Àìwalé-ayé-máyà Ló Jẹ́ Kí N Lè sin Jèhófà
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Àìwalé-ayé-máyà Ló Jẹ́ Kí N Lè sin Jèhófà
GẸ́GẸ́ BÍ CLARA GERBER MOYER TI SỌ Ọ́
Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún ni mí, n kò lè rìn dáadáa mọ́, àmọ́, ọpọlọ mi ṣì jí pépé. Mo mà dúpẹ́ o, pé mo láǹfààní láti máa sin Jèhófà látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé! Àìwalé-ayé-máyà rara ti jẹ́ kí ohun iyebíye yìí ṣeé ṣe.
A BÍ mi ní August 18, 1907, ní Alliance, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, nínú àwa ọmọ márùn-ún, èmi làgbà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà tí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ báa ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, gun kẹ̀kẹ́ wá sí oko táa ti ń sin màlúù. Màmá mi, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Laura Gerber, ló bá lẹ́nu ọ̀nà, ó sì béèrè bóyá ó mọ ìdí táa fi fàyè gba ìwà ibi. Ìgbà gbogbo ní ọ̀ràn yìí sì máa ń kọ màmá mi lóminú.
Lẹ́yìn tí òun àti Baba, tí kò sí nílé nígbà yẹn, ti jọ jíròrò rẹ̀, Màmá béèrè fún ìdìpọ̀ mẹ́fà ìwé náà, Studies in the Scriptures. Ó kà á tán pátápátá, òtítọ́ Bíbélì tó ń kọ́ sì ru ìfẹ́ rẹ̀ sókè gan-an. Ó ka Ìdìpọ̀ kẹfà ìwé The New Creation, ó sì lóye dáadáa pé ó ṣe pàtàkì láti ṣe batisí nínú omi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Nígbà tí ò mọ bó ṣe máa rí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ló bá ní kí Dádì ṣèrìbọmi fóun nínú odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ kan tó wà lóko wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́ sákòókò òtútù oṣù March 1916.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Màmá rí ìkéde tó jáde nínú ìwé ìròyìn kan nípa àsọyé tí yóò wáyé ní Gbọ̀ngàn Daughters of Veterans ní Alliance. Àkòrí àsọyé náà ni “Ìwéwèé Ọlọ́run Látọdúnmọ́dún.” Kíá ara rẹ̀ ti wà lọ́nà, nítorí àkòrí àsọyé yẹn náà ni orúkọ Ìdìpọ̀ Kìíní ti ìwé Studies in the Scriptures. La bá so kẹ̀kẹ́ mọ ẹṣin lẹ́yìn, kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí ló sì gbé gbogbo ìdílé wa lọ sí ìpàdé wa àkọ́kọ́. Láti ìgbà yẹn la ti ń ṣèpàdé nílé
àwọn ará nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sunday àti Wednesday. Kété lẹ́yìn náà, aṣojú ìjọ Kristẹni kan wá tún ìrìbọmi ṣe fún Màmá. Dádì, tó jẹ́ pé iṣẹ́ oko kì í jẹ́ kó ráyè fún nǹkan míì, wá nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó sì ṣèrìbọmi ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn.Pípàdé Àwọn Tó Ń Mú Ipò Iwájú
Ní June 10, 1917, J. F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn, ṣèbẹ̀wò sí Alliance láti sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Èé Ṣe Tí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Fi Ń Bára Wọn Jà?” Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí nígbà yẹn, èmi pẹ̀lú àwọn àbúrò mi méjì, Willie àti Charles, la bá àwọn òbí mi lọ. Àwọn tó wá síbẹ̀ pọ̀, wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún. Lẹ́yìn tí Arákùnrin Rutherford parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wá ló ya fọ́tò lẹ́yìn òde Gbọ̀ngàn Colombia, níbi tó ti sọ àsọyé náà. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ní ibì kan náà, A. H. Macmillan sọ àsọyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ìjọba Ọlọ́run Tó Ń Bọ̀.” Àǹfààní ńlá ni ìbẹ̀wò tí àwọn arákùnrin wọ̀nyí ṣe sí ìlú wa jẹ́.
Àwọn Àpéjọpọ̀ Mánigbàgbé Táa Ṣe Nígbà Yẹn Lọ́hùn-ún
Àpéjọpọ̀ táa ṣe ní Atwater lọ́dún 1918, ní Ohio, níbi tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà díẹ̀ sí Alliance, ni àpéjọpọ̀ tí màá kọ́kọ́ lọ. Màmá béèrè lọ́wọ́ aṣojú Society tó wá síbẹ̀ bóyá mo ti dàgbà tó láti ṣèrìbọmi. Lọ́kàn ara mi, mo gbà pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ dáadáa láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, nítorí náà, wọ́n gbà pé kí n ṣèrìbọmi ní ọjọ́ yẹn nínú odò kan tó wà lẹ́bàá oko ńlá kan tí wọ́n gbin ápù sí. Mo pààrọ̀ aṣọ mi nínú àgọ́ kan tí àwọn ará ti pa fún ète yẹn, aṣọ àwọ̀sùn kan tí mo ti ń lò tipẹ́, tó sì nípọn ni mo wọ̀ tí mo fi ṣèrìbọmi.
Ní September 1919, èmi àti àwọn òbí mi wọkọ̀ rélùwéè lọ sí Sandusky, ní Ohio, ní Adágún Erie. Ibẹ̀ la ti wọ ọkọ̀ ojú omi, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́ a ti dé Cedar Point, ibi táa ti fẹ́ ṣe àpéjọpọ̀ wa tí a kò ní gbàgbé láé. Nígbà táa sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ ojú omi, ilé oúnjẹ kékeré kan wà lẹ́bàá èbúté náà. Mo ra ẹran lílọ̀ níbẹ̀, èyí tí mo kà sóúnjẹ olówó nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Wò ó, àjẹpọ́nnulá ni! Góńgó iye àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ táa fi ọjọ́ mẹ́jọ ṣe náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje. Nítorí tí kò sí ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn, mo yáa tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ , kí n bàa lè máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ dáradára.
Àpéjọpọ̀ yìí la ti mú ìwé ìròyìn tí yóò ṣèkejì Ilé Ìṣọ́ jáde, èyí táa pè ní The Golden Age (táa ń pè ní Jí! nísinsìnyí). Láti lè wà ní àpéjọpọ̀ yẹn, mo pa ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ, ṣùgbọ́n, ó tó bẹ́ẹ̀, ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Cedar Point jẹ́ ibi tó dáa, tó ṣeé gbafẹ́ lọ, wọ́n ní àwọn ọlọ́wọ́-ṣíbí níbẹ̀, tí wọ́n ń se oúnjẹ fáwọn tó wá sí àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, fún àwọn ìdí kan, àwọn ọlọ́wọ́-ṣíbí àti àwọn agbáwo daṣẹ́ sílẹ̀, ni àwọn ará, àwọn Kristẹni, táwọn náà ò kẹ̀rẹ̀ nínú oúnjẹ sísè bá múṣẹ́ ṣe, ní wọ́n bá ń se oúnjẹ fáwọn tó wá ṣèpàdé. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn Jèhófà ló máa ń fúnra wọn gbọ́únjẹ ní àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wọn.
A tún láǹfààní láti padà sí Cedar Point ní September 1922 fún àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́sàn-án, iye àwọn tó sì wá lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún. Ibẹ̀ ni Arákùnrin Rutherford ti rọ̀ wá pe “ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi pẹ̀lú pípín ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé ìròyìn The Golden Age ní àwọn ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn.
Mímọrírì Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 1918, mo bá wọn lọ́wọ́ nínú pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, The Fall of Babylon, fún àwọn tó wà ní oko ìtòsí wa. Nítorí ọ̀rinrin, a óò gbé òkúta ìgbosẹ̀ sórí ààrò nílé, a óò wá fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé e lọ́ sóko, ká lè máa fi mọ́ ẹsẹ̀ wa lọ́hùn-ún, kí òtútù lè dín kù. A ó wọ ẹ̀wù kóòtù àwọ̀kanlẹ̀, a óò tún dé ate, nítorí pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin kò ní ohun tó lè mú inú rẹ̀ móoru, àmọ́, ó nílé lórí, ó sì ní kọ́tìnì lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Ṣùgbọ́n, àwọn àkókò yẹn jẹ́ àkókò aláyọ̀.
Ní 1920, a ṣe àkànṣe ìwé The Finished Mystery, táa pè ní ZG, ó rí bí ìwé ìròyìn. a Èmi àti àwọn òbí mi jọ pín ìwé yìí fáwọn èèyàn ní Alliance ni. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ńṣe ni olúkúlùkù máa ń dá lọ sí ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, nítorí náà, ìbẹ̀rù ni mo fi lọ sí abẹ́ àtẹ́rígbà ilé kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn jókòó sí. Lẹ́yìn tí mo ti sọ̀rọ̀ mi tán, obìnrin kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mà dára o,” ló bá gba ìwé náà. Ìwé ZG mẹ́tàlá ni mo fi síta lọ́jọ́ yẹn, ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tí màá sọ̀rọ̀ fún ìgbà pípẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé.
Nígbà tí mo tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àrùn òtútù àyà kọ lu Màmá, ó sì lé lóṣù kan tí Màmá ò fi lè dìde. Àbúrò mi obìnrin tó kéré jù lọ, Hazel, ṣì jẹ́ ọmọdé nígbà yẹn, nítorí náà mo fi ilé ìwé sílẹ̀ láti lọ bá wọn ṣiṣẹ́ oko, kí n sì lè tọ́jú àwọn àbúrò mi. Síbẹ̀, ìdílé wa fọwọ́ dan-in dan-in mu òtítọ́ Bíbélì, a kì í sì í pa ìpàdé ìjọ jẹ.
Ní 1928, nígbà Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀ la fún ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Where Are the Nine?” Ó jíròrò ìwé Lúùkù 17:11-19, níbi tí Bíbélì ti sọ pé adẹ́tẹ̀ kan ṣoṣo nínú adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá ló wá fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù fún bó ṣe wò wọ́n sàn lọ́nà ìyanu. Ìyẹn wọ̀ mí lọ́kàn gidigidi. Mo béèrè lọ́wọ́ ara mi pé, ‘Bawo ni mo ṣe moore tó?’
Níwọ̀n ìgbà tí nǹkan ti wá ń lọ geere nínú ilé báyìí, tí ara mí le, tí n kò sì ní ẹrù iṣẹ́ kankan tó dè mí mọ́lẹ̀, mo pinnu láti filé sílẹ̀, kí n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn òbí mi gbà mí níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, èmi àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi, Agnes Aleta, gba lẹ́tà ibi táa yàn wá sí, nígbà tó sì di August 28, 1928, a wọ rélùwéè ní déédéé aago mẹ́sàn-án alẹ́. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kò ní ju àpò ìkẹ́rù kan àti báàgì kékeré kan tí a lè fi kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà táa dé ibùdókọ̀, àwọn arábìnrin mi àti àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, làwa náà bá bú sẹ́kún. Mo rò pé a ò ní ríra mọ́, níwọ̀n bí a ti gbà gbọ́ pé Amágẹ́dọ́nì kò ní pẹ́ dé mọ́. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí ibi táa rán wa lọ ní Brooksville, Kentucky.
A gba yàrá kékeré kan nínú ilé ìbùwọ̀ kan, a sì ra oúnjẹ alágolo, a tún fúnra wa ṣe ìpápánu tiwa. Lójoojúmọ́ la máa ń ṣiṣẹ́ ní ibi tó yàtọ̀ síra, ṣe la sì máa ń dá ṣiṣẹ́, tí a sì ń fi ìwé ńlá márùn-ún lọ àwọn onílé pẹ̀lú ọrẹ tó dín díẹ̀ ní dọ́là méjì owó Amẹ́ríkà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a kárí ìlú náà, a sì pàdé àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Bíbélì.
Nígbà tó fi máa tó oṣù mẹ́ta, kò sílé táà tíì dé lágbègbè Brooksville àti Augusta. Nítorí náà, a lọ ṣiṣẹ́ nílùú Maysville, Paris, àti Richmond. Ní ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, a kárí ọ̀pọ̀ ìgbèríko tó wà ní Kentucky tí kò sí ìjọ níbẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí tí wọ́n ń wakọ̀ wá láti Ohio sábà máa ń wá ràn wá lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn Àpéjọpọ̀ Mìíràn Tí Kò Ṣeé Gbàgbé
Ẹ wò ó, àpéjọpọ̀ táa ṣe ní Colombus, Ohio, ní July 24-30, 1931, kò ṣeé gbàgbé rárá. Ibẹ̀ la ti kéde pé orúkọ náà táa fà yọ látinú Bíbélì, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, la ó fi máa pè wá. (Aísáyà 43:12) Ṣáájú ìgbà yẹn, táwọn èèyàn bá bi wá pé ẹ̀sìn wo ni tiwa, a óò dáhùn pé, “Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé.” Ṣùgbọ́n ìyẹn ò fi wá hàn yàtọ̀ dáadáa, níwọ̀n bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti pọ̀ lọ jàra nínú onírúurú ẹ̀sìn yòókù.
Agnes, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi ṣègbéyàwó, ó wá ku èmi nìkan; nítorí náà, inú mi dùn nígbà tí wọ́n kéde rẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń fẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí wọn yóò jọ máa ṣiṣẹ́ lè wá sí ibì kan. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Bertha àti Elsie Garty àti Bessie Ensminger. Wọ́n ní mọ́tò méjì, wọ́n sì ń wá ẹni tí yóò ṣìkẹrin wọn. A jọ kúrò ní àpéjọpọ̀ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò pàdé rí.
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn a ṣiṣẹ́ jákèjádò ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Nígbà yẹn, bí ìgbà ọ̀gìn-nìtìn ti ń sún mọ́lé, a béèrè fún ibi táa ti lè máa wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ tó móoru tó wà ní ìhà gúúsù ti Àríwá Carolina, Virginia, àti Maryland. Ní ìgbà ìrúwé, a padà sí àríwá. Báwọn aṣáájú ọ̀nà ti máa ń ṣe nìyẹn nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ní 1934, John Booth àti Rudolph Abbuhl, tí wọ́n tẹ̀ lé àṣà yìí, mú Ralph Moyer àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, Willard, lọ́wọ́ lọ sí Hazard, ní Kentucky.
Mo ti pàdé Ralph lọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ìgbà àpéjọpọ̀ ńlá táa ṣe ní Washington, D.C., ní May 30 sí June 3, 1935, la túbọ̀ láǹfààní láti mọ́ra wa dáadáa. Èmi àti Ralph jókòó papọ̀ níbi ọ̀dẹ̀dẹ̀ nígbà tí àsọyé náà tó dá lórí “àwọn Ìṣípayá 7:9-14) Títí di àkókò yìí, a gbà gbọ́ pé àwọn ògìdìgbó náà jẹ́ ẹgbẹ́ kejì nínú àwọn tó ń lọ sí ọ̀run, àwọn tí ìgbàgbọ́ tiwọn kò tó ti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Ìṣípayá 14:1-3) Nítorí náà, mi ò fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára wọn!
ògìdìgbó,” tàbí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ń lọ lọ́wọ́. (Nígbà tí Arákùnrin Rutherford wá ṣàlàyé pé àwọn ògìdìgbó wọ̀nyẹn jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn olóòótọ́ tí yóò la Amágẹ́dọ́nì já, tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn. Lẹ́yìn náà, ó ké sí gbogbo àwọn ògìdìgbó náà láti dìde dúró. Mi ò dìde, àmọ́ Ralph dìde ni tiẹ̀. Lẹ́yìn èyí, nǹkan wá túbọ̀ yé mi sí i, nítorí náà, ọdún 1935 ni mo báwọn jẹ àkàrà àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ gbẹ̀yìn níbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Ṣùgbọ́n, Màmá jẹ ẹ́ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní November 1957.
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Títí Ayé
Èmi àti Ralph máa ń kọ lẹ́tà síra. Mò ń sìn ní Adágún Placid, New York, nígbà tí òun ń sìn ní Pennsylvania. Ní 1936 ó kọ́ ilé kékeré kan tó ṣeé gbé sẹ́yìn ọkọ̀ rẹ̀. Ó gbé e láti Pottstown, Pennyslvania, lọ sí Newark, New Jersey, nítorí àpéjọpọ̀ tí wọ́n ṣe níbẹ̀ ní October 16 sí 18. Lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ọ̀pọ̀ nínú àwa táa jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, lọ kí Ralph nínú ọkọ̀ àfiṣelé rẹ̀. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ jọ dúró sínú ọkọ̀ àfiṣelé náà, lẹ́bàá ibi ìfabọ́, ló bá béèrè pé, “Ǹjẹ́ ọkọ̀ àfiṣelé yìí wù ẹ́?”
Nígbà tí mo forí dáhùn pé ó wù mí, ó tún béèrè pé, “Ṣé ó wù ẹ́ láti máa gbénú ẹ̀?”
Mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni,” ló bá fẹnu kò mí lẹ́nu lọ́nà tí n kò lè gbàgbé láé. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, a gba ìwé àṣẹ ìgbéyàwó. Ní October 19, ọjọ́ kejì tí àpéjọpọ̀ parí, a lọ sí Brooklyn, a lọ wo ilé ìtẹ̀wé Watch Tower Society. Ibẹ̀ la ti béèrè fún àgbègbè táa ti lè máa wàásù. Grant Suiter ló ń bójú tó ìpínlẹ̀ náà nígbà yẹn, ó sì béèrè pé ta ló fẹ́ máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ralph sọ pé: “Àwa méjèèjì ni, táa bá lè ṣègbéyàwó.”
Arákùnrin Suiter fèsì pé: “Bẹ́ẹ bá padà wá ní aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́, a ó ṣètò ẹ̀.” Nítorí náà, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn a ṣègbéyàwó ní ilé Ẹlẹ́rìí kan ní Brooklyn Heights. A bá àwọn ọ̀rẹ́ wa kan jẹun ní ilé àrójẹ kan tó wà ládùúgbò náà, lẹ́yìn ìyẹn la wọkọ̀ lọ sí ibi tí ọkọ̀ àfiṣelé Ralph wà ní Newark, New Jersey.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn táa fi mú ọ̀nà Heathsville pọ̀n, ìyẹn ni Virginia, ibi táa kọ́kọ́ yàn fún wa láti lọ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà. A ṣiṣẹ́ ní Ìgbèríko Northumberland, lẹ́yìn náà, a ṣí lọ sí àwọn ìgbèríko tó wà ní Fulton àti Franklin ní Pennsylvania. Ní 1939, wọ́n pe Ralph láti wá ṣiṣẹ́ alábòójútó àgbájọ ìpínlẹ̀, iṣẹ́ kan tó ń béèrè pé a ó máa bẹ ọ̀pọ̀ ìjọ wo ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. A bẹ àwọn ìjọ tó wà ní ìpínlẹ̀ Tennessee wò. Ní ọdún kejì, a bí Allen, ọmọkùnrin wa, nígbà tó sì di ọdún 1941, iṣẹ́ alábòójútó àgbájọ ìpínlẹ̀ gbélẹ̀. Ní wọ́n bá rán wa lọ sí Marion, Virginia, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Láyé ọjọ́un, ìyẹn túmọ̀ sí lílo igba wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lóṣooṣù.
Mímú Ara Mi Bá Ipò Tó Yí Padà Mu
Lọ́dún 1943, mo rí i pé ó pọndandan kí n fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe sílẹ̀. Gbígbé nínú ọkọ̀ àfiṣelé tí kò tóbi, títọ́jú ọmọ kékeré, gbígbọ́únjẹ, rírí i pé aṣọ gbogbo wa wà ní mímọ́ àti lílo nǹkan bí ọgọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù ni gbogbo èyí tí mo lè ṣe. Ṣùgbọ́n Ralph ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe.
A kó padà sí Alliance, Ohio, ní 1945, a ta ọkọ̀ àfiṣelé wa, táa ti lò fún ọdún mẹ́sàn-án, a sì kó lọ sí ilé tó wà ní oko wa lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Níbẹ̀, ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ iwájú ilé, la bí ọmọbìnrin wa, Rebekah, sí. Ralph lọ ṣiṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ ní ìgboro, ó sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ. Èmi ń ṣiṣẹ́ lóko, mo sì ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé mi fún wa ní ilẹ́ àti ilé lọ́fẹ̀ẹ́, Ralph kọ̀ ọ́. Kò fẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ lílépa ire Ìjọba náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
Ní 1950, a ṣí lọ sí Pottstown, Pennsylvania, a sì gba ilé kan níbẹ̀, táa ti ń san dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lóṣù. Ní ọgbọ̀n ọdún tó tẹ̀ lé e, owó ilé náà ò kọjá dọ́là márùndínlọ́gọ́rin lóṣù kan. Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti má walé ayé máyà. (Mátíù 6:31-33) Ọjọ́ mẹ́ta láàárín ọ̀sẹ̀ ni Ralph fi ń ṣiṣẹ́ irun gígẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọmọ wa méjèèjì, a máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, a tún máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ralph sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága ní ìjọ àdúgbò náà. Nítorí tí a kò walé ayé máyà, ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ikú Olólùfẹ́ Mi
Ní May 17, 1981, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba la wà táa ti ń gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn lọ́wọ́. Ralph ò mọ bó ṣe ń ṣe òun, ló bá rìn lọ́ sẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó kọ ìwé pélébé kan, ó ní kí olùtọ́jú èrò lọ fún mi, ó kọ ọ́ síbẹ̀ pé òun fẹ́ máa lọ sílé. Ralph kì í ṣe báyìí, lèmi náà bá ní kí ẹnì kan tètè fọkọ̀ gbé mi lọ sílé ní kíá. Láàárín wákàtí kan, àrùn rọpárọsẹ̀ tí ń mú gbogbo ara kú tipiri pa Ralph. Nígbà tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, ni wọ́n kéde pé ọkùnrin ti lọ.
Ní oṣù yẹn sì rèé, Ralph ti lo ohun tó lé ní àádọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Iye ọdún iṣẹ́ alákòókò kíkún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ti lé ní ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta. Àwọn tó ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti lé ní ọgọ́rùn-ún, tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìbùkún nípa tẹ̀mí táa rí gbà ju ohun yòówù táa ti yááfì ní àwọn ọdún wọ̀nyí.
Mo Dúpẹ́ fún Àwọn Àǹfààní Tí Mo Ní
Fún ọdún méjìdínlógún tó ti kọjá, èmi nìkan ni mò ń gbé, tí mò ń dá lọ́ sí ìpàdé, mo ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn níbi tí agbára mi bá gbé e dé, mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní báyìí, ilé àwọn àgbà tó ti fẹ̀yìn tì ni mò ń gbé. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé tí mo ní kò tó nǹkan, mo sì pinnu pé n kò fẹ́ tẹlifíṣọ̀n. Ṣùgbọ́n ìgbésí ayé mi tẹ́ mi lọ́rùn, ó sì kún fún ọrọ̀ nípa tẹ̀mí. Àwọn òbí mi àti àwọn arákùnrin mi méjèèjì jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú, àwọn arábìnrin mi méjèèjì ṣì wà nínú òtítọ́ láìyẹsẹ̀.
Mo láyọ̀ pé ọmọ mi, Allen, ń sìn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó ti ń ri ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ sínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ káàkiri, ó sì ti bá wọn ri ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí wọ́n lò fún àwọn àpéjọpọ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Aya rẹ̀ jẹ́ adúróṣinṣin, ìránṣẹ́ Jèhófà, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ń sìn bí alàgbà. Ọmọbìnrin mi, Rebekah Karres, ti lo ohun tó lé ní ọdún márùndínlógójì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, nínú rẹ̀, ó lo ọdún mẹ́rin ní oríléeṣẹ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn. Òun àti ọkọ rẹ̀ ti lo ọdún márùndínlọ́gbọ̀n nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní onírúurú ibi ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Jésù sọ pé Ìjọba náà dà bí ohun ìṣúra kan táa fi pa mọ́, ṣùgbọ́n tó ṣeé wá rí. (Mátíù 13:44) Mo dúpẹ́ pé ìdílé mi rí ohun ìṣúra yẹn ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ẹ wo àǹfààní ńlá tó jẹ́ láti bojú wẹ̀yìn wo ọgọ́rin ọdún iṣẹ́ ìsìn tí mo yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run—láìkábàámọ̀ kankan! Ká ní mo tún lè láǹfààní láti tún ìgbésí ayé mi lò, màá tún lò ó bí mo ti ṣe lò ó yìí gẹ́lẹ́, òdodo ọ̀rọ̀ ni o: ‘Inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run sàn ju ìyè.’—Sáàmù 63:3.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé The Finished Mystery ni ìdìpọ̀ keje nínú ọ̀wọ́ àwọn ìwé náà, Studies in the Scriptures, èyí tí Charles Taze Russell kọ mẹ́fà àkọ́kọ́ lára wọn. Lẹ́yìn tí Russell kú ni ìwé Studies in the Scriptures, jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A gbọ́ àsọyé Arákùnrin Rutherford ní 1917 ní Alliance, Ohio
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti Ralph níwájú ọkọ̀ àfiṣelé tó kọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àti àwọn ọmọ mi méjèèjì lónìí