Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkùnrin Àwòfiṣàpẹẹrẹ Kan Tó Tẹ́wọ́ Gba Ìbáwí

Ọkùnrin Àwòfiṣàpẹẹrẹ Kan Tó Tẹ́wọ́ Gba Ìbáwí

Ọkùnrin Àwòfiṣàpẹẹrẹ Kan Tó Tẹ́wọ́ Gba Ìbáwí

“ÀWỌN Ọ̀nì Ilẹ̀ Zambia Ń Jẹ Ọgbọ̀n Ènìyàn Lóṣù Kan.” Ohun tí ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Áfíríkà sọ lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn nìyẹn. Ohun tí onímọ̀ nípa ẹranko kan, tó máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹranko afàyàfà wọ̀nyí, sọ ni pé, “àwọn ọkùnrin méjìlá ló lè di ọ̀nì kan ṣoṣo mú.” Ìrù rẹ̀ tó mú ju ayùn àti párì rẹ̀ kíkàmàmà mú kí ọ̀nì jẹ́ àkòtagìrì ẹranko!

Ó hàn gbangba pé ọ̀nì ni Ẹlẹ́dàá pè ní “Léfíátánì,” kí ó lè lo “ọba lórí gbogbo ẹranko ẹhànnà ọlọ́lá-ńlá” yìí láti kọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. (Jóòbù 41:1, 34) Èyí ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ sẹ́yìn ní ilẹ̀ Úsì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá ibì kan ní àríwá Arébíà. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣàpèjúwe ẹ̀dá yìí, ó sọ fún Jóòbù pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó ṣàyàgbàǹgbà tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi ru ú sókè. Ta sì ni ẹni tí ó lè kò mí lójú?” (Jóòbù 41:10) Òótọ́ ní o! Táa bá ń bẹ̀rù ọ̀nì lásánlàsàn, ẹ ó rí i pé ó yẹ ká bẹ̀rù àtisọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni tí ó dá a! Jóòbù fi bí òun ṣe mọrírì ẹ̀kọ́ yìí tó hàn nípa jíjẹ́wọ́ àṣìṣe rẹ̀.—Jóòbù 42:1-6.

Nígbà táa bá mẹ́nu kan Jóòbù, a lè rántí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó fi hàn ní ti pé ká fara da àdánwò. (Jákọ́bù 5:11) Láìsí àní-àní, Jèhófà fẹ́ràn Jóòbù, kó tiẹ̀ tó di pé a dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò pàápàá. Lójú Ọlọ́run, ní àkókò yẹn, “kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:8) Ó yẹ kí èyí sún wa láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jóòbù, níwọ̀n bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yòó ti ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí àwa náà ṣe lè mú inú Ọlọ́run dùn.

Ìbátan Rẹ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Ló Fi Ṣáájú

Ọlọ́rọ̀ ni Jóòbù. Yàtọ̀ sí wúrà, ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn, ẹgbẹ̀ẹ́dógún ràkúnmí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹgbẹ̀rún màlúù, àti àwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀ gan-an. (Jóòbù 1:3) Àmọ́, Jèhófà ni Jóòbù gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe ọrọ̀. Ó sọ pé: “Bí mo bá fi wúrà ṣe ìgbọ́kànlé mi, tàbí tí mo sọ fún wúrà pé, ‘Ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi!’ Bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé dúkìá mi pọ̀, àti nítorí pé ọwọ́ mi ti rí àwọn nǹkan púpọ̀ . . . , ìyẹn pẹ̀lú yóò jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́, nítorí èmi ì bá ti sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè.” (Jóòbù 31:24-28) Bíi ti Jóòbù, a gbọ́dọ̀ ka níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run sí ohun tí ó ṣeyebíye gan-an ju àwọn ohun ìní ti ara lọ.

Fífi Àìṣègbè Bá Àwọn Ènìyàn Bíi Tirẹ̀ Lò

Báwo ni Jóòbù ṣe bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò? Ẹ̀rí pé wọ́n rí i ní aláìṣègbè àti ẹni tó ṣeé sún mọ́ fara hàn nínú ọ̀rọ̀ tí Jóòbù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé mo ti máa ń kọ ìdájọ́ ẹrúkùnrin mi, tàbí ti ẹrúbìnrin mi nínú ẹjọ́ wọn lábẹ́ òfin pẹ̀lú mi, nígbà náà, kí ni mo lè ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì béèrè fún ìjíhìn, kí ni mo lè fi dá a lóhùn?” (Jóòbù 31:13, 14) Jóòbù mọyì àánú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àánú hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí mà jẹ́ o, pàápàá fún àwọn tó bá wà ní ipò àbójútó nínú ìjọ Kristẹni! Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú, ẹni tí kì í ṣègbè, àti ẹni tó ṣeé sún mọ́.

Jóòbù tún fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tí kì í ṣe ara agboolé rẹ̀. Nígbà tó ń fi bó ṣe ń ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn hàn, ó sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé mo ti máa ń dá ẹni rírẹlẹ̀ dúró kí wọ́n má ṣe ní inú dídùn, tí mo sì mú kí ojú opó kọṣẹ́, . . . bí mo bá fi ọwọ́ mi síwá-sẹ́yìn lòdì sí ọmọdékùnrin aláìníbaba, nígbà tí mo bá rí i pé a nílò ìrànwọ́ mi ní ẹnubodè, kí ibi palaba èjìká mi já bọ́ kúrò ní èjìká, kí apá mi sì ṣẹ́ kúrò ní egungun apá òkè.” (Jóòbù 31:16-22) Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa gba ti àwọn tí a mọ̀ pé wọn ò rí já jẹ, táa mọ̀ nínú ìjọ wa rò.

Nítorí ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan tó ní sí àwọn èèyàn bíi tirẹ̀, Jóòbù tún fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn àjèjì. Abájọ tó fi sọ pé: “Kò sí àtìpó tí yóò sùn mọ́jú ní òde; ilẹ̀kùn mi ni mo ṣí síhà ipa ọ̀nà.” (Jóòbù 31:32) Àpẹẹrẹ rere mà lèyí jẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí o! Nígbà tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Bíbélì bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ẹ̀mí aájò àlejò táa fi tẹ́wọ́ gbà wọ́n lè mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àmọ́ ṣá o, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn Kristẹni mìíràn náà nílò aájò àlejò táa fìfẹ́ ṣe pẹ̀lú.—1 Pétérù 4:9; 3 Jòhánù 5-8.

Jóòbù ní ẹ̀mí tó dára sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá. Kì í dunnú sí àjálù tó bá dé bá ẹni tí ó kórìíra rẹ̀. (Jóòbù 31:29, 30) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fẹ́ kí òun ṣoore fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti rí nígbà tó ṣe tán láti gbàdúrà fún àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ olùtùnú èké fún un.—Jóòbù 16:2; 42:8, 9; fi wé Mátíù 5:43-48.

Kì í Ṣe Oníṣekúṣe

Jóòbù jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀, kò jẹ́ gba ọkàn-àyà rẹ̀ láyè láti máa fà sí obìnrin mìíràn lọ́nà tí kò bójú mu. Jóòbù sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá? Bí ọkàn-àyà mi bá ti di rírélọ sọ́dọ̀ obìnrin kan, tí mo sì ń lúgọ àní ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé alábàákẹ́gbẹ́ mi, kí aya mi fi ọlọ lọ nǹkan fún ọkùnrin mìíràn, kí àwọn ọkùnrin mìíràn sì kúnlẹ̀ lórí rẹ̀. Nítorí ìyẹn yóò jẹ́ ìwà àìníjàánu, ìyẹn yóò sì jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́.”—Jóòbù 31:1, 9-11.

Jóòbù kò jẹ́ kí ìfẹ́ ìṣekúṣe wọ ọkàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipa ọ̀nà títọ́ ló ń lépa. Abájọ ti Jèhófà Ọlọ́run fi fẹ́ràn ọkùnrin olóòótọ́ yìí, ẹni tó sapá gidigidi láti gbógun ti àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn di oníṣekúṣe!—Mátíù 5:27-30.

Ipò Tẹ̀mí Ìdílé Rẹ̀ Jẹ Ẹ́ Lọ́kàn

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ Jóòbù máa ń ṣètò fún àkànṣe àsè, èyí tí gbogbo àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ máa ń pésẹ̀ sí. Tí àwọn ọjọ́ àsè wọ̀nyí bá sì ti kọjá tán, Jóòbù á wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn gan-an nípa àwọn ọmọ rẹ̀, kó má lọ jẹ́ pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Jèhófà láwọn ọ̀nà kan. Nípa bẹ́ẹ̀ Jóòbù máa ń gbégbèésẹ̀ kíá, nítorí tí ìtàn Ìwé Mímọ́ náà sọ pé: “A sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn ọjọ́ àkànṣe àsè náà bá ti lọ ní àlọyíká, Jóòbù a ránṣẹ́, a sì sọ wọ́n di mímọ́; a sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, a sì rú àwọn ẹbọ sísun ní ìbámu pẹ̀lú iye gbogbo wọn; nítorí, Jóòbù a sọ pé, ‘bóyá àwọn ọmọ mi ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wọn.’” (Jóòbù 1:4, 5) Ẹ wo bí àníyàn tí Jóòbù ní fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ láti ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà, kí wọ́n sì rìn ní ọ̀nà Rẹ̀, ti ní láti wọ̀ wọ́n lọ́kàn tó!

Lónìí, àwọn Kristẹni olórí ìdílé ní láti máa fún àwọn ìdílé wọn nítọ̀ọ́ni látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tímótì 5:8) A sì tún rí i pé ó dára láti máa gbàdúrà fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni.—Róòmù 12:12.

Fífaradà Á Lábẹ́ Ìdánwò Títí Dópin

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń ka Bíbélì ló mọ̀ nípa ìdánwò líle koko tó dé bá Jóòbù. Sátánì Èṣù ti sọ pé tọ́ràn bá dójú ẹ̀ tán, Jóòbù yóò bú Ọlọ́run. Jèhófà fara mọ́ ìpèníjà yìí, kò sì pẹ́ rárá tí Sátánì mú àjálù wá bá Jóòbù. Ó pàdánù gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ̀. Èyí tó wá burú jù ni pé, gbogbo àwọn ọmọ tó bí pátá ló kú. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Sátánì fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀.—Jóòbù, orí kìíní àti ìkejì.

Kí ni àbájáde rẹ̀? Nígbà tí aya rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ láti bú Ọlọ́run, Jóòbù sọ pé: “Bí ọ̀kan nínú àwọn òpònú obìnrin ṣe ń sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sọ̀rọ̀. Àwa ha lè gba kìkì ohun rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kí a má sì gba ohun búburú pẹ̀lú?” Àkọsílẹ̀ Bíbélì náà fi kún un pé: “Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.” (Jóòbù 2:10) Bẹ́ẹ̀ ni, Jóòbù fara dà á títí dé òpin, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú fara da àwọn àdánwò, kí a sì fẹ̀rí hàn pé ojúlówó ìfẹ́ tí a ní fún Jèhófà ló ń mú kí a máa sin Ọlọ́run.—Mátíù 22:36-38.

Fífi Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Gba Ìbáwí

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jóòbù gbà jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, síbẹ̀ kì í ṣe ẹni pípé. Òun alára sọ pé: “Ta ní lè mú ẹni tí ó mọ́ jáde láti inú ẹni tí kò mọ́? Kò sí ẹnì kankan.” (Jóòbù 14:4; Róòmù 5:12) Nítorí náà, nígbà tí Ọlọ́run sọ pé Jóòbù jẹ́ aláìlẹ́bi, òótọ́ ọ̀rọ̀ ni, ní ti pé ó ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run retí lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Ẹ wo bí èyí ṣe fúnni níṣìírí tó!

Jóòbù fara da àdánwò rẹ̀, àmọ́, ó gbé àbùkù kan yọ. Bí wọ́n ṣe gbọ́ nípa àjálù kan tó dé bá a làwọn mẹ́ta kan tí wọ́n pe ara wọn ní olùtùnú ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. (Jóòbù 2:11-13) Wọ́n ní Jèhófà ń fìyà jẹ Jóòbù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó ti dá. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, àwọn ẹ̀sùn èké wọ̀nyí bí Jóòbù nínú gan-an, ó sì sapá gidigidi láti gbèjà ara rẹ̀. Àmọ́, ó wá kí àṣejù bọ̀rọ̀ náà níbi tó ti ń gbìyànjú àtiṣàlàyé ara rẹ̀. Họ́wù, àní Jóòbù tiẹ̀ sọ̀rọ̀ bi ẹni pé òun jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run pàápàá lọ!—Jóòbù 35:2, 3.

Nítorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ Jóòbù, Ó lo ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti fi àṣìṣe Jóòbù hàn án. Ìtàn náà sọ pé: “Ìbínú Élíhù . . . wá gbóná. Ìbínú rẹ̀ ru sí Jóòbù lórí pípolongo tí ó polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Élíhù kíyè sí: “Jóòbù wí pé, ‘Dájúdájú mo jàre, Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti yí ìdájọ́ mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.’” (Jóòbù 32:2; 34:5) Síbẹ̀síbẹ̀, Élíhù ò ṣe bíi ti àwọn “olùtùnú” mẹ́ta yẹn rárá, kò dórí ìparí èrò tó lòdì, kó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé Ọlọ́run ń fìyà jẹ Jóòbù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Dípò ìyẹn, Élíhù sọ bí òun ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìṣòtítọ́ Jóòbù jáde, ó sì kìlọ̀ fún un pé: “Ẹjọ́ ń bẹ níwájú [Jèhófà], nítorí náà kí o fi tàníyàn-tàníyàn dúró dè é.” Ká sòótọ́, ńṣe ló yẹ kí Jóòbù dúró de Jèhófà dípò tó fi ń fìbínú gbèjà ara rẹ̀. Élíhù wá mú un dá Jóòbù lójú pé: “[Ọlọ́run] kì yóò fi ojú kékeré wo ìdájọ́ òdodo àti ọ̀pọ̀ yanturu òdodo.”—Jóòbù 35:14; 37:23.

Èrò inú Jóòbù ń wá àtúnṣe. Nítorí náà, Jèhófà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ kan, ó jẹ́ kó mọ bí ènìyàn ṣe kéré tó tí a bá fi wéra pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe tóbi lọ́lá tó. Jèhófà tọ́ka sí ilẹ̀ ayé, òkun, àwọn ọ̀run, àwọn ẹranko, àti ọ̀pọ̀ àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá mìíràn. Níkẹyìn, Ọlọ́run wá sọ̀rọ̀ nípa Léfíátánì—ọ̀nì. Jóòbù fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí, nípa ṣíṣe èyí, ó tún fún wa ní àpẹẹrẹ kan láti tẹ̀ lé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, síbẹ̀, a ó ṣe àṣìṣe. Bí àṣìṣe kan bá nípọn, Jèhófà lè lo àwọn ọ̀nà kan láti bá wa wí. (Òwe 3:11, 12) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó gún ẹ̀rí ọkàn wa ní kẹ́ṣẹ́ lè wá sí wa lọ́kàn. Ilé Ìṣọ́ tàbí àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde lè sọ àwọn nǹkan kan tó lè jẹ́ ká mọ ibi táa ti kùnà. Ó sì tún lè jẹ́ pé Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan ló máa rọra tọ́ka síbi táa ti kùnà láti fi ìlànà Bíbélì sílò. Irú ẹ̀mí wo la ó fi hàn sí irú ìbáwí bẹ́ẹ̀? Jóòbù fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn, ó ní: “Mo yíhùn padà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.” —Jóòbù 42:6.

Jèhófà San Èrè fún Un

Jèhófà san èrè fún Jóòbù, ó jẹ́ kí ìránṣẹ́ òun wà láàyè fún ogóje ọdún sí i. Ohun tó rí gbà láàárín àkókò yẹn sì pọ̀ gan-an ju gbogbo ohun tó pàdánù tẹ́lẹ̀ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kú níkẹyìn, ó dájú pé yóò ní àjíǹde sínú ayé tuntun ti Ọlọ́run.—Jóòbù 42:12-17; Ìsíkíẹ́lì 14:14; Jòhánù 5:28, 29; 2 Pétérù 3:13.

Àwa náà lè ní ìdánilójú pé a óò rí ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún rẹ̀ gbà táa bá fi ìdúróṣinṣin sìn ín, táa sì tẹ́wọ́ gba gbogbo ìbáwí táa bá fún wa láti inú Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò ní ìrètí tó dájú pé a óò gbé nínú ètò àwọn nǹkan titun ti Ọlọ́run. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ó bọlá fún Ọlọ́run. A óò rí èrè ìwà títọ́ wa gbà, ìyẹn yóò sì wà lára ẹ̀rí tó fi hàn pé kì í ṣe tìtorí ìmọtara-ẹni-nìkan làwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe ń sìn ín, bí kò ṣe nítorí ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n ní sí i. Àǹfààní ńlá ni yóò mà jẹ́ fún wa o, táa bá lè mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀, bí Jóòbù olóòótọ́ ti ṣe, tó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí!—Òwe 27:11.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Jóòbù fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó, àtàwọn mìíràn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

A san èrè gọbọi fún Jóòbù, nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó fi gba ìbáwí