀rọ̀ Hábákúkù fi hàn pé òru yóò di ọ̀sán, ọ̀sán náà yóò sì wá mọ́lẹ̀ ju bí oòrùn ṣe ń mọ́lẹ̀ lọ. Bóyá àpèjúwe táa mí sí nípa Amágẹ́dónì máa ṣẹlẹ̀ ní ti gidi ni o, bóyá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni o, ohun kan dájú, ìyẹn ni pé, Jèhófà ni yóò borí, kò ní jẹ́ kí ọ̀tá kankan sá àsálà.

Ìgbàlà Dájú Fáwọn Èèyàn Ọlọ́run!

12. Kí ni Ọlọ́run yóò ṣe sí àwọn ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wo la ó gbà là?

12 Wòlíì náà ń báa lọ láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń pa àwọn ọ̀tá Rẹ̀ run. Nínú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkejìlá, a kà pé: “Ìdálẹ́bi ni o fi la ilẹ̀ ayé kọjá. Tìbínú-tìbínú ni o fi pa àwọn orílẹ̀-èdè bí ọkà.” Síbẹ̀, Jèhófà kò ní wulẹ̀ máa pani run láìdá ẹnì kankan sí. A ó gba àwọn ènìyàn kan là. Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá sọ pé: “O sì jáde lọ fún ìgbàlà àwọn ènìyàn rẹ, láti gba ẹni àmì òróró rẹ là.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò gba àwọn ẹni àmì òróró, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ là. Nígbà náà, ìparun Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, yóò ti parí pátápátá. Ṣùgbọ́n, lónìí, àwọn orílẹ̀-èdè ń gbìyànjú láti pa ìjọsìn mímọ́ gaara rẹ́. Láìpẹ́, agbo ọmọ ogun ti Gọ́gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yóò kọlu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 38:1–39:13; Ìṣípayá 17:1-5, 16-18) Ǹjẹ́ ìkọlù Sátánì yẹn yóò láṣeyọrí? Rárá o! Ìgbà yìí ni Jèhófà yóò fi tìbínú-tìbínú pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí ọkà, ‘ti yóò fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ìgbà tí a bá fọ́ ọkà sí wẹ́wẹ́ ní ilẹ̀ ìpakà. Ṣùgbọ́n yóò gba àwọn tí ń sìn ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́ là.—Jòhánù 4:24.

13. Báwo ni Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá ṣe máa nímùúṣẹ?

13 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí la fi ṣàpèjúwe bí a ó ṣe pa àwọn olubi run yán-án yán-án: “O [Jèhófà] fọ́ olórí sí wẹ́wẹ́ kúrò ní ilé ẹni burúkú. A tú ìpìlẹ̀ sí borokoto, títí dé ọrùn.” (Hábákúkù 3:13) “Ilé” tí à ń sọ yìí ni ètò burúkú tí agbára Sátánì Èsù mú kó gbèrú. A ó fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́. A ó fọ́ “olórí” tàbí àwọn aṣáájú tí wọ́n lòdì sí Ọlọ́run túútúú. Gbogbo ilé náà la óò wó palẹ̀, títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀. Kò ní sí mọ́. Ìtura náà yóò mà kúkú pọ̀ o!

14-16. Ní ìbámu pẹ̀lú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Jèhófà àti àwọn ọ̀tá wọn?

14 Ní Amágẹ́dónì, ìdàrúdàpọ̀ yóò bá àwọn tó ń gbìyànjú láti pa “àwọn ẹni àmì òróró” Jèhófà run. Ní ìbámu pẹ̀lú Hábákúkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrìnlá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún, wòlíì náà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó ní: “O fi àwọn ọ̀pá tirẹ̀ gún orí àwọn jagunjagun rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbéra bí ìjì líle láti tú mi ká. Ayọ̀ pọ̀rọ́ wọn dà bí ti àwọn tí ó ti pinnu tán láti jẹ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ run ní ibi ìlùmọ́. O fi àwọn ẹṣin rẹ rin òkun já, la òkìtì alagbalúgbú omi.”

15 Nígbà tí Hábákúkù sọ pé “àwọn jagunjagun . . . gbéra bí ìjì líle láti tú mi ká,” wòlíì náà gbẹnu sọ fún àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn dánàdánà tó ba sí ibùba, àwọn orílẹ̀-èdè yóò yọ sí àwọn olùjọsìn Jèhófà lójijì láti pa wọ́n run. Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wọ̀nyí yóò yọ “ayọ̀ pọ̀rọ́,” ọkàn wọn yóò ti balẹ̀ pé àwọn yóò ṣàṣeyọrí. Àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ yóò dà bí aláìlera, bí “àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí agbo ọmọ ogun àwọn tí ń ta ko Ọlọ́run bá kọlù wọ́n, Jèhófà yóò mú kí wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn. Wọn yóò fi ohun ìjà, tàbí “àwọn ọ̀pá” wọn kọlu àwọn jagunjagun wọn.

16 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò pin síbẹ̀ yẹn o. Jèhófà yóò lo agbo ọmọ ogun tẹ̀mí tí agbára wọn ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ láti yanjú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó ṣẹ́kù. Ní lílo “àwọn ẹṣin,” ìyẹn ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ́run tó wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, Jèhófà yóò yan gẹ́gẹ́ bí akọgun gba inú “òkun” àti “òkìtì alagbalúgbú omi” kọjá, ìyẹn ni, ìran ènìyàn tó jẹ́ ọ̀tá, tí wọ́n ń ru gùdù. (Ìṣípayá 19:11-21) Nígbà náà la óò mú àwọn ẹni ibi kúrò ní ilẹ̀ ayé. Ẹ ò rí i pé ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá yìí fakíki!

Ọjọ́ Jèhófà Ń Bọ̀!

17. (a) Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Hábákúkù? (b) Báwo la ṣe lè dà bí Hábákúkù báa ti ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà?

17 A lè ní ìdánilójú pé ọ̀rọ̀ Hábákúkù yóò ṣẹ láìpẹ́. Kò ní pẹ́. Kí ni wàá ṣe sí ohun tóo ti mọ̀ yìí? Rántí pé Ọlọ́run ló mí sí Hábákúkù tó fi kọ̀wé rẹ̀. Jèhófà yóò gbégbèésẹ̀ o, gbẹgẹdẹ á sì gbiná lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ náà. Abájọ tí wòlíì náà fi kọ̀wé pé: “Mo gbọ́, ṣìbáṣìbo sì bá ikùn mi; ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ sí ìró náà; ìjẹrà bẹ̀rẹ̀ sí wọnú egungun mi; ṣìbáṣìbo sì bá mi nínú ipò mi, kí n lè fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de ọjọ́ wàhálà, de gígòkè wá rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, kí ó lè gbé sùnmọ̀mí lọ bá wọn.” (Hábákúkù 3:16) Ṣìbáṣìbo bá Hábákúkù gidigidi—ìyẹn ò sì yani lẹ́nu. Ṣùgbọ́n, ṣé ìgbàgbọ́ rẹ̀ mì? Rára o! Ó múra tán láti dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ ńlá Jèhófà. (2 Pétérù 3:11, 12) Ǹjẹ́ kì í ṣe irú ẹ̀mí yìí ló yẹ ká ní? Dájúdájú òun ni! A ní ìgbàgbọ́ kíkún pé àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù yóò ní ìmúṣẹ. Ṣùgbọ́n títí di ìgbà náà, ẹ jẹ́ ká fi sùúrù dúró dè é.

18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hábákúkù ń retí ìṣòro, irú ẹ̀mí wo ló ní?

18 Ogun sábà máa ń fa ìṣòro, àní fáwọn tó bá ṣẹ́gun lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pàápàá. Ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ lè wà. A lè pàdánù dúkìá. Sànmánì lè lọ́ tín-ín-rín. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ sí wa, kí la máa ṣe? Hábákúkù ní ìwà táa lè fara wé, nítorí ó wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má yọ ìtànná, àjàrà sì lè má mú èso jáde; iṣẹ́ igi ólífì lè yọrí sí ìkùnà ní ti tòótọ́, àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú sì lè má mú oúnjẹ wá ní ti tòótọ́; a lè ya agbo ẹran nípa kúrò nínú ọgbà ẹran ní ti tòótọ́, ọ̀wọ́ ẹran sì lè má sí nínú àwọn gbàgede; Síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Hábákúkù 3:17, 18) Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, Hábákúkù ń retí ìṣòro, kódà ó ń retí ìyàn pàápàá. Síbẹ̀, kò sígbà kan tí kò ní ìdùnnú nínú Jèhófà, ọ̀dọ̀ ẹni tí ìgbàlà rẹ̀ ti wá.

19. Ìṣòro wo ló ń dé bá ọ̀pọ̀ Kristẹni, ṣùgbọ́n ìdánilójú wo la lè ní báa bá fi Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa?

19 Lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tí Jèhófà fẹ́ bá àwọn olubi jà kò tíì dé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wàhálà ńlá bá. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò jẹ́ apá kan ‘àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀’ nínú agbára ìjọba. (Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:10, 11) Ọ̀pọ̀ lára àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ló ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ń pọ́n lójú gidigidi, ìṣòro tó kọjá sísọ ni èyí sì mú kí wọ́n dojú kọ. Ohun tó jọ èyí sì lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni mìíràn lọ́jọ́ iwájú. Kí òpin tó dé, ó ṣeé ṣe kí ‘igi ọ̀pọ̀tọ́ má yọ ìtànná’ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa. Ṣùgbọ́n, a mọ ohun tó fà á, tí nǹkan fi rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì ń fún wa lókun. Yàtọ̀ síyẹn, a ń tì wá lẹ́yìn. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ [ti Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Ìyẹn kì í ṣe ìdánilójú pé a ó gbé ìgbésí ayé onígbẹdẹmukẹ o, ṣùgbọ́n ó mú un dá wa lójú pé báa bá fi Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, òun yóò máa tọ́jú wa.—Sáàmù 37:25.

20. Bí ìṣòro ìgbà díẹ̀ bá tilẹ̀ wà, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

20 Ìṣòro ìgbà díẹ̀ yòówù táa bá dojú kọ, ẹ máà jẹ́ ká sọ ìgbàgbọ́ nù nínú agbára Jèhófà tí ń gbani là. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Áfíríkà, ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, àti ní àwọn ibòmíràn dojú kọ àwọn ìṣòro tó lékenkà, àmọ́, wọ́n ń báa nìṣó láti máa ‘yọ ayọ̀ ńlá nínú Jèhófà.’ Gẹ́gẹ́ bí tiwọn, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwa náà jáwọ́ nínú ṣíṣe ohun kan náà tí wọ́n ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká rántí pé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ní Orísun “ìmí” wa. (Hábákúkù 3:19) Kò ní já wa kulẹ̀ láé. Ó dájú pé Amágẹ́dónì yóò dé, ó sì dájú pé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò tẹ̀ lé e. (2 Pétérù 3:13) Nígbà náà ni “ilẹ̀ ayé yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Hábákúkù 2:14) Títí di àkókò àgbàyanu yẹn, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hábákúkù. Ní gbogbo ìgbà, ẹ jẹ́ ká máa ‘yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà, ká sì máa kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà wa.’

Ṣé O Rántí?

• Báwo ni àdúrà Hábákúkù ṣe lè nípa lórí wa?

• Èé ṣe tí Jèhófà fi ń yan?

• Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù sọ nípa ìgbàlà?

• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká fi dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ǹjẹ́ o mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run yóò fi bá àwọn olubi jà ní Amágẹ́dónì?