Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Kan Wà Nínú Bíbélì Tó Jẹ́ Ẹnà?

Ǹjẹ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Kan Wà Nínú Bíbélì Tó Jẹ́ Ẹnà?

Ǹjẹ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Kan Wà Nínú Bíbélì Tó Jẹ́ Ẹnà?

NÍ NǸKAN bí ọdún méjì lẹ́yìn tí wọ́n pa Olórí Ìjọba Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí, Yitzhak Rabin, lọ́dún 1995, akọ̀ròyìn kan sọ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀ tóun ní nínú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, òún ti rí àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà níbi tó fara sin sí nínú Bíbélì èdè Hébérù àtètèkọ́ṣe. Akọ̀ròyìn náà tó ń jẹ́ Michael Drosnin, kọ̀wé pé ó lé ní ọdún kan ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí òún ti ń gbìyànjú láti kìlọ̀ fún olórí ìjọba náà ṣùgbọ́n tí gbogbo ìsapá òun ti já sásán.

Wọ́n ti tẹ àwọn ìwé àti àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn jáde nísinsìnyí tó ń sọ pé ẹnà yìí fìdí ẹ̀rí tó ṣe tààrà múlẹ̀ pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run. Ṣé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ wà lóòótọ́? Ṣé ọ̀rọ̀ tó jọ ẹnà ló yẹ kó mú wa gbà gbọ́ pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run?

Ṣé Èrò Yẹn Jẹ́ Tuntun Ni?

Èrò pé ẹnà kan fara sin sáàárín àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kì í ṣe tuntun. Ó jẹ́ lájorí èròǹgbà inú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kábálà, tàbí ìgbàgbọ́ àbáláyé ìfòyemọlọ́run tí àwọn Júù ní. Àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Kábálà ti sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì ní ìtumọ̀ gidi míì yàtọ̀ sí èyí tí a rí kà lásán. Wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lo àwọn lẹ́tà Hébérù kọ̀ọ̀kan bí àmì ni, tó jẹ́ pé táa bá lóye wọn dáadáa, à á mọ òótọ́ ibẹ̀ gan-an. Lójú tiwọn, lẹ́tà ọ̀rọ̀ Hébérù kọ̀ọ̀kan àti ibi tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì ni Ọlọ́run fi síbẹ̀ pẹ̀lú ète pàtó lọ́kàn.

Jeffrey Satinover, tó jẹ́ olùwádìí nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ẹnà nínú Bíbélì sọ pé àwọn Júù afòyemọlọ́run yìí gbà gbọ́ pé agbára ìfòyemọ̀ kíkàmàmà fara sin sínú àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ìròyìn ìṣẹ̀dá nínú Jẹ́nẹ́sísì. Ó kọ̀wé pé: “Ká má fọ̀rọ̀ gùn, Jẹ́nẹ́sísì kì í wulẹ̀ ṣe ìwé àlàyé lásán; òun gan-an ni wọ́n wò ṣe ìṣẹ̀dá, ó jẹ́ ìlànà ìṣiṣẹ́ tó wà lọ́kàn Ọlọ́run tó wá gbé jáde lọ́nà tó ṣeé fojú rí.”

Olùkọ́ kan nínú ẹ̀sìn Kábálà ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Bachya ben Asher láti Saragossa, ní ilẹ̀ Sípéènì, kọ̀wé nípa àwọn ìsọfúnni kan tó fara sin tí a ṣí payá fún un nígbà tó ka ibì kan nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ó ní òún ń fo lẹ́tà méjìlélógójì kí òún tó ka ibòmíràn. Orí ìlànà fífo iye lẹ́tà pàtó kan láti lè ṣàwárí àwọn ìsọfúnni tó fara sin ni wọ́n gbé èròǹgbà àmì inú Bíbélì ìgbàlódé kà.

Kọ̀ǹpútà Ló “Gbé Ìtumọ̀” Ẹnà Náà “Yọ”

Kí kọ̀ǹpútà tó dé, agbára tí èèyàn ní láti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì lọ́nà yìí láàlà. Àmọ́, nígbà tó di August 1994, ìwé ìròyìn Statistical Science tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde, nínú èyí tí Eliyahu Rips, láti Yunifásítì tí ń ṣèwádìí èdè Hébérù tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àti àwọn olùwádìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti sọ pé àwọ́n ṣe àwọn ohun kan tó yani lẹ́nu. Wọ́n ní àwọ́n sún gbogbo lẹ́tà ọ̀rọ̀ Hébérù tó wà nínú ẹsẹ ìwé Jẹ́nẹ́sísì pọ̀ tí kò fi sí àlàfo láàárín wọn, àwọ́n sì tò wọ́n lọ́nà tí àwọn á fi lè fo àwọn lẹ́tà náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láìjẹ́ kí ibi tí àwọn ń fò pọ̀ jura lọ, wọ́n ní bẹ́ẹ̀ làwọ́n ṣe táwọn fi rí orúkọ àwọn rábì mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tó lókìkí níbi tó fara sin sí nínú ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn, àti àwọn ìsọfúnni míì, bí ọjọ́ ìbí wọn àti ọjọ́ tí wọ́n kú, nítòsí orúkọ wọn. a Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àyẹ̀wò, àwọn olùwádìí náà tẹ èsì ìwádìí wọn jáde, wọ́n ní àdììtú ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì pọ̀ gan-an ju ohun tó lè jẹ́ èèṣì lọ—wọ́n jẹ́ ẹ̀rí àwọn ìsọfúnni tó ní ìmísí, táa dìídì fi pa mọ́ bí àmì sínú Jẹ́nẹ́sísì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.

Ìlànà yìí ni akọ̀ròyìn Drosnin lò tó fi ṣe àyẹ̀wò tiẹ̀, ó ń wá àwọn ìsọfúnni tó fara sin nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì èdè Hébérù. Gẹ́gẹ́ bí Drosnin ti sọ, ó ní òún rí orúkọ Yitzhak Rabin tó fara sin sínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì náà tó tò ní ẹgbẹ̀rìnlélógún dín méjìdínlọ́gbọ̀n [4,772] lẹ́tà léraléra. Nípa títo àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì náà lọ́nà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fi ní ẹgbẹ̀rìnlélógún dín méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́tà, ó wá rí i pé orúkọ Rabin (nígbà tó kà á lóròó), lọ dábùú ìlà kan (nínú Diutarónómì 4:42, tó wà níbùú) tí Drosnin tú sí “apààyàn tí yóò pànìyàn.”

Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó pààyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ ni ìwé Diutarónómì 4:42 ń sọ o. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Drosnin ní òún ṣe náà, wọ́n ní ìlànà tó lò, tí kò bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì mu, ṣeé fi wá àwọn ìsọfúnni tó jọ ìyẹn nínú ìwé èyíkéyìí. Ṣùgbọ́n Drosnin ò gbà fún wọn o, ó pè wọ́n níjà pé: “Tí àwọn tó ń ṣe òfíntótó mi bá rí ìsọfúnni tó fara sin nípa àwọn tó fẹ́ pa Olórí Ìjọba kan nínú [ìwé ìtàn àròsọ] tó ń jẹ́ Moby Dick, màá gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́.”

Ṣé Ìyẹn Ni Ẹ̀rí Pé Ó Ní Ìmísí?

Ọ̀jọ̀gbọ́n Brendan McKay, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Kọ̀ǹpútà ní Yunifásítì Ìjọba Ọsirélíà, mú iṣẹ́ ṣe lórí ìpèníjà Drosnin, ó sì fi kọ̀ǹpútà ṣèwádìí gidigidi lórí àwọn ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì inú ìwé Moby Dick. b McKay ní òún lo ìlànà kan náà tí Drosnin ṣàlàyé pé òún lò, òún sì rí “àwọn àsọtẹ́lẹ̀” nípa ikú Indira Gandhi, Martin Luther King, Kékeré, John F. Kennedy, Abraham Lincoln, àti àwọn míì. McKay sọ pé òún rí i pé ìwé Moby Dick tún “sàsọtẹ́lẹ̀” ikú Yitzhak Rabin.

Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n McKay àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tún padà sórí ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì lédè Hébérù, wọ́n tún gbé ìbéèrè dìde sí àbájáde àyẹ̀wò tí Rips àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe. Àròyé tí àwọn yẹn ṣe ni pé èsì wọ̀nyẹn ò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn àdììtú ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí, kàkà bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́ àti ìlànà àwọn olùwádìí náà ni gbogbo rẹ̀—ọgbọ́n orí làwọn olùwádìí náà lò tí wọ́n fi to ìsọfúnni náà jọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé ṣì ń fa ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra wọn lọ́wọ́.

Ọ̀ràn míì tún yọjú nígbà tí wọ́n sọ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fi irú àwọn àdììtú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pa mọ́ sáàárín àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù “tí gbogbo èèyàn ń lò” tàbí ti “àtètèkọ́ṣe” ni. Ọ̀gbẹ́ni Rips àtàwọn olùwádìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ pé àwọn gbé ìwádìí tí àwọn ṣe karí “ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì tí gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gbà, tí gbogbo èèyàn ń lò.” Ọ̀gbẹ́ni Drosnin kọ̀wé pé: “Àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi kọ gbogbo Bíbélì tó jẹ́ èdè Hébérù àtètèkọ́ṣe tó wà nísinsìnyí ló bára mu látòkèdélẹ̀.” Ṣùgbọ́n ṣé lóòótọ́ ni? Dípò kó jẹ́ ọ̀rọ̀ “tí gbogbo èèyàn ń lò,” onírúurú ẹ̀dà Bíbélì Lédè Hébérù làwọn èèyàn ń lò láyé ìsinyìí, tí a gbé karí onírúurú ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọfúnni inú Bíbélì ò yàtọ̀, àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi kọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyẹn ò bára mu látòkèdélẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ tó wà lónìí ni wọ́n gbé karí Ìwé Àfọwọ́kọ Alábala ti Leningrad—odindi Ìwé Hébérù táwọn Masorete ṣàdàkọ rẹ̀, tó tíì wà pẹ́ jù lọ—tí wọ́n dà kọ ní nǹkan bí ọdún 1000 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n Rips àti Drosnin lo ẹ̀dà Bíbélì mìíràn, tó ń jẹ́ Koren. Shlomo Sternberg, tí í ṣe olùkọ́ nínú ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, tó tún jẹ́ onímọ̀ ìṣirò ní Yunifásítì Harvard, ṣàlàyé pé Ìwé Àfọwọ́kọ Alábala ti Leningrad “fi lẹ́tà mọ́kànlélógójì yàtọ̀ sí ẹ̀dà Koren tí Drosnin lò, nínú ìwé Diutarónómì nìkan.” Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí wọ́n dà kọ ní ohun tó lé ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn wà nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Ọ̀nà ìkọ̀wé tí wọ́n lò nínú àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí sábà máa ń yàtọ̀ gan-an sí èyí tí àwọn Masorete lò nínú èyí tí wọ́n dà kọ. Nínú àwọn àkájọ ìwé kan, wọ́n fi ọ̀pọ̀ lẹ́tà kún un láti fi ìró àwọn fáwẹ́lì hàn, nítorí pé wọn ò tíì hùmọ̀ ọgbọ́n fífi fáwẹ̀lì síbi tó yẹ kó wà nígbà yẹn. Nínú àwọn àkájọ ìwé míì, wọ́n lo àwọn lẹ́tà tí kò pọ̀ tó yẹn. Ìfiwéra kan tí wọ́n ṣe láàárín gbogbo àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fi hàn pé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì ò yingin. Ṣùgbọ́n, ó tún fi hàn kedere pé ọ̀nà ìkọ̀wé àti iye àwọn lẹ́tà wọ́n yàtọ̀ síra.

Tí a bá ń wá àwọn àlàyé tí a rò pé ó fara sin, a nílò àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í yí padà. Tí a bá yí lẹ́tà kan padà nínú rẹ̀, á ba bí wọ́n ṣe tò ó jẹ́ pátápátá—á sì ba àlàyé inú ẹ̀ náà jẹ́, ìyẹn tó bá tiẹ̀ ní ìkankan nínú. Ọlọ́run pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní fáráyé mọ́ nípasẹ̀ Bíbélì. Ṣùgbọ́n kì í ṣe lẹ́tà kọ̀ọ̀kan ló pa mọ́, bíi pé àwọn ọ̀ràn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ló gbà á lọ́kàn, bí ìyípadà tó ti dé bá ọ̀nà ìkọ̀wé bọ́dún ti ń gorí ọdún. Ǹjẹ́ ìyẹn ò wá fi hàn pé kò kó àwọn ọ̀rọ̀ tó fara sin pa mọ́ sínú Bíbélì?— Aísáyà 40:8; 1 Pétérù 1:24, 25.

Ǹjẹ́ A Nílò Ẹnà Nínú Bíbélì?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lọ́nà tó ṣe kedere pé, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Àlàyé tó ṣe kedere, tó sì ṣe tààrà tí a rí nínú Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro láti lóye tàbí láti mú lò, àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló yàn láti má ṣe kà á sí. (Diutarónómì 30:11-14) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ṣàlàyé kedere nínú Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí tó gbámúṣé tí a fi lè gbà gbọ́ pé ó ní ìmísí. c Láìdà bíi ẹnà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kì í ṣe àdábọwọ́ ẹnì kan, wọn ò sì “wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí.”—2 Pétérù 1:19-21.

Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé, “kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 1:16) Èròǹgbà pé ẹnà wà nínú Bíbélì wá láti inú àṣà ìfòyemọlọ́run tí àwọn Júù ń dá, nínú èyí tí wọ́n ti ń lo àwọn ìlànà “àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá” tó ń bo ìtumọ̀ kedere ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ní ìmísí mọ́lẹ̀, tó sì ń lọ́ ọ lọ́rùn. Láìsí iyèméjì, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fúnra rẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu lílo irú àṣà ìbẹ́mìílò bẹ́ẹ̀.—Diutarónómì 13:1-5; 18:9-13.

Inú wa dùn gan-an pé a ní ìsọfúnni àti ìtọ́ni Bíbélì tó ṣe kedere, tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run! Ìyẹn sì dára ju gbígbìyànjú láti mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wa nípa wíwá àwọn ìsọfúnni tó fara sin kiri, èyí tó wá láti inú ìtumọ̀ àdábọwọ́ èèyàn àti èròǹgbà tí wọ́n ń fi kọ̀ǹpútà gbé lárugẹ.—Mátíù 7:24, 25.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú èdè Hébérù, wọ́n tún lè fi àwọn lẹ́tà rọ́pò nọ́ńbà. Nítorí náà, nínú àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù, àwọn lẹ́tà la fi pinnu àwọn déètì dípò nọ́ńbà.

b Èdè Hébérù ò ní fáwẹ̀lì nínú o. Ẹni tó bá ń kà á ló máa ń fi fáwẹ̀lì sáàárín ọ̀rọ̀ níbàámu pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ ohun tó ń kà. Bí èèyàn ò bá fi ti àyíká ọ̀rọ̀ ṣe, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó ń kà lè yí padà pátápátá tó bá lo àwọn fáwẹ̀lì tí ìró wọ́n yàtọ̀. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ní àwọn fáwẹ̀lì láàárín ọ̀rọ̀ tiẹ̀, èyí tó ń mú kí iṣẹ́ ìwádìí bẹ́ẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ṣòro gan-an, kó sì níbi téèyàn lè ṣe é dé.

c Láti rí ìsọfúnni sí i nípa ìmísí Bíbélì àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.