Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run

Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run

Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run

“A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí.”—2 PÉTÉRÙ 1:19.

1, 2. Àpẹẹrẹ wo lo lè mú wá nípa èké mèsáyà?

 ỌJỌ́ ti pẹ́ táwọn èké mèsáyà ti ń gbìyànjú láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ní ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, ọkùnrin kan tó pe ara rẹ̀ ní Mósè fi yé àwọn Júù tó wà ní erékùṣù Kírétè pé òun ni mèsáyà, òun sì ti dé láti dá wọn nídè kúrò nínú ìnira. Nígbà tí ọjọ́ ìdáǹdè tí wọ́n dá pé, wọ́n tẹ̀ lé e gorí ibi gegele kan lẹ́bàá Òkun Mẹditaréníà. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n sáà ti bẹ́ sínú òkun, pé òkun yóò pínyà fún wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó bẹ́ jùà sínú omi ló bómi lọ, ni èké mèsáyà yẹn bá bẹ́sẹ̀ẹ rẹ̀ sọ̀rọ̀.

2 Ní ọ̀rúndún kejìlá, “mèsáyà” míì tún yọjú nílẹ̀ Yemen. Alákòóso ibẹ̀ sọ pé kó fáwọn lámì táwọn á fi mọ̀ pé mèsáyà ni. Ni “mèsáyà” yìí bá sọ pé kí alákòóso náà pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ òun lórí. Ó ní wàràwéré lòun máa jíǹde, ìyẹn á sì jẹ́ àmì fún un. Alákòóso náà gbà láti ṣe bó ṣe wí—ibi tí “mèsáyà” ilẹ̀ Yemen yẹn parí ayé tiẹ̀ náà sí nìyẹn.

3. Ta ni Mèsáyà tòótọ́ náà, kí sì ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fi hàn?

3 Òtúbáńtẹ́ làwọn èké mèsáyà àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ́n ti já sí, àmọ́ fífiyèsí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kò lè jáni kulẹ̀ láé. Jésù Kristi, Mèsáyà tòótọ́ náà, ni ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ sí lára. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Mátíù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere ń fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yọ, ó kọ̀wé pé: “‘Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní ìhà kejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè! àwọn ènìyàn tí ó jókòó nínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá kan, àti ní ti àwọn tí ó jókòó ní ẹkùn ilẹ̀ òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀ là sórí wọn.’ Láti ìgbà náà lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ wíwàásù, ó sì ń wí pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 4:15-17; Aísáyà 9:1, 2) Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ ńlá” náà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sì fi hàn pé òun ni Wòlíì tí Mósè ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Àwọn tó bá kọ̀ láti fetí sí Jésù yóò pa run.—Diutarónómì 18:18, 19; Ìṣe 3:22, 23.

4. Báwo ni Jésù ṣe mú Aísáyà 53:12 ṣẹ?

4 Jésù tún mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 53:12 ṣẹ, ó kà pé: “Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú, àwọn olùrélànàkọjá ni a sì kà á mọ́; òun fúnra rẹ̀ sì ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pàápàá, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣìpẹ̀ nítorí àwọn olùrélànàkọjá.” Jésù mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ fi ìwàláàyè òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ìràpadà, nítorí náà, ó fún ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lókun. (Máàkù 10:45) Ọ̀nà títayọ tó gbà ṣe èyí ni nípa yíyíra padà lọ́nà ológo.

Ìyípadà Ológo Náà Gbé Ìgbàgbọ́ Ró

5. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìyípadà ológo náà?

5 Ìyípadà ológo náà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀. Jésù sọ pé: “A ti yan Ọmọ ènìyàn tẹ́lẹ̀ láti wá nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ . . . Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:27, 28) Ǹjẹ́ àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì fojú rí Jésù tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀ ní ti gidi? Mátíù 17:1-7 sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì mú wọn wá sí orí òkè ńlá kan tí ó ga fíofío ní àwọn nìkan. A sì yí i padà di ológo níwájú wọn.” Àrà mérìíyìírí! “Ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀. Sì wò ó! Mósè àti Èlíjà sì fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.” Bákan náà, “àwọsánmà mímọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n,” wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run tìkára rẹ̀ tó sọ pé: “‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.’ Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, àyà sì fò wọ́n gidigidi. Nígbà náà ni Jésù wá sí tòsí, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì wí pé: ‘Ẹ dìde, ẹ má sì bẹ̀rù.’”

6. (a) Èé ṣe tí Jésù fi pe ìyípadà ológo náà ní ìran? (b) Kí ni ìyípadà ológo náà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?

6 Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé orí ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn Òkè Ńlá Hámónì ni ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà yìí ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́ta náà wà mọ́jú. Ó dájú pé òru ni ìyípadà ológo náà wáyé, ìyẹn ló tún jẹ́ kó hàn kedere. Ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi pè é ní ìran ni pé, Mósè àti Èlíjà, tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́, kò sí níbẹ̀ ní ti gidi. Kristi nìkan ló wà níbẹ̀ táa lè rí. (Mátíù 17:8, 9) Irú ìmọ́lẹ̀ mọ̀nà-ǹ-kọ-yẹ̀rì bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù rí ìran àwòyanu tó ṣàpẹẹrẹ wíwàníhìn-ín ológo Jésù nínú agbára Ìjọba náà. Mósè àti Èlíjà dúró fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù, ìran náà sì ṣe ìtìlẹyìn tó lágbára fún ẹ̀rí tí Jésù jẹ́ nípa Ìjọba náà àti ipò ọba rẹ̀ ọjọ́ iwájú.

7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Pétérù ṣì rántí ìyípadà ológo náà dáadáa?

7 Ìyípadà ológo náà fi kún ìgbàgbọ́ àwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àwọn tó máa kó ipa aṣáájú nínú ìjọ Kristẹni. Ojú Jésù tó mọ́lẹ̀ yòò, aṣọ rẹ̀ tó mọ́ gbòò bí ọjọ́, àti ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tó kéde pé Jésù ni Ọmọ Òun, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí wọ́n ní láti máa fetí sí—gbogbo rẹ̀ ló bá a mu wẹ́kú. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì náà ò tíì gbọ́dọ̀ sọ nípa ìran náà fún ẹnikẹ́ni, ìyẹ́n dẹ̀yìn àjíǹde Jésù. Ní nǹkan bí ọdún méjìlélọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà, Pétérù ṣì rántí ìran yìí dáadáa. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípa fífi tí a fi ojú rí ọlá ńlá rẹ̀. Nítorí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí ògo ọlọ́lá ńlá gbé irú ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí wá fún un pé: ‘Èyí ni ọmọ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi tẹ́wọ́ gbà.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a gbọ́ tí a gbé wá láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ńlá mímọ́ náà.”—2 Pétérù 1:16-18.

8. (a) Kí ni ìkéde tí Ọlọ́run ṣe nípa Ọmọ rẹ̀ pe àfiyèsí sí? (b) Kí ni àwọsánmà táa rí nígbà ìyípadà ológo náà fi hàn?

8 Apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìyípadà ológo yìí ni kíkéde tí Ọlọ́run kéde pé: “Èyí ni ọmọ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi tẹ́wọ́ gbà.” Gbólóhùn yìí darí àfiyèsí sọ́dọ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run ti gbé gorí ìtẹ́, ẹni tí gbogbo ẹ̀dá gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí. Ìkùukùu tó ṣíji bò wọ́n ló fi hàn pé ìmúṣẹ ìran yìí yóò jẹ́ èyí tí a kò lè fojú rí. Kìkì nípa lílo ìfòyemọ̀ ni àwọn tó bá mọ “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù nínú agbára Ìjọba náà, èyí tí a kò lè fojú rí, yóò fi mọ̀ ọ́n. (Mátíù 24:3) Ní tòótọ́, ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa ìran náà fún ẹnikẹ́ni kí òun tó jíǹde fi hàn pé ẹ̀yìn àjíǹde rẹ̀ ni ìgbéga àti ìṣelógo rẹ̀ yóò tó wáyé.

9. Èé ṣe tó fi yẹ kí ìyípadà ológo náà túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lágbára?

9 Lẹ́yìn tí Pétérù sọ̀rọ̀ nípa ìyípadà ológo náà, ló wá sọ pé: “Nítorí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bíi fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn-àyà yín. Nítorí ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí. Nítorí a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:19-21) Ṣe ni ìyípadà ológo náà túbọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. A gbọ́dọ̀ fiyè sí ọ̀rọ̀ yẹn, kí a má sì fetí sí “àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá,” tí Ọlọ́run kò tì lẹ́yìn, tí inú rẹ̀ kò sì dùn sí. Ńṣe ló yẹ kí ìyípadà ológo náà túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ lágbára, nítorí pé ìran yẹn tó ṣàpẹẹrẹ ògo àti agbára Jésù nínú Ìjọba náà ti ní ìmúṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rí tó dájú wà pé Kristi ti wà ní ọ̀run nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba alágbára.

Bí Ìràwọ̀ Ojúmọ́ Náà Ṣe Yọ

10. Ta ni tàbí kí ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” tí Pétérù mẹ́nu kàn, èé sì ti ṣe tóo fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

10 Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún [ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀] ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn-àyà yín.” Ta ni tàbí kí ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” náà? Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ náà “ìràwọ̀ ojúmọ́” fara hàn nínú Bíbélì, ìtumọ̀ rẹ̀ sì jọ ti “ìràwọ̀ òwúrọ̀.” Ìwé Ìṣípayá 22:16 pe Jésù Kristi ní “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò.” Ní àwọn àsìkò kan lọ́dún, irú àwọn ìràwọ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa ń yọ kẹ́yìn lójú ọ̀run lápá ìlà oòrùn. Àwọn ló máa ń yọ ní gẹ́rẹ́ kí oòrùn tó yọ, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ló máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ojúmọ́ ti ń mọ́. Pétérù pe Jésù ní “ìràwọ̀ ojúmọ́” lẹ́yìn tí Ó gba agbára Ìjọba. Nígbà yẹn, Jésù yọ bí ọjọ́ nígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, títí kan ilẹ̀ ayé wa! Gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tó jẹ́ Ìràwọ̀ Ojúmọ́, ó ń ṣàpẹẹrẹ ojúmọ́ tó ń mọ́ bọ̀, tàbí sànmánì tuntun tó ń wọlé bọ̀, fún gbogbo aráyé onígbọràn.

11. (a) Èé ṣe tí 2 Pétérù 1:19 kò fi túmọ̀ sí pé inú ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn gan-an ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” ti yọ? (b) Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé 2 Pétérù 1:19?

11 Èrò tí ọ̀pọ̀ ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì gbé yọ ni pé ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù tó wà nínú 2 Pétérù 1:19 tọ́ka sí ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn. Ọkàn-àyà àgbàlagbà ò lè ju ìwọ̀n àádọ́talénígba sí ọ̀ọ́dúnrún gíráàmù lọ. Báwo wá ni Jésù Kristi, tí ń bẹ ní ọ̀run nísinsìnyí, tó tún jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ológo tí kò lè kú mọ́, ṣe lé yọ nínú ẹ̀yà ara mọ́ńbé yìí tí ń bẹ nínú ènìyàn? (1 Tímótì 6:16) Àmọ́ ṣá, ọ̀ràn yìí kan ọkàn-àyà wa ìṣàpẹẹrẹ, nítorí pé ọkàn-àyà wa ìṣàpẹẹrẹ ni a fi ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n fara balẹ̀ wo 2 Pétérù 1:19, wàá sì rí i pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi àmì ìdánudúró díẹ̀ sẹ́yìn gbólóhùn tó sọ pé “títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ,” ó tipa bẹ́ẹ̀ yà á sọ́tọ̀ kúrò lára gbólóhùn náà “nínú ọkàn-àyà yín.” A lè ṣàlàyé ẹsẹ yìí báyìí: ‘A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bíi fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, ìyẹn, ní ọkàn-àyà yín, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ.’

12. Ipò wo ni ọkàn-àyà gbogbo aráyé wà, àmọ́ ọkàn-àyà àwọn ojúlówó Kristẹni ńkọ́?

12 Ipò wo ni ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ gbogbo aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ wà? Inú òkùnkùn tẹ̀mí ni o jàre! Àmọ́ o, tó bá ṣe pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, ńṣe ló dà bíi pé fìtílà kan wà tó mọ́lẹ̀ rokoṣo nínú ọkàn-àyà wa, tó jẹ́ pé tí kì í bá ṣe ti fìtílà yìí ni, inú òkùnkùn ni ì bá wà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pétérù ti fi hàn, kìkì nípa fífiyèsí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run tí ń lani lóye nìkan ni àwọn ojúlówó Kristẹni fi lè wà lójúfò rekete, kí wọ́n sì mọ̀ pé ojúmọ́ ti mọ́. Wọn yóò mọ òtítọ́ náà pé gbogbo ìṣẹ̀dá ni Ìràwọ̀ Ojúmọ́ yọ fún, kì í ṣe inú ọkàn-àyà ẹlẹ́ran ara ló ti yọ.

13. (a) Èé ṣe táa fi ní ìdánilójú pé Ìràwọ̀ Ojúmọ́ ti yọ? (b) Èé ṣe táwọn Kristẹni fi lè fara da àwọn ipò lílekoko tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wà lónìí?

13 Ìràwọ̀ Ojúmọ́ ti yọ o! Èyí á dá wa lójú gbangba táa bá fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí Jésù sọ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀. Lónìí, à ń rí ìmúṣẹ rẹ̀ bí a ti ń rí àwọn àgbáàràgbá ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, àti wíwàásù ìhìn rere náà kárí ayé. (Mátíù 24:3-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ipò lílekoko tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ kan àwa náà táa jẹ́ Kristẹni, síbẹ̀ a lè fara dà á nítorí pé a ní àlàáfíà àti ayọ̀ inú ọkàn-àyà. Èé ṣe? Nítorí pé a ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, a sì gba àwọn ohun tó ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la gbọ́. A mọ̀ pé ìgbà tó dáa jù lọ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọlé dé nítorí pé a ti wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ “àkókò òpin”! (Dáníẹ́lì 12:4) Ayé ti bá ara rẹ̀ nínú hílàhílo tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Aísáyà 60:2, pé: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” Báwo lèèyàn ṣe lè rọ́nà gbà jáde nínú òkùnkùn biribiri yìí? Èèyàn ní láti fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run nísinsìnyí, kó tó pẹ́ jù. Àwọn olóòótọ́ ọkàn gbọ́dọ̀ yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run, Orísun ìyè àti ìmọ́lẹ̀. (Sáàmù 36:9; Ìṣe 17:28) Kìkì nípa ṣíṣe èyí lèèyàn fi lè ní ìlàlóye àti ìrètí tòótọ́ pé òun yóò gbádùn ọjọ́ iwájú tó mìrìngìndìn tí Ọlọ́run ti pète fún aráyé onígbọràn.—Ìṣípayá 21:1-5.

“Ìmọ́lẹ̀ Ti Wá sí Ayé”

14. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe táa bá fẹ́ kí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu inú Bíbélì kàn wá?

14 Ìwé Mímọ́ mú un ṣe kedere pé Jésù Kristi ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba. Nítorí pé ó ti gorí àlééfà ní ọdún 1914, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu yòókù yóò ṣẹ. Kí ìmúṣẹ yìí lè kàn wá, a ní láti fi hàn pé a jẹ́ onínú tútù tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tó sì ń ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ táa dá nígbà àìmọ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó fẹ́ràn òkùnkùn kò ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun o. Jésù sọ pé: “Èyí ni ìpìlẹ̀ fún ìdájọ́, pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí pé àwọn iṣẹ́ wọn burú. Nítorí ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa fi ìbáwí tọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan tí ó jẹ́ òótọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a bàa lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Jòhánù 3:19-21.

15. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ táa bá ṣàìnáání ìgbàlà tí Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀?

15 Ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ti tàn kárí ayé nípasẹ̀ Jésù, ó sì ṣe pàtàkì láti fetí sí i. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run, ẹni tí ó tipasẹ̀ àwọn wòlíì bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà, ti tipasẹ̀ Ọmọ kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin ọjọ́ wọ̀nyí, ẹni tí òun yàn ṣe ajogún ohun gbogbo.” (Hébérù 1:1, 2) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ táa bá ṣàìnáání ìgbàlà tí Ọlọ́run mú kí ó ṣeé ṣe nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀? Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ bá já sí èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, tí gbogbo ìrélànàkọjá àti ìwà àìgbọràn sì gba ẹ̀san iṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo; báwo ni a ó ṣe yè bọ́ bí a bá ti ṣàìnáání ìgbàlà tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀ ní ti pé a bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ nípasẹ̀ Olúwa wa, tí àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fìdí èyí múlẹ̀ fún wa, nígbà tí Ọlọ́run dara pọ̀ ní jíjẹ́rìí pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu àti onírúurú iṣẹ́ agbára àti pẹ̀lú ìpínfúnni ẹ̀mí mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀?” (Hébérù 2:2-4) Òótọ́ ni o, Jésù ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìpolongo ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀.—Ìṣípayá 19:10.

16. Èé ṣe táa fi lè gbé gbogbo ọkàn wa lé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run?

16 Gẹ́gẹ́ báa ti mọ̀, Pétérù sọ pé: “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí.” Èèyàn ò lè dá gbé àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ jáde, ṣùgbọ́n a lè gbé gbogbo ọkàn lé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run ló pilẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, ó ti jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mòye bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ní ìmúṣẹ. Ní tòótọ́, ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé a ti ń rí ìmúṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ látọdún 1914. Ó sì dá wa lójú hán-ún pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yòókù nípa òpin ètò àwọn nǹkan burúkú yìí yóò ní ìmúṣẹ. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá a nìṣó ní fífiyèsí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run bí a ṣe ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn. (Mátíù 5:16) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń mú kí ‘ìmọ́lẹ̀ tàn fún wa nínú òkùnkùn biribiri’ tó bo ilẹ̀ ayé dẹ́dẹ́ẹ́dẹ́ lónìí!—Aísáyà 58:10.

17. Èé ṣe táa fi ń fẹ́ ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

17 Ìmọ́lẹ̀ ló máa ń jẹ́ ká ríran. Òun náà ló máa ń jẹ́ kí irúgbìn dàgbà sókè, kó lè pèsè ọ̀kan-kò-jọ̀kan oúnjẹ fún wa. A ò lè wà láàyé láìsí ìmọ́lẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wá ńkọ́? Òun ló ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà, tó sì ń fi ọjọ́ ọ̀la tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sọ tẹ́lẹ̀ hàn wá. (Sáàmù 119:105) Jèhófà Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ ‘rán ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ jáde.’ (Sáàmù 43:3) Dájúdájú, ó yẹ ká fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún irú ìpèsè bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe láti gba ìmọ́lẹ̀ “ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run” sínú, kí ó lè tànmọ́lẹ̀ sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa.—2 Kọ́ríńtì 4:6; Éfésù 1:18.

18. Kí ni Ìràwọ̀ Ojúmọ́ Jèhófà ti wà ní sẹpẹ́ láti ṣe báyìí?

18 Inú wa mà dùn o, pé a mọ̀ pé lọ́dún 1914, Jésù Kristi, tí í ṣe Ìràwọ̀ Ojúmọ́, yọ nígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìran ìyípadà ológo rẹ̀ ṣẹ! Ìràwọ̀ Ojúmọ́ Jèhófà ti yọ, ó ti wà ní sẹpẹ́ láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ, kí ìyípadà ológo náà lè túbọ̀ ní ìmúṣẹ síwájú sí i—ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Lẹ́yìn tí ètò ògbólógbòó yìí bá lọ ní àlọ rámirámi, Jèhófà yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” níbi tí a ó ti máa yìn ín lógo títí ayé gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé àti Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́. (2 Pétérù 3:13) Kó tó dọjọ́ ńlá yẹn, ẹ jẹ́ ká máa rìn nìṣó nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run nípa fífiyèsí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

• Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ìyípadà ológo Jésù?

• Báwo ni ìyípadà ológo náà ṣe ń gbé ìgbàgbọ́ ró?

• Ta ni tàbí kí ni Ìràwọ̀ Ojúmọ́ Jèhófà, ìgbà wo ló sì yọ?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ìyípadà ológo náà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìràwọ̀ Ojúmọ́ ti yọ. Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe yọ àtìgbà tó yọ?