Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí!

Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí!

Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí!

“Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ.”—JEREMÁYÀ 1:19.

1. Iṣẹ́ wo ni Jeremáyà rí gbà, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó lẹ́nu rẹ̀?

 JÈHÓFÀ yan Jeremáyà tí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé láti ṣe wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè. (Jeremáyà 1:5) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Jòsáyà, Ọba rere tó ṣàkóso Júdà. Iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà ń jẹ́ ń bá a lọ ní gbogbo àkókò rúkèrúdò tó gbòde kan kí Bábílónì tó ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù títí dìgbà tí wọ́n fi kó àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ sígbèkùn.—Jeremáyà 1:1-3.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe ki Jeremáyà láyà, kí sì ni bíbá wòlíì yẹn jà yóò túmọ̀ sí?

2 Ó dájú pé àwọn iṣẹ́ ìdájọ́ tí Jeremáyà fẹ́ jẹ́ yóò fa àtakò. Fún ìdí yìí, Ọlọ́run ki Jeremáyà láyà nítorí ohun tí ń bẹ níwájú. (Jeremáyà 1:8-10) Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí ki wòlíì náà láyà: “Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” (Jeremáyà 1:19) Ẹní bá ń bá Jeremáyà jà, Ọlọ́run ló ń bá jà. Lónìí, Jèhófà ní àwùjọ àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n dà bíi wòlíì, tí iṣẹ́ wọ́n jọ ti Jeremáyà. Bíi ti Jeremáyà, wọ́n ń fi ìgboyà kéde ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Ìkéde yìí sì ń nípa lórí ẹni gbogbo àti orílẹ̀-èdè gbogbo, bóyá sí rere tàbí sí búburú, ó sinmi lé bí wọ́n bá ṣe dáhùn sí i. Gẹ́gẹ́ bó sì ṣe rí nígbà Jeremáyà, àwọn kan wà lónìí tí wọ́n ń bá Ọlọ́run jà nípa títako àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ tó yàn fún wọn.

Wọ́n Gbéjà Ko Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà

3. Èé ṣe tí wọ́n fi ń gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

3 Látìgbà tí ọ̀rúndún ogún ti bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti ń gbéjà ko àwọn ènìyàn Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn tí ń pète ibi ti sapá láti ṣèdíwọ́ fún ìpolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àní láti dá a dúró pàápàá. Olórí Elénìní wa, Èṣù, tí ‘ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, tó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ,’ ló ń tì wọ́n ṣe é. (1 Pétérù 5:8) Lẹ́yìn tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin lọ́dún 1914, Ọlọ́run gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun fún ayé, ó sì pàṣẹ fún un pé: “Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.” (Lúùkù 21:24; Sáàmù 110:2) Agbára Ìjọba yẹn ni Kristi lò láti fi lé Sátánì jáde kúrò lọ́run, ó sì sé e mọ́ àgbègbè ilẹ̀ ayé. Inú wá ń bí Èṣù burúkú-burúkú sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, nítorí ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú lòun ní. (Ìṣípayá 12:9, 17) Kí wá ni àtakò àwọn tó ń bá Ọlọ́run jà léraléra yìí ń yọrí sí?

4. Àwọn àdánwò wo ló dé bá àwọn èèyàn Jèhófà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919 àti 1922?

4 Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò ìgbàgbọ́. Wọ́n fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n parọ́ mọ́ wọn, àwùjọ èèyànkéèyàn ń lé wọn káàkiri, wọ́n lù wọ́n nílùkulù. Bí Jésù ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n di “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:9) Nínú ìgbónára eléwèlè ìgbà ogun, àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run lo àrékérekè tí wọ́n lò nínú ọ̀ràn Jésù Kristi. Wọ́n fún àwọn èèyàn Jèhófà lórúkọ tí kì í ṣe tiwọn, wọ́n pè wọ́n ní adìtẹ̀-síjọba, wọ́n sì nawọ́ gán àwọn òpómúléró ètò àjọ Ọlọ́run tí a lè fojú rí. Ní May 1918, ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú J. F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society, àti méje lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fáwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ wọ̀nyí, wọ́n sì kó wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní ìlú Atlanta, Georgia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n tú wọn sílẹ̀. Ní May 1919, kóòtù tí ń gbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn lágbègbè ibẹ̀ ṣèdájọ́ pé àwọn tó gbẹ́jọ́ wọn tẹ́lẹ̀ ṣègbè, ó sì fagi lé ìdájọ́ tí wọ́n ṣe. Wọ́n ní kí wọ́n tún ẹjọ́ yẹn gbọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ìjọba láwọn ò ṣẹjọ́ mọ́, wọ́n sì ní Arákùnrin Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n rárá. Ni wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò wọn, àwọn àpéjọpọ̀ tó wáyé ní ìlú Cedar Point, Ohio, lọ́dún 1919 àti lọ́dún 1922 sì mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tún bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

5. Kí lojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ní Jámánì lábẹ́ ìjọba Násì?

5 Àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ yọjú lọ́dún 1930 sí 1939, ilẹ̀ Ítálì, Jámánì, àti Japan sì para pọ̀ di Alágbára. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún yẹn, wọ́n dojú inúnibíni tó burú jáì kọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, pàápàá ní ilẹ̀ Jámánì lábẹ́ àkóso Násì. Wọ́n fòfin dè wọ́n. Wọ́n ń túlé wọn wò, wọ́n sì ń fàṣẹ ọba kó àwọn tí ń gbébẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni wọ́n jù sínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ torí pé wọ́n kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Ète tí wọ́n fi dojú ìjà kọ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ ni láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rẹ́ nílẹ̀ àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀. a Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Jámánì lọ láti lọ jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Lábẹ́ Ìjọba Násì kọ ìwé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ kan lórí ohun tó jẹ́ èrò tiwọn, láti lè rí i dájú pé àwọn Ẹlẹ́rìí ò rọ́wọ́ mú. Wọ́n ní: “Àwọn ilé ẹjọ́ wa kò gbọ́dọ̀ kùnà kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí òfin wí lásán; ṣùgbọ́n dandan ní kí wọ́n rọ́nà gbé e gbà, láìka ìṣòro tó lè jẹ yọ lójú ohun tí òfin wí, láti rí i pé wọ́n ṣe ojúṣe pàtàkì tiwọn.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé ìdájọ́ òdodo ò lè sí rárá. Àwọn Násì wá dúró lórí ohun tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ eléwu, tàbí pé ó ń ṣèpalára, ó sì ‘ń ṣèdíwọ́ fún ìlànà ìjọba Násì.’

6. Akitiyan wo ni wọ́n ṣe láti dá iṣẹ́ wa dúró nígbà Ogun Àgbáyé Kejì àti lẹ́yìn náà?

6 Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n fòfin de àwọn ènìyàn Ọlọ́run, wọ́n sì ká wọn lọ́wọ́ kò ní ilẹ̀ Kánádà, Ọsirélíà, àtàwọn ilẹ̀ míì tó wà nínú àjọ Kájọlà Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—ní ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, àtàwọn erékùṣù Caribbean àti ti Pàsífíìkì. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọ̀tá tó jẹ́ ẹni sàràkí-sàràkí àtàwọn èèyàn tí wọ́n purọ́ tàn jẹ bẹ̀rẹ̀ sí ‘fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.’ (Sáàmù 94:20) Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀ràn lórí àsíá kíkí, àtàwọn òfin àdúgbò tó ka ìwàásù àtilé-délé léèwọ̀ ni a gbé lọ ilé ẹjọ́, àwọn ìdájọ́ tó gbè wá, táwọn adájọ́ ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wá di ìtìlẹyìn alágbára fún níní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wuni. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà, ìmọ̀ràn ọ̀tá dòfo. Nígbà tí ogun náà parí ní Yúróòpù, wọ́n fi wá lọ́rùn sílẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n mú lóǹdè nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni wọ́n tú sílẹ̀, àmọ́ ìjà ò tíì tán o. Kété lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ni Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí fínná mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà. Wọ́n lo àṣẹ ọba láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìwàásù wa àti láti fòpin sí i, wọn ò fẹ́ kí àwọn ìwé Bíbélì jáde mọ́, wọ́n tún fẹ́ fòpin sáwọn àpéjọ táà ń ṣe ní gbangba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n rán lẹ́wọ̀n, wọ́n sì sọ àwọn míì dèrò àgọ́ ìmúnisìn.

Ìwàásù Ń Lọ Ní Pẹrẹu!

7. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Poland, Rọ́ṣíà, àtàwọn ilẹ̀ míì láwọn ọdún àìpẹ́ yìí?

7 Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà kàn ń tẹ̀ síwájú ní pẹrẹu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé abẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ni ilẹ̀ Poland ṣì wà, wọ́n fàyè gba ìpàdé ọlọ́jọ́ kan lọ́dún 1982. Àwọn ìpàdé àgbáyé wáyé níbẹ̀ lọ́dún 1985. A sì ṣe àwọn ìpàdé àgbáyé ńlá níbẹ̀ lọ́dún 1989, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló sì wá láti ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti Ukraine. Ọdún yẹn ni ilẹ̀ Hungary àti Poland gba ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè lábẹ́ òfin. Wọ́n bi odi ìlú Berlin wó ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1989. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn Jámánì gba iṣẹ́ wa láyè lábẹ́ òfin, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà, a sì ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé nílùú Berlin. Nígbà tó sì di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún mẹ́wàá tó gbẹ̀yìn ọ̀rúndún ogún, a sapá láti wá àwọn ará kàn ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. A tún lọ bá àwọn kan lára àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba nílùú Moscow, nígbà tó sì di ọdún 1991, wọ́n forúkọ ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Láti ìgbà yẹn, iṣẹ́ wa ń tẹ̀ síwájú pẹrẹu nílẹ̀ Rọ́ṣíà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira tí wọ́n fìgbà kan rí jẹ́ ara ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́.

8. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Jèhófà láàárín ọdún márùnlélógójì lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí?

8 Bí inúnibíni ṣe ń dáwọ́ dúró láwọn ibì kan, ló ń le sí i láwọn ibòmíràn. Láàárín ọdún márùnlélógójì lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ló kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní gba Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè lábẹ́ òfin. Láfikún sí i, ilẹ̀ mẹ́tàlélógún ní Áfíríkà, mẹ́sàn-án ní Éṣíà, mẹ́jọ ní Yúróòpù, mẹ́ta ní Látìn Amẹ́ríkà, àti mẹ́rin ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tó jẹ́ erékùṣù ni wọ́n tiẹ̀ ti fòfin dè wá tàbí kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa.

9. Kí lojú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rí ní Màláwì?

9 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1967, wọ́n ṣe inúnibíni kíkorò sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì. Nítorí pé àwọn ará wa tó wà ní ilẹ̀ náà fẹ́ wà láìdásí tọ̀tún-tòsì gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, wọ́n kọ̀ láti ra àwọn káàdì ẹgbẹ́ ìṣèlú. (Jòhánù 17:16) Lẹ́yìn ìpàdé kan tí ẹgbẹ́ ìṣèlú Malawi Congress Party ṣe lọ́dún 1972, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ìkà sí wa ní pẹrẹu. Wọ́n lé àwọn ará kúrò nílé wọn, wọn ò sì gbà wọ́n síṣẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló sá kúrò lórílẹ̀-èdè náà torí kí wọ́n má bàa pa wọ́n. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn tó bá Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ jà borí bí? Rárá o! Ní báyìí tí ipò nǹkan ti yídà, ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ́gbẹ̀rìndínlógún dín ní mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [43,767] akéde Ìjọba náà ló ròyìn ní Màláwì lọ́dún 1999, àwọn tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ló sì pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè níbẹ̀. A ti kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun sí olú ìlú orílẹ̀-èdè náà báyìí.

Wọ́n Ń Wá Nǹkan Tí Wọ́n Lè Fi Kẹ́wọ́

10. Gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn Dáníẹ́lì, kí làwọn tí ń tako àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ṣe lóde òní?

10 Àwọn apẹ̀yìndà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àtàwọn yòókù kò rára gba òdodo ọ̀rọ̀ tí à ń sọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí. Bí àwọn ètò ẹ̀sìn kan ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ń fínná mọ́ àwọn alátakò wa, ni àwọn náà bá ń wá ọ̀nà òfin awúrúju láti fi dá ìjà tí wọ́n ń bá wa jà láre. Ọgbọ́n wo ni wọ́n máa ń ta nígbà mìíràn? Tóò, kí làwọn onítẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun ṣe nígbà tí wọ́n fẹ́ gbéjà ko Dáníẹ́lì? Dáníẹ́lì 6:4, 5 kà pé: “Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ń wá ọ̀nà láti rí ohun àfiṣe-bojúbojú lòdì sí Dáníẹ́lì nípa ìjọba náà; ṣùgbọ́n wọn kò lè rí ohun àfiṣe-bojúbojú tàbí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan rárá, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí kò sì sí ìwà àìnáání tàbí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan rárá tí a rí nínú rẹ̀. Nítorí náà, àwọn abarapá ọkùnrin náà sọ pé: ‘A kò lè rí ohun àfiṣe-bojúbojú kankan rárá nínú Dáníẹ́lì yìí, bí kò ṣe pé a bá rí i lòdì sí i nínú òfin Ọlọ́run rẹ̀.’” Lónìí, ẹ̀wẹ̀, àwọn alátakò ń wá ohun tí wọ́n máa fi kẹ́wọ́. Ìbòòsí “àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ eléwu” ni wọ́n ń ké, wọ́n sì ń fẹ́ yí orúkọ yìí sórí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nípa lílo ọ̀nà ìbanilórúkọjẹ́, àti àpẹ́sọ ọ̀rọ̀ àti irọ́ pípa, wọ́n ń gbógun ti ọ̀nà ìjọsìn wa, wọ́n sì ń bá wa jà nítorí pé a rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run.

11. Àwọn ẹ̀sùn èké wo làwọn kan tó ń tako Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi kàn wọ́n?

11 Ní àwọn ilẹ̀ kan, onírúurú àwọn ẹlẹ́sìn àti olóṣèlú kò gbà pé ìjọsìn wa jẹ́ “ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run . . . wa.” (Jákọ́bù 1:27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìgbòkègbodò Kristẹni wa ti ń lọ lọ́wọ́, ńṣe làwọn alátakò tún ń sọ pé a kì í ṣe “ẹ̀sìn táyé mọ̀.” Kété ṣáájú Ìpàdé Àgbáyé táa ṣe lọ́dún 1998, ìwé ìròyìn kan nílùú Áténì gbé ọ̀rọ̀ tí àlùfáà ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì sọ jáde pé, “[Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kì í ṣe ‘ẹ̀sìn táyé mọ̀,’” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kóòtù Ilẹ̀ Yúróòpù Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti sọ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ìwé ìròyìn mìíràn nílùú kan náà ròyìn pé aṣojú ẹ̀sìn kan sọ pé: “[Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kì í ṣe ‘ìjọ Kristẹni’ rárá, torí pé wọ́n ti jìnnà pátápátá sí Jésù Kristi, ẹni tí àwọn Kristẹni gbà gbọ́.” Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí o, nítorí kò sí ètò ẹ̀sìn míì tó ń tẹnu mọ́ fífìwà jọ Jésù tó Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

12. Báa ṣe ń jagun tẹ̀mí náà, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?

12 A máa ń wọ́nà láti gbèjà ìhìn rere àti láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin. (Fílípì 1:7) Síwájú sí i, a ò ní juwọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní dẹ ọwọ́ tí a fi mú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run. (Títù 2:10, 12) Gẹ́gẹ́ bíi Jeremáyà, a ti ‘di ìgbáròkó wa lámùrè, a ó sì máa sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wa,’ a ò ní jẹ́ kí àwọn tí ń bá Ọlọ́run jà kó ìpayà bá wa rárá. (Jeremáyà 1:17, 18) Ọ̀rọ̀ Mímọ́ Jèhófà ti la ipa ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà fún wa, ọ̀nà yẹn ò sì láṣìmọ̀. Láéláé, àwa ò ní jẹ́ gbára lé ahẹrẹpẹ “apá tí ó jẹ́ ẹran ara,” bẹ́ẹ̀ ni a ò ní wá “ibi ìsádi lábẹ́ òjìji Íjíbítì,” ìyẹn ni, ayé yìí. (2 Kíróníkà 32:8; Aísáyà 30:3; 31:1-3) Báa ṣe ń jagun tẹ̀mí lọ, a ní láti máa bá a lọ ní fífi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí a jẹ́ kí ó máa tọ́ ìṣísẹ̀ wa, kí a má sì gbára lé òye tiwa. (Òwe 3:5-7) Láìṣe pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń tọ́ wa sọ́nà, ‘asán’ ni gbogbo iṣẹ́ wa yóò já sí.—Sáàmù 127:1.

Wọ́n Ń Ṣenúnibíni sí Wa, Àmọ́ A Ò Ní Bọ́hùn

13. Èé ṣe táa fi lè sọ pé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gbógun ti Jésù tó, wọn ò rí i gbé ṣe?

13 Jésù ni òléwájú lára àwọn tó ń fọkàn sin Jèhófà láìbọ́hùn. Òun ni wọ́n fẹ̀sùn èké kàn pé ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, àti pé ó ń dàlú rú. Lẹ́yìn tí Pílátù wádìí ọ̀ràn náà, ó fẹ́ tú Jésù sílẹ̀. Àmọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pọ oró sáwùjọ tó wà níbẹ̀ nínú, làwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé kí wọ́n kan Jésù mọ́gi, láìṣẹ̀láìrò. Wọ́n ní kí wọ́n dá Bárábà sílẹ̀ dípò Jésù—Bárábà tó jẹ́ pé ìdìtẹ̀ síjọba àti ìpànìyàn ló bá lọ sẹ́wọ̀n! Pílátù tún gbìyànjú láti rọ àwọn kìígbọ́kìígbà alátakò wọ̀nyẹn pé kí wọ́n sinmi agbaja, kí wọ́n jáwọ́ nínú ọ̀ràn náà, ṣùgbọ́n, níkẹyìn, nígbà tí wàhálà wọn fẹ́ le ju tiẹ̀ lọ, lòun náà bá tẹ̀ síbi tí wọ́n tẹ̀ sí. (Lúùkù 23:2, 5, 14, 18-25) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù kú lórí òpó igi, síbẹ̀ gbogbo bí àwọn elèṣù wọ̀nyí ṣe ń bínú Ọmọ Ọlọ́run aláìlẹ́ṣẹ̀-lọ́rùn, tí wọ́n ń gbógun lọ́tùn-ún lósì, wọn ò rí i gbé ṣe, nítorí pé Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Òun fúnra rẹ̀. Nígbà tó sì di Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù táa ṣe lógo yìí tú ẹ̀mí mímọ́ jáde, èyí tó fìdí ìjọ Kristẹni múlẹ̀, ìjọ táa pè ní “ìṣẹ̀dá tuntun.”—2 Kọ́ríńtì 5:17; Ìṣe 2:1-4.

14. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn Júù onísìn dojúùjà kọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?

14 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn làwọn onísìn tún bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì, àmọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi wọ̀nyẹn kò yéé sọ nípa ohun tí wọ́n ti rí, tí wọ́n sì ti gbọ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbàdúrà pé: “Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn, kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” (Ìṣe 4:29) Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn nípa jíjẹ́ kí wọ́n kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó sì fún wọn lágbára láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo polongo iṣẹ́ náà. Kò pẹ́ tí wọ́n tún pàṣẹ pé kí àwọn àpọ́sítélì dáwọ́ wíwàásù dúró, ṣùgbọ́n Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù fèsì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Híhalẹ̀ mọ́ wọn, fífàṣẹ ọba mú wọn, àti nínà wọ́n lẹ́gba kò lè mú wọn ṣíwọ́ jíjẹ́ kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú.

15. Ta ni Gàmálíẹ́lì, ìmọ̀ràn wo ló sì gba àwọn onísìn tí ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?

15 Báwo ni ọ̀ràn yìí ṣe rí lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọnnì? “Ó dùn wọ́n wọra, wọ́n sì ń fẹ́ láti pa [àwọn àpọ́sítélì].” Àmọ́, olùkọ́ Òfin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì, tó jẹ́ Farisí, wà níbẹ̀, ẹni iyì sì ni láwùjọ. Ó ní kí àwọn àpọ́sítélì bọ́ sóde gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn fúngbà díẹ̀, ó wá gba àwọn onísìn tí ń dún mọ̀huru-mọ̀huru nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyè sí ara yín ní ti ohun tí ẹ ń pète-pèrò láti ṣe nípa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. . . . Mo wí fún yín pé, Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;) bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Ìṣe 5:33-39.

Ohun Ìjà Yòówù Tí Wọ́n Bá Ṣe sí Wa Ò Ní Ṣiṣẹ́

16. Tóo bá fẹ́ sọ ọ́ lọ́rọ̀ tìrẹ, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìdánilójú tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀?

16 Ìmọ̀ràn tó dáa nìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì, inú àwa náà sì máa ń dùn táwọn èèyàn bá gbèjà wa. A sì mọ̀ pé àwọn ẹjọ́ táwọn adájọ́ tí kì í ṣègbè ti dá nílé ẹjọ́ ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti máa ṣe ẹ̀sìn tó bá wuni. Àmọ́ o, ńṣe ni inú ń bí àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù àtàwọn aṣáájú míì ní Bábílónì Ńlá, tí í ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, nítorí pé a rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣípayá 18:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn, àtàwọn ìsọ̀ǹgbè wọn, ń bá wa jà, kinní kan dá wa lójú, òun ni pé: “‘Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—Aísáyà 54:17.

17. Báwọn alátakò tilẹ̀ ń bá wa jà, èé ṣe tá ò fi ní mikàn?

17 Ńṣe làwọn ọ̀tá wa kàn ń bá wa jà láìnídìí, àmọ́ àwa ò ní tìtorí ìyẹn jọ̀gọ̀ nù o. (Sáàmù 109:1-3) Àwa ò ní gbà láé, kí àwọn tó kórìíra iṣẹ́ Bíbélì tí a ń jẹ́ kó wa láyà jẹ, ká sì wá sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé ìjà wa nípa tẹ̀mí á máa le sí i ni, síbẹ̀ a mọ ibi tọ́ràn náà máa jálẹ̀ sí. Gẹ́gẹ́ bíi Jeremáyà, a óò rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà tó sọ pé: “Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” (Jeremáyà 1:19) Bẹ́ẹ̀ ni, àwá mọ̀ pé àwọn tó bá ń bá Ọlọ́run jà kò ní borí!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Wọ́n Dúró Ṣinṣin Láìbẹ̀rù Nígbà Tí Ìjọba Násì Ń Pọ́n Wọn Lójú,” ojú ìwé 24 sí 28.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

• Èé ṣe tí wọ́n fi ń gbógun ti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

• Lọ́nà wo làwọn alátakò ti gbà bá àwọn èèyàn Jèhófà jà?

• Èé ṣe tó fi lè dá wa lójú pé àwọn tó ń bá Ọlọ́run jà kò ní borí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

A mú un dá Jeremáyà lójú pé Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn tó la àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn èèyànkéèyàn gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

J. F. Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Nínú ọ̀ràn ti Jésù, àwọn tó bá Ọlọ́run jà kò borí