Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọn Ò Tiẹ̀ Ga, Wọ́n Lọ́kàn Tó Dára

Bí Wọn Ò Tiẹ̀ Ga, Wọ́n Lọ́kàn Tó Dára

Bí Wọn Ò Tiẹ̀ Ga, Wọ́n Lọ́kàn Tó Dára

BÁWO ló ṣe máa rí ná, ká ní o ò ga ju rúlà méjì àtààbọ̀ lọ, ṣùgbọ́n tóo fẹ́ bá àwọn ẹni tóò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run? Laura lè sọ bó ṣe rí fún ọ. Nígbà tó pé ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, gbogbo gíga rẹ̀ ò ju rúlà méjì àtààbọ̀ lọ. Ní Quito, lórílẹ̀-èdè Ecuador lòun àti arábìnrin rẹ̀ María jọ ń gbé, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún nìyẹn, òun náà rọ́jú fi sẹ̀ǹtímítà mẹ́wàá lé ní rúlà méjì àtààbọ̀ ni. Ẹ jẹ́ kí wọn ṣàlàyé ohun tójú wọn ń rí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wọn.

“A máa ń rìn tó ìdajì kìlómítà ká tó débi táa ti máa wọ bọ́ọ̀sì lọ sí ìpínlẹ̀ táa ti ń wàásù àti ibi táa tí ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni. Láti ibi tí bọ́ọ̀sì yẹn máa ń já wa sí la óò tún ti rin ìrìn ìdajì kìlómítà mìíràn ká tó débi táa ó ti wọ bọ́ọ̀sì kejì. Ohun tó tún burú níbẹ̀ ni pé, àwọn ajá rírorò márùn-ún ló wà lọ́nà táa máa ń gbà. A sì bẹ̀rù ajá gan-an ni nítorí pé lójú tiwa, wọ́n tóbi tó ẹṣin. Igi la fi ń lé wọn padà nígbà tọ́ràn bá dójú ẹ̀, a óò wá fi igi yìí pa mọ́ síbì kan lẹ́bàá ọ̀nà ká tó wọnú bọ́ọ̀sì ká lè rígi náà lò nígbà táa bá ń padà lọ sílé.

“Àtiwọnú bọ́ọ̀sì ọ̀hún pàápàá, iṣẹ́ ńlá ló jẹ́ fún wa. A óò dúró sórí òkìtì pàǹtírí tó wà níbi tí bọ́ọ̀sì máa ń dúró kó lè rọrùn fún wa láti wọlé. Àwọn awakọ̀ kan máa ń wakọ̀ wọn dé ibi òkìtì pàǹtírí náà, àmọ́ àwọn mìíràn kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Tọ́ràn bá sì ti rí báyìí, ẹni tó ga jù nínú àwa méjèèjì ni yóò ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó kúrú jù. A ní láti sọdá òpópónà márosẹ̀ ká tó lè dé ibi táa ó ti wọ bọ́ọ̀sì kejì—iṣẹ́ ńlá gidi nìyẹn sì jẹ́ fún àwọn ẹsẹ̀ kúńkú-kúńkú táa ní. Nítorí táa kéré gan-an, ìṣòro ńlá mìíràn ni gbígbé àpò ńlá tí ìwé kún inú rẹ̀ tún jẹ́. Kí ẹrù wa lè fúyẹ́, Bíbélì tó ṣeé tì bọ àpò la máa ń lò, ìwọ̀nba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ la sì máa ń kó lọ́wọ́.

“Láti kékeré làwa méjèèjì ti máa ń tijú. Gbogbo àwọn aládùúgbò wa ló mọ̀ pé ẹ̀rù máa ń bà wá láti bá àwọn ẹni táà mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, inú wọn sì dùn láti rí wa táa ń kan ilẹ̀kùn ilé wọn, wọ́n sì máa ń fetí sọ́rọ̀ wa dáadáa. Àmọ́, láwọn ibi tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ wá, ojú aràrá lásánlàsàn làwọn èèyàn máa fi ń wò wá; nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò kì í sábà ka iṣẹ́ wa sí. Síbẹ̀síbẹ̀, mímọ̀ táa mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló fọkàn wa balẹ̀ táa fi lè máa bá iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà nìṣó. A tún máa ń ní ìgboyà nígbà táa bá ronú lórí ohun tó wà nínú Òwe 3:5, 6.”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Laura àti Màríà fi hàn, níní ìforítì láìka àléébù ara táa lè ní sí ń fi ògo fún Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí a mú ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ẹran ara’ òun, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun kan tó ń pọ́n ọn lójú, kúrò. Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Bẹ́ẹ̀ ni, kò dìgbà táa bá mú àléébù ara wa kúrò ká tó lè sin Ọlọ́run. Ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún táa ní nínú Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo ipòkípò táa bá wà dáadáa. Nítorí pé ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wo ‘ẹ̀gún tó wà nínú ara’ rẹ̀ nìyí, ó ṣeé ṣe fún un láti sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:9, 10) Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.

Lóde òní, Ọlọ́run ń lo àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn fún un pátápátá láti gbé iṣẹ́ ribiribi ṣe. Àwọn bíi mélòó kan lára wọn sì ní àléébù ara láwọn ọ̀nà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn ló ń retí ìwòsàn àtọ̀runwá lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọn ò dúró dìgbà tí Ọlọ́run bá yanjú gbogbo ìṣòro wọn tán kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Ǹjẹ́ o ní àléébù ara èyíkéyìí? Fọkàn balẹ̀! Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ, o lè wà lára àwọn bíi Pọ́ọ̀lù, Laura, àti María. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́ láyé ọjọ́un, a lè wá sọ nípa tiwọn náà pé: “Láti ipò àìlera, a sọ wọ́n di alágbára.”—Hébérù 11:34.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

María

Laura

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

María ń ran Laura lọ́wọ́ láti wọnú bọ́ọ̀sì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

“Àwọn ajá máa ń bà wá lẹ́rù gan-an ni nítorí pé lójú tiwa, wọ́n tóbi tó ẹṣin”

Nísàlẹ̀: Laura àti María àtàwọn tí wọ́n ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì