Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Párádísè Wo Ni Jésù Ṣèlérí fún Aṣebi Tó Kú Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀?

Párádísè Wo Ni Jésù Ṣèlérí fún Aṣebi Tó Kú Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀?

Párádísè Wo Ni Jésù Ṣèlérí fún Aṣebi Tó Kú Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀?

ÀKỌSÍLẸ̀ Lúùkù fi hàn pé, aṣebi kan tí wọ́n pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù Kristi sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó fi gbèjà Jésù, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé kí Jésù rántí òun nígbà tó ‘bá dé inú ìjọba rẹ̀.’ Èsì tí Jésù fún un ni pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:39-43) Dájúdájú àmì ìdánudúró díẹ̀ tó fara hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní láti sinmi lórí bí olùtumọ̀ ṣe lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sí, nítorí pé a kò lo àmì ìdánudúró kankan nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Gíríìkì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àmì ìdánudúró táa ń lò nínú ọ̀nà tí a ń gbà kọwé lóde òní ni a kò mọ̀ títí fi di nǹkan bí ọ̀rúndún kẹsàn-án Sànmánì Tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùtumọ̀ ló fi àmì ìdánudúró díẹ̀ síwájú ọ̀rọ̀ náà, “lónìí,” tí èyí sì wá jẹ́ káwọn èèyàn rò pé aṣebi náà wọ Párádísè ní ọjọ yẹn gan-an, kò sí ohunkóhun tó ti èyí lẹ́yìn nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yòókù. Jésù fúnra rẹ̀ kú, ó sì wà nínú ibojì títí di ọjọ́ kẹta, a sì jí i dìde gẹ́gẹ́ bi “àkọ́so” nínú àwọn tí a jí dìde. (Ìṣe 10:40; 1 Kọ́ríńtì 15:20; Kólósè 1:18) Ogójì ọjọ́ lẹ́yìn ìyẹn ló gòkè lọ sí ọ̀run.—Jòhánù 20:17; Ìṣe 1:1-3, 9.

Nítorí náà, ẹ̀rí tó wà níbẹ̀ ni pé, lílò tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “lónìí” kì í ṣe láti sọ ọjọ́ tí aṣebi náà wọnú Párádísè bí kò ṣe pé ó ń pe àfiyèsí sí ọjọ́ tó ṣèlérí yẹn fún un àti àkókò náà gan-an tí aṣebi náà fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jésù. Ọjọ́ yìí ni àwọn tó yọrí ọlá jù lọ lára àwọn aṣáájú ìsìn tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn Jésù fúnra rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì dá a lẹ́bi, ẹ̀yìn ìyẹn làwọn aláṣẹ Róòmù wá dájọ́ ikú fún un. Ó wá di ẹni tí wọ́n ń kẹ́gàn tí wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín. Ṣùgbọ́n, ànímọ́ tó gbàfiyèsí gan-an àti ẹ̀mí tó yẹ ká gbóríyìn fún ni aṣebi tó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ yìí fi hàn ní ti pé kò ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èrò ń ṣe, àmọ́, dípò ìyẹn, ńṣe ló ń gbèjà Jésù, tó sì fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ipò Ọba rẹ̀ tó ń bọ̀. Nígbà tí wọ́n ti wá mọ̀ pé kókó tí ọ̀rọ̀ yẹn ń tẹ̀ mọ́ni lọ́kàn ni àkókò tí a ṣe ìlérí yẹn kì í ṣe àkókò tó ní ìmúṣẹ, àwọn ìtumọ̀ mìíràn irú àwọn tó wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí Rotherham àti Lamsa túmọ̀, àwọn ìtumọ̀ tó wà ní èdè Jámánì, tí Reinhardt àti W. Michaelis túmọ̀, títí kan ìtumọ̀ ti èdè Árámáìkì tí Cureton ṣe ní ọrúndún kárùn-ún Sànmánì Tiwa, ló lo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà kan tó jọra pẹ̀lú bó ṣe kà nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a ṣàyọlò rẹ̀ níhìn-ín yìí.

Pẹ̀lú ohun tí a mọ̀ nípa Párádísè tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, ó hàn gbangba pe kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run ti Kristi. Kó tó di pé ọ̀rọ̀ yìí wáyé lọ́jọ́ yẹn la ti nawọ́ wíwọnú Ìjọba ọ̀run sí àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ ṣá o, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n ti ‘dúró tì í gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò rẹ̀,’ aṣebi yìí sì rèé, kò tí ì ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, kíkú tó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù yìí, ìwà arúfin tó hù ló fà á. (Lúùkù 22:28-30; 23:40, 41) Ó ṣe kedere pé aṣebi yìí kò tí ì di ẹni tí a fi omi àti ẹ̀mí “tún bí,” èyí tí Jésù sọ pé ó pọndandan fún ẹnì kan láti ṣe kó tó lè wọ Ìjọba ọ̀run. (Jòhánù 3:3-6) Bẹ́ẹ̀ náà ní aṣebi yìí kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn ‘aṣẹ́gun’ tí Jésù Kristi sọ pé wọn yóò wà pẹ̀lú òun lórí ìtẹ́ lókè ọ̀run, tí wọ́n sì ní ìpín nínú “àjíǹde èkíní.”— Ìṣípayá 3:11, 12, 21; 12:10, 11; 14:1-4; 20:4-6.

Èrò tí àwọn ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ fúnni ni pé, Jésù ń tọ́ka sí àgbègbè kan tó dà bíi párádíse ní Hédíìsì tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àyè kan tàbí ibi kan tí a dìídì ṣe fún àwọn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ohun tí wọ́n sọ ni pé àwọn ráábì ti àwọn Júù tó wà lákókò yẹn kọ́ni pé irú párádísè bẹ́ẹ̀ wà fún àwọn tó ti kú tí wọ́n ń retí àjíǹde. Lórí ẹ̀kọ́ àwọn ráábì yìí ni ìwé atúmọ̀ èdè náà, Dictionary of the Bible, láti ọwọ́ Hasting fi sọ pé: “Bí ẹ̀kọ́ Ráábì ṣe dé ọ̀dọ̀ wa fi onírúurú èrò orí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, táa bá sì wo ọ̀pọ̀ lára wọn, ó ṣòro láti mọ àkókò táa lè sọ pé wọ́n bọ́ sí. . . . Táa bá wo bí ìwé náà ṣe sọ ọ́, ó lè dà bí pé àwọn kan ka Párádíse sí orí ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀, àwọn mìíràn kà á sí apá ibi kan ní Ṣìọ́ọ̀lù, àwọn mìíràn sì wà tí wọ́n gbà pé kì í ṣe ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìsàlẹ̀ ayé, bí kò ṣe ọ̀run . . . Àmọ́ àwọn iyèméjì kan wà lórí apá díẹ̀ lára èyí, ó kéré tán. Ká sòótọ́, inú ẹ̀sìn àwọn Júù la ti wá rí àwọn èrò orí wọ̀nyí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ibi tí wọ́n ti hàn kedere jù lọ, tí àlàyé wọn sì kún rẹ́rẹ́ jù lọ ni inú ẹ̀sìn Àjùmọ̀ṣe ti àwọn Júù ní sànmánì ojú dúdú . . . Àmọ́, a ò wá mọ bó ti ṣe pẹ́ tó. Ó kéré tán, àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Júù tó jẹ́ ògbólógbòó . . . dà bí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ fàyè gba èrò kan tí kò ṣe gúnmọ́ nípa Párádísè. Ó sọ̀rọ̀ nípa Gehinnom kan fún àwọn ẹni ibi, àti Gan Eden kan, tàbí ọgbà Édẹ́nì, fún àwọn olódodo. Ó wá ń kọni lóminú bóyá ó ní ìtumọ̀ tó ju àwọn èrò wọ̀nyí, tó sì fidí Párádísè kan ní Ṣìọ́ọ̀lù múlẹ̀.”—1905, Ìdìpọ̀ Kẹta, ojú ìwé 669, 670.

Kódà ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọ́ni, ó jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu rárá láti gbà gbọ́ pé Jésù lè tan irú èròǹgbà bẹ́ẹ̀ kálẹ̀, látàrí bó ṣe dẹ́bi fún àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Bíbélì mu, èyí tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù gbé kalẹ̀. (Mátíù 15:3-9) Àfàìmọ̀ ni kò fi ní jẹ́ pé párádísè tí Júù arúfin tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ yìí mọ̀ nípa rẹ̀ ni Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí a ṣàlàyé rẹ̀ nínú ìwé àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ìyẹ̀n ni Párádísè ti Édẹ́nì. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, ìlérí tí Jésù ṣe náà ní láti tọ́ka sí mímú irú párádíse orí ilẹ̀ ayé bẹ́ẹ̀ padà wá. Látàrí èyí, ìlérí tó ṣe fún aṣebi náà fún wa ní ìrètí tó dání lójú pé irú àwọn aláìṣòdodo bẹ́ẹ̀ yóò jíǹde, tí wọn ó sì láǹfààní àtigbé nínú Párádísè tí a mú padà wá náà.—Fi wé Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 20:12, 13; 21:1-5; Mátíù 6:10.