Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹranko Ọlọ́pọlọ-pípé Lásán Ha Ni Ènìyàn Bí?

Ẹranko Ọlọ́pọlọ-pípé Lásán Ha Ni Ènìyàn Bí?

Ẹranko Ọlọ́pọlọ-pípé Lásán Ha Ni Ènìyàn Bí?

“Ǹjẹ́ ohun táa gbà gbọ́ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ tiẹ̀ ṣe pàtàkì?”

Ìbéèrè tí ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ní Brazil fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìyẹn, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Ẹranko Ọlọ́pọlọ-Pípé Lásán Ha Ni Ènìyàn Bí?” Olùkọ́ rẹ̀ ló pè é pé kó wá bá kíláàsì náà sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè yẹn, lẹ́yìn tí olùkọ́ náà ti gba ẹ̀dà kan lára ìtẹ̀jáde Jí! ti June 22, 1998, tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn.

Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí yìí tẹnu mọ́ bi ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tí wọ́n gbé ka àbá orídámisí ṣe jẹ́ jàǹbá ńlá. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí i pé àbá ẹfolúṣọ̀n ti mú kí àwọn kan máa wo ogun bí ohun kan tó kàn jẹ́ ara ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ kí àwọn ènìyàn lè máa làkàkà láti wà láàyè, tí èyí sì ti ṣèrànwọ́ láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún gbígbé ètò ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ àti ti Násì lárugẹ.

Akẹ́kọ̀ọ́ náà fi hàn pé ohun tí ènìyàn fi yàtọ̀ sí ẹranko gùn jàn-ànrànjan-anran. Ó sọ pé: “èèyàn nìkan ló lè mọyì nǹkan tẹ̀mí. Kìkì àwọn èèyàn ló lè mọ ìtumọ̀ àti ète ìgbésí ayé. Ẹ̀dá ènìyàn nìkan ni ikú máa ń bà nínú jẹ́, àwọn ló máa ń fẹ́ mọ orírun wọn, àwọn ló sì nífẹ̀ẹ́ láti wà láàyè títí láé. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó láti lo àkókò lórí wíwádìí díẹ̀ sí i nípa orírun wa!”

Olùkọ́ náà gbóríyìn fún ọ̀rọ̀ àtàtà náà. Ó sọ pé ohun tó mú kí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí yìí kẹ́sẹ járí ni pé ó máa ń kàwé gan-an. Gbogbo ẹni tó wà nílé ìwé yẹn ló mọ ọmọbìnrin náà sẹ́ni tó máa ń ka àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì bíi Jí! àti Ilé Ìṣọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàníyàn gan-an lórí ipa tí àbá ẹfolúṣọ̀n ń ní lórí ọkàn àti èrò inú àwọn ọ̀dọ́. Nítorí ìdí èyí ni ìjọ tí ọmọbìnrin yìí ń dara pọ̀ mọ́ fi gba àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí níyànjú láti mú ẹ̀dà Jí! tí June 22, 1998, lọ fún àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn nílé ìwé. Nǹkan bí igba ó lé ọgbọ̀n ìwé ìròyìn ni wọ́n pín káàkiri onírúurú ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní ìlú ńlá náà. Olórí Ẹ̀ka Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì ilé ẹ̀kọ́ kan san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Jí!.

Bẹ́ẹ̀ ni, ohun táa gbà gbọ́ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ mà ṣe pàtàkì o! Ọ̀dọ́mọdé yìí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti fi hàn pé níní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá ti mú kí ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ pátápátá.