Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́

Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́

Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́

‘TẸ́LẸ̀ rí, mo jẹ́ onínúnibíni tí kò sẹ́ni tó jọ mí lójú,’ èyí ni ohun tí ọkùnrin agbéraga kan tó tún jẹ́ oníjàgídíjàgan tẹ́lẹ̀ rí sọ. Asọ̀rọ̀ òdì gbáà ló jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí, kò lójú àánú, ó ti fìtínà àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, ó sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n o, ó wá sọ̀rọ̀ ìmoore lẹ́nu, ó ní: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi.” Ó lè ya èèyàn lẹ́nu pé ọ̀gbẹ́ni oníbìínú, tó ń ṣe bí ajá dìgbòlugi yìí wá di Kristẹni olùṣòtítọ́ táa mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—1 Tímótì 1:12-16; Ìṣe 9:1-19.

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ṣe irú ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe. Àmọ́, gbogbo wa la ò kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kí ló fà á? Nítorí pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Ní àfikún sí i, ó rọrùn gan-an láti tètè sọ̀rètí nù, ká bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ọ̀ràn wa ti burú ju kí Ọlọ́run ṣíjú àánú wò wá lọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ronú nípa àwọn èrò ibi tó wà lọ́kàn ẹ̀, ó kígbe pé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè tó béèrè yẹn, ó kọ̀wé pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!”—Róòmù 7:24, 25.

Báwo ni Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ olódodo ṣe lè ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀? (Sáàmù 5:4) Ṣàkíyèsí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.” Ẹlòmíì tó rí àánú Ọlọ́run gbà ṣàlàyé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.”—1 Jòhánù 2:1, 2.

Èé ṣe tó fi pe Jésù Kristi ní “olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba”? Báwo sì ni Jésù ṣe jẹ́ “ẹbọ ìpẹ̀tù” fún ẹ̀ṣẹ̀?

Ìdí Táa Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́

Jésù wá sí ayé ‘kí ó lè fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Mátíù 20:28) Ìràpadà ni iye tí a san láti gba ẹnì kan tàbí ohun kan padà, kí wọ́n lè dá onítọ̀hún sílẹ̀ tàbí kí wọ́n lè yọ̀ǹda nǹkan náà. Ọ̀rọ̀ ìṣe tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, “ìràpadà,” ní ìtumọ̀ kí ohun kan kájú ẹ̀ṣẹ̀ kan, tàbí kó tó láti fi ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 78:38) Irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó wà nínú Mátíù 20:28, ni wọ́n lò ní pàtàkì láti fi tọ́ka sí iye tí wọ́n ń san láti fi gba àwọn tí wọ́n kó ní òǹdè lójú ogun sílẹ̀ tàbí láti fi gba àwọn ẹrú sílẹ̀. Láti ṣe ohun tí ìdájọ́ òdodo ń béèrè, a ó fi ohun kan tó bá ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun táa pàdánù ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀.

Àìgbọràn tí ọkùnrin àkọ́kọ́ ṣe sí Ọlọ́run ló sọ aráyé sí oko ẹrú. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta, ọkùnrin pípé yẹn—Ádámù—yàn láti ṣe àìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ta ara rẹ̀ àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tí kò tíì bí sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ádámù wá tipa bẹ́ẹ̀ ba ẹ̀bùn ìwàláàyè ẹ̀dá pípé tiẹ̀ àti ti gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ jẹ́.—Róòmù 5:12, 18, 19; 7:14.

Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run ṣètò pé kí wọ́n máa fi ẹranko ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tàbí kí wọ́n fi kájú rẹ̀. (Léfítíkù 1:4; 4:20, 35) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi ìwàláàyè ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ lélẹ̀ bíi pàṣípààrọ̀ fún ti ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. (Léfítíkù 17:11) Nítorí náà, a tún lè pe “ọjọ́ ètùtù” ní “ọjọ́ ìràpadà.”—Léfítíkù 23:26-28.

Ṣùgbọ́n, nítorí pé ẹranko rẹlẹ̀ sí ènìyàn, “kò ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò [pátápátá].” (Hébérù 10:1-4) Kí ẹbọ tó lè ní ìtóye tó pọ̀ tó láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí tí yóò fi mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá, ìtóye náà gbọ́dọ̀ ṣe déédéé pẹ̀lú ohun tí Ádámù gbé sọ nù. Ìdíwọ̀n òdodo béèrè pé kí ọkùnrin pípé kan (Jésù Kristi) rọ́pò ohun tí ọkùnrin pípé mìíràn (Ádámù) gbé sọ nù lọ́nà tó ṣe rẹ́gí. Ìwàláàyè ẹ̀dá pípé nìkan la lè fi san ohun tí yóò tún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù rà padà kúrò nínú oko ẹrú tí bàbá wọn àkọ́kọ́ tà wọ́n sí. Ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè ni, “ọkàn fún ọkàn.”—Ẹ́kísódù 21:23-25.

Nígbà tí Ádámù ṣẹ̀, tí Ọlọ́run sì dájọ́ ikú fún un, àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò tíì bí ṣì wà ní abẹ́nú rẹ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kú pẹ̀lú rẹ̀. Jésù, ọkùnrin pípé náà, tí í ṣe “Ádámù ìkẹyìn,” fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti má ṣe bímọ, kó sì ní ìdílé. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Nígbà tó kú gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé táa fi rúbọ, àwọn ọmọ tí kò tíì bí ṣì wà ní abẹ́nú rẹ̀. Nítorí náà, a lè sọ pé ìran ènìyàn ọjọ́ iwájú tó wà ní abẹ́nú rẹ̀ kú pẹ̀lú rẹ̀. Lọ́nà ẹ̀tọ́, Jésù ka ìdílé Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ń kú sí ìdílé ara rẹ̀. Kò lo ẹ̀tọ́ tó ní láti bímọ, kó sì ní ìdílé ti ara rẹ̀. Nípa fífi ìwàláàyè ènìyàn pípé rẹ̀ rúbọ, Jésù tún gbogbo aráyé tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù rà padà, kí wọ́n lè di ìdílé Rẹ̀, Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún wọn.—Aísáyà 9:6, 7.

Ẹbọ ìràpadà Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún aráyé onígbọràn láti rí ojú àánú Ọlọ́run, kí wọ́n sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Kò sí ohun mìíràn táa tún lè ṣe ju pé ká máa yin Jèhófà nítorí ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí ìràpadà náà fi hàn, ìràpadà tó jẹ́ pé ohun tó ná òun àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kúrò ní kèrémí. (Jòhánù 3:16) Jésù sì fi hàn pé lóòótọ́ lòún jẹ́ “olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba” nígbà tó jíǹde sí ìwàláàyè lọ́run, tó sì gbé ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún Ọlọ́run ní òkè ọ̀run. a (Hébérù 9:11, 12, 24; 1 Pétérù 3:18) Àmọ́, báwo ni Jésù Kristi ṣe ń fi hàn nísinsìnyí pé òún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ wa ní ọ̀run?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo orí kẹ́rin àti ìkeje ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York Inc., ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìwàláàyè Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé ni iye táa fi ra àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù padà