Ríran Onírúurú Ènìyàn Lọ́wọ́ Nílẹ̀ Netherlands
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ríran Onírúurú Ènìyàn Lọ́wọ́ Nílẹ̀ Netherlands
ÁBÚRÁHÁMÙ jẹ́ ọkùnrin kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò lẹ́gbẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí a pè é,” Ábúráhámù ṣègbọràn sí ohùn Ọlọ́run, ó sì “jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ.” Lẹ́yìn tí Ábúráhámù kó gbogbo ìdílé rẹ̀, ó “ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí” fún ọgọ́rùn-ún ọdún tó kù fún un nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Hébérù 11:8, 9.
Bákan náà ni lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti tẹ́wọ́ gba ìpèníjà kíkó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn kí wọ́n lè sìn ní ibi tí àìní ti pọ̀. Àwọn mìíràn ti kọ́ èdè mìíràn kí wọ́n lè jẹ́rìí fún àwọn àjèjì tó ń ya wọ orílẹ̀-èdè wọn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti fi hàn, ẹ̀mí tó dára tí wọ́n ní yìí ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” sílẹ̀ ní Netherlands, níbi tó jẹ́ pé mílíọ̀nù kan lára mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn tó ń gbébẹ̀ ló wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn.—1 Kọ́ríńtì 16:9.
◻ Orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ni Bahram, tó fìgbà kan jẹ́ ẹni tí ń dá àwọn tó ń ja ìjà Kung Fu lẹ́kọ̀ọ́, ti wá. Ó gba ẹ̀dà Bíbélì kan àti àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society bíi mélòó kan. Láàárín oṣù kan, Bahram wá mọ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá òun àti ìyàwó rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, àmọ́ ìṣòro kan wá wà níbẹ̀—ẹni tí ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò gbọ́ èdè wọn. Wọ́n rántí pé àpèjúwe làwọn fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, “tọwọ́ tẹsẹ̀” ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀. Nígbà tó yá, ó ṣeé ṣe fún Bahram àti ìyàwó rẹ̀ láti rí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àbínibí wọn, kíá ni wọ́n sì tẹ̀ síwájú lọ́nà tó yá kánkán. Bahram ti di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi báyìí.
◻ Àwọn tọkọtaya ọmọ ilẹ̀ Netherlands, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, lọ bá ọkùnrin ará Indonesia tó dúró síwájú ilé ìtajà ńlá kan. Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tí tọkọtaya náà bá a sọ̀rọ̀ ní èdè tirẹ̀. Wọ́n wá ṣètò bí wọn ó ṣe wá bá a nílé tó ń gbé. Wọ́n wá rí i pé ó ti lé lógún ọdún tó fi gbé ní Rọ́ṣíà, láàárín àkókò yẹn ló sì di oníṣègùn tí ń tọ́jú àwọn obìnrin. Ó ní òun ò gba pé Ọlọ́run wà o, àmọ́ ó sọ pé gbogbo ìgbà tí òun bá ti gbẹ̀bí ọmọ kan lòun máa ń ṣe kàyéfì pé, “Áá àá, ara ènìyàn mà pé o! Ìyanu ńlá ni!” Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó bìkítà nípa ìran ènìyàn. (1 Pétérù 5:6, 7) Ó ti di arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi báyìí, ó sì ń sìn pẹ̀lú ìjọ Indonesia tó wà ní Amsterdam.
◻ Àwùjọ àwọn aṣáájú ọ̀nà kan ti pegedé nínú wíwàásù fún àwọn ènìyàn tó ń sọ onírúurú èdè, tí wọ́n ń gúnlẹ̀ sí Rotterdam, tó jẹ́ ọ̀kan lára èbúté ọkọ̀ òkun tó tóbi jù lọ lágbàáyé. Ìyọrísí ìgbòkègbodò àwùjọ àwọn oníwàásù tí wọ́n jẹ́ onítara wọ̀nyí ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wa ọkọ̀ òkun, títí kan ọ̀gákọ̀ kan, alábòójútó kan, àti ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ nígbà kan rí, ti gba òtítọ́. Àwọn náà ti ń ṣèrànwọ́ láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo ayé báyìí.—Mátíù 24:14.
Bí ó ti rí ní àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Netherlands ti pinnu láti ṣe ipa tiwọn ní kíkéde ìhìn rere àìnípẹ̀kun fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ahọ́n, àti ènìyàn.—Ìṣípayá 14:6.