Ǹjẹ́ O Ní “Èrò Inú Kristi”?
Ǹjẹ́ O Ní “Èrò Inú Kristi”?
“Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní . . . ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—RÓÒMÙ 15:5.
1. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà yàwòrán Jésù nínú ọ̀pọ̀ àwòrán Kirisẹ́ńdọ̀mù, èé sì ti ṣe tí kò fi tọ́ láti júwe Jésù lọ́nà bẹ́ẹ̀?
“KÒ SẸ́NI tó rí ẹ̀rín lẹ́nu ẹ̀ rí.” Bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe Jésù nìyẹn nínú ìwé kan tí wọ́n parọ́ pé ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ọba Róòmù ló kọ ọ́. Ìwé yìí, tí wọ́n kọ bó ṣe wà láti ọ̀rúndún kọkànlá la gbọ́ pé ó ti nípa púpọ̀ lórí ọ̀pọ̀ oníṣẹ́-ọnà. a Nínú ọ̀pọ̀ àwòrán, ńṣe ni wọ́n ya Jésù tó lejú koko, tó ṣe bí ẹni tí kì í rẹ́rìn-ín. Àmọ́ ìyẹn ò bá irú ẹni tí Jésù jẹ́ mu rárá, ẹni tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó lọ́yàyà, ẹni tó nínúure, àtẹ̀mí ìbánikẹ́dùn.
2. Báwo la ṣe lè mú “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní” dàgbà, kí sì ni èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
2 Ó ṣe kedere pé, báa bá fẹ́ mọ ẹni tó ń jẹ́ Jésù gan-an, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrònú wa àti ọkàn-àyà wa kún fún òye pípéye nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an nígbà tó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ nípa àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere tó fún wa ní òye tó jinlẹ̀ nípa “èrò inú Kristi”—ìyẹn ni pé, ká mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀, ojú ìwòye rẹ̀, èrò rẹ̀, àti ọ̀nà tó gbà ń ronú. (1 Kọ́ríńtì 2:16) Báa ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè mú “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní” dàgbà. (Róòmù 15:5) Nípa báyìí, a ó lè túbọ̀ mọ ọ̀nà tí a óò máa gbà lo ìgbésí ayé wa àti bí a óò ṣe máa bá àwọn ẹlòmíràn lò, kí a lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fún wa.—Jòhánù 13:15.
Ó Ṣeé Sún Mọ́
3, 4. (a) Báwo ni ìtàn táa kọ sínú ìwé Máàkù 10:13-16 ṣe wáyé? (b) Kí ni Jésù ṣe nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ dá àwọn ọmọdé lẹ́kun àtiwá sọ́dọ̀ rẹ̀?
3 Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ẹ́ wà lọ́dọ̀ Jésù. Nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tọmọdé tàgbà, tí wọ́n wá láti inú ipò tó yàtọ̀ síra ló tọ̀ ọ́ wà láìfòyà. Ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn táa kọ sínú Máàkù orí kẹwàá, ẹsẹ ìkẹtàlá sí ìkẹrìndínlógún. Ó ṣẹlẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ parí, ìyẹn nígbà tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù fún ìgbà ìkẹyìn láti lọ kú ikú oró.—Máàkù 10:32-34.
4 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ Jésù, kó lè súre fún wọn, títí kan àwọn ọmọ kékeré. b Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ dá àwọn ọmọdé náà lẹ́kun àtiwá sọ́dọ̀ Jésù. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti rò pé Jésù kò ní fẹ́ kí àwọn ọmọdé yọ òun lẹ́nu rárá nínú ọ̀sẹ̀ mánigbàgbé tó wà yìí. Ṣùgbọ́n èrò wọn kò tọ̀nà. Nígbà tí Jésù rí ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń ṣe, inú rẹ̀ kò dùn sí i. Jésù ní kí àwọn ọmọdé náà máa bọ̀, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” (Máàkù 10:14) Nígbà náà ló wá ṣe ohun kan tó fi hàn pé lóòótọ́ ló jẹ́ ẹni tó bìkítà, tó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó sì gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.” (Máàkù 10:16) Ó hàn gbangba pé bí Jésù ṣe gbé àwọn ọmọdé náà sí apá rẹ̀, ará tù wọ́n pẹ̀sẹ̀ láti wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
5. Kí ni ìtàn tó wà nínú Máàkù 10:13-16 sọ fún wa nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́?
5 Ìtàn kúkúrú yìí sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́. Ṣàkíyèsí pé ó jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti wà ní ipò gíga ní ọ̀run tẹ́lẹ̀, kò dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ àwọn ènìyàn aláìpé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn. (Jòhánù 17:5) Ǹjẹ́ kò yẹ fún àfiyèsí pé ara tu àwọn ọmọdé pàápàá lọ́dọ̀ rẹ̀? Ó dájú pé ká ní ẹnì kan tó máa ń kanra, tó máa ń lejú koko, tí kì í rẹ́rìn-ín, tí ojú rẹ̀ ṣáà máa ń kọ́rẹ́ lọ́wọ́ ni, wọn ò ní sún mọ́ ọn! Tọmọdé tàgbà ló sún mọ́ Jésù nítorí pé wọ́n rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ èèyàn, ó bìkítà, ó sì dá wọn lójú pé kò ní lé wọn dà nù.
6. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè túbọ̀ di ẹni tó ṣeé sún mọ́?
6 Nípa ṣíṣàṣàrò lórí ìtàn yìí, a le bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo ní èrò inú Kristi? Ǹjẹ́ mo ṣeé sún mọ́?’ Ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ṣeé sún mọ́, àwọn ọkùnrin tí wọ́n dà bí “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù,” làwọn àgùntàn Ọlọ́run ń fẹ́. (Aísáyà 32:1, 2; 2 Tímótì 3:1) Ẹ̀yin alàgbà, bẹ́ẹ̀ bá fi ojúlówó ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí àwọn arákùnrin yín, tí ẹ sì ṣe tán láti lo ara yín nítorí tiwọn, wọn yóò mọ̀ pé ẹ ò fọ̀ràn àwọn ṣeré rárá. Wọn yóò rí i lójú yín, wọ́n yóò gbọ́ ọ nínú ohùn yín, wọn yóò sì rí i nínú ìṣe yín. Irú ojúlówó ìfẹ́ àti àníyàn bẹ́ẹ̀ yóò lè mú kí wọ́n lè fọkàn tán yín, yóò sì wá rọrùn fún àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn ọmọdé, láti tọ̀ yín wá. Kristẹni arábìnrin kan ṣàlàyé ìdí tí ó fi lè sọ ìṣòro rẹ̀ fún alàgbà kan, ó ní: “Ó bá mi sọ̀rọ̀ ní pẹ̀lẹ́tù, lọ́nà tó fi ìyọ́nú hàn. Ká ní kò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kò ní gbọ́ kó lẹ́nu mi. Ó fọkàn mi balẹ̀.”
Gbígba Tàwọn Ẹlòmíràn Rò
7. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun gba ti àwọn ẹlòmíràn rò? (b) Èé ṣe tí Jésù fi la ojú ọkùnrin afọ́jú kan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?
7 Jésù jẹ́ agbatẹnirò. Àánú àwọn èèyàn tètè máa ń ṣe é. Rírí tó rí àwọn tí àìsàn ń pọ́n lójú lásán mú kí ó káàánú wọn débi tó fi wo àrùn wọn sàn. (Mátíù 14:14) Ó tún máa ń wo ibi tí agbára àwọn ẹlòmíràn mọ àti ohun tí wọ́n nílò. (Jòhánù 16:12) Nígbà kan, àwọn ènìyàn mú ọkùnrin afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ Jésù pé kó wò ó sàn. Jésù la ojú ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n ó ṣeé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Ó kọ́kọ́ jẹ́ kí ọkùnrin náà rí àwọn ènìyàn fírífírí—“àwọn ohun tí ó jọ igi, ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn káàkiri.” Lẹ́yìn náà ni Jésù wá la ojú rẹ̀ pátápátá. Èé ṣe tó fi wo ọkùnrin náà sàn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé? Èyí lè jẹ́ nítorí pé kí ìmọ́lẹ̀ tó bá bù yẹ̀rì lójijì àti wìtìwìtì ilé ayé yìí má lọ tún dá wàhálà míì sílẹ̀ fún onítọ̀hún tí kò ríran rí láyé ẹ̀.—Máàkù 8:22-26.
8, 9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní kété tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ àgbègbè Dékápólì? (b) Ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe wo ọkùnrin kan tó jẹ́ adití sàn.
8 Tún gbé ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Àjọ Ìrékọjá ọdún 32 Sànmánì Tiwa yẹ̀ wò. Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti wọ àgbègbè Dekapólì, èyí tó wà ní ìlà oòrùn Òkun Gálílì. Ibẹ̀ làwọn èrò rẹpẹtẹ ti rí i, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn tára wọn ò dá àti àwọn amúkùn-ún wá sọ́dọ̀ Jésù, kó lè wò wọ́n sàn. (Mátíù 15:29, 30) Ohun kan rèé tó gbàfiyèsí, Jésù mú ọkùnrin kan láàárín èrò náà, ó sì fún un ní ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀. Òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Máàkù, ẹnì kan ṣoṣo tó ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀.—Máàkù 7:31-35.
9 Adití ni ọkùnrin yìí, agbára káká ló fi lè sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti rí i pé ara ọkùnrin yìí kò balẹ̀ láàárín èrò tó wà yìí tàbí kó ti rí i pé ojú ń tì í. Jésù wá ṣe ohun kan tó ṣàjèjì. Ó mú ọkùnrin náà kúrò láàárín èrò, ó mú un lọ sí ibi kọ́lọ́fín. Jésù wá fara ṣàpèjúwe ohun tó fẹ́ ṣe fún ọkùnrin náà. Ó “fi àwọn ìka rẹ bọ àwọn etí ọkùnrin náà àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.” (Máàkù 7:33) Lẹ́yìn èyí, Jésù gbójú sókè ọ̀run, ó sì gbàdúrà tó kún fún ìmí ẹ̀dùn. Gbogbo ìgbésẹ̀ yìí ń jẹ́ kí ọkùnrin yìí mọ̀ pé, ‘Agbára Ọlọ́run ni mo fẹ́ fi ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ọ yìí.’ Níkẹyìn, Jésù wí pé: “Là.” (Máàkù 7:34) Bí etí ọkùnrin náà ṣe là nìyẹn, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ dáadáa.
10, 11. Báwo la ṣe lè gba ti àwọn ẹlòmíràn rò nínú ìjọ? nínú ilé?
10 Jésù mà lẹ́mìí ìgbatẹnirò o! Ó lójú àánú, ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó ní yìí ló sì sún un láti hùwà lọ́nà tí kò fi mú ọkàn wọn gbọgbẹ́. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó dára táa bá lè mú ẹ̀mí ìrònú Kristi dàgbà, ká sì máa fi irú ẹ̀mí yẹn hàn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (1 Pétérù 3:8) Èyí ń béèrè pé ká sọ̀rọ̀, ká sì hùwà lọ́nà tí yóò fi hàn pé à ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò.
11 Nínú ìjọ, a lè jẹ́ ẹni tó ń gba ti àwọn ẹlòmíràn ró nípa bíbuyì fún wọn, ká máa bá wọn lò báa ṣe fẹ́ káwọn náà máa bá wa lò. (Mátíù 7:12) Ìyẹn yóò kan pé ká máa ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ táa fẹ́ sọ àti ọ̀nà tí a ó gbà sọ ọ́. (Kólósè 4:6) Rántí pé, ‘ọ̀rọ̀ aláìnírònú lè dà bí ìgúnni idà.’ (Òwe 12:18) Nínú ìdílé ńkọ́? Tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú kì í fi ọ̀ràn ara wọn ṣeré rárá. (Éfésù 5:33) Wọ́n máa ń yẹra fún ọ̀rọ̀ aṣa, tàbí ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni ṣáá, tàbí sísọ òkò ọ̀rọ̀ síni—gbogbo èyí ló lè mú kí ọkàn ẹni gbọgbẹ́, tí ọgbẹ́ náà kò sì ní tètè san. Àwọn ọmọ pàápàá máa ń mọ nǹkan lára, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ sì máa ń gba èyí rò. Tí wọ́n bá nílò ìtọ́sọ́nà, irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ yóò ṣe é lọ́nà tí yóò fi hàn pé wọ́n fi ọ̀wọ̀ tó yẹ àwọn ọmọ wọn wọ̀ wọ́n, wọn kò sì ní fẹ́ dójú ti àwọn ọmọ. c (Kólósè 3:21) Nígbà táa bá gba tàwọn ẹlòmíràn rò, ńṣe là ń fi hàn pé a ní èrò inú Kristi.
Fífọkàn Tán Àwọn Ẹlòmíràn
12. Èrò tó ṣe déédéé, tó sì ṣe wẹ́kú wo ni Jésù ní nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
12 Jésù ní èrò tó ṣe déédéé, tó sì ṣe wẹ́kú nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó mọ̀ dájú pé wọn kì í ṣe ẹni pípé. Ó ṣe tán, ó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ènìyàn. (Jòhánù 2:24, 25) Pàápàá jù lọ, kì í ṣe àìpé tó wà lára wọn ló ń wò, bí kò ṣe àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Ó sì tún rí i pé àwọn ọkùnrin tí Jèhófà ti fà wọ̀nyí, èèyàn rere ni wọ́n máa dà. (Jòhánù 6:44) Ẹ̀mí rere tí Jésù ní sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ hàn nínú ọ̀nà tó gbà hùwà sí wọn, tó sì fi bá wọn lò. Ohun kan ni pé, ó fi hàn pé òun ṣe tán láti fọkàn tán wọn.
13. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?
13 Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán wọn? Nígbà tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó gbé iṣẹ́ bàǹtà-banta kan lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró lọ́wọ́. Ó fa iṣẹ́ bíbójútó ire Ìjọba rẹ̀ yíká ayé lé wọn lọ́wọ́. (Mátíù 25:14, 15; Lúùkù 12:42-44) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fi hàn nínú àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá pé òun fọkàn tán wọn. Nígbà tó sọ oúnjẹ di púpọ̀ lọ́nà ìyanu kí ogunlọ́gọ̀ èèyàn lè rí nǹkan jẹ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló gbéṣẹ́ pípín oúnjẹ náà fún.—Mátíù 14:15-21; 15:32-37.
14. Báwo ni wàá ṣe ṣàkópọ̀ ìtàn tó wà nínú Máàkù 4:35-41?
14 Tún gbé ìtàn tó wà nínú Máàkù 4:35-41 yẹ̀ wò. Ní àkókò yìí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ré Òkun Gálílì kọjá. Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn lórí omi, ni Jésù bá fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lẹ́yìn ọkọ̀, ní oorun bá gbé e lọ. Àmọ́, kò pẹ́ púpọ̀ sígbà yẹn, ni “ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá kan bẹ́ sílẹ̀.” Irú ìjì báyìí kì í ṣe tuntun ní ojú Òkun Gálílì. Nítorí pé apá ìsàlẹ̀ ayé ni òkun yìí wà (nǹkan bí igba mítà ló sì fi rẹlẹ̀ sí ìtẹ́jú òkun), atẹ́gùn ibẹ̀ máa ń móoru ju ti àgbègbè tó wà nítòsí ibẹ̀ lọ, èyí sì máa ń fa ìṣòro ojú ọjọ́. Ní àfikún sí èyí, ẹ̀fúùfù líle tún máa ń fẹ́ wá sí Àfonífojì Jọ́dánì láti Òkè Hámónì, èyí tó wà ní ìhà àríwá. Bí ojú ọjọ́ bá parọ́rọ́, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ìjì líle tún lè dé. Ronú nípa èyí ná, kò sí àní-àní pé Jésù mọ̀ pé ìjì sábà máa ń jà lágbègbè yìí, nítorí Gálílì la ti tọ́ ọ dàgbà. Síbẹ̀, ó fara balẹ̀ sùn ní tiẹ̀, nítorí pé ó fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n jáfáfá, apẹja kúkú ni àwọn kan lára wọn.—Mátíù 4:18, 19.
15. Báwo la ṣe lè fara wé bí Jésù ti ṣe múra tán láti fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
15 Ǹjẹ́ a lè fara wé bí Jésù ṣe múra tán láti fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ó máa ń nira fún àwọn kan láti fa iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Wọ́n á ṣáà fẹ́ máa darí gbogbo nǹkan fúnra wọn ni. Wọ́n lè máa ronú pé, ‘Bí mo bá fẹ́ kí nǹkan yọrí sí dáadáa, àfi kí n yáa ṣe é fúnra mi!’ Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ gbogbo nǹkan la fẹ́ máa ṣe fúnra wa, a ò ní pẹ́ gbó, ó sì ṣeé ṣe ká máa fi ìdílé wa sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan. Ìyẹn nìkan kọ́ o, bá ò bá fa àwọn ẹrù iṣẹ́ kan lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, a lè máà jẹ́ kí wọ́n nírìírí, kí wọ́n má sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ì bá dára báa bá lè kọ́ láti máa fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn, ká sì máa fa ẹrù iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Ó yẹ ká lè béèrè lọ́wọ́ ara wa láìṣàbòsí pé, ‘Níbi táa dé yìí, ǹjẹ́ mo ní èrò inú Kristi? Ǹjẹ́ mo máa ń fi tinútinú fa ẹrù iṣẹ́ kan pàtó lé àwọn mìíràn lọ́wọ́, tí mo sì ń fọkàn tán wọn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe?’
Ó Fi Hàn Pé Òun Gbára Lé Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Òun
16, 17. Ní alẹ́ tó kẹ́yìn ìwàláàyè Jésù lórí ilẹ̀ ayé, báwo ni ó ṣe fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé wọn yóò fi òun sílẹ̀?
16 Ọ̀nà pàtàkì mìíràn tún wà tí Jésù gbà fi ẹ̀mí tó dáa hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun gbára lé wọn. Èyí hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ afinilọ́kànbalẹ̀ tó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ní alẹ́ tó kẹ́yìn ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣàkíyèsí ohun tó ṣẹlẹ̀.
17 Ọwọ́ Jésù dí púpọ̀ ní alẹ́ ọjọ́ yìí. Ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní àwòkọ́ṣe kan nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ó wẹ ẹsẹ̀ wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ló dá oúnjẹ alẹ́ Olúwa sílẹ̀, èyí tí wọn yóò máa fi ṣèrántí ikú rẹ̀. Bí wọ́n ti ń parí èyí ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí bára wọn fà á, tí wọ́n ń jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. Ṣé sùúrù Jésù kúkú pọ̀, ìyẹn ni kò fi nà wọ́n ní patiyẹ ọ̀rọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló bá wọn fèròwérò. Ó wá sọ fún wọn nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ó ní: “Gbogbo yín ni a óò mú kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní òru yìí, nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò kọlu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn agbo ni a ó sì tú ká káàkiri.’” (Mátíù 26:31; Sekaráyà 13:7) Ó mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń bá òun jẹ, tí wọ́n ń ba òun mu yóò sá fi òun sílẹ̀ nígbà wàhálà. Síbẹ̀, kò fi wọ́n bú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a bá ti gbé mi dìde, dájúdájú, èmi yóò lọ ṣáájú yín sí Gálílì.” (Mátíù 26:32) Bẹ́ẹ̀ ni, ó mú un dá wọn lójú pé, bí wọ́n tilẹ̀ fi òun sílẹ̀, òun kò ní fi wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí ìṣòro líle koko yìí bá kọjá lọ, òun yóò tún pàdé wọn.
18. Iṣẹ́ bàǹtà-banta wo ni Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ ní Gálílì, báwo sì ni àwọn àpọ́sítélì ṣe ṣiṣẹ́ náà?
18 Jésù mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ní Gálílì, Jésù tó jí dìde fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n ṣe olóòótọ́, àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn ti wá dúró dè é. (Mátíù 28:16, 17; 1 Kọ́ríńtì 15:6) Ibẹ̀ ni Jésù ti fa ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta kan lé wọn lọ́wọ́, ó ní: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ìwé Ìṣe sì fi hàn gbangba pé àwọn àpọ́sítélì ṣe iṣẹ́ yẹn kúnnákúnná. Wọ́n fi tọkàntọkàn mú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere náà ní ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 2:41, 42; 4:33; 5:27-32.
19. Kí ni ìgbésẹ̀ Jésù lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ kọ́ wa nípa èrò inú Kristi?
19 Kí ni ìtàn tó ṣe kedere yìí kọ́ wa nípa èrò inú Kristi? Jésù ti rí àléébù tó wà lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, síbẹ̀ ó “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Pẹ̀lú àléébù wọn yìí, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun gbára lé wọn. Ṣàkíyèsí pé ìgbọ́kànlé tí Jésù ní nínú wọn kì í ṣe àṣìṣe. Ìgbọ́kànlé tó ní nínú wọn àti bó ṣe gbára lé wọn fún wọn lókun láti pinnu nínú ọkàn wọ́n pé, àwọn yóò máa bá iṣẹ́ tó fún àwọn lọ.
20, 21. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí tó dáa hàn sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
20 Báwo la ṣe lè fi èrò inú Kristi hàn lọ́nà yìí? Má ṣe ní èrò òdì nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ. Bóo bá ní èrò òdì sí wọn, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ àti ìwà rẹ yóò fi hàn. (Lúùkù 6:45) Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ fún wa pé, ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Èrò rere ni ìfẹ́ máa ń ní, kì í ní èrò burúkú. Ńṣe ló máa ń gbéni ró, kì í bani jẹ́. Ó máa ń rọrùn fáwọn èèyàn láti fà mọ́ ẹni tó bá fìfẹ́ hàn sí wọn, tó sì ń fún wọn ní ìṣírí ju ẹni tó ń dáyà fò wọ́n. A lè gbé àwọn ẹlòmíràn ró, kí a sì fún wọn níṣìírí nípa fífi hàn pé a gbọ́kàn lé wọn. (1 Tẹsalóníkà 5:11) Bó bá jẹ́ pé bíi ti Kristi, a ní ẹ̀mí tó dáa sí àwọn arákùnrin wa, a ó máa bá wọn lò lọ́nà tó lè gbé wọn ró, a ó sì lè rí ànímọ́ rere tó wà lára wọn.
21 Níní èrò inú Kristi àti fífi í hàn tún jinlẹ̀ ju pé ká kàn máa ṣe àwọn ohun kan tí Jésù ṣe. Gẹ́gẹ́ báa ti mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, báa bá fẹ́ dà bíi Jésù lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́ láti máa wo nǹkan pẹ̀lú ojú tó fi ń wò ó. Àwọn ìwé Ìhìn Rere ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ànímọ́ mìíràn tó ní, ó jẹ́ ká mọ ìrònú rẹ̀ àti ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ tí a yàn fún un, àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò ìwọ̀nyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ìwé náà, ẹni tó ṣe awúrúju yẹn ṣàpèjúwe ìrísí Jésù, títí kan àwọ̀ irun orí rẹ̀, ti irùngbọ̀n rẹ̀, àti tí ẹyinjú rẹ̀. Atúmọ̀ Bíbélì nì, Edgar J. Goodspeed ṣàlàyé pé awúrúju yìí “wáyé nítorí kí àwọn èèyàn baà lè tẹ́wọ́ gba àpèjúwe tí ayàwòrán náà ṣe nípa ìrísí Jésù nínú ìwé rẹ̀.”
b Kò sí àní-àní pé, ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà yàtọ̀ síra. Ọ̀rọ̀ náà táa pè ní “àwọn ọmọ kékeré” níhìn-ín la tún lò fún ọmọbìnrin Jáírù, ọmọ ọdún méjìlá. (Máàkù 5:39, 42; 10:13) Ṣùgbọ́n, nígbà tí Lúùkù ń kọ ìtàn yìí kan náà, ó lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún àwọn ọmọ ọwọ́.—Lúùkù 1:41; 2:12; 18:15.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìwọ Ha Ń Bọlá fún Iyì Wọn Bí? nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1998.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni Jésù ṣe nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbìyànjú láti dá àwọn ọmọdé lẹ́kun àtiwá sọ́dọ̀ọ rẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé òun gba ti àwọn ẹlòmíràn rò?
• Báwo la ṣe lè fara wé bí Jésù ṣe múra tán láti fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
• Báwo la ṣe lè fara wé bí Jésù ṣe gbọ́kàn lé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ara tu àwọn ọmọdé pẹ̀sẹ̀ lọ́dọ̀ Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jésù fi ìyọ́nú bá àwọn ẹlòmíràn lò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìbùkún ni àwọn alàgbà tó ṣeé sún mọ́ jẹ́