Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Máa Wá Jèhófà Àti Okun Rẹ̀”

“Ẹ Máa Wá Jèhófà Àti Okun Rẹ̀”

“Ẹ Máa Wá Jèhófà Àti Okun Rẹ̀”

“Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 KÍRÓNÍKÀ 16:9.

1. Kí ni agbára, báwo làwọn èèyàn sì ṣe ń lò ó?

 AGBÁRA lè túmọ̀ sí àwọn nǹkan bíi mélòó kan. Ó lè túmọ̀ sí pé kí ẹnì kan láǹfààní àtidarí àwọn ẹlòmíràn, kó ní àṣẹ lórí wọn, tàbí kó ní ipa lórí èrò wọn; ó tún lè túmọ̀ sí kí ẹnì kan tóótun láti gbégbèésẹ̀ tàbí láti ṣe ohun kan tó gbàfiyèsí; ó sì lè túmọ̀ sí pé kí èèyàn lágbára àtiṣiṣẹ́ (ìyẹn ni okun); bẹ́ẹ̀ ló sì lè túmọ̀ sí kéèyàn ní ọpọlọ tó jí pépé tàbí kó lè fìyàtọ̀ sáàárín ìwà rere àti ìwà burúkú. Àmọ́, tó bá kan ọ̀ràn ká lo agbára, àwọn èèyàn ò lórúkọ rere. Nígbà tí òpìtàn nì, Lord Acton ń sọ̀rọ̀ nípa agbára tó wà lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú, ó ní: “Ńṣe ni agbára máa ń gunni, báa bá wá lọ gbé gbogbo agbára léèyàn lọ́wọ́, gàràgàrà ni yóò máa gun olúwa ẹ̀.” Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ táa ti rí nínú àwọn ìtàn táà ń gbọ́ lóde òní fi hàn pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ tí Lord Acton sọ. Ní ọ̀rúndún ogún yìí, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀” ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Oníwàásù 8:9) Àwọn aláṣẹ oníkùmọ̀ tí agbára ń gùn gàràgàrà ti ṣi agbára wọn lò lọ́nà tó burú jáì, wọ́n sì ti fẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn ṣòfò. Agbára tí a kò bá fi ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo darí, léwu.

2. Ṣàlàyé bí àwọn ànímọ́ mìíràn ṣe nípa lórí ọ̀nà tí Jèhófà gba ń lo agbára rẹ̀.

2 Láìdàbí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ohun rere ni Ọlọ́run máa ń lo ọgbọ́n rẹ̀ fún. “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Kíróníkà 16:9) Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó ṣeé ṣàkóso. Sùúrù ló mú kí Ọlọ́run fawọ́ ìparun àwọn ẹni ibi sẹ́yìn kó lè fún wọn láǹfààní àtironú-pìwàdà. Ìfẹ́ ló mú kó máa ran oòrùn rẹ̀ sórí onírúurú ènìyàn—olódodo àti aláìṣòdodo. Níkẹyìn, ìdájọ́ òdodo yóò sún un láti lo agbára rẹ̀ tí kò láàlà láti mú ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, ìyẹn Sátánì Èṣù.—Mátíù 5:44, 45; Hébérù 2:14; 2 Pétérù 3:9.

3. Èé ṣe tí agbára ńlá tí Ọlọ́run ní fi jẹ́ ìdí pàtàkì fún wa láti gbẹ́kẹ̀ lé e?

3 Agbára ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí Baba wa ọ̀run ní jẹ́ ìdí pàtàkì táa fi ní láti gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì fọkàn tán an—ní ti àwọn ìlérí rẹ̀ àti ààbò rẹ̀. Bí ọmọdé kan bá wà láàárín àwọn àjèjì, ọkàn rẹ̀ yóò balẹ̀ tó bá ti lè di ọwọ́ bàbá rẹ̀ mú, nítorí ó mọ̀ pé baba òun kò ní jẹ́ kí ewu kankan wu òun. Bákan náà ni Baba wa ọ̀run, ẹni tí “ó pọ̀ gidigidi ní agbára láti gbani là,” yóò dáàbò bò wá, tí kò ní jẹ́ kí ewu èyíkéyìí wu wa títí ayé, bí a bá rìn pẹ̀lú rẹ̀. (Aísáyà 63:1; Míkà 6:8) Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti jẹ́ Baba rere, ó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Agbára rẹ̀ tí kò láàlà fúnni ní ẹ̀rí ìdánilójú pé ‘ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí ó tìtorí rẹ̀ rán an.’—Aísáyà 55:11; Títù 1:2.

4, 5. (a) Kí ni ìyọrísí rẹ̀ nígbà tí Ásà Ọba gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé Jèhófà? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táa bá gbà pé èèyàn lè bá wa yanjú ìṣòro wa?

4 Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti pinnu pé a kò ní fojú kéré ààbò tí Baba wa ọ̀run ń fún wa? Nítorí pé ó ṣeé ṣe kí ipò nǹkan mọ́kàn ẹni pòrúurùu, kí a sì wá gbàgbé ibi tí ààbò wa tòótọ́ wà. Èyí la rí nínú àpẹẹrẹ Ásà Ọba, ọkùnrin kan táa lè sọ pé lọ́nà púpọ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Lákòókò tí Ásà jẹ́ ọba, àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Etiópíà, tí wọ́n jẹ́ alágbára, ló wá bá Júdà jà. Nígbà tí Ásà rí i pé ọwọ́ àwọn ọ̀tá le ju tàwọn lọ, ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, ní ti rírannilọ́wọ́, kò jámọ́ nǹkan kan lọ́dọ̀ rẹ yálà àwọn ènìyàn púpọ̀ ní ń bẹ tàbí àwọn tí kò ní agbára. Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ ni a gbára lé, orúkọ rẹ sì ni a fi dojú kọ ogunlọ́gọ̀ yìí. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú ní okun láti dojú kọ ọ́.” (2 Kíróníkà 14:11) Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Ásà, ó sì fún un ní ìṣẹ́gun pátápátá.

5 Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Ásà ti ń fi òtítọ́ sìn, ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú agbára Jèhófà láti gbani là bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀. Nígbà tó ń wá bí òun ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìjọba àríwá Ísírẹ́lì tó fẹ́ bá a jà, Síríà ló yíjú sí fún ìrànwọ́. (2 Kíróníkà 16:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tó fún Bẹni-Hádádì, Ọba Síríà mú kí Ísírẹ́lì dáwọ́ ogun tó fẹ́ bá a jà dúró, síbẹ̀ májẹ̀mú tí Ásà lọ bá Síríà dá fi hàn pé kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Hánáánì wòlíì dìídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Àwọn ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà kì í ha ṣe ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ gan-an ní ti jíjẹ́ ògìdìgbó, nínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti nínú àwọn ẹlẹ́ṣin; nítorí gbígbé tí o gbára lé Jèhófà, òun kò ha sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́?” (2 Kíróníkà 16:7, 8) Síbẹ̀síbẹ̀, Ásà kọ ìbáwí àfitọ́nisọ́nà yìí sílẹ̀. (2 Kíróníkà 16:9-12) Nígbà tí a bá dojú kọ ìṣòro, ẹ má ṣe jẹ̀ ká gbà pé èèyàn lè bá wa yanjú ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, nítorí pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ìjákulẹ̀ ni gbígbẹ́kẹ̀lé agbára ènìyàn yóò yọrí sí.—Sáàmù 146:3-5.

Máa Wa Agbára Tí Jèhófà Ń Fúnni

6. Èé ṣe tí a fi ní láti “máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀”?

6 Jèhófà lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára, kó sì tún dáàbò bò wọ́n. Bíbélì gbà wá níyànjú pé kí a “máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀.” (Sáàmù 105:4) Èé ṣe? Nítorí pé, nígbà tí a bá fi okun Ọlọ́run ṣe àwọn nǹkan, a ó lo agbára wa fún àǹfààní àwọn ẹlòmíràn, dípò tí a ó fi lò ó fún ìpalára wọn. Kò síbòmíràn táa ti lè rí àpẹẹrẹ èyí ju ọ̀dọ̀ Jésù Kristi lọ, ẹni tó fi “agbára Jèhófà” ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. (Lúùkù 5:17) Jésù láǹfààní láti sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀, olókìkí, tàbí ọba kan tí gbogbo ayé yóò máa wárí fún, ká ló fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni. (Lúùkù 4:5-7) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà àti láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, láti ràn wọ́n lọ́wọ́, àti láti wò wọ́n sàn. (Máàkù 7:37; Jòhánù 7:46) Àpẹẹrẹ tó dáa lèyí mà jẹ́ fún wa o!

7. Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì wo là ń mú dàgbà nígbà táa bá fi okun Ọlọ́run ṣe àwọn nǹkan dípò okun tiwa fúnra wa?

7 Láfikún sí i, táa bá ń fi “okun tí Ọlọ́run ń fúnni” ṣe àwọn nǹkan, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Pétérù 4:11) Àwọn tó ń wá agbára fún ara wọn máa ń di ọ̀yájú. Irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni ti Ọba Ásíríà nì, Esari-hádónì, ẹni tó ń ṣe fọ́ńté pé: “Mo lágbára, mo lágbára gan-an ni, akọni ni mí, mo sígbọnlẹ̀, àkòtagìrì ni mí.” Ní òdìkejì sí èyí, Jèhófà “yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ohun tí ó lágbára.” Nípa bẹ́ẹ̀, bí Kristẹni tòótọ́ kan bá ń ṣògo, inú Jèhófà ni kó ti máa ṣe é, nítorí ó mọ̀ pé kì í ṣe agbára tòun lòun fi ṣe àwọn ohun tí òun ṣe. ‘Rírẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run’ yóò fún wa ní ìgbéga tòótọ́.—1 Kọ́ríńtì 1:26-31; 1 Pétérù 5:6.

8. Kí la gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ká tó lè rí agbára Jèhófà gbà?

8 Báwo la ṣe lè rí okun Ọlọ́run lò? Lákọ̀ọ́kọ́, a ní láti béèrè fún un nínú àdúrà. Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé Baba òun yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè fún un. (Lúùkù 11:10-13) Ṣàgbéyẹ̀wò bí èyí ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lágbára nígbà tí wọ́n yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò àwọn aṣáájú ìsìn tó pàṣẹ fún wọn láti ṣíwọ́ jíjẹ́rìí nípa Jésù. Nígbà tí wọ́n gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a dáhùn àdúrà àtọkànwá wọn, ẹ̀mí mímọ́ sì fún wọn lágbára láti máa bá wíwàásù ìhìn rere náà lọ láìṣojo.—Ìṣe 4:19, 20, 29-31, 33.

9. Dárúkọ orísun kejì tí okun tẹ̀mí ti ń wá, kí o sì tọ́ka sí àpẹẹrẹ kan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi bí èyí ṣe gbéṣẹ́ hàn.

9 Èkejì, a lè gba okun tẹ̀mí láti inú Bíbélì. (Hébérù 4:12) Agbára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn kedere nígbà ayé Jòsáyà Ọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba Jùdíà yìí ti kó òrìṣà àwọn kèfèrí kúrò ní ilẹ̀ náà, rírí tí wọ́n wá rí Òfin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì láìròtẹ́lẹ̀ tún mú kó túbọ̀ tẹra mọ́ ètò ìfọ̀mọ́ yìí. a Lẹ́yìn tí Jòsáyà fúnra rẹ̀ ka Òfin ọ̀hún fáwọn ènìyàn náà tán ni gbogbo orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ wá bá Jèhófà dá májẹ̀mú, bí wọ́n tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tí ìbọ̀rìṣà lẹ́ẹ̀kejì nìyẹn, lọ́tẹ̀ yìí wọ́n wá ṣe é tẹ̀mítẹ̀mí. Àbájáde rere tí àtúnṣe tí Jòsáyà ṣe yìí mú wá ni pé ní “gbogbo ọjọ́ rẹ̀, wọn kò yà kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn.”—2 Kíróníkà 34:33.

10. Kí ni ọ̀nà kẹta táa fi lè rí okun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì?

10 Ẹ̀kẹta, a ń gba okun látọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa lọ sí ìpàdé déédéé kí wọ́n lè ‘ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà,’ kí wọ́n sì lè máa fún ara wọn níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) Nígbà tí Pétérù jáde lẹ́wọ̀n lọ́nà ìyanu, ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, nítorí náà, ó lọ tààrà sí ilé ìyá Jòhánù Máàkù, níbi tí “àwọn púpọ̀ díẹ̀ kóra jọ sí, tí wọ́n sì ń gbàdúrà.” (Ìṣe 12:12) Dájúdájú, wọ́n lè jókòó sílé ara wọn kí wọ́n sì máa tibẹ̀ gbàdúrà. Àmọ́, wọ́n yàn láti kóra jọ láti gbàdúrà, kí wọ́n sì fúnra wọn níṣìírí lákòókò líle koko yẹn. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù parí ìrìn àjò rẹ̀ gígùn, tó jẹ́ eléwu, tó ń rìn lọ sí Róòmù, ó bá àwọn arákùnrin kan pàdé ní Pútéólì, lẹ́yìn náà, ó tún pàdé àwọn mìíràn tí wọ́n ti rin ìrìn àjò láti wá pàdé rẹ̀. Kí ló wá ṣe? “Bí Pọ́ọ̀lù sì ti tajú kán rí wọn [ìyẹn àwọn tó wá pàdé rẹ̀], ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:13-15) Wíwà tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i tún fún un lókun. Àwa pẹ̀lú máa ń rí okun gbà nínú bíbá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́. Níwọ̀n ìgbà táa bá ṣì láǹfààní àtibá ara wa kẹ́gbẹ́, táa sì lágbára àtiṣe bẹ́ẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbìyànjú àtidá nìkan rin ojú ọ̀nà híhá náà tó lọ sí ìyè.—Òwe 18:1; Mátíù 7:14.

11. Sọ àwọn ipò kan táa ti dìídì nílò “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”

11 Nípa gbígbàdúrà déédéé, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti bíbá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́, a óò “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.” (Éfésù 6:10) Láìsí iyèméjì, gbogbo wa pátá la nílò “agbára nínú Olúwa.” Àìsàn ti sọ àwọn kan di ẹni tí kò lágbára mọ́, ọjọ́ ogbó ò jẹ́ kí ara àwọn míì ṣe ṣámúṣámú mọ́, ọkọ tàbí ìyàwó àwọn ẹlòmíì sì ti kú. (Sáàmù 41:3) Àwọn mìíràn ń fara da àtakò látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Àwọn òbí, ní pàtàkì àwọn tó ń dá nìkan tọ́mọ, lè rí i pé bíbójútó iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti bíbójútó ìdílé lákòókò kan náà jẹ́ ẹrù iṣẹ́ kan tó ń tánni lókun. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ nílò okun láti kojú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, kí wọ́n sì sọ pé rárá, àwọn ò ní báwọn lo oògùn líle, àwọn ò sì ní hùwà pálapàla. Kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ lọ́ tìkọ̀ láti béèrè “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” lọ́dọ̀ Jèhófà, láti kojú irú àwọn ìpèníjà bẹ́ẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

‘Fífi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀’

12. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?

12 Síwájú sí i, Jèhófà ń fi agbára fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. A kà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà pé: “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. . . . Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Aísáyà 40:29-31) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù alára gba agbára láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Òun ló sì fà á ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fi gbéṣẹ́. Ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́.” (1 Tẹsalóníkà 1:5) Ìwàásù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lágbára láti yí ìgbésí ayé àwọn tí ó fetí sílẹ̀ sí i padà.

13. Kí ló fún Jeremáyà lókun láti forí tì í láìka àtakò sí?

13 Nígbà tí a bá bá àwọn tó lẹ́mìí ìdágunlá pàdé lágbègbè táa ti ń wàásù—ó lè jẹ́ àgbègbè kan táa ti ń wàásù déédéé fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́, tí a ò fi bẹ́ẹ̀ ráwọn tó fìfẹ́ hàn—ìyẹn lè bà wá lọ́kàn jẹ́. Bákan náà ni Jeremáyà ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí àtakò, ìfiniṣẹ̀sín, àti ẹ̀mí ìdágunlá tó dojú kọ. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Èmi kì yóò mẹ́nu kan [Ọlọ́run], èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n kò lè dákẹ́. Iṣẹ́ táa fi rán an “dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun rẹ̀.” (Jeremáyà 20:9) Kí ló sọ agbára rẹ̀ dọ̀tun lójú ọ̀pọ̀ ìdààmú bẹ́ẹ̀? Jeremáyà sọ pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú mi bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà.” (Jeremáyà 20:11) Mímọyì tí Jeremáyà mọyì ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ táa fi rán an àti iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un ló jẹ́ kó tẹ́wọ́ gba ìṣírí tí Jèhófà fún un.

Agbára Láti Pani Lára àti Agbára Láti Múni Lára Dá

14. (a) Báwo ni ahọ́n ṣe jẹ́ ohun èlò alágbára tó? (b) Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ tó fi wàhálà tí ahọ́n lè dá sílẹ̀ hàn.

14 Kì í ṣe gbogbo agbára táa ní ló wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tààrà o. Fún àpẹẹrẹ, ahọ́n lágbára láti pani lára, ó sì lágbára láti múni lára dá. Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Àbájáde ọ̀rọ̀ ráńpẹ́ tí Sátánì bá Éfà jíròrò fi hàn bí yánpọnyánrin tí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lè dá sílẹ̀ ti pọ̀ tó. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Jákọ́bù 3:5) Ọ̀pọ̀ wàhálà làwa náà lè fahọ́n wa dá sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí ẹnì kan sọ nípa bí ọ̀dọ́mọbìnrin kan ṣe sanra tó lè mú kí ọmọbìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í febi pa ara rẹ̀. Sísọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ẹnì kan lásọtúnsọ láìronújinlẹ̀ lè ba ọ̀rẹ́ táa ti ń ṣe bọ̀ tipẹ́ jẹ́. Dájúdájú, ó yẹ ká ṣàkóso ahọ́n wa.

15. Báwo lá ṣe lè lo ahọ́n wa láti gbéni ró àti láti múni lára dá?

15 Síbẹ̀síbẹ̀, bí ahọ́n ti ṣe lè gbéni ró bẹ́ẹ̀ náà ló lè bani jẹ́. Òwe Bíbélì nì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń lo agbára ahọ́n wọn láti tu àwọn tó sorí kọ́ àtàwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́mìí ìbánikẹ́dùn lè fún àwọn ọ̀dọ́langba níṣìírí, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ń kojú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè pani lára. Ahọ́n ẹni tó ronú jinlẹ̀ kó tó sọ̀rọ̀ lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ arúgbó níṣìírí pé wọ́n ṣì wúlò fún wa, àti pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀rọ̀ onínúure lè mú ara àwọn tó ń ṣàìsàn le. Lékè gbogbo rẹ̀, a lè lo ahọ́n wa láti sọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tó lágbára fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́. Pípòkìkí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í ṣe ohun tó kọjá agbára wa táa bá fọkàn sí i. Bíbélì sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27.

Lílo Agbára Lọ́nà Tó Tọ́

16, 17. Nígbà tí wọ́n bá ń lo ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn, báwo ni àwọn alàgbà, òbí, àwọn ọkọ àti aya ṣe lè fara wé Jèhófà?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbára ńlá gbogbo ni Jèhófà, síbẹ̀ ó ń fi ìfẹ́ darí ìjọ. (1 Jòhánù 4:8) Láti fara wé e, àwọn Kristẹni alábòójútó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ bìkítà fun agbo Ọlọ́run—wọ́n ń lo ọlá àṣẹ tí wọ́n ní, wọn ò lò ó nílòkulò. Lóòótọ́, àwọn ìgbà mìíràn wà táwọn alábòójútó ní láti “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú,” àmọ́, wọ́n ń ṣe èyí “pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Tímótì 4:2) Nítorí náà, léraléra làwọn alàgbà máa ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sí àwọn tó ní ọlá àṣẹ nínú ìjọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pétérù 5:2, 3; 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.

17 Àwọn òbí àtàwọn ọkọ náà ní ọlá àṣẹ tí Jèhófà fún wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ lo agbára yìí láti ṣèrànwọ́, láti fúnni lókun, àti láti ṣìkẹ́ ẹni. (Éfésù 5:22, 28-30; 6:4) Àpẹẹrẹ ti Jésù fi hàn pé a lè lo ọlá àṣẹ dáradára lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Bí ìbáwí bá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí kò sì ṣe ségesège, àwọn ọmọ kò ni sorí kọ́. (Kólósè 3:21) Ìgbéyàwó máa ń lókun nígbà tí àwọn Kristẹni ọkọ bá fi ìfẹ́ lo ipò orí wọn, tí àwọn aya sì ní ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ fún ipò orí tí ọkọ wọn dì mú dípò tí wọn ó fi kọjá àyè tí Ọlọ́run fi wọ́n sí, tí wọn ó fẹ́ máa jẹ gàba lé ọkọ wọn lórí tàbí kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ṣáà ti sọ labẹ́ gé.—Éfésù 5:28, 33; 1 Pétérù 3:7.

18. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká fara wé àpẹẹrẹ Jèhófà ní ṣíṣàkóso ìbínú wa? (b) Kí ló yẹ káwọn tó ní ọlá àṣẹ gbìyànjú láti gbìn sọ́kàn àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn?

18 Àwọn tó ní ọlá àṣẹ nínú ìdílé àti nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an láti ṣàkóso ìbínú wọn, nítorí pé dípò ìfẹ́, ẹ̀rù ni ìbínú máa ń gbìn síni lọ́kàn. Wòlíì Náhúmù sọ pé: “Jèhófà ń lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára.” (Náhúmù 1:3; Kólósè 3:19) Bí ẹnì kan bá lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀, ìyẹn fi hàn pé ó ní okun, àmọ́ bí ẹnì kan bá jẹ́ onínúfùfù, ìyẹn fi hàn pé onítọ̀hún kò lágbára. (Òwe 16:32) Nínú ìdílé àti nínú ìjọ lápapọ̀, góńgó náà ni pé kí a gbin ìfẹ́ síni lọ́kàn—ìfẹ́ fún Jèhófà, ìfẹ́ fún ẹnì kìíní-kejì, àti ìfẹ́ fún ìlànà títọ́. Ìfẹ́ ni ìdè tó lágbára jù lọ fún ìrẹ́pọ̀ pípé, òun ló sì lágbára jù lọ láti súnni ṣe ohun tí ó tọ́.—1 Kọ́ríńtì 13:8, 13; Kólósè 3:14.

19. Kí ni ìdánilójú tó ń tuni nínú tí Jèhófà fúnni, irú ẹ̀mí wo ló sì yẹ kí a ní?

19 Ohun táa fi lè sọ pé a mọ Jèhófà ni ká mọ bí agbára rẹ̀ ṣe tó. Nípasẹ̀ Aísáyà, Jèhófà sọ pé: “Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.” (Aísáyà 40:28) Agbára Jèhófà kò lópin. Tí a bá gbára lé e, tí a kò gbára lé ara wa, kò ní fi wá sílẹ̀. Ó mú un dá wa lójú pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 41:10) Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká fi hàn sí àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Bíi ti Jésù, ẹ jẹ́ kí a máa lo agbára èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún wa láti ṣèrànwọ́ àti láti gbéni ró. Ẹ jẹ́ ká máa ṣàkóso ahọ́n wa kí ó lè máa múni lára dá, dípò tí yóò fi máa pani lára. Ẹ jẹ́ ká sì máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí a dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, kí a sì di alágbára ńlá nínú agbára Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 16:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní kedere, àwọn Júù rí ojúlówó ẹ̀dà Òfin Mósè, tó ti wà nínú tẹ́ńpìlì láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn.

Ṣé O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀?

• Àwọn ọ̀nà wo la fi lè rí agbára gbà lọ́dọ̀ Jèhófà?

• Báwo la ṣe lè lo agbára tí ahọ́n ní?

• Báwo ni ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fúnni ṣe lè jẹ́ ìbùkún?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jésù lo okun Jèhófà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Pípòkìkí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í ṣe ohun tó kọjá agbára wa, táa bá fọkàn sí i