Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mímọ “Èrò Inú Kristi”

Mímọ “Èrò Inú Kristi”

Mímọ “Èrò Inú Kristi”

“‘Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?’ Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú ti Kristi.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 2:16.

1, 2. Kí ni Jèhófà rí i pé ó yẹ ká mọ̀ nípa Jésù nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀?

 BÁWO ni Jésù ṣe rí gan-an? Kí ni àwọ̀ irun rẹ̀? Ṣéèyàn dúdú ni àbí pupa? Irú àwọ̀ wo ni ẹyinjú rẹ̀ ní? Báwo ló ṣe ga tó? Báwo ló ṣe sanra tó? Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, onírúurú àwòrán Jésù làwọn oníṣẹ́-ọnà ti yà, báa ti ń ráwọn tó bójú mu, bẹ́ẹ̀ la tún ń rí àwọn míì tí ò bójú mu rárá. Àwọn kan yà á, ó jọ ọkùnrin tó taagun, tí ara rẹ̀ le, àwọn míì sì yà á, ó wá dà bí ọkùnrin hẹ́gẹhẹ̀gẹ kan, tí àwọ̀ rẹ̀ ti ṣì.

2 Èyí ó wù ó jẹ́, Bíbélì ò sọ nípa ìrísí Jésù. Dípò ìyẹn, Jèhófà rí i pé ohun mìíràn ń bẹ tó ṣe pàtàkì ju sísọ̀rọ̀ nípa ìrísí Jésù, ìyẹn ni mímọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere kò wulẹ̀ ròyìn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nìkan, àmọ́ wọ́n tún jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀, wọ́n sì tún jẹ́ ká mọ irú èrò tó ní, tó fi sọ àwọn ohun tó sọ, tó sì fi hu àwọn ìwà tó hù. Àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí a mí sí wọ̀nyí ràn wá lọ́wọ́ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “èrò inú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 2:16) Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ bí Jésù ṣe ń ronú, ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀, ká sì mọ ìwà rẹ̀. Èé ṣe? Ó kéré tán ìdí méjì wà tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀.

3. Táa bá mọ èrò inú Kristi dáadáa, òye wo la óò ní?

3 Èkíní, èrò inú Kristi ló lè jẹ́ ká mọ èrò inú Jèhófà Ọlọ́run. Jésù mọ Baba rẹ̀ dáadáa débi tó fi lè sọ pé: “Kò . . . sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́ bí kò ṣe Baba; ẹni tí Baba sì jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ, àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Lúùkù 10:22) Ó jọ pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé, ‘Tóo bá fẹ́ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, wá rí mi.’ (Jòhánù 14:9) Látàrí èyí, nígbà táa bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀, láì wulẹ̀ déènà pẹnu, ohun tí à ń kọ́ gan-an ni bí Jèhófà ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára òun náà. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa pẹ́kípẹ́kí.—Jákọ́bù 4:8.

4. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ dà bíi Kristi, kí la gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́, èé sì ti ṣe?

4 Èkejì ni pé, táa bá mọ èrò inú Kristi yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Títẹ̀lé Jésù kò wulẹ̀ túmọ̀ sí pé ká máa tún àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, ká sì máa wo àwọn ìṣe rẹ̀ ṣe. Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé ìrònú àti ìmọ̀lára ló ń darí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, títẹ̀lé Kristi ń béèrè pé ká ní irú “ẹ̀mí ìrònú” kan náà tó ní. (Fílípì 2:5) Lédè mìíràn, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ dà bíi Kristi, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́ bí èrò wa àti ojú ìwòye wa yóò ṣe máa bá ti Jésù mu, ìyẹn túmọ̀ sí pé, a ó ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí débi tí agbára wa bá gbé e dé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn aláìpé. Wàyí o, pẹ̀lú ọlá àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere, ẹ jẹ́ ká wa gbé kúlẹ̀kúlẹ̀ èrò inú Kristi yẹ̀ wò. Ohun tí a ó kọ́kọ́ jíròrò ni àwọn ohun tí ó nípa lórí èrò àti ìmọ̀lára Jésù.

Ìwàláàyè Rẹ̀ Kó Tó Di Ènìyàn

5, 6. (a) Ipa wo ni àwọn tí à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ní lórí wa? (b) Ta ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run ń bá kẹ́gbẹ́ kó tó wá sáyé, ipa wo sì ni ìyẹn ni lórí rẹ̀?

5 Àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa lè nípa lórí wa, wọ́n lè nípa lórí ìrònú wa, lórí ojú ìwòye wa, wọ́n sì lè nípa lórí ìwà wa, yálà sí rere tàbí sí búburú. a (Òwe 13:20) Ronú nípa ẹni tí Jésù ń bá kẹ́gbẹ́ nígbà tó wà lọ́run, kó tó wá sáyé. Ìhìn Rere Jòhánù darí àfiyèsí sí ìwàláàyè Jésù kó tó di ènìyàn, ìyẹn nígbà tó jẹ́ “Ọ̀rọ̀,” tàbí Agbọ̀rọ̀sọ, fún Ọlọ́run. Jòhánù sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan. Ẹni yìí ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:1, 2) Níwọ̀n bí Jèhófà kò ti ní ìbẹ̀rẹ̀, sísọ pé Ọ̀rọ̀ wà pẹ̀lú Ọlọ́run “ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” gbọ́dọ̀ máa tọ́ka sí ìgbà tí Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. (Sáàmù 90:2) Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Nítorí náà, ó ti wà kí á tó dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù àti àgbáálá ayé táa lè fojú rí.—Kólósè 1:15; Ìṣípayá 3:14.

6 Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì kan ti fojú bù ú, àgbáálá ayé wa táa lè fojú rí ti wà báyìí, ó kéré tán, ó ti lé ní bílíọ̀nù méjìlá ọdún. Bí ìfojúbù wọn yẹn bá tiẹ̀ jọ pé ó tọ̀nà, á jẹ́ pé Ọmọ tó jẹ́ àkọ́bí fún Ọlọ́run ti ń gbádùn wíwà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí fún àìmọye ọdún kí á tó dá Ádámù. (Fi wé Míkà 5:2) Nípa báyìí, àjọṣe onífẹ̀ẹ́, tó sì jinlẹ̀ ló wà láàárín àwọn méjèèjì. Gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, a sọ̀rọ̀ àkọ́bí Ọmọ yìí kó tó di ènìyàn pé: “Mo . . . wá jẹ́ ẹni tí [Jèhófà] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Dájúdájú, bíbá Orísun ìfẹ́ rìn tímọ́tímọ́ fún àìníye ọdún ní ipa tó jinlẹ̀ gidigidi lórí Ọmọ Ọlọ́run! (1 Jòhánù 4:8) Ọmọ yìí wá mọ ìrònú, ojú ìwòye àti ọ̀nà Baba rẹ̀ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ó sì tún fi í hàn ju bí ẹnikẹ́ni tí lè ṣe lọ.—Mátíù 11:27.

Ìgbésí Ayé Jésù Lórí Ilẹ̀ Ayé àti Àwọn Ohun Tó Nípa Lórí Rẹ̀

7. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run wá sáyé?

7 Ọmọ Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́, nítorí ète tí Jèhófà ní fún un ni pé, kí Ọmọ rẹ̀ lè di Àlùfáà Àgbà oníyọ̀ọ́nú, ẹni tí yóò lè “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” (Hébérù 4:15) Ọ̀kan lára ìdí tí Ọmọ náà fi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ni pé kó lè kúnjú òṣùwọ̀n yìí. Nígbà tó wà níhìn-ín, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀, Jésù láǹfààní láti wà nínú àwọn ipò tó ti máa ń wò láti ọ̀run tẹ́lẹ̀, ó sì wá mọ bó ṣe ń rí lára. Ìgbà yìí ló tó láǹfààní fúnra rẹ̀ láti mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa ènìyàn àti bó ṣe máa ń nípa lórí wa. Àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀ ẹ́, tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́, tébi sì pa á. (Mátíù 4:2; Jòhánù 4:6, 7) Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún fara da oríṣiríṣi ìnira àti ìjìyà. Ó tipa báyìí “kọ́ ìgbọràn,” ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tóótun dáradára fún iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà.—Hébérù 5:8-10.

8. Kí la mọ̀ nípa kùtùkùtù ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé?

8 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Ìtàn ìgbà ọmọdé rẹ̀ kò gùn rárá. Kódà, Mátíù àti Lúùkù nìkan ló sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táa bí i. Àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere náà mọ̀ pé Jésù ti ń gbé ní ọ̀run kó tó wá sáyé. Ju ohunkóhun mìíràn lọ, ìwàláàyè rẹ̀ kó tó di ènìyàn yìí ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Síbẹ̀síbẹ̀, ènìyàn gidi ni Jésù jẹ́ látòkèdélẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, ó ní láti dàgbà, kó kúrò lọ́mọ ọwọ́, kó dàgbà di ọmọdékùnrin, kó di ọ̀dọ́, kó tó wá di géńdé, gbogbo àkókò yìí sì rèé, ẹ̀kọ́ ló ń kọ́. (Lúùkù 2:51, 52) Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan kan nípa kùtùkùtù ìgbésí ayé Jésù tó jẹ́ pé ó nípa lórí rẹ̀.

9. (a) Ẹ̀rí wo lo fi hàn pé inú ìdílé tálákà la bí Jésù sí? (b) Báwo ni ipò nǹkan ti ṣeé ṣe kí ó rí nínú ilé tí Jésù ti dàgbà?

9 Ó hàn gbangba pé, ìdílé tálákà la bí Jésù sí. Ẹbọ tí Jósẹ́fù àti Màríà wá rú ní tẹ́ńpìlì, ní nǹkan bí ogójì ọjọ́ lẹ́yìn táa bí i jẹ́rìí sí èyí. Dípò tí wọn yóò fi mú ọ̀dọ́ àgbò àti ẹyẹlé kan tàbí oriri kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ, “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” ni wọ́n mú wá. (Lúùkù 2:24) Gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè, àwọn tálákà ni irú ìṣètò ẹbọ yìí wà fún. (Léfítíkù 12:6-8) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìdílé kékeré yìí bẹ̀rẹ̀ sí tóbi. Ó kéré tán, Jósẹ́fù àti Màríà bí ọmọ mẹ́fà lẹ́yìn táa ti bí Jésù lọ́nà ìyanu. (Mátíù 13:55, 56) Èyí fi hàn pé inú ìdílé ńlá ni Jésù dàgbà sí, ó sì jọ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ.

10. Kí ló fi hàn pé Màríà àti Jósẹ́fù jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run?

10 Àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló tọ́ Jésù dàgbà, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀. Èèyàn bí Màríà, ìyá tó bí i lọ́mọ ṣọ̀wọ́n láwùjọ àwọn obìnrin. Rántí pé nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ń kí i, ó wí pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” (Lúùkù 1:28) Jósẹ́fù pàápàá jẹ́ olùfọkànsìn. Lọ́dọọdún, kò lè ṣe kó má rìnrìn àjò aláàádọ́jọ kìlómítà lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ́ ṣayẹyẹ Ìrékọjá. Màríà pẹ̀lú kì í pa á jẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìkì àwọn ọkùnrin la pa á láṣẹ fún láti máa wá síbẹ̀. (Ẹ́kísódù 23:17; Lúùkù 2:41) Nígbà kan, lẹ́yìn tí Jósẹ́fù àti Màríà ti wá Jésù ọmọ ọdún méjìlá tí-tí-tí, wọ́n lọ bá a nínú tẹ́ńpìlì láàárín àwọn olùkọ́. Jésù sọ fún àwọn òbí rẹ̀ tó ti dààmú gidigidi pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” (Lúùkù 2:49) Ọ̀rọ̀ náà, “Baba” ti gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń fi Jésù lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń jẹ́ kó gbà pé ẹnì kan wà níbì kan. Ó dájú pé wọ́n á ti sọ fún un pé Jèhófà ni Baba rẹ̀ gan-an. Ní àfikún sí i, Jósẹ́fù ti ní láti jẹ́ alágbàtọ́ rere fún Jésù. Ó dájú pé Jèhófà kò ní yan òǹrorò ẹ̀dá kan tàbí ìkà ènìyàn láti tọ́ Ọmọ Rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún un dàgbà!

11. Iṣẹ́ wo ni Jésù kọ́, kí ni ṣíṣe irú iṣẹ́ yìí ń béèrè lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì?

11 Nígbà tí Jésù fi wà ní Násárétì, ó kọ́ṣẹ́ káfíńtà, àfàìmọ̀ ni kò fi jẹ́ ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ rẹ̀, Jósẹ́fù, ló ti kọ́ ọ. Jésù mọṣẹ́ ọ̀hún dójú àmì, débi tí wọ́n fi pè é ní “káfíńtà.” (Máàkù 6:3) Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, a máa ń gbéṣẹ́ ilé kíkọ́ fún àwọn káfíńtà, wọ́n máa ń báni kan ohun ọ̀ṣọ́ ilé (títí kan tábìlì, àpótí, àti bẹ́ǹṣì), wọ́n sì máa ń báni kan ohun èlò oko. Justin Martyr, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní, Dialogue With Trypho, èyí tó ṣe ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, kọ̀wé nípa Jésù pé: “Nígbà tó wà láyé, ó fẹ́ràn iṣẹ́ káfíńtà gan-an, ó fẹ́ràn kíkan ohun èlò ìtúlẹ̀ àti àjàgà.” Irú iṣẹ́ yẹn ò rọrùn, nítorí káfíńtà ayé àtijọ́ kò lè rí igi rà lọ́jà. Àfàìmọ̀ ni kò ní jẹ́ pé, ńṣe ni yóò wọnú igbó lọ, tí yóò lọ wá igi tó fẹ́ lò, tí yóò fi àáké gé e lulẹ̀, kó tó wá rù ú wá sílé. Nítorí náà, Jésù mọ bó ti nira tó kéèyàn tó lè ṣiṣẹ́ àṣejẹ, ó mọ bó ti nira tó láti mú àwọn oníbàárà ẹni lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì mọ bó ṣe nira tó láti rówó gbọ́ bùkátà.

12. Kí ló fi hàn pé Jósẹ́fù kú ṣáájú Jésù, kí sì ni èyí béèrè lọ́wọ́ Jésù?

12 Gẹ́gẹ́ bí àrẹ̀mọ, ó ṣeé ṣe kí Jésù ti ṣèrànwọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé náà, pàápàá bó ṣe jọ pé Jósẹ́fù kú ṣáájú Jésù. b Ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ti January 1, 1900 wí pé: “Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi hàn pé Jósẹ́fù kú nígbà tí Jésù ṣì wà lọ́mọdé, ó fi kún un pé bí Jésù ṣe wá gba iṣẹ́ káfíńtà nìyẹn, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé náà. A rí ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ díẹ̀ tó ti èyí lẹ́yìn níbi táa ti pe Jésù fúnra rẹ̀ ní káfíńtà, táa sọ̀rọ̀ nípa màmá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n tí a kò sọ ohunkóhun nípa Jósẹ́fù. (Máàkù 6:3) . . . Látàrí èyí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, gbogbo ọdún méjìdínlógún nínú ìgbésí ayé Olúwa wa, láti ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ [tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Lúùkù 2:41-49] títí di ìgbà tó ṣe batisí, iṣẹ́ aá-jẹ aá-mu ló ń ṣe.” Kò sí àní-àní pé Màríà àti àwọn ọmọ rẹ̀, títí kan Jésù pàápàá, mọ bí ìbànújẹ́ ikú ọkọ àti baba ọ̀wọ́n ṣe lè dorí ẹni kodò.

13. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, èé ṣe tí kò fi sí ènìyàn mìíràn tó tún ní irú ìmọ̀, òye, àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tó ní?

13 Ó ṣe kedere pé a ò bí Jésù sínú ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé mẹ̀kúnnù ló gbé. Nígbà tó wá di ọdún 29 Sànmánì Tiwa, ó tó àkókò fún un láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ táa ti yàn fún un látọ̀run. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún yẹn, ó ṣèrìbọmi, ó si di Ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí. ‘Ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún un,’ èyí tó fi hàn gbangba pé ó lè rántí ìwàláàyè tó ti gbé ní ọ̀run tẹ́lẹ̀ rí, títí kan ìrònú àti ìmọ̀lára tó ní nígbà náà lọ́hùn-ún. (Lúùkù 3:21, 22) Nítorí náà, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀, òye, àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí kò sí ènìyàn mìíràn tó ní irú rẹ̀ rí. Abájọ tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere fi lo ọ̀pọ̀ jù lọ àkókò wọn lórí ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Síbẹ̀síbẹ̀ pàápàá, kò ṣeé ṣe fún wọn láti kọ ohun gbogbo tó sọ, tó sì ṣe. (Jòhánù 21:25) Ṣùgbọ́n ohun táa mí sí wọn láti kọ, ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èrò inú ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí yìí.

Irú Ẹni Tí Jésù Jẹ́

14. Báwo ni àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó lójú àánú àtẹ̀mí ìbánikẹ́dùn?

14 Ìwà tí Jésù ní tó fara hàn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ni pé, ó jẹ́ ẹni kan tó lójú àánú àtẹ̀mí ìbánikẹ́dùn. Ìmọ̀lára tó fi hàn pọ̀ jọjọ: ó káàánú adẹ́tẹ̀ (Máàkù 1:40, 41); ó banú jẹ́ nítorí àwọn tí ọkàn wọn yigbì (Lúùkù 19:41, 42); ó fi ìbínú òdodo hàn sí àwọn oníwọra tó ń pààrọ̀ owó. (Jòhánù 2:13-17) Jésù mà lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò o, ó lè torí ọ̀rọ̀ ẹlòmíì bú sẹ́kún, kì í sì í fi ìmọ̀lára rẹ̀ pa mọ́. Nígbà ti Lásárù, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú, rírí tí Jésù rí Màríà, arábìnrin Lásárù tó ń sunkún, orí òun náà wú, omi bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú rẹ̀, ó sì sunkún níṣojú àwọn ẹlòmíràn.—Jòhánù 11:32-36.

15. Báwo ni ojú àánú tí Jésù ní ṣe hàn gbangba nínú bó ṣe máa ń wo àwọn ẹlòmíràn àti ọ̀nà tó máa ń gbà bá wọn lò?

15 Ohun tó fi ojú àánú tí Jésù ní hàn gbangba ni bó ṣe máa ń wo àwọn ẹlòmíràn àti ọ̀nà tó máa ń gbà bá wọn lò. Ó fà mọ́ àwọn òtòṣì àti àwọn táa fayé ni lára, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ‘wá ìtura fún ọkàn wọn.’ (Mátíù 11:4, 5, 28-30) Ọwọ́ rẹ̀ ò dí jù láti gbọ́ ti àwọn tí ojú ń pọ́n, yálà obìnrin onísun ẹ̀jẹ̀ tó rọra fọwọ́ kan ẹ̀wù rẹ̀ tàbí afọ́jú oníbáárà tí kò gbà kí wọ́n pa òun lẹ́nu mọ́. (Mátíù 9:20-22; Máàkù 10:46-52) Ànímọ́ rere tó wà lára àwọn èèyàn ni Jésù ń wò, ó sì gbóríyìn fún wọn; síbẹ̀, ó tún ṣe tán láti báni wí nígbà tó bá pọndandan. (Mátíù 16:23; Jòhánù 1:47; 8:44) Láyé ìgbà kan tó jẹ́ pé òmìnira táwọn obìnrin ní kò tó nǹkan, Jésù buyì fún wọn, ó sì fọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n. (Jòhánù 4:9, 27) Abájọ táwọn obìnrin kan fi fínnúfíndọ̀ ṣèránṣẹ́ fún un láti inú ohun ìní tiwọn fúnra wọn.—Lúùkù 8:3.

16. Kí ló fi hàn pé Jésù kò wa ilé ayé mọ́yà àti pé ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kò jọ ọ́ lójú?

16 Jésù kò wa ilé ayé mọ́yà rárá. Ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kò jọ ọ́ lójú. Tó bá jẹ́ nípa tara, ó jọ pé, ohun tó ní kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ó sọ pé òun “kò ní ibì kankan láti gbé orí [òun] lé.” (Mátíù 8:20) Lọ́wọ́ kan náà, Jésù máa ń fi kún ayọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nígbà kan tó lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ọ̀kan táwọn èèyàn ti sábà máa ń lùlù, tí wọ́n ti ń kọrin, tí wọ́n á sì máa yọ̀, ó hàn gbangba pé kò wá síbẹ̀ láti wá ba ayẹyẹ náà jẹ́. Àní, ibẹ̀ ni Jésù ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́. Nígbà tí wáìnì tán, ó sọ omi di wáìnì tó dára, ohun mímu kan “tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” (Sáàmù 104:15; Jòhánù 2:1-11) Látàrí èyí, ó ṣeé ṣe fún pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ náà láti máa bá a lọ, kò sì sí àní-àní pé kò jẹ́ kójú ti tọkọtaya náà. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn gbangba, nítorí pé ọ̀pọ̀ ìgbà la tún sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní àṣekára, tó sì ṣe é fún àkókò gígùn.—Jòhánù 4:34.

17. Èé ṣe tí kò fi yani lẹ́nu pé Jésù jẹ́ Àgbà Olùkọ́, kí sì ni àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ fi hàn?

17 Àgbà Olùkọ́ ni Jésù jẹ́. Púpọ̀ lára ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ hàn, ìyẹn làwọn ohun tí òun fúnra rẹ̀ mọ̀ dáadáa. (Mátíù 13:33; Lúùkù 15:8) Ọ̀nà tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kò láfiwé rárá, ó ṣe kedere, ó rọrùn, ó sì ṣeé mú lò. Ohun tó tiẹ̀ tún jọni lójú jù ni ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ fi hàn pé ó fẹ́ kí àwọn olùgbọ́ òun mọ ìrònú, ìmọ̀lára, àti àwọn ọ̀nà Jèhófà.—Jòhánù 17:6-8.

18, 19. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jésù fi ṣàkàwé Baba rẹ̀? (b) Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

18 Lọ́pọ̀ ìgbà tí Jésù bá ń lo àpèjúwe, ó máa ń lo àkàwé tó ṣe kedere nípa Baba rẹ̀, èyí tí a ò ní lè tètè gbàgbé. Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn kàn sọ̀rọ̀ nípa àánú Ọlọ́run. Ọ̀tọ̀ sì ni pé kéèyàn fi Jèhófà wé baba tí ń dárí jini, ẹni tí rírí tó rí ọmọ rẹ̀ tó ń padà bọ̀ wálé mórí rẹ̀ wú tó bẹ́ẹ̀ tó fi ‘sáré, tó sì rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀, tó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.’ (Lúùkù 15:11-24) Nígbà tí Jésù ò tẹ́wọ́ gba àṣà líle yẹn, ìyẹn àṣà tó ń mú káwọn aṣáájú ìsìn fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn gbáàtúù, ó ṣàlàyé pé Baba òun jẹ́ Ọlọ́run tó ṣeé sún mọ́, ẹni tó ṣe tán láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ agbowó òde tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, dípò gbígbọ́ àdúrà ṣekárími tí Farisí onígbèéraga gbà. (Lúùkù 18:9-14) Jésù fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tó bìkítà, ẹni tó mọ ìgbà tí ológoṣẹ́ bíńtín bá já bọ́ sílẹ̀. Jésù wá fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29, 31) Abájọ tí háà fi ṣe àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n rí “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Jésù, òun ló sì fà á tí wọn ò fi fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. (Mátíù 7:28, 29) Kódà, nígbà kan, “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n ń tẹ̀ lé e kiri láìjẹun!—Máàkù 8:1, 2.

19 A mà dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ ká mọ èrò inú Kristi nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ o! Àmọ́, báwo la ṣe lè ní èrò inú Kristi nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Èyí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Ìṣípayá 12:3, 4 fi hàn pé ẹni tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí bá ń bá kẹ́gbẹ́ lè nípa lórí wọn. Ibẹ̀ la ti fi Sátánì hàn gẹ́gẹ́ bí “dírágónì” tó lo agbára rẹ̀ lórí “àwọn ìràwọ̀,” tàbí àwọn ọmọ ẹ̀mí, tó tipa bẹ́ẹ̀ kó wọn sọ̀dí, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ọ̀tẹ̀ tó dì.—Fi wé Jóòbù 38:7.

b Ìgbà táa rí Jésù ọmọ ọdún méjìlá nínú tẹ́ńpìlì la ti sọ̀rọ̀ Jósẹ́fù kẹ́yìn. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jósẹ́fù wá síbi àsè ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà, nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. (Jòhánù 2:1-3) Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù táa kàn mọ́gi sọ fún Jòhánù, àpọ́sítélì rẹ̀ tó fẹ́ràn jọjọ pé, kó máa tọ́jú Màríà. Ká ní Jósẹ́fù ṣì wà láàyè ni, Jésù kò ni sọ bẹ́ẹ̀.—Jòhánù 19:26, 27.

Ṣé O Rántí?

• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ “èrò inú Kristi” dáadáa?

• Ta ni Jésù bá kẹ́gbẹ́ kó tó di ènìyàn?

• Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ipò wo ló bá ara rẹ̀, ipa wo sì ni wọ́n ní lórí rẹ̀?

• Kí ni àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ìwà Jésù?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Inú ìdílé ńlá ni Jésù dàgbà sí, ó sì jọ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Òye àti ìdáhùn Jésù ọmọ ọdún méjìlá ya àwọn olùkọ́ lẹ́nu