Ìgbàgbọ́ Wọn Mú Èrè Wá
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìgbàgbọ́ Wọn Mú Èrè Wá
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù jẹ́ ọkùnrin kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tayọ lọ́lá, ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Àwọn ìrírí wọ̀nyí, tó wá láti Mòsáńbíìkì, fi hàn bí Jèhófà ṣe ń san èrè fún ìgbàgbọ́ tó lágbára, tó sì ń gbọ́ àdúrà àtọkànwá.
• Arábìnrin opó kan láti àríwá ẹkùn Niassa ṣàníyàn nípa bí òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yóò ṣe lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé tí Ọlọ́run Fẹ́.” Nínú àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó ń tà lọ́jà tó wà ládùúgbò ló ti ń rí ìwọ̀nba owó díẹ̀ tó ń ná, àmọ́ nígbà tí ọjọ́ àpéjọpọ̀ sún mọ́lé, gbogbo owó tó ní lọ́wọ́ ò ju èyí tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi máa wọkọ̀ ojú irin délẹ̀ ìpàdé lọ, kò sì sí owó tí wọn ó fi wọkọ̀ padà. Síbẹ̀síbẹ̀, ó pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé ìpèsè Jèhófà, kò sì yí àwọn ètò tó ti ṣe láti lọ sí àpéjọpọ̀ náà padà.
Lòun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà bá wọ ọkọ̀ ojú irin o. Bí ọkọ̀ ṣe ń lọ ni kọ̀ǹdọ́kítọ̀ wá béèrè owó tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ rẹ̀. Bí kọ̀ǹdọ́kítọ̀ náà ṣe rí káàdì tó lẹ̀ máyà ló béèrè pé irú káàdì wo lèyí jẹ́. Arábìnrin náà dá a lóhùn pé káàdì tí wọ́n fi máa dá òun mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó ń lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ni kọ̀ǹdọ́kítọ̀ náà bá béèrè pé: “Ibo ni wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọpọ̀ yìí?” Lẹ́yìn tó gbọ́ pé ẹkùn Nampula tó múlé gbè wọ́n, tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà sọ́dọ̀ wọn ni wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọpọ̀ náà, ó wá ṣe ohun kan tí wọn ò retí rárá, ó ní kó san ìdajì owó tó yẹ kó san fún tíkẹ́ẹ̀tì! Ó wá gba ìdajì owó tó ṣẹ́ kù, ó fi ṣe owó tíkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n máa fi wọkọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń padà bọ̀ wálé, ó sì fún wọn ní tíkẹ́ẹ̀tì náà. Ẹ wo bí ayọ̀ obìnrin yìí ṣe kún tó pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!—Sáàmù 121:1, 2.
• Láti nǹkan bi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní obìnrin kan tó lẹ́mìí ìjọsìn ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ọ̀nà tó tọ́ láti sìn ín han òun. Ṣọ́ọ̀ṣì tó ń dara pọ̀ mọ́ máa ń pa ètò ìsìn pọ̀ mọ́ àwọn àṣà àbáláyé, ó wá ń kọminú bí ìjọsìn yìí bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn tàbí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ní mo máa ń rántí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 7:7 pé: ‘Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.’ Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló wà lọ́kàn mi tí mo fi wá ń gbàdúrà déédéé pé kí Ọlọ́run darí mi sí òtítọ́. Lọ́jọ́ kan, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wa sọ pé kí gbogbo àwọn tó ń ta nǹkan lọ́jà àdúgbò mú iye owó kan pàtó àti díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n ń tà wá fún òun kí òun lè súre fún wọn. Mo ka ohun tó ń béèrè yìí sí ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ìdí nìyẹn tí n ò fi mú ohunkóhun wá. Bí pásítọ̀ ṣe rí i pé n ò mú ‘ọrẹ’ wá, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bú mi lójú gbogbo mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì. Ọjọ́ yẹn ni mo wá rí i pé kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká gbà sin òun nìyí, bí mo ṣe fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ nìyẹn. Ní gbogbo àkókò yẹn, mi ò dákẹ́ àdúrà gbígbà pé kí n ṣáà rí òtítọ́.
“Níkẹyìn, mo kó ìtìjú tà, mo lọ bá ìbátan kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fún mi ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kà á báyìí ni mo rí i pé Ọlọ́run ti ń dáhùn àdúrà mi. Láìpẹ́, ẹnì kejì mi náà bẹ̀rẹ̀ sí mọyì òtítọ́ Bíbélì, la bá fẹsẹ̀ ìgbéyàwó wa múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́, níkẹyìn, ọkọ mi wá dùbúlẹ̀ àìsàn tó kọjá sísọ. Àmọ́ títí tó fi kú ló ń gbà mí nímọ̀ràn pé kí n máa ní ìforítì bí mo ti ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́ náà, kí a lè tún pàdé lẹ́ẹ̀kan sí i ní Párádísè.
“Títí láé ni n ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó gbọ́ àdúrà mi, ó sì fi ọ̀nà tí ó tọ́ láti sin òun hàn mí. Àdúrà mi tún gbà ní ti pé mo ti rí gbogbo àwọn ọmọ mi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí wọ́n ti di ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.”