Fífi Ọkàn-Àyà Táa Ti Múra Sílẹ̀ Wá Jèhófà
Fífi Ọkàn-Àyà Táa Ti Múra Sílẹ̀ Wá Jèhófà
ÀLÙFÁÀ ilẹ̀ Ísírẹ́lì nì, Ẹ́sírà, jẹ́ olùṣèwádìí, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, adàwékọ, àti olùkọ́ Òfin tó tayọ lọ́lá. Ó tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn Kristẹni òde òní ní ti iṣẹ́ ìsìn àfitọkàntọkànṣe. Lọ́nà wo? Ní ti pé, nígbà tó ń gbé ní Bábílónì, ìlú tí àwọn ọlọ́run èké kún inú rẹ̀, tó sì jẹ́ pé ẹ̀mí èṣù làwọn ara ibẹ̀ ń jọ́sìn, ó ń fọkàn sin Ọlọ́run rẹ̀.
Ẹ̀mí ìfọkànsin Ọlọ́run tí Ẹ́sírà ní yìí kò ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ fún un ni. Àní, ó sọ fún wa pé, òun ‘múra ọkàn-àyà òun sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́.’—Ẹ́sírà 7:10.
Gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sírà, báwọn èèyàn Jèhófà lóde òní tilẹ̀ ń gbé nínú ayé tó kórìíra ìjọsìn tòótọ́, gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe ní wọn ó ṣe. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí àwa náà ṣe lè múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀, ìyẹn ni ẹni táa jẹ́ nínú lọ́hùn-ún—ìrònú wa, ìwà wa, ohun táa nífẹ̀ẹ́ sí, àti góńgó wa—láti “ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́.”
Mímúra Ọkàn-Àyà Wa Sílẹ̀
“Láti múra sílẹ̀” túmọ̀ sí “láti gbára dì fún ète kan: láti ṣe ohun kan táa fẹ́ lò fún ète kan pàtó.” Dájúdájú, bóo bá ti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tóo sì ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, nígbà náà, ọkàn-àyà rẹ ti gbára dì, a sì lè fi wé “erùpẹ̀ àtàtà” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú òwe afúnrúngbìn.—Mátíù 13:18-23.
Àmọ́ ṣá o, ó ń béèrè pé ká máa kíyè sí ọkàn-àyà wa, ká sì máa tún un ṣe. Èé ṣe? Ìdí méjì ló wà. Àkọ́kọ́ ni pé, nítorí àwọn ìrònú tó lè pani lára, àwọn ohun tó dà bí èpò lè dàgbà nínú wa, pàápàá jù lọ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí nígbà tí “afẹ́fẹ́” ètò Sátánì ti wá kún fún àwọn irúgbìn tí kò dára rárá, èyí tó jẹ́ ti ìrònú ẹran ara. (2 Tímótì 3:1-5; Éfésù 2:2) Ìdí kejì ní í ṣe pẹ̀lú erùpẹ̀ náà fúnra rẹ̀. Bí a kò bá tọ́jú rẹ̀, erùpẹ̀ lè gbẹ táútáú, ó lè le koránkorán, kó má sì lè méso jáde mọ́. Tàbí kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rìn lórí ilẹ̀ ọgbà náà láìbìkítà, kí wọ́n sì wá ki erùpẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni erùpẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ inú ọkàn-àyà wa ṣe rí. Ó lè má lè méso jáde mọ́ bí a bá pa á tì tàbí tí a bá jẹ́ kí àwọn tí kò ní ire wa nípa tẹ̀mí lọ́kàn máa rìn lórí rẹ̀ bó ṣe wù wọ́n.
Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó fún gbogbo wa pé ká fi ìṣílétí Bíbélì yìí sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Òwe 4:23.
Àwọn Ohun Tó Lè Sọ “Erùpẹ̀” Ọkàn-Àyà Wa Di Ilẹ̀ Ọlọ́ràá
Ẹ jẹ́ á gbé àwọn kókó tàbí ànímọ́ díẹ̀ yẹ̀ wò, tó lè sọ “erùpẹ̀” ọkàn-àyà wa di ọlọ́ràá, kí ó bàa lè méso jáde dáradára. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó lè mú kí ọkàn-àyà wa dára sí i, ṣùgbọ́n níhìn-ín, a óò jíròrò mẹ́fà: mímọ àìní wa nípa tẹ̀mí, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, jíjẹ́ olóòótọ́, níní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, àti ìfẹ́.
“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” ni Jésù wí. (Mátíù 5:3) Bí ìgbà tí ebi gidi bá ń pa wá, tó máa ń rán wa létí pé ó yẹ ká jẹun, mímọ àìní wa nípa tẹ̀mí yóò jẹ́ kí ebi jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí máa pa wá. Gẹ́gẹ́ báa ṣe dá wa, irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ máa ń wu àwa ènìyàn jẹ, nítorí pé, ó ń fún ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń jẹ́ kó ní ète. Pákáǹleke látọ̀dọ̀ ètò Sátánì tàbí ṣíṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tó bá di pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lè sọ wá di ẹni tí kò mọ ohun táa ṣaláìní. Àní, Jésù alára sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.
Ní ti gidi, oúnjẹ tí à ń jẹ déédéé, tó dára, tó sì gbámúṣé máa ń fúnni ní ìlera tó jíire, ó sì tún máa ń jẹ́ kí ọ̀fun ẹni máa dá tòó-tòó nígbà tí àkókò oúnjẹ mìíràn bá tó. Bákan náà ló rí nípa tẹ̀mí. O lè má ka ara rẹ sí ẹni tó fẹ́ràn ìwé kíkà, ṣùgbọ́n tóo bá sọ ọ́ dàṣà láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tóo sì ń ka àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì déédéé, wàá rí i pé wọn yóò túbọ̀ máa wù ọ́ kà. Àní, á tilẹ̀ máa ṣe ẹ́ bíi pé kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ti tó. Nítorí náà, má ṣe tètè juwọ́ sílẹ̀; sapá gidigidi láti jẹ́ kí oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé máa wù ọ́ jẹ.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ń Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Rọ̀
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kókó pàtàkì nínú níní ọkàn-àyà táa ti múra sílẹ̀ nítorí pé ó ń sọ wá di ẹni tó ṣeé kọ́, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti tètè gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́. Gbé àpẹẹrẹ rere ti Jòsáyà Ọba yẹ̀ wò. Nígbà tó wà lórí oyè, wọ́n rí ìwé Òfin Ọlọ́run táa fún Mósè. Nígbà tí Jòsáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ Òfin náà, ó wá rí bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣìnà ìjọsìn mímọ́ gaara tó, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó sì sunkún níwájú Jèhófà. Èé ṣe tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wọ ọba náà lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé ọkàn-àyà rẹ̀ “rọ̀,” tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Jèhófà kíyè sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jòsáyà, ó rí i pé ọkàn rẹ̀ kò yigbì, ó sì bù kún un bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.—2 Àwọn Ọba 22:11, 18-20.
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ran àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́, àwọn ‘tí kò mọ̀wé, àwọn gbáàtúù,’ ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì lò ó, èyí tó jẹ́ pé “àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye,” ìyẹn “nípa ti ara” kò mọ̀. (Ìṣe 4:13; Lúùkù 10:21; 1 Kọ́ríńtì 1:26) Àwọn táa mẹ́nu kàn kẹ́yìn wọ̀nyí kò ṣe tán láti gba ọ̀rọ̀ Jèhófà nítorí pé ìgbéraga ti mú kí ọkàn wọn yigbì. Ṣe ẹ wá rí ìdí rẹ̀ tí Jèhófà fi kórìíra ìgbéraga?—Òwe 8:13; Dáníẹ́lì 5:20.
Jíjẹ́ Aláìlábòsí àti Níní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Lọ́kàn
Wòlíì Jeremáyà kọ̀wé pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Onírúurú ọ̀nà ni àdàkàdekè yìí gbà ń fi ara rẹ̀ hàn, bíi ìgbà tí a bá ń wá àwíjàre lẹ́yìn táa ti ṣe ohun tí kò tọ́. Ó tún máa ń fara hàn nígbà tí a kò bá ka àléébù táa ní sí. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ aláìlábòsí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ọkàn-àyà tí ń ṣàdàkàdekè, nípa ríràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni táa jẹ́ gan-an, kí a sì lè sunwọ̀n sí i. Onísáàmù fi irú ẹ̀mí òótọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nígbà tó gbàdúrà pé: “Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò; yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.” Ó ṣe kedere pé, onísáàmù náà ti múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti tẹ́wọ́ gba àtúnṣe àti àyẹ̀wò tí Jèhófà bá ṣe lára òun, kódà bó bá tilẹ̀ jẹ́ pé yóò túmọ̀ sí gbígbà pé òun ní àwọn ìwà tí kò sunwọ̀n, kí òun bàa lè borí wọn.—Sáàmù 17:3; 26:2.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tó wé mọ́ “kíkórìíra ohun búburú,” jẹ́ ohun tó ń ranni lọ́wọ́ gan-an nínú yíyọ́ ara ẹni mọ́. (Òwe 8:13) Ẹni tó níbẹ̀rù Jèhófà lọ́kàn máa ń mọyì inúrere-onífẹ̀ẹ́ àti ìwà rere Jèhófà, ó tún mọ̀ dáadáa pé Jèhófà lè fìyà jẹni, kódà ó lè fikú pa ẹni tó bá ṣàìgbọràn sí i. Jèhófà fi hàn pé àwọn tó bá bẹ̀rù òun yóò ṣègbọràn sí òun nígbà tó sọ nípa Ísírẹ́lì pé: “Kìkì bí wọn yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ nígbà gbogbo, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin!”—Diutarónómì 5:29.
Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń ṣe kì í ṣe láti máa mú wa gbọ̀n jìnnìjìnnì kí a lè tẹrí ba fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó máa ń sún wa láti ṣègbọràn sí Baba wa onífẹ̀ẹ́, ẹni táa mọ̀ pé ó ní ire wa lọ́kàn. Ní tòótọ́, irú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ máa ń gbéni ga, ó ń fúnni láyọ̀, èyí sì ni Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi hàn.—Aísáyà 11:3; Lúùkù 12:5.
Ọkàn-Àyà Táa Múra Sílẹ̀ Máa Ń Nígbàgbọ́ Gan-An
Ọkàn-àyà tó bá ní ìgbàgbọ́ gan-an mọ̀ pé ohunkóhun tí Jèhófà bá béèrè tàbí tó bá pà Aísáyà 48:17, 18) Ẹni tó bá ní irú ọkàn-àyà bẹ́ẹ̀ máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn tó jinlẹ̀ nínú fífi ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Òwe 3:5, 6, sílò, èyí tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Ṣùgbọ́n, ọkàn-àyà tí kò bá ní ìgbàgbọ́, kò ní fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, pàápàá jù lọ bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá wé mọ́ fífi àwọn ohun kan rúbọ, bíi jíjẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni túbọ̀ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì láti lè pọkàn pọ̀ sórí ire Ìjọba náà. (Mátíù 6:33) Abájọ tí Jèhófà fi ka ọkàn-àyà tí kò nígbàgbọ́ sí ọkàn-àyà “burúkú.”—Hébérù 3:12.
láṣẹ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń tọ̀nà, ó sì máa ń jẹ́ fún àǹfààní wa. (Ọ̀pọ̀ ọ̀nà là ń gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, títí kan ohun tí à ń ṣe ní kọ̀rọ̀ yàrá wa. Fún àpẹẹrẹ, ronú lórí ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:7 pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Ìgbàgbọ́ táa bá ní nínú irú ìlànà yìí yóò hàn nínú irú sinimá tí à ń wò, irú ìwé tí à ń kà, báa ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó, yóò sì tún hàn nínú àdúrà wa. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ tó lágbára tó sún wa láti fúnrúgbìn “pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn” jẹ́ kókó pàtàkì nínú níní ọkàn-àyà táa ti múra sílẹ̀ láti tẹ́wọ́ gba Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti láti ṣègbọràn sí i.—Gálátíà 6:8.
Ìfẹ́—Ànímọ́ Tó Tóbi Jù Lọ
Ju gbogbo ànímọ́ yòókù lọ, ìfẹ́ ló ń mú kí ọkàn-àyà wa ṣe tán láti gba Ọ̀rọ̀ Jèhófà wọlé. Nípa báyìí, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fi wé ìgbàgbọ́ àti ìrètí, ó ṣàpèjúwe ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí “èyí tí ó tóbi jù lọ nínú [àwọn ànímọ́ wọ̀nyí].” (1 Kọ́ríńtì 13:13) Ọkàn-àyà tó kún fún ìfẹ́ fún Ọlọ́run máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn tó jinlẹ̀ àti ayọ̀ tó wà nínú ṣíṣe ìgbọràn sí i; kì í sì í bínú sí àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè fún. Àpọ́sítélì Jòhánù wí pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Pẹ̀lú èrò kan náà lọ́kàn, Jésù wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 14:23) Ṣàkíyèsí pé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ bù-fún-mi-n-bù-fún-ọ. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ìfẹ́ bá mú kí wọ́n sún mọ́ ọn.
Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, ó sì mọ̀ pé a máa ń dẹ́ṣẹ̀ sí òun nígbà gbogbo. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò jìnnà sí wa. Ohun tí Jèhófà ń wá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni “ọkàn-àyà pípé pérépéré,” èyí tó ń sún wa láti sìn ín tọkàntọkàn pẹ̀lú “inú dídùn.” (1 Kíróníkà 28:9) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà mọ̀ pé ó ń gba àkókò àti ìsapá ká tó lè ní ànímọ́ rere nínú ọkàn-àyà wa, kí a sì mú èso ti ẹ̀mí jáde. (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, ó ń mú sùúrù fún wa, “nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Nípa fífi irú ìwà bẹ́ẹ̀ hàn, Jésù kò fìgbà kankan ṣe lámèyítọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nítorí àléébù wọn ṣùgbọ́n ó fi sùúrù ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì fún wọn níṣìírí. Ǹjẹ́ irú ìfẹ́, àánú, àti sùúrù tí Jèhófà àti Jésù ní yìí ń sún ọ láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn?—Lúùkù 7:47; 2 Pétérù 3:9.
Bó bá ń ṣòro fún ẹ nígbà mìíràn láti pa àwọn ìwà kan tó ti mọ́ ẹ lára tì, tàbí láti jáwọ́ nínú wọn, ìyẹn ni àwọn ìwà táa lè fi wé èpò, àwọn ìwà tó ti di bárakú, má ṣe banú jẹ́, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, sapá láti rí i pé o sunwọ̀n sí i, kí o “máa ní ìforítì nínú àdúrà,” títí kan bíbẹ Jèhófà nígbà gbogbo fún ẹ̀mí rẹ̀. (Róòmù 12:12) Pẹ̀lú ìrànwọ́ rẹ̀ tó ń fínnúfíndọ̀ ṣe, gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sírà, wàá lè ní ọkàn-àyà táa ti múra sílẹ̀ dáradára “láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àní nígbà tí Ẹ́sírà wà ní Bábílónì ó ń fọkàn sin Ọlọ́run rẹ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Garo Nalbandian