Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Kọbi Ara Sí Ìkìlọ̀!

Máa Kọbi Ara Sí Ìkìlọ̀!

Máa Kọbi Ara Sí Ìkìlọ̀!

GBÀ-Ù-Ù! Bí Òkè Fugen tó wà ní Japan ṣe dún nìyẹn nígbà tó tú atẹ́gùn àteérú gbígbóná jáde ní June 3, 1991. Ohun tó tú jáde tó gbóná girigiri yìí wá tú dà sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ènìyàn mẹ́tàlélógójì ni kiní ọ̀hún pa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tólúwa kó yọ ni iná jó kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Igbe “omi o, omi o, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa lómi” làwọn kan ń ké. Àwọn panápaná, àtàwọn ọlọ́pàá sa gbogbo ipá wọn láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

LÁTI nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú àkókò yẹn làwọn èèyàn ti ṣàkíyèsí pe ṣóńṣó orí Òkè Fugen ti sán, nípa bẹ́ẹ̀ àwọn aláṣẹ àtàwọn tó ń gbé nítòsí ibẹ̀ tí múra sílẹ̀ de ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Ó ti lé ní ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú àkókò yẹn tí wọ́n ti kìlọ̀ pé káwọn èèyàn kó kúrò lágbègbè yẹn. Bó ṣe ku ọjọ́ kan gẹ́ẹ́ kí òkè náà bú làwọn ọlọ́pàá sọ fún àwọn oníròyìn pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ sí àwọn àgbègbè táa ti ní káwọn ènìyàn kó kúrò náà. Síbẹ̀, ibi eléwu yẹn gan-an làwọn mẹ́tàlélógójì tó kú yẹn wà lọ́sàn-án ọjọ́ burúkú yìí.

Kí ló wá dé tọ́pọ̀ èèyàn tún fi lọ ságbègbè yẹn tàbí tí wọn ò fi kó kúrò níbẹ̀? Àwọn àgbẹ̀ kan tí wọ́n ti fìgbà kan kó kúrò nílé wọn tún padà lọ yẹ àwọn ohun ìní wọn àtoko tí wọ́n fi sílẹ̀ wò. Àwọn mẹ́ta tó jẹ́ onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín gbìyànjú àtisún mọ́ òkè ayọnáyèéfín náà dáadáa, nítorí ìmọ̀ tí wọ́n ti ní nípa rẹ̀, wọ́n fẹ́ rí fìn-ín-ìn ìdí kókò. Àwọn oníròyìn bíi mélòó kan àtàwọn onífọ́tò ta félefèle níbi tí ko yẹ kí wọ́n rìn dé nítorí àtirí kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìyọnáyèéfín náà yóò ṣe rí. Àwọn awakọ̀ mẹ́ta tí àwọn oníròyìn háyà wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn panápaná tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn wà lẹ́nu iṣẹ́. Kò sẹ́ni tó lọ ságbègbè eléwu náà láìnídìí kan pàtó—àbárèbábọ̀ rẹ̀ sì ni pé wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ṣé O Wà Lágbègbè Eléwu?

Ó lè má jẹ́ gbogbo wa ló ń gbé nítòsí òkè ayọnáyèéfín kan tó lè bú gbàù. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ oníláabi kan tí yóò kárí ayé ló ń bọ̀ ńkọ́, tó sì wá fi gbogbo wa táa wà nínú ayé sínú ewu? Ìwé kan tẹ́rìí fi hàn pé ó jẹ́ orísun àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé fọkàn tán kìlọ̀ fún wa nípa ìjábá kan tí yóò ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé, ó sì ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí pé: “Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a ó sì mì. . . . Gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò.” (Mátíù 24:29, 30) Ìṣẹ̀lẹ̀ mériyìírí tí yóò kárí gbogbo àgbáyé la ṣàpèjúwe rẹ̀ níhìn-ín bí èyí tí ó kan “gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé.” Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ oníláabi kan tí yóò kan gbogbo wa pátá.

Ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé fọkàn tán yìí ni Bíbélì. Ó dùn mọ́ni pé, àyíká ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táa mẹ́nu kan lókè yìí ṣàpèjúwe kíkún rẹ́rẹ́ nípa àwọn nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ kí àjálù tí yóò kárí ayé náà tó dé. Gan-an gẹ́gẹ́ bíi sísán àpáta àti àwọn àmì ìyọnáyèéfín mìíràn ṣe ta àwọn aláṣẹ ìlú Shimabara lólobó, tí wọ́n fi dá ibi tó jẹ́ eléwu mọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ní Bíbélì fún wa ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti wà lójúfò kí a sì múra ara wa sílẹ̀ láti lè la ewu tó ń bọ̀ já. A lè kọ́gbọ́n lára àjálù tó wáyé ní Òkè Fugen, ká sì wá fòye mọ̀ pé, gbẹgẹdẹ yóò gbiná láìpẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Yomiuri/Orion Press/Sipa Press

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Yomiuri/Orion Press/Sipa Press