Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Agbára Àdúrà

Agbára Àdúrà

Agbára Àdúrà

Ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní ìlú Náhórì tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Ni ọkùnrin ará Síríà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Élíésérì bá dé síbi kànga kan lẹ́yìn òde ìlú náà tòun ti ràkúnmí mẹ́wàá tí wọ́n ń wọ́ tẹ̀ léra wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ ló ti rẹ Élíésérì, tí òùngbẹ sì ń gbẹ ẹ́, ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn ló ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ilẹ̀ òkèèrè ló ti wá síbí, ó wá wá ìyàwó fún ọmọ ọ̀gá rẹ̀. Ní àfikún sí i, ìyàwó yìí tún ní láti jẹ́ ìbátan ọ̀gá rẹ̀. Ọgbọ́n wo ló fẹ́ dá sí iṣẹ́ tó le koko bí ojú ẹja yìí?

ÉLÍÉSÉRÌ nígbàgbọ́ nínú agbára àdúrà. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó jọni lójú, táa lè fi wé ti ọmọdé, ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ yìí, ó ní: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, jọ̀wọ́, mú kí ó ṣẹlẹ̀ níwájú mi ní òní yìí, kí o sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ọ̀gá mi Ábúráhámù. Kíyè sí i, èmi dúró níbi ìsun omi, àwọn ọmọbìnrin àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sì ń jáde bọ̀ wá fa omi. Kí ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí èmi bá wí fún pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí èmi lè mu,’ tí yóò sì wí ní ti gidi pé, ‘Mu, èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ,’ ẹni yìí ni kí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ, fún Ísákì; kí o sì tipa èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ dídúró ṣinṣin hàn sí ọ̀gá mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:12-14.

Ìgbàgbọ́ tí Élíésérì ní nínú agbára àdúrà kò já sásán. Àrà ńlá lèyí o, obìnrin àkọ́kọ́ tó wá sí ìdí kànga náà jẹ́ ọmọ ọmọ arákùnrin Ábúráhámù! Rèbékà lorúkọ ẹ̀, omidan ni, kò tí ì bara ẹ̀ jẹ́, ó sì rẹwà. Ohun tó tún yani lẹ́nu ni pé, kì í ṣe pé ó fún Élíésérì lómi mu nìkan ni, àní ó tún bomi fáwọn ràkúnmí náà, kí ó lè pòùngbẹ wọn. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí ẹbí fikùnlukùn lórí ọ̀ràn náà, Rèbékà gbà tinútinú láti bá Élíésérì lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà réré, láti di aya ọmọ Ábúráhámù, ìyẹn Ísákì. Ẹ wo bí Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà Élíésérì lọ́nà tó yani lẹ́nu, tó sì ṣe tààrà nígbà yẹn lọ́hùn-ún tí Ọlọ́run máa ń dá sí ọ̀ràn aráyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́nà ìyanu!

Ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú àdúrà Élíésérì pọ̀ jọjọ. Ó fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó ta yọ, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àìmọtara-ẹni-nìkan tó sì ní lórí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn tún pabanbarì. Àdúrà Élíésérì tún fi hàn pé ó jẹ́ ẹni tó ń fara mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá aráyé lò. Kò sí àní-àní pé ó mọ̀ pé ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni Ábúráhámù, ó sì tún mọ̀ nípa ìlérí Rẹ̀ pé ìbùkún ọjọ́ ọ̀la yóò dé sórí aráyé nípasẹ̀ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 12:3) Nípa báyìí, Élíésérì bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ yìí: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù.”

Jésù Kristi jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, òun sì ni ẹni tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún aráyé onígbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Lónìí, báa bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, ó ṣe pàtàkì pé ká fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bá aráyé lò nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Jésù Kristi sọ pé: “Bí ẹ bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí àwọn àsọjáde mi sì dúró nínú yín, ẹ béèrè ohun yòówù tí ẹ bá fẹ́, yóò sì ṣẹlẹ̀ fún yín.”—Jòhánù 15:7.

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ní ìrírí rẹ̀ pé òótọ́ ni ohun tí Jésù sọ yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sì dájú pé ìgbàgbọ́ tó ní nínú agbára àdúrà kò já sásán rárá. Ó gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti kó gbogbo àníyàn wọn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú àdúrà, ó jẹ́rìí sí i pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:6, 7, 13) Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àdúrà tí Pọ́ọ̀lù gbà ni Ọlọ́run dáhùn? Ẹ jẹ́ á wò ó.

Kì Í Ṣe Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Ń Gbọ́

Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tí kò fi ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe, Pọ́ọ̀lù rí ìpọ́njú tó pè ní ‘ẹ̀gún inú ẹran ara.’ (2 Kọ́ríńtì 12:7) Èyí lè jẹ́ másùnmáwo àti ìdààmú tí àwọn alátakò àti “àwọn èké arákùnrin” ń fà. (2 Kọ́ríńtì 11:26; Gálátíà 2:4) Ó sì lè jẹ́ pé ojú ń dùn ún, tí èyí sì ń fa ìrora fún un. (Gálátíà 4:15) Èyí ó wù ó jẹ́, ‘ẹ̀gún inú ẹran ara’ yìí gbo Pọ́ọ̀lù gidigidi. Ó kọ̀wé pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo pàrọwà sí Olúwa pé kí ó lè kúrò lára mi.” Ṣùgbọ́n, a ò dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù. A ṣàlàyé fún Pọ́ọ̀lù pé àǹfààní nípa tẹ̀mí tó ti gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, irú bí agbára àtifarada àdánwò, ti tó fún un. Síwájú sí i, Ọlọ́run wí pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:8, 9.

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Élíésérì àti ti Pọ́ọ̀lù? Dájúdájú Jèhófà Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí àdúrà àwọn tó bá fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sìn ín. Ṣùgbọ́n èyí ò túmọ̀ sí pé ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tí wọ́n bá béèrè, nítorí pé ojú Ọlọrun ríran jìnnà ju tiwa lọ. Ó mọ ohun tó lè ṣe wá láǹfààní ju bí àwa fúnra wa ti mọ̀ ọ́n lọ. Ohun tó tún ṣe pàtàkì jù ni pé, ìgbà gbogbo ló máa ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ táa kọ sínú Bíbélì.

Àkókò fún Ìwòsàn Tẹ̀mí

Ọlọ́run ṣèlérí pé nígbà Ìṣàkóso Ọmọ òun fún Ẹgbẹ̀rúndún lórí ayé, òun yóò wo gbogbo àrùn aráyé sàn, ì báà jẹ́ àìsàn ti ara, tàbí ti ọpọlọ, tàbí ti ìmọ̀lára. (Ìṣípayá 20:1-3; 21:3-5) Àwọn Kristẹni olóòótọ́ ń hára gàgà láti rí ọjọ́ ọ̀la táa ṣèlérí yìí, wọ́n sì nígbàgbọ́ pé lágbára Ọlọ́run, á ṣeé ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò retí irú ìwòsàn lọ́nà ìyanu bẹ́ẹ̀ báyìí, wọ́n ń gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìtùnú àti okun láti kojú irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 55:22) Bí wọ́n bá ṣàìsàn, wọ́n lè gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ láti lè rí ìtọ́jú tó dáa tí apá wọn yóò ká.

Àwọn ẹ̀sìn kan máa ń fún àwọn aláìsàn níṣìírí láti gbàdúrà fún ìwòsàn nísinsìnyí, wọ́n sì máa ń tọ́ka sí ìwòsàn ìyanu tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n ète pàtàkì wà tí wọ́n fi ṣe irú iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn. Wọ́n fi hàn pé Jésù Kristi ni Mèsáyà tòótọ́ náà, wọ́n sì tún fi hàn pé a ti yí ojú rere Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè Júù lọ sí ọ̀dọ̀ ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìdí múlẹ̀. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a nílò àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu láti fún ìgbàgbọ́ ìjọ Kristẹni táa ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lókun. Nígbà tí ìjọ kékeré náà ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, tó sì ti lè dá dúró, àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu “wá sí òpin.”—1 Kọ́ríńtì 13:8, 11.

Ní àkókò tíná ti jó dórí kókó yìí, ṣe ni Jèhófà Ọlọ́run ń darí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwòsàn nípa tẹ̀mi, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Nígbà tí àkókò ṣì wà yìí, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ kíákíá bí a ti ń rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:6, 7.

Ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló ń mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà láti rí ìwòsàn tẹ̀mí gbà. (Mátíù 24:14) Nípa fífún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti máa bá iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí lọ, Jèhófà Ọlọ́run ń ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n sì wá sí ipò ìbátan tó gún régé níwájú rẹ̀ kí òpin ètò burúkú yìí tó dé. Gbogbo àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà fún irú ìwòsàn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún ìrànwọ́ láti ṣe irú iṣẹ́ ìwòsàn yìí ni àdúrà wọn máa ń gbà.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Élíésérì àti Rèbékà /The Doré Bible Illustrations/Dover Publications