Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sá Kúrò Lágbègbè Eléwu!

Sá Kúrò Lágbègbè Eléwu!

Sá Kúrò Lágbègbè Eléwu!

IṢẸ́ àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín ni láti kíyè sí nǹkan, kí wọ́n sì gbé bó ṣe léwu tó yẹ̀ wò kí wọ́n lè ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa òkè tó lè bú lójijì. (Bí Òkè Fugen ti bú gbàù làwọn ọlọ́pàá lé gbogbo èèyàn kúrò níbi eléwu náà.) Bákan náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń kíyè sí àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan,” wọ́n sì ń ta àwọn èèyàn tó kù lólobó ewú tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ níwájú.—Mátíù 24:3.

Nínú orí Bíbélì kan náà tó kìlọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan tó sún mọ́lé, tí yóò kárí ayé, la ti kà nípa àwọn ìgbésẹ̀ tí yóò kọ́kọ́ yọjú ṣáájú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn. . . . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké yóò sì dìde, wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà; àti nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù. . . . A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:7-14.

Kò dìgbà táa bá di ẹni tó ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ìròyìn ká tó mọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ní ìmúṣẹ báyìí. Àtọdún 1914 gan-an la ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mọ̀ ọ́n lára. Ogun àgbáyé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti jà nínú ọ̀rúndún yìí, ogun abẹ́lé ò sì lóǹkà, àwọn ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ládùúgbò náà wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ti ìsìn ń jà ràn-ìn. Àwọn ogun wọ̀nyẹn ti mú kí ọ̀wọ́n oúnjẹ fìyà tó kúrò ní kèrémí jẹ àwọn ènìyàn, ká má tí ì sọ tí ipò òṣì tí àwọn ìjábá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ máa ń kó àwọn ènìyàn sí. Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti bá ìsẹ̀lẹ̀ rín. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ló ti dìde, tí wọ́n láwọn aṣáájú tọ́wọ́ wọn ò mọ́, tí ìtara òdì sì ti fọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn wọn lójú. “Pípọ̀ sí i ìwà àìlófin” ti sọ àwọn ènìyàn di ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́, ọ̀rọ̀ fífi ìfẹ́ hàn sí aládùúgbò ẹni sì ti di nǹkan àtijọ́.

Ó dájú pé iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn iṣẹ́ tó jẹ́ apá mìíràn lára àmì táà ń wí yìí, ti di èyí tí á ń ṣe jákèjádò ayé. Ìwọ tún padà ṣí ẹ̀yìn ìwé yìí ná, kí o sì kíyè sí ọ̀rọ̀ náà “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà” tó wà lára àkọlé rẹ̀. Ilé Ìṣọ́ tí a ń tẹ̀ jáde lédè méjìléláàádóje, tí a sì ti pín ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù méjìlélógún rẹ̀ káàkiri jẹ́ irin iṣẹ́ pàtàkì kan fún àwọn tó ń kéde “ìhìn rere ìjọba yìí” ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé. Iṣẹ́ tí ìhìn rere náà tún ní nínú ni pé Ẹlẹ́dàá àgbáyé náà, Jèhófà Ọlọ́run, ti fìdí Ìjọba ọ̀run múlẹ̀, èyí tí yóò pa ètò àwọn nǹkan búburú run, tí yóò sì mú párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé. Láìsí àní-àní, àmì pé Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ láìpẹ́ tí hàn gbangba báyìí, èyí sì fi hàn pé inú ewu lẹ̀mí àwọn èèyàn inú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí wà.—Fi wé 2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4; Ìṣípayá 6:1-8.

Ọjọ́ Amúnikún-fún-Ẹ̀rù ti Jèhófà

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí àkókò bá tó fún Jèhófà láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ? Gbọ́ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere: “Èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti àwọn ìṣùpọ̀ èéfín adúró-bí-ọwọ̀n. A óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 2:30, 31.

Ọjọ́ yẹn ti sún mọ́lé o, ọjọ́ tó kún fún ẹ̀rù, tí ìparun tí yóò mú wá yóò ju tí ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín tàbí ìsẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí lọ. Wòlíì Sefanáyà sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi. . . . Nípa iná ìtara rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run, nítorí tí yóò mú ìparun pátápátá, ọ̀kan tí ń jáni láyà ní tòótọ́, wá bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.” Bó tilẹ̀ jẹ pé “fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà,” síbẹ̀ ọ̀nà kan wà láti la ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù yẹn já.—Sefanáyà 1:14-18.

Kí a lè mọ ọ̀nà tí a óò gbà, Sefanáyà sọ pé: “Kí ìlànà àgbékalẹ̀ náà tó bí ohunkóhun, kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò, kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó wá sórí yín, ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sefanáyà 2:2, 3) A lè rí ààbò táa bá ‘ń wá Jèhófà, táa ń wá òdodo, táa sì ń wá ọkàn tútù.’ Àwọn wo ló ń wá Jèhófà lónìí?

Ó dájú pé bóo bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “Jèhófà,” ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọkàn rẹ̀ ń lọ nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe. O lè ti gba ìwé ìròyìn yìí lọ́wọ́ ọ̀kan lára wọn. Èèyàn rere, tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìwà àìtọ́ èyíkéyìí ni wọ́n. Wọ́n ń sakun láti fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ ara wọn láṣọ, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú níní ọkàn tútù. (Kólósè 3:8-10) Ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà táa lè fojú rí jákèjádò ilẹ́ ayé, èyí tí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò kọ̀ọ̀kan ń ṣojú fún, ni wọ́n gbà pé ó mú kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, ìwọ náà lè dara pọ̀ mọ́ ‘gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,’ ìyẹn láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé, kí o sì wà ní ibi ìsádi tí wọ́n wà.—1 Pétérù 5:9.

Wá Ibi Ìsádi Nísinsìnyí

Kí wíwá Jèhófà tó lè jẹ́ ibi ìsádi wa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kí nìyẹn ní nínú? Bíbélì dáhùn rẹ̀ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Táa bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ já ara wa gbà lọ́wọ́ àjọṣe èyíkéyìí táa bá ni pẹ̀lú ayé búburú ìsinsìnyí, èyí tó sábà máa ń fara hàn nínú ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń ní sí Ọlọ́run.

Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé-ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími-kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) Àìmọye ènìyàn lónìí ló jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ló ń tì wọ́n—ìyẹn ni àìlèṣàkóso ìfẹ́ tí wọ́n ń ni fún ìbálòpọ̀ takọtabo, fífi ìwọra wá owó, àti ṣíṣi agbára lò. Àmọ́ táa bá fẹ́ wà ní ọ̀dọ̀ Jèhófà, a ní láti ṣẹ́pá irú àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀.— Kólósè 3:5-8.

Ó ṣeé ṣe kí o ti máa ka ìwé ìròyìn yìí látìgbàdégbà, o sì ti lè fara mọ́ bó ṣe ń ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Síbẹ̀ o lè máa lọ́ tìkọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ṣá, ká sọ pé ìjábá kan fẹ́ ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa, ǹjẹ́ a lè sọ pé táa bá sáà ti gbọ́ ìkìlọ̀ nìkan, ọ̀rọ̀ ti bùṣe nìyẹn? Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Òkè Fugen bú gbàù jẹ́ ká mọ̀ pé a ní láti kọbi ara sí ìkìlọ̀. Rántí pé ó kéré tán àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára àwọn oníròyìn àtàwọn tó fẹ́ lọ ya fọ́tò ìbúgbàù náà ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Àní, ibi tí onífọ́tò kan ti fi ìka lé bọ́tìnì tí yóò fi ya fọ́tò lára kámẹ́rà rẹ̀ ló kú sí. Onímọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ayọnáyèéfín kan—tó ti sọ tẹ́lẹ̀ pé, “Tó bá ṣẹlẹ̀ pé n óò kú lọ́jọ́ kan, ó wù mí kó jẹ́ pé ẹ̀bá òkè ayọnáyèéfín kan ni n óò kú sí”—lóòótọ́, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ bó ṣe sọ pé kí ó rí fún òun gẹ́lẹ́. Gbogbo wọn pátá ló fara jin iṣẹ́ wọn àti góńgó tí wọ́n ń lépa. Síbẹ̀, wọ́n fi ẹ̀mí wọn di—èrè ṣíṣàìkọbi ara sí ìkìlọ̀ nìyẹn.

Ọ̀pọ̀ ló gbọ́ ìsọfúnni lónìí pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ètò àwọn nǹkan búburú yìí run, tí wọ́n wá ń wo ìkìlọ̀ náà bóyá òótọ́ ni bóyá kì í ṣòótọ́. Wọ́n lè máa ronú pé, ‘ó lè dé lóòótọ́,’ ‘àmọ́ kì í ṣòní.’ Bó ṣe wù wọ́n ni wọ́n ṣe ń sún ọjọ́ Jèhófà síwájú kí wọ́n lè ráyè ṣe ohun tó dà bíi pé ó ṣe pàtàkì jù lọ lójú tiwọn lákòókò yìí.

Bárúkù ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí pé Bárúkù jẹ́ akọ̀wé fún Jeremáyà, wòlíì ìgbàanì, o fi tìgboyà-tìgboyà kìlọ̀ ìparun tó ń bọ̀ sórí Jerúsálẹ́mù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ ìgbà kan wà tí iṣẹ́ rẹ̀ yìí sú u. Ìgbà yẹn ni Jèhófà wá tún èrò rẹ̀ ṣe pé: “Ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.” Ìbáà jẹ́ ọrọ̀ ni o, bó jẹ́ òkìkí ni tàbí ohun àlùmọ́nì, Bárúkù ò sáà gbọ́dọ̀ ‘wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ̀.’ Ohun kan ṣoṣo ló gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí, ìyẹn ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, yóò gba ‘ọkàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ.’ (Jeremáyà 45:1-5) Bákan náà, kàkà tí a ó fi ‘máa wá àwọn ohun ńláńlá fún ara wa,’ Jèhófà la gbọ́dọ̀ máa wá, èyí tó lè dáàbò bo ẹ̀mí tiwa fúnra wa.

Ní Òkè Fugen, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá àtàwọn panápaná tó yọ̀ǹda ara wọn ló jẹ́ pé ẹnu iṣẹ́ yẹn ni wọ́n wà nígbà tí iná tó ṣẹ́ yọ látinú òkè ayọnáyèéfín náà jó wọn. Wọ́n ń gbìyànjú àtiṣèrànwọ́, kí wọ́n sì dáàbò bo àwọn èèyàn tó wà nínú ewu ni o. Wọ́n dà bí àwọn ọkùnrin àtobìnrin ọlọ́kàn rere tí wọ́n ń fi torí tọrùn ṣe wàhálà kí ayé yìí lè sunwọ̀n sí i. Bó ti wù kí èrò wọn dára tó, “èyí tí a ṣe ní wíwọ́ ni a kò lè mú tọ́.” (Oníwàásù 1:15) Ipò nǹkan ìsinsìnyí ti wọ́ kọjá èyí tí a lè mú tọ́. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà kí ẹnì kan fi ara rẹ̀ ṣe “ọ̀rẹ́ ayé” nípa gbígbìyànjú láti dáàbò bo ètò àgbáyé tí Ọlọ́run ti pinnu láti mú kúrò?

Tóo Bá Ti Sá Kúrò, Má Padà O

Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn sá kúrò nínú ètò nǹkan eléwu yìí, àmọ́, ọ̀tọ̀ pátápátá tún ni pé kí èèyàn dúró sábẹ́ ààbò lọ́dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pétérù 2:17) Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gbàgbé àwọn àgbẹ̀ tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti sá kúrò nítòsí Òkè Fugen, wọ́n tún padà lọ yẹ oko wọn tó wà nítòsí ibẹ̀ wò. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń ṣàníyàn láti padà lọ máa gbé ìgbésí ayé “tó tí mọ́ wọn lára” tí wọ́n ti ń gbé tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ìwọ náà rí i pé ìpinnu wọn láti padà lọ yẹn ò bọ́gbọ́n mu rárá. Bóyá kì í tiẹ̀ ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìyẹn. Wọ́n ti lè sọdá sí àgbègbè eléwu náà, tí wọ́n sì dúró síbẹ̀ fúngbà díẹ̀ láìsí ohunkóhun tó ṣẹlẹ̀. Nígbà tó tún dọjọ́ míì, wọ́n ti lè dúró pẹ́ ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ, síbẹ̀ tí ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀. Ó lè jẹ́ pé kíkúrò níbi ààbò ti wá mọ́ wọn lára, tọ́kàn wọ́n sì ti balẹ̀ pé báwọn tiẹ̀ sọdá ságbègbè eléwu yẹn, kò sí ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tí ìyẹn sì wá fọkàn wọn balẹ̀ pé àwọn lè dúró pẹ́ sí i.

Jésù Kristi tọ́ka sí bí irú ipò kán náà yóò ṣe wáyé nígbà “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Ó sọ pé: “Bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:3, 38, 39.

Ṣàkíyèsí pé Jésù mẹ́nu kan jíjẹ, mímu, àti gbígbéyàwó. Kò sí èyí tó burú lójú Jèhófà nínú gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Kí ló wá burú nígbà náà? Àwọn èèyàn ọjọ́ Nóà “kò fiyè sí i,” wọ́n kàn ń gbé ìgbésí ayé wọn lọ ní rẹbutu ni. Èèyàn ò lè máa gbé ìgbésí ayé “tó ti mọ́ ọn lára” lákòókò pàjáwìrì. Tóo bá ti lè sá kúrò, tàbí tóo ya ara rẹ sọ́tọ̀ kúrò lára ayé tí a ti dá lẹ́bi yìí, o gbọ́dọ̀ gbéjà ko ohunkóhun tó bá fẹ́ mú ọ lẹ́mìí àtipadà lọ jàǹfààní èyíkéyìí tó lè tibẹ̀ jáde. (1 Kọ́ríńtì 7:31) Ó lè ṣeé ṣe kí ìrìn gbéregbère mú ọ kúrò níbi ààbò tẹ̀mí náà kóo sì tún padà wá síbẹ̀ láìfarapa, ẹnikẹ́ni tiẹ̀ lè má kíyè sí i pàápàá. Àmọ́, ìyẹn lè wá ki ọ́ láyà, kó tún mú ọ padà sínú ayé lẹ́ẹ̀kan sí i, kóo wá pẹ́ níbẹ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ. Láìpẹ́ wàá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé: “Òní kọ́ lòpin máa dé.”

Tún ronú nípa àwọn awakọ̀ mẹ́ta tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn níbi tí wọ́n ti ń dúró de àwọn oníròyìn àtàwọn tó ń ya fọ́tò nígbà tí òkè ayọnáyèéfín tú ooru inú rẹ̀ jáde. Àwọn kan lónìí lè máa bá àwọn tó fẹ́ padà sínú ayé rìn. Ohun yòówù kó fa èyí, ó hàn gbangba pé kò tọ́ rárá láti jẹ́ kí nǹkankan tì wá padà sínú àgbègbè eléwu náà.

Gbogbo àwọn tó kàgbákò ìbúgbàù Òkè Fugen ló kúrò níbi ààbò, tí wọ́n bọ́ sí àgbègbè tí ewu wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé òkè náà yóò bú gbàù lọ́jọ́ kan, kò sí ọ̀kan lára wọn tó ronú pé ọjọ́ yẹn ló máa jẹ́. Nítorí pé a ti rí àmì ìparí ètò àwọn nǹkan, ọ̀pọ̀ ló fọkàn sí pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé nígbà kan ṣá, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kó pẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ rò pé ọjọ́ náà kì í “ṣòní” rárá. Ó léwu láti ní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀.

Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” A gbọ́dọ̀ wà lójúfò, “ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,” kí a máa ‘sa gbogbo ipá wa kí òun lè bá wa nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.’ (2 Pétérù 3:10-14) Lẹ́yìn ìparun ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí, ohun tó ń dúró dè wá ni párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba ohunkóhun láyè láti tì wá lọ síbi eléwu o, nítorí ó lè jẹ pé ọjọ́ táa bá sọdá sínú ayé gan-an ni ọjọ́ Jèhófà yóò dé.

Dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà ní ibi ìsádi tí wọ́n wà, kí o sì dúró tì wọ́n.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà ní ibi ìsádi tí wọ́n wà, kí o sì dúró tì wọ́n

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Iwasa/Sipa Press