Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa

Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa

Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa

“Ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán.”—SÁÀMÙ 27:11.

1, 2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ̀ lóde òní? (b) Kí ni lílo gbogbo àǹfààní tó wà nínú àwọn ìpàdé wa wé mọ́?

 JÈHÓFÀ ni Orísun ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́, gẹ́gẹ́ báa ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa báa ti ń rìnrìn àjò lọ ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán. Jèhófà ń ṣamọ̀nà wa nípa fífún wa ní ìtọ́ni ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Sáàmù 119:105) Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù ìgbàanì, pẹ̀lú ọkàn ìmoore la fi gbà pé kí Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà wa, tí a sì ń gbàdúrà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rẹ, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán.”—Sáàmù 27:11.

2 Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń pèsè ìtọ́ni lónìí ni nípasẹ̀ àwọn ìpàdé Kristẹni. Ǹjẹ́ a ń lo gbogbo àǹfààní ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí nípa (1) wíwá sí ìpàdé déédéé, (2) títẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, àti (3) ṣíṣetán láti lọ́wọ́ nínú àwọn apá tó kan àwùjọ? Láfikún sí i, ǹjẹ́ a ń fi ìmoore hàn nígbà táa bá fún wa nímọ̀ràn tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dúró “ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán”?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Lọ Sípàdé Déédéé?

3. Báwo ni òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ṣe mú ìwà rere ti wíwá sí ìpàdé déédéé dàgbà?

3 Láti ìgbà táwọn akéde Ìjọba kan ti wà lọ́mọdé ni wọ́n ti ń wá sípàdé déédéé. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rántí pé: “Nígbà témi àtẹ̀gbọ́n mi ṣì kéré ní àwọn ọdún 1930, a kìí béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí wa bóyá a máa lọ sípàdé. A mọ̀ pé dandan ni, àyàfi tí ara wa ò bá yá. Ìdílé wa kì í sì í pa ìpàdé jẹ.” Gẹ́gẹ́ bíi ti Ánà, wòlíì obìnrin nì, arábìnrin yìí ‘kì í pa wíwà ní ibi ìjọsìn Jèhófà jẹ.’—Lúùkù 2:36, 37.

4-6. (a) Èé ṣe tí àwọn akéde Ìjọba kan fi máa ń pa ìpàdé jẹ? (b) Èé ṣe tí wíwá sí ìpàdé fi di dandan gbọ̀n?

4 Ǹjẹ́ o wà lára àwọn tó máa ń wá sípàdé Kristẹni déédéé, àbóo ti di ẹni tí a kì í sábà rí nípàdé? Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n rò pé àwọn ń ṣe dáadáa gan-an ti pinnu láti yẹra wọn wò fínnífínní. Fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọ́n ń kọ iye ìpàdé tí wọ́n ń wá sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n wá yẹ àkọsílẹ̀ náà wò lẹ́yìn sáà kan, ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí iye ìpàdé tí wọ́n ti pa jẹ.

5 Ẹnì kan lè sọ pé, ‘Ìyẹn ò mà jẹ́ bàbàrà o. Wàhálà táwọn èèyàn ń rún mọ́ra lónìí ò mà kéré, òun ni ò mà jẹ́ kó rọrùn láti máa wá sípàdé déédéé.’ Òótọ́ ni pé, àkókò oníwàhálà là ń gbé yìí. Òmíràn tún ni pé, kàkà kéwé àgbọn dẹ̀, líle ni yóò máa le sí i lọ̀ràn ilé ayé ọ̀hún. (2 Tímótì 3:13) Ṣùgbọ́n ṣé ìyẹn gan-an ò wá sọ wíwá sí ìpàdé déédéé di dandan gbọ̀n? Tí a ò bá jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé kánú déédéé láti gbé wa ró, a ò lè kojú wàhálà tí ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí ń mú wá. Áà, bí a ò bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé, a mà lè dán wa wò láti pa “ipa ọ̀nà àwọn olódodo” tì pátápátá! (Òwe 4:18) Lóòótọ́, nígbà táa bá padà sílé lẹ́yìn táa ti ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ tó ti rẹ̀ wá, ìpàdé lè má wù wáá lọ. Ṣùgbọ́n, táa bá gbìyànjú, táa lọ, bó ti wù kó rẹ̀ wá tó, a ó jàǹfààní, a ó sì fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba níṣìírí.

6 Hébérù orí kẹwàá, ẹsẹ ìkẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tún sọ ìdí mìíràn táa fi ní láti máa wá sípàdé déédéé. Níbẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí pé kí wọ́n máa péjọ pọ̀ ‘pàápàá jù lọ bí wọ́n ti ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé “ọjọ́ Jèhófà” ti sún mọ́lé. (2 Pétérù 3:12) Báa bá parí èrò sí pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣì jìnnà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ kí àwọn ìlépa ti ara bo àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó pọndandan mọ́lẹ̀, irú bíi wíwá sípàdé. Nígbà náà, Jésù kìlọ̀ pé, ‘lójijì ọjọ́ yẹn yóò dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn.’—Lúùkù 21:34.

Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa

7. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ máa fiyè sí nǹkan táa bá ń sọ nínú ìpàdé?

7 Ká kàn máa wá sípàdé nìkan kò tó. A gbọ́dọ̀ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, ká fiyè sí nǹkan tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. (Òwe 7:24) Èyí kan àwọn ọmọ wa pẹ̀lú. Tí ọmọ kan bá lọ sílé ìwé, a retí pé kó fiyè sí ohun tí olùkọ́ ń sọ, kódà nígbà tí kókó ẹ̀kọ́ náà kò bá wù ú tàbí tó bá dà bíi pé kò yé e. Olùkọ́ mọ̀ pé bí ọmọ náà bá ń gbìyànjú láti fiyè sí nǹkan tí òun ń kọ́ ọ, yóò jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ náà, bó ti wù ó mọ. Nígbà náà, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn ọmọ tí wọ́n ti tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ máa fiyè sí ìtọ́ni tí a bá ń pèsè láwọn ìpàdé Kristẹni kàkà tí a ó fi yọ̀ǹda kí wọ́n máa sùn nígbà típàdé bá ti bẹ̀rẹ̀? Lóòótọ́, “àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye” wà lára àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (2 Pétérù 3:16) Ṣùgbọ́n kò yẹ ká fojú kéré agbára tí ọmọdé kan ní láti kẹ́kọ̀ọ́. Ọlọ́run kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí à ń kọ Bíbélì, ó pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ èwe láti ‘fetí sílẹ̀ àti láti bẹ̀rù Jèhófà, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin rẹ̀ ṣẹ,’ èyí tó sì dájú pé àwọn kan lára rẹ̀ ṣòro fún àwọn ọmọdé láti lóye. (Diutarónómì 31:12; fi wé Léfítíkù 18:1-30.) Lónìí ńkọ́, ǹjẹ́ ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé yàtọ̀?

8. Kí làwọn ìgbésẹ̀ táwọn òbí kan ń gbé láti ran àwọn ọmọ wọ́n lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ nípàdé?

8 Àwọn Kristẹni òbí mọ̀ pé ohun tí àwọn ọmọ wọn ń kọ́ nínú ìpàdé wà lára báa ṣe ń pèsè fún àìní wọn nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, àwọn òbí kan máa ń ṣètò pé kí àwọn ọmọ wọn sùn díẹ̀ ṣáájú ìpàdé, kí ara bàa lè tù wọ́n nígbà tí wọ́n bá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n sì ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn òbí kan lè dìídì díwọ̀n àkókò táwọn ọmọ wọn yóò fi máa wo tẹlifíṣọ̀n ní alẹ́ ọjọ́ tí ìpàdé ku ọ̀la tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fọgbọ́n sọ pé kò sáyè fún tẹlifíṣọ̀n wíwò lọ́jọ́ yẹn. (Éfésù 5:15, 16) Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń dín ohun tó lè pín ọkàn àwọn ọmọ wọn níyà kù, wọ́n ń fún wọn níṣìírí láti máa fetí sílẹ̀, láti máa kẹ́kọ̀ọ́, níbi tí ọjọ́ orí wọn àti òye wọn bá mọ.—Òwe 8:32.

9. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ànímọ́ ìfetísílẹ̀ dàgbà?

9 Àwọn àgbàlagbà ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó wí pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Lóde òní, ẹnu dùn-ún ròfọ́, agada ọwọ́ ṣeé bẹ́ gẹdú ní ọ̀rọ̀ yìí. Ká sòótọ́, iṣẹ́ tó lágbára ni kéèyàn ó fetí sílẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n a lè mú ànímọ́ ìfetísílẹ̀ dàgbà. Bóo bá ń fetí sí àsọyé Bíbélì tàbí apá kan nínú ìpàdé, gbìyànjú láti fa àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ náà yọ. Máa rò ó lọ́kàn rẹ pé, kí ni olùbánisọ̀rọ̀ náà fẹ́ sọ lẹ́yìn èyí tó ń sọ lọ́wọ́. Kíyè sí àwọn kókó tó lè wúlò fún ọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ tàbí nínú ìgbésí ayé rẹ. Bí o ti ń gbé àwọn kókó náà yẹ̀ wò, máa fọpọlọ ronú lé wọn lórí. Gbìyànjú láti kọ nǹkan díẹ̀ sílẹ̀.

10, 11. Báwo ni àwọn òbí kan ṣe ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó túbọ̀ ń fetí sílẹ̀, àwọn ọgbọ́n wo lo ti dá tó o rí i pé ó ṣèrànwọ́?

10 Ìgbà téèyàn bá wà lọ́mọdé ló rọrùn jù lọ láti kọ́ báa ṣe ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Kódà kó tó di pé wọ́n ń kọ́ bí wọn yóò ṣe mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, àwọn òbí máa fún àwọn ọmọ wọn tí wọn ń lọ jẹ́lé-ó-sinmi níṣìírí láti “kọ nǹkan sílẹ̀” nígbà típàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ táa pe ọ̀rọ̀ tí wọ́n mọ̀ dáadáa bí “Jèhófà,” “Jésù,” tàbí “Ìjọba,” wọ́n á sàmì sórí bébà. Lọ́nà yìí, àwọn ọmọ lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n ń sọ látorí pèpéle.

11 Kódà àwọn ọmọ tó ti dàgbà pàápàá nílò ìṣírí kí wọ́n lè máa pọkàn pọ̀. Nígbà tí olórí ìdílé kan ṣàkíyèsí pé ọmọ òun, ọmọ ọdún mọ́kànlá kò fọkàn sí ohun tí wọ́n ń sọ nígbà àpéjọpọ̀ Kristẹni kan, ó fún ọmọ náà ní Bíbélì kan, ó ní kó máa ṣí i, bí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ bá ti ń pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Baba náà, tí òun pẹ̀lú ń kọ nǹkan sílẹ̀, ń wo ọmọ rẹ̀ bó ṣe ń ṣí Bíbélì náà. Lẹ́yìn èyí, ọmọ náà fi gbogbo ara fọkàn sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà.

Jẹ́ Ká Gbọ́ Ohùn Rẹ

12, 13. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti kópa nínú kíkọrin nínú ìjọ?

12 Dáfídì Ọba kọrin pé: “Èmi yóò rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà, láti mú kí a gbọ́ ohùn ìdúpẹ́ lọ́nà tí ó dún sókè.” (Sáàmù 26:6, 7) Ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pèsè àǹfààní tó dára fún wa láti sọ ìgbàgbọ́ wa jáde ketekete. Ọ̀nà kan táa lè gbà ṣe èyí ni ká máa kópa nínú orin kíkọ nínú ìjọ. Èyí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa, ṣùgbọ́n ó rọrùn láti gbójú fò ó dá.

13 Àwọn ọmọ kan tí wọn ò tíì mọ̀wéé kà máa ń há àwọn orin Ìjọba tí a ó kọ ní àwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sórí. Inú wọn máa ń dùn bí wọ́n ti ń bá àwọn àgbàlagbà kọrin pọ̀. Ṣùgbọ́n, bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà, kíkọrin Ìjọba lè má fi bẹ́ẹ̀ wù wọ́n mọ́. Àwọn àgbàlagbà mìíràn gan-an máa ń tijú láti kọrin nípàdé. Síbẹ̀, orin jẹ́ apá kan ìjọsìn wa, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ti jẹ́ apá kan ìjọsìn wa. (Éfésù 5:19) À ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti yin Jèhófà lógo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ṣé a ò wá lè gbé ohùn wá sókè láti fògo fún un nípa kíkọ orin ìyìn ni, yálà a lóhùn tó dùn tàbí ohùn gẹ̀dẹ̀gbẹ̀?—Hébérù 13:15.

14. Èé ṣe tó fi ń béèrè pé ká múra ohun tí a ó kọ nínú ìpàdé ìjọ sílẹ̀ dáadáa?

14 A tún ń mú ìyìn wá fún Ọlọ́run nígbà táa bá sọ̀rọ̀ tó gbéni ró lákòókò tí apá tí àwùjọ lè lóhùn sí bá ń lọ lọ́wọ́ láwọn ìpàdé wa. Àmọ́, èyí ń béèrè pé ká ti múra sílẹ̀. Ó ń gba àkókò ká tó lè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lójú méjèèjì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!” (Róòmù 11:33) Ẹ̀yin olórí ìdílé, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ọgbọ́n Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti fi hàn. Ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó takókó, kí o sì ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìpàdé.

15. Àwọn àbá wo ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti dáhùn ní ìpàdé?

15 Bóo bá fẹ́ máa dáhùn nípàdé déédéé, èé ṣe tóò fi múra ohun tóo fẹ́ sọ sílẹ̀? Kò pọndandan pé kóo sọ̀rọ̀ púpọ̀. Ká ní ẹsẹ Bíbélì kan lo kà dáadáa tàbí ọ̀rọ̀ díẹ̀ tóo kó jọ dáadáa ló sọ látọkànwá, a ó mọrírì rẹ̀. Àwọn akéde kan tiẹ̀ máa ń sọ fún olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ pé kó pe àwọn láti dáhùn ìpínrọ̀ kan pàtó, kí wọn má bàa pàdánù àǹfààní náà láti sọ ìgbàgbọ́ wọn jáde.

Àwọn Aláìnírìírí Yóò Di Ọlọgbọ́n

16, 17. Ìmọ̀ràn wo ni alàgbà kan fún ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, èé sì ti ṣe tó fi gbéṣẹ́?

16 Nínú ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sábà máa ń rán wa létí pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ń tuni lára. Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, láti ṣàtúnṣe sí àwọn àléébù táa ní, láti dènà àwọn àdánwò, láti tún padà dúró gbọn-in nípa tẹ̀mí bó bá jẹ́ pé a ti ṣi ẹsẹ̀ gbé nígbà kan.—Sáàmù 19:7.

17 Àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n nírìírí máa ń wà ní sẹpẹ́ láti pèsè ìmọ̀ràn táa gbé ka Ìwé Mímọ́, èyí tó lè yanjú àwọn àìní wa. Gbogbo ohun táa ní láti ṣe kò ju pé ká “fà á jáde,” nípa wíwá àwọn ìmọ̀ràn wọn tí wọ́n ń gbé ka Bíbélì. (Òwe 20:5) Lọ́jọ́ kan, ọ̀dọ́ onítara kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ béèrè lọ́wọ́ alàgbà kan pé kó fóun nímọ̀ràn lórí ohun tí òun lè ṣe láti túbọ̀ wúlò nínú ìjọ. Alàgbà náà, tó mọ ọ̀dọ́mọkùnrin náà dáadáa, ṣí Bíbélì rẹ̀ sí 1 Tímótì 3:3, èyí tó sọ pé àwọn ọkùnrin táa yàn sípò gbọ́dọ̀ jẹ́ “afòyebánilò.” Ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé fún ọmọkùnrin yìí, ọ̀nà tó lè gbà máa fi òye bá àwọn ènìyàn lò. Ǹjẹ́ arákùnrin ọ̀dọ́ yìí gbaná jẹ nítorí ìmọ̀ràn tí a kò fi bọpo bọyọ̀ tó rí gbà yìí? Rárá o! Ó ṣàlàyé pé: “Bíbélì ni alàgbà náà lò, nítorí náà, mo gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìmọ̀ràn náà ti wá.” Nítorí tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà moore, ó fi ìmọ̀ràn náà sílò, ó sì tẹ̀ síwájú dáradára.

18. (a) Kí ló ran Kristẹni ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti dènà àdánwò ní ilé ẹ̀kọ́? (b) Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tóo bá dojú kọ àdánwò?

18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún lè ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tímótì 2:22) Ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ìwé mẹ́wàá dènà àdánwò jálẹ̀ gbogbo àkókò tó fi wà nílé ẹ̀kọ́ nípa ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan pàtó àti fífi wọ́n sílò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ronú nípa ìmọ̀ràn táa kọ sínú Òwe orí kẹtàlá, ẹsẹ ogún pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó lo ìṣọ́ra débi pé kìkì àwọn tó bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ló ń bá rìn. Ó ronú lọ́kàn rẹ̀ pé: “Kò sí nǹkan tí mo fi dáa ju àwọn ẹlòmíì lọ. Bí mo bá lọ kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, màá fẹ́ máa ṣe ohun táwọn ọ̀rẹ́ mi fẹ́, ìyẹn sì lè kó mi sí wàhálà.” Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù táa kọ sínú 2 Tímótì 1:8 tún ràn ọ̀dọ́mọbìnrin náà lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Má tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa, . . . ṣùgbọ́n kó ipa tìrẹ nínú jíjìyà ibi fún ìhìn rere.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn yẹn, ó fi tìgboyàtìgboyà sọ àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ táa gbé ka Bíbélì fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Nígbàkigbà tí wọ́n bá ti ní kó wá bá àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀, yóò yan kókó ẹ̀kọ́ kan tó yọ̀ǹda fún un láti fi ọgbọ́n jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run.

19. Èé ṣe tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan kò fi lè dènà pákáǹleke tó wà nínú ayé yìí, ṣùgbọ́n kí ló fún un lókun nípa tẹ̀mí?

19 Táa bá tiẹ̀ fẹ́ ṣáko lọ́ kúrò “ní ipa ọ̀nà àwọn olódodo,” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti tọ́ ìṣísẹ̀ wa sọ́nà. (Òwe 4:18) Èyí ni ohun tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń gbé ní Áfíríkà kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní tààràtà. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀ ẹ́ wò, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó gbádùn ohun tó ń kọ́, ṣùgbọ́n kò pẹ́ púpọ̀ tó fi wọnú ẹgbẹ́ búburú nílé ìwé. Kò pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n fi kó ṣíṣe ìṣekúṣe ràn án. Ó sọ pé: “Ẹ̀rí-ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí dààmú mi, ni mo bá pa ìpàdé tì, tí n ò lọ mọ́.” Nígbà tó tún yá, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ àṣírí yìí: “Mo rí i pé olórí ohun tó fa gbogbo èyí ni pé ebi tẹ̀mí pa mí. N kì í dá kẹ́kọ̀ọ́. Ìdí nìyẹn tí n kò fi lè borí àdánwò yẹn. Lẹ́yìn náà mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Díẹ̀díẹ̀, mo padà di alágbára nípa tẹ̀mí, mo sì tún ìgbésí ayé mi ṣe. Èyí sì jẹ́ ẹ̀rí tó dáa fáwọn tó kíyè sí àwọn ìyípadà tí mo ṣe. Mo ṣèrìbọmi, nísinsìnyí, mo láyọ̀.” Kí ló fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí lókun láti borí àìlera rẹ̀? Ó padà di alágbára nípa tẹ̀mí nípa dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

20. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè dènà ogun Sátánì?

20 Ẹ̀yin èwe Kristẹni, ogun gidi lẹ dojú kọ lónìí o! Bẹ́ẹ bá fẹ́ dènà ogun Sátánì, ẹ gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé. Ó dájú pé onísáàmù náà, tóun náà jẹ́ ọ̀dọ́ mọ èyí dáadáa. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún pípèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí ‘ọ̀dọ́mọkùnrin lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.’—Sáàmù 119:9.

Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Bá Darí Wa Sí, Ibẹ̀ La Ó Gbà

21, 22. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé ọ̀nà òtítọ́ ti nira jù?

21 Jèhófà kó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ó mú wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Lójú èèyàn, ọ̀nà tó yàn láti gbà ti lè dà bí èyí tó jìnnà jù. Dípò tí Jèhófà yóò fi mú wọn gba ọ̀nà tó yá jù, ọ̀nà tó ṣe tààrà, tó gba Òkun Mẹditaréníà kọjá, ó mú wọn gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ, ọ̀nà tó ṣòro láti gbà. Àmọ́ ṣá o, inú rere ni Ọlọ́run fi hàn sí wọn pẹ̀lú ohun tó ṣe yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà òkun ló yá jù, ilẹ̀ àwọn Filísínì oníkanra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá gbà kọjá. Yíyàn tí Jèhófà yan ọ̀nà mìíràn ni kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn Filísínì ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn.

22 Bákan náà, ọ̀nà tí Jèhófà ń mú wa gbà lónìí lè dà bí èyí tó ṣòro nígbà mìíràn. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ là ń ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó kún fọ́fọ́ fún àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni, títí kan àwọn ìpàdé ìjọ, ìdákẹ́kọ̀ọ́, àti iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó lè jọ pé àwọn ọ̀nà mìíràn rọrùn. Ṣùgbọ́n o, àyàfi táa bá tẹ̀ lé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń darí wa la fi lè dé ibi tí à ń fi torítọrùn ṣiṣẹ́ láti dé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti gba ìtọ́ni pàtàkì látọ̀dọ̀ Jèhófà, ká sì wà ní “ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán” títí láé!—Sáàmù 27:11.

Ṣé O Lè Ṣàlàyé?

Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká mú wíwá sí ìpàdé Kristẹni déédéé ní ọ̀kúnkúndùn?

Kí làwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ nínú ìpàdé?

Kí ni fífetísílẹ̀ dáadáa wé mọ́?

Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn láwọn ìpàdé?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi ìyìn fún Jèhófà láwọn ìpàdé Kristẹni