Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayẹyẹ Pàtàkì Ṣé Ìwọ Náà Á Wá?

Ayẹyẹ Pàtàkì Ṣé Ìwọ Náà Á Wá?

Ayẹyẹ Pàtàkì Ṣé Ìwọ Náà Á Wá?

NÍ ỌJỌ́ mánigbàgbé kan, ní ohun tí ó lé ní egbèjìdínlógún dín lọ́gọ́rùn-ún [3,500] ọdún sẹ́yìn, Jèhófà Ọlọ́run ní kí agboolé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan tó wà lóko ẹrú ní Íjíbítì pa ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ kan, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn àti àtẹ́rígbà ilé wọn. Lálẹ́ ọjọ́ tí à ń wí yẹn, áńgẹ́lì Ọlọ́run ré kọjá àwọn ilé tí a sàmì sí lọ́nà yìí, ṣùgbọ́n ó pa àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì nínú ilé wọn. Lẹ́yìn náà ni wọ́n dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ní àyájọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn làwọn Júù máa ń ṣayẹyẹ Ìrékọjá.

Gbàrà tí Jésù ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá rẹ̀ tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tán, ó dá àpèjẹ kan sílẹ̀, èyí tí yóò wà fún ṣíṣe ìrántí ikú ìrúbọ tó kú. Ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní búrẹ́dì aláìwú, ó sì wí pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.” Lẹ́yìn náà, ó bu wáìnì sínú ife kan fún wọn, ó sì wí pé: “Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” Jésù tún sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Mátíù 26:26-28; Lúùkù 22:19, 20) Nítorí náà, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa ṣe ìrántí ikú rẹ̀.

Lọ́dún yìí, ayẹyẹ ìrántí ikú Jésù bọ́ sí ọjọ́ Wednesday, April 19, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò kóra jọ pọ̀ ní alẹ́ ọjọ́ pàtàkì yìí láti ṣe Ìrántí yìí bí Jésù ṣe ní ká máa ṣe é. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ láti dara pọ̀ mọ́ wa níbi ayẹyẹ yìí. Jọ̀wọ́ béèrè àkókò àti ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò ti ṣe ìpàdé náà.