Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀ Nípa Ìrètí Kristẹni ní Senegal

Bíbá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀ Nípa Ìrètí Kristẹni ní Senegal

Àwa Jẹ́ Irú Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́

Bíbá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀ Nípa Ìrètí Kristẹni ní Senegal

LÁTI ìgbà láéláé ni ẹja ti jẹ́ oúnjẹ gidi fún ènìyàn. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn èèyàn ti ń pẹja nínú àwọn òkun ilẹ̀ ayé, àwọn adágún omi, àtàwọn odò. Àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi jẹ́ apẹja nínú Òkun Gálílì. Àmọ́, Jésù wá nawọ́ pípa oríṣi ẹja mìíràn sí wọn. Èyí jẹ́ pípa ẹja nípa tẹ̀mí tó jẹ́ pé kì í ṣe apẹja nìkan ló máa ṣe láǹfààní ṣùgbọ́n yóò tún ṣe ẹja náà láǹfààní pẹ̀lú.

Nítorí ìdí èyí, Jésù sọ fún Pétérù tó jẹ́ apẹja pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:10) Irú ẹja pípa yìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lónìí ní ohun tó lé ní ọgbọ̀nlénígba ilẹ̀, títí kan Senegal. (Mátíù 24:14) Níhìn-ín làwọn “apẹja ènìyàn” tòde òní ti ń fi tìgboyàtìgboyà sọ ìrètí Kristẹni wọn fún àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 4:19.

Ṣóńṣó ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni Senegal wà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbègbè aṣálẹ̀ oníyẹ̀pẹ̀ tó bá Sàhárà pààlà ní ìhà àríwá títí dé igbó títutù rinrin ti àgbègbè Casamance ní ìhà gúúsù. Senegal jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ẹ̀fúùfù aṣálẹ̀ máa ń gbá mọ́ tónítóní, tó sì tún ń gbádùn atẹ́gùn títutù tó ń tuni lára, èyí tó ń wá láti Àtìláńtíìkì. Àwọn ènìyàn tó ń gbé ibí yìí lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án. A mọ àwọn ará Senegal mọ aájò àlejò. Ọ̀pọ̀ lára wọn ní kì í ṣe Kristẹni. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, nígbà táwọn mìíràn jẹ́ darandaran, tó máa ń kó màlúù, ràkúnmí àtàwọn ewúrẹ́ jẹ̀. Àwọn àgbẹ̀ náà tún wà lára wọn, àwọn tí wọ́n máa ń ṣọ̀gbìn ẹ̀pà, òwú, àti ìrẹsì. Bẹ́ẹ̀ làwọn apẹja tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú, àwọn tí wọ́n máa ń kó ẹja kún inú àwọ̀n wọn láti Òkun Àtìláńtíìkì àti láti àwọn onírúurú odò ńlá tó yí orílẹ̀-èdè náà ká. Ipa tí ilé iṣẹ́ ẹja tó wà níbẹ̀ ń kó nínú ètò ọrọ̀ ajé Senegal kò kéré. Àní oúnjẹ tó gbayì jù níbẹ̀ ni ceebu jën, oúnjẹ aládùn kan tó jẹ́ àsèpọ̀ ìrẹsì, ẹja, àti ẹ̀fọ́.

“Apẹja Ènìyàn”

Àwọn ẹgbẹ̀rin àti mẹ́tàlélọ́gọ́ta [863] ènìyàn tó ń fìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run ló wà ní Senegal. Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950 ni ẹja pípa nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ níhìn-ín. A ṣí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society kan sí Dakar, tó jẹ́ olú ìlú náà ní ọdún 1965. Àwọn míṣọ́nnárì, ìyẹn àwọn “apẹja” bẹ̀rẹ̀ sí í dé láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré. Bí iṣẹ́ “ẹja pípa” ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, tí bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Kristẹni sì ń tẹ̀ síwájú láìdabọ̀ ní Senegal. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a kọ́ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tuntun sí Almadies, tó wà ní ẹ̀yìn ìlú Dakar, a sì yà á sí mímọ́ fún Jèhófà ní June 1999. Áà, ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà!

Ìpèníjà Títẹ́wọ́ Gba Òtítọ́

Onírúurú èèyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀ síra la máa ń kàn sí déédéé, àwọn kan lára wọn sì ti fi ẹ̀mí tó dára hàn sí ìhìn iṣẹ́ tó ń fúnni ní ìrètí táa rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ò nímọ̀ Bíbélì, wọ́n láyọ̀ láti gbọ́ pé àwọn ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún àwọn wòlíì olóòótọ́ ìgbàanì kò ní pẹ́ ní ìmúṣẹ.

Ó sábà máa ń gba ìgboyà láti dúró ti àwọn ìlànà Kristẹni láìyẹsẹ̀, pàápàá nígbà tí ọ̀rọ̀ àṣà ìdílé àti ti ìbílẹ̀ bá wọ̀ ọ́. Fún àpẹẹrẹ, àṣà ìkóbìnrinjọ gbalẹ̀ gan-an ní Senegal. Gbé ọ̀ràn ọkùnrin kan yẹ̀ wò, ẹni tó ní ìyàwó méjì nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ ó lè nígboyà láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Kristẹni, kó sì fara mọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún láti jẹ́ ọkọ aya kan? (1 Tímótì 3:2) Ṣe yóò lè mú aya ìgbà èwe rẹ̀, ìyẹn ni obìnrin tó kọ́kọ́ fẹ́? Ohun tó ṣe gan-an nìyẹn, ó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tó nítara ní ọ̀kan lára àwọn ìjọ ńlá tó wà ní àgbègbè Dakar báyìí. Ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjìlá ló ti gba òtítọ́ báyìí, ìyàwó rẹ̀ àgbà ló bí mẹ́wàá lára àwọn ọmọ náà fún un, méjì sì jẹ́ látọ̀dọ̀ ìyàwó kejì tó fẹ́ tẹ́lẹ̀.

Ìdènà mìíràn tí kì í jẹ́ kó rọrùn láti tẹ́wọ́ gba ìrètí Kristẹni tún lè jẹ́ àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ṣe ó wá túmọ̀ sí pé ẹnì kan tí kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ò lè gba òtítọ́ kó sì máa ṣe ohun tó béèrè ni? Rárá o, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ Marie yẹ̀ wò, ìyá ọlọ́mọ mẹ́jọ, tó sì jẹ́ alákitiyan. Kíá ló rí i pé ó ṣe pàtàkì fún òun láti jíròrò ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọmọ òun lójoojúmọ́ kí wọ́n tó lọ sílé ìwé àti kóun náà tó lọ síbi iṣẹ́. Àmọ́, ọ̀nà wo ni yóò wá gbé e gbà nígbà tí ò mọ̀wé kà? Tó bá ti jí láàárọ̀ kùtù hàì, á mú ìwé kékeré Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ lọ́wọ́, yóò wá dúró sójú pópó eléruku tó gba iwájú ilé rẹ̀ kọjá. Bó bá ti rí àwọn èèyàn tó ń kọjá, yóò béèrè bí wọ́n bá mọ̀wé kà. Nígbà tó bá rẹ́nì kan tó lè kàwé, a mú ìwé kékeré náà lé e lọ́wọ́, á wá fí taratara sọ pé: “Mi ò mọ̀wé kà, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o lè ka ibí yìí sí mi létí lónìí?” Yóò wá fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí onítọ̀hún ń kà. Ohun tó máa ṣe tẹ̀ lé ìyẹn ni pé yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún, yóò sí wọlé kíá láti wá bá àwọn ọmọ rẹ̀ jíròrò ẹsẹ náà kí wọ́n tó máa lọ sílé ìwé!

Onírúurú Ènìyàn Ló Fìfẹ́ Hàn

Ní Senegal, a lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó sẹ́bàá títì tí wọ́n ń ta ẹja, ẹ̀fọ́, tàbí kí wọ́n máa ta èso lọ́jà tàbí kí wọ́n jókòó sábẹ́ igi oṣè ràbàtà, kí wọ́n máa mu ataya, ìyẹn tíì eléwé, tó korò lẹ́nu. Nítorí pé àwọn arákùnrin méjì kan ti pinnu láti sọ ìhìn rere náà fún gbogbo ẹni táwọn bá bá pàdé ni wọ́n ṣe lọ bá ọkùnrin aláàbọ̀ ara kan sọ̀rọ̀ níbi tó ti ń ṣagbe lójú pópó. Lẹ́yìn tí wọ́n kí i, wọ́n ní: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fún ẹ lówó, ṣùgbọ́n tí wọn kì í dúró bá ẹ sọ̀rọ̀. A wá bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ṣe pàtàkì púpọ̀, tó sì ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la rẹ̀.” Ó ya alágbe náà lẹ́nu. Àwọn arákùnrin náà wá ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ, wọ́n ní: “A fẹ́ bi ọ́ ní ìbéèrè kan. Kí lo rò pé ó fà á tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí nínú ayé? Alágbe náà fèsì pé: “Bó ṣe wu Ọlọ́run nìyẹn.”

Àwọn arákùnrin náà wá bá a fọ̀rọ̀ wérọ̀ nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ṣàlàyé ìwé Ìṣípayá orí kọkànlélógún ẹsẹ ìkẹrin fún un. Ìhìn iṣẹ́ tó fúnni ní ìrètí yìí wọ alágbe náà lọ́kàn gan-an, ohun tó tún wú u lórí jù ni pé ẹnì kan lè nífẹ̀ẹ́ òun débi tó fi dúró bá òun jíròrò Bíbélì. Omijé wá lé ròrò sójú ẹ̀. Kàkà kó béèrè owó, ṣe ló bẹ àwọn arákùnrin náà pé kí wọ́n máa kó gbogbo owó tó wà nínú igbá báárà òun lọ! Ó bẹ̀ wọ́n débi pé gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ ló ń wò wọ́n. Gbogbo ọgbọ́n táwọn arákùnrin náà ní ni wọ́n lò láti bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́jú owó náà. Ó gbà níkẹyìn, àmọ́, ó ní wọ́n gbọ́dọ̀ padà wá bẹ òun wò.

Yunifásítì ńlá tó wà ní Dakar náà ń fi kún ẹja tí à ń rí kó sínú àwọ̀n tẹ̀mí náà. Ibẹ̀ ní akẹ́kọ̀ọ́ kan tó wà ni ẹ̀ka ìṣègùn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jean-Louis, ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kíá ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́, tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó sì ṣe ìrìbọmi. Ohun tó wù ú ni pé kí òun sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, àmọ́ ó tún ń gbádùn ẹ̀kọ́ ìṣègùn tó ń kọ́. Nítorí àdéhùn kan tó wà láàárín òun àti orílẹ̀-èdè tirẹ̀, ó di dandan fún un láti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò kan náà. Kété lẹ́yìn tó gboyè gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn tó dáńgájíá ni wọ́n pè é láti wá sìn gẹ́gẹ́ bíi dókítà tí yóò máa tọ́jú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ńlá kan ní Áfíríkà. Ọ̀dọ́kùnrin mìíràn tí wọ́n tún bá pàdé ní Yunifásítì Dakar ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ báyìí.

Dájúdájú, èrè wà nínú ẹja pípa nípa tẹ̀mí ní Senegal. Wọ́n mọrírì ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an, a sì ti ń tẹ̀ wọ́n jáde ní èdè Wolof, tó jẹ́ èdè àdúgbò náà. Gbígbọ́ ìhìn rere náà ní èdè àbínibí wọn tí fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí-ọkàn níṣìírí láti fìfẹ́ hàn lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n moore. Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ẹja ìṣàpẹẹrẹ la óò rí kó, bí àwọn onítara “apẹja ènìyàn” tó wà ní Senegal ti ń fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà bá a nìṣó ní bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Kristẹni wọn.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

SENEGAL

[Àwòrán]

Bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Kristẹni ní Senegal

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.