Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Dúró Ṣinṣin Láìbẹ̀rù Nígbà Tí Ìjọba Násì Ń Pọ́n Wọn Lójú

Wọ́n Dúró Ṣinṣin Láìbẹ̀rù Nígbà Tí Ìjọba Násì Ń Pọ́n Wọn Lójú

Wọ́n Dúró Ṣinṣin Láìbẹ̀rù Nígbà Tí Ìjọba Násì Ń Pọ́n Wọn Lójú

Ní June 17, 1946, Ọbabìnrin Wilhelmina ti ilẹ̀ Netherlands rán iṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ìdílé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Amsterdam. Ó lóun kan sáárá sí Jacob van Bennekom, ọmọkùnrin wọn nínú ìdílé náà, ẹni tí ìjọba Násì pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ìgbìmọ̀ ìlú Doetinchem, ìlú kan tó wà ní ìlà oòrùn Netherlands, pinnu pé àwọn yóò forúkọ Bernard Polman sọ àdúgbò kan nílùú yẹn, ọkùnrin yìí pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n pa nígbà ogun náà.

ÈÉ ṢE tí ìjọba Násì fi kọjúùjà sí Jacob, Bernard, àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mìíràn ní Netherlands nígbà Ogun Àgbáyé Kejì? Kí sì ni ohun tó fún àwọn Ẹlẹ́rìí yìí lókun láti jẹ́ olóòótọ́ lójú inúnibíni kíkorò fún ọ̀pọ̀ ọdún, táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn àti ọbabìnrin wọn pàápàá fi wá ń yìn wọ́n, tí wọ́n sì ń kan sáárá sí wọn? Ká lè mọ̀dí abájọ, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó yọrí sí irú ìforígbárí tó jọ ti Dáfídì òun Gòláyátì, èyí tó wáyé láàárín àwùjọ kékeré àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá ìjọba Násì.

Wọ́n Fòfin Dè Wọ́n—Àmọ́ Agbára Wọn Ń Pọ̀ Sí I

May 10, 1940 lẹgbẹ́ ọmọ ogun ìjọba Násì rọ́ dé Netherlands. Gbàrà tí wọ́n dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí pé ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí ń pín kiri ń tú àṣírí gbogbo iṣẹ́ burúkú tí ìjọba Násì ń ṣe, àti nítorí pé àwọn ìwé náà ń ṣe alágbàwí Ìjọba Ọlọ́run. Kò tiẹ̀ tíì pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta táwọn Násì gbógun wá sí Netherlands, tí wọ́n ti gbé òfin kan jáde nídàákọ́ńkọ́, tí wọ́n sọ pé àwọn fòfin de Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní March 10, 1941, ni ìròyìn kan sọ ọ́ fáráyé gbọ́ pé wọ́n ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n ní ńṣe ni wọ́n ń dáná ọ̀tẹ̀ “lòdì síjọba àti gbogbo ètò ẹ̀sìn.” Wọ́n wá túbọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fimú fínlẹ̀, wọ́n ń ṣọdẹ àwọn Ẹlẹ́rìí kiri.

Àmọ́, ó yẹ fún àfiyèsí pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àjọ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí wọ́n ń pè ní Gestapo ń ṣọ́ gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì, ètò àjọ Kristẹni kan ṣoṣo ló ń ṣe inúnibíni sí burúkú-burúkú. Òpìtàn ará Dutch náà, Ọ̀mọ̀wé Louis de Jong sọ pé: “Ètò ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni wọ́n ṣe inúnibíni sí lọ́nà tó yọrí sí ikú—ètò ẹ̀sìn yìí ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Het Koninkrijk der Nederlanden in de Tweede Wereldoorlog (Ìjọba Netherlands Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì).

Àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Dutch lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn Gestapo láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn, kí wọ́n sì mú wọn. Ní àfikún, alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó ya ojo, tó sì di apẹ̀yìndà, fún ìjọba Násì ní ìsọfúnni nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà tó fi máa di ìparí April 1941, àádọ́fà lé mẹ́ta Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti mú. Ǹjẹ́ ìkọlù yìí dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró?

Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn wà nínú Meldungen aus den Niederlanden (Ìròyìn Láti Netherlands), ìwé àṣírí kan tí Sicherheitspolizei (àwọn Ọlọ́pàá Inú) Jámánì kọ ní April 1941. Ìròyìn náà sọ nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Ẹ̀ya ìsìn táa kà léèwọ̀ yìí ṣì ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ ní rabidun ní gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n ń ṣèpàdé tí kò bófin mu, wọ́n sì ń lẹ àwọn ìwé tó ní àkọlé bíi ‘Ṣíṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run jẹ́ ìwà ọ̀daràn’ àti ‘Jèhófà yóò pa àwọn onínúnibíni run yán-ányán-án’” kiri. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ìwé táa ń sọ yìí kan náà ròyìn pé “bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ọlọ́pàá Inú tún múra kankan lòdì sí ìgbòkègbodò àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe ni ìgbòkègbodò wọ́n ń pọ̀ sí i.” Òótọ́ ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé wọ́n lè mú àwọn, síbẹ̀ wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, wọ́n fi ìwé tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ààbọ̀ [350,000] sóde lọ́dún 1941 nìkan!

Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún agbo àwọn Ẹlẹ́rìí kéréje yìí tí kò ju ọgọ́rùn-ún mélòó kan, ṣùgbọ́n tí ń pọ̀ sí i níye, láti ní ìgboyà láti kojú àwọn ọ̀tá wọn tó lè da jìnnìjìnnì boni? Gẹ́gẹ́ bíi ti Aísáyà wòlíì ìgbàanì, Ọlọ́run làwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rù, kì í ṣe ènìyàn. Èé ṣe? Nítorí wọn ò jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ ìkìyà tí Jèhófà sọ fún Aísáyà, pé: “Èmi—èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú. Ta ni ọ́ tí ìwọ yóò fi máa fòyà ẹni kíkú?”—Aísáyà 51:12.

Àìṣojo Ń Gbéni Níyì

Nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 1941, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti mú ti wọ igba ó lé mọ́kànlélógójì. Àmọ́ o, àwọn díẹ̀ ṣojo. Willy Lages, táwọn èèyàn kà sí òǹrorò lára àwọn ọlọ́pàá inú Jámánì, la gbọ́ pé ó sọ pé “ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ̀ jálẹ̀ láti tú ẹnikẹ́ni fó, àmọ́ ìwọ̀nba kéréje lára àwọn mẹ́ńbà ètò ẹ̀sìn yòókù ló lè dákẹ́.” Àlùfáà ará Dutch nì, Johannes J. Buskes, tóun àtàwọn Ẹlẹ́rìí kan jọ ṣẹ̀wọ̀n, ṣe àlàyé kan tó ti ọ̀rọ̀ Lages lẹ́yìn. Ní 1951, Buskes kọ̀wé pé:

“Mo rántí pé nígbà yẹn, wọ́n níyì gan-an lójú mi nítorí bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run àti bí ìgbàgbọ́ wọ́n ti lágbára tó. Mi ò lè gbàgbé ọ̀dọ́mọkùnrin kan láé—mi ò rò pé ó lè ju ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún péré lọ—tó lọ pín àwọn ìwé ìléwọ́ tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Hitler àti Ìjọba rẹ̀. . . . Wọn ì bá tú u sílẹ̀ láàárín oṣù mẹ́fà ká ní ó ṣèlérí pé òun ò ní ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́. Àmọ́, ó ní láéláé òun ò lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀, wọ́n wá ní kó nìṣó ní Jámánì, kó lọ máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó níbẹ̀ títí lọ gbére nínú àgọ́ ìmúnisìn. A kúkú mọ ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Àárọ̀ ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n ń mú un lọ, a kí i pé ó dìgbòóṣe, mo sì sọ fún un pé ọkàn wa ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a ó sì máa gbàdúrà fún un. Èsì kan ṣoṣo tó fọ̀ ni pé: ‘Ẹ má ṣàníyàn nípa mi. Ó dájú pé Ìjọba Ọlọ́run á dé.’ Èèyàn ò lè gbàgbé irú nǹkan báyìí, bó ti wù kónítọ̀hún kórìíra ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí tó.”

Láìka àtakò tó burú jáì sí, iye àwọn Ẹlẹ́rìí ń pọ̀ sí i ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ni wọ́n, ní kété ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, iye yẹn ti di egbèje dín mọ́kànlélógún [1,379] lọ́dún 1943. Ó ṣeni láàánú pé nígbà tí ọdún yẹn máa fi parí, mẹ́rìnléláàádọ́ta ló kú sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún lé láàádọ́ta tí wọ́n mú. Títí di ọdún 1944, ọ̀kànlélógóje Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Netherlands ló ṣì wà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ káàkiri.

Ọdún Tó Gbẹ̀yìn Inúnibíni Násì

June 6, 1944 làwọn ọmọ ogun Alájọṣepọ̀ gbógun ti ilẹ̀ Faransé, kò sì kádún lẹ́yìn náà tí inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí fi dópin. Nígbà yẹn, ọwọ́ ọ̀tá ti ń ba àwọn Násì àtàwọn alájọṣe wọn. Ńṣe lèèyàn máa rò pé èyí á tiẹ̀ jẹ́ káwọn Násì ṣíwọ́ fífìtínà àwọn Kristẹni aláìmọwọ́ mẹsẹ̀. Síbẹ̀, lọ́dún yẹn, wọ́n ṣì tún mú méjìdínláàádọ́ta àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n tún pa méjìdínláàádọ́rin àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n, ní àfikún sáwọn tí wọ́n ti pa tẹ́lẹ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Jacob van Bennekom, táa mẹ́nu kàn ṣáájú.

Jacob ọmọ ọdún méjìndínlógún wà lára okòó dín lẹ́gbẹ̀ta àwọn tó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1941. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tó fi iṣẹ́ olówó ńlá kan sílẹ̀ nítorí kò sí bó ṣe lè wà láìdásí tọ̀tún-tòsì gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tó bá ń bá iṣẹ́ yẹn lọ. Ó wá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí mẹ́séńjà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Wọ́n ká àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ ọn lọ́wọ́ nígbà tó ń kó wọn lọ síbì kan, wọ́n sì mú un. Ní August 1944, Jacob ẹni ọdún mọ́kànlélógún kọ̀wé sí ìdílé rẹ̀ láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan nílùú Rotterdam, pé:

“Ọkàn mi balẹ̀ dáadáa, ayọ̀ sì kún inú mi. . . . Ó ti di ẹ̀ẹ̀mẹrin tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò báyìí. Ojú mi rí màbo nígbà méjì àkọ́kọ́, wọ́n lù mí, ẹ̀mí mi fẹ́ẹ̀ẹ́ bọ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ okun àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa, títí di báa ti ń wí yìí, mi ò tú àṣírí kankan sí wọn lọ́wọ́. . . . Mo ti ń sọ àsọyé fún wọn níbí o, àsọyé mẹ́fà ni mo ti sọ, àpapọ̀ iye àwọn tó wá gbọ́ ọ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ó lé méjì. Àwọn kan nínú wọ́n fìfẹ́ hàn gan-an ni, wọ́n sì ti ṣèlérí pé gbàrà tí àwọ́n bá ti jáde níbí, àwọ́n á máa tẹ̀ síwájú.”

Ní September 14, 1944, wọ́n mú Jacob lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan nílùú Amersfoort nílẹ̀ Dutch. Ṣe ló tún ń bá ìwàásù rẹ̀ nìṣó níbẹ̀. Báwo ló ṣe ń ṣe é? Ẹnì kan tí wọ́n jọ ṣẹ̀wọ̀n rántí pé: “Àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń sáré mú àmukù sìgá táwọn wọ́dà bá mu kù, wọ́n sì máa ń fi àwọn bébà Bíbélì pọ́n sìgá. Nígbà míì, Jacob máa ń lè ka ọ̀rọ̀ díẹ̀-dìẹ̀-díẹ̀ láti inú bébà Bíbélì kí wọ́n tó fi wọ́n pọ́n sìgá. Ojú ẹsẹ̀ ló máa ń fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wàásù fún wa. Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ sí pe Jacob ní ‘Ọ̀gbẹ́ni Oníbíbélì.’”

Ní October 1944, Jacob wà lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ní kó wa kòtò ńlá tí wọ́n fẹ́ fi dẹ páńpẹ́ de àwọn ọkọ̀ arọ̀jò ọta. Jacob kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ní ṣe irú iṣẹ́ yẹn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn òun kò ní jẹ́ kóun kọ́wọ́ ti ogun jíjà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo làwọn wọ́dà máa ń halẹ̀ mọ́ ọn, kò tìtorí ìyẹn juwọ́ sílẹ̀. Ní October 13, ọ̀gá kan lọ mú un ní ibi tí wọ́n há òun nìkan mọ́, ó mú un wá síbi tí wọ́n ti ń wa kòtò náà. Jacob tún kọ̀ jálẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n pàṣẹ pé kí Jacob fi ọwọ́ ara ẹ̀ gbẹ́ sàréè ara ẹ̀, wọ́n sì yìnbọn pa á.

Wọn Ò Dẹ̀yìn Lẹ́yìn Àwọn Ẹlẹ́rìí

Ìdúró gbọn-in Jacob àtàwọn yòókù bí àwọn Násì nínú gan-an, èyí jẹ́ kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn Ẹlẹ́rìí kiri. Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ń wá ni Evert Kettelarij, ọmọ ọdún méjìdínlógún. Evert kọ́kọ́ bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, ó sì lọ sá pa mọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe, wọ́n he é, wọ́n sì lù ú bí ẹní máa pa á, kí ó lè dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù fún wọn. Ó kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sì fi í ránṣẹ́ sí Jámánì kó lọ máa ṣiṣẹ́ bí ẹrú níbẹ̀.

Ní oṣù kan náà, ìyẹn October 1944, àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọkọ ẹ̀gbọ́n Evert kiri, ìyẹn Bernard Luimes. Nígbà tọ́wọ́ wọn tẹ̀ ẹ́, òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí méjì ni wọ́n jọ wà—àwọn ni Antonie Rehmeijer àti Albertus Bos. Albertus ti lo oṣù mẹ́rìnlá ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, gbàrà tí wọ́n tú u sílẹ̀ ló tún bẹ̀rẹ̀ sí fi ìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu. Àwọn Násì kọ́kọ́ lu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nílùkulù, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá yìnbọn pa wọ́n. Ogun yẹn ti parí ká tó rí òkú wọn, ká tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ tún wọn sin. Ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ló ròyìn nípa bí wọ́n ṣe pa wọ́n yìí kété lẹ́yìn ogun náà. Ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ kankan tó lòdì sófin Ọlọ́run fáwọn Násì, ìwé ìròyìn náà sì fi kún un pé “nítorí èyí, wọ́n fi ẹ̀mí wọn dí i.”

Kó tó dìgbà yẹn, ní November 10, 1944, wọ́n mú Bernard Polman, táa mẹ́nu kàn ṣáájú, wọ́n sì ní kó lọ máa ṣe iṣẹ́ kan tó jẹ mọ ọ̀ràn ogun. Òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí láàárín gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àfipámúniṣe náà, òun nìkan ló sì fàáké kọ́rí pé òun ò ni ṣiṣẹ́ náà. Kò sí nǹkan táwọn wọ́dà ò ṣe kí ó lè gbà láti ṣe iṣẹ́ náà. Wọn ò fún un lóúnjẹ rárá. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí fi kùmọ̀, ṣọ́bìrì, àti ìdí ìbọn lù ú. Kò mọ síbẹ̀ o, wọ́n tún fi túláàsì mú un pé kó gba inú omi tó tutù bíi yìnyín, tó dé orúnkún, kọjá, lẹ́yìn náà ni wọ́n tún tì í mọ́ àjàalẹ̀ tó ní ọ̀rinrin, ibẹ̀ ló wà mọ́jú nínú aṣọ rẹ̀ tó tutù rinrin. Síbẹ̀, Bernard ò juwọ́ sílẹ̀.

Nígbà yẹn, wọ́n jẹ́ kí méjì lára àwọn arábìnrin Bernard tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n rọ̀ ọ́ pé kí ó pèrò dà, ṣùgbọ́n èyí kò mú un bọ́hùn. Nígbà tí wọ́n bi Bernard bóyá ó lóhun táwọn lè ṣe fún un, ó gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa lọọlé, kí wọ́n lọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí i wá jẹ́ kíyàwó rẹ̀ tó wà nínú oyún wá bẹ̀ ẹ́ wò, wọ́n rò pé ìyàwó rẹ̀ á lè ṣe é kó juwọ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ńṣe ni àbẹ̀wò obìnrin náà àti ọ̀rọ̀ ìyànjú tó tẹnu rẹ̀ jáde túbọ̀ fún Bernard lókun láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ní November 17, 1944, márùn-ún lára àwọn tó ti ń dá Bernard lóró yìnbọn pa á níṣojú àwọn yòókù tí wọ́n ń kó ṣiṣẹ́ bí ẹrú. Àní lẹ́yìn tí Bernard kú tán pàápàá, tí ọta ìbọn ti ba gbogbo ara rẹ̀ jẹ́, orí ọ̀gá wọn gbóná débi pé ó fa ìbọn ìléwọ́ tirẹ̀ yọ, ó sì yìn ín fọ́ ojú Bernard méjèèjì.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà òǹrorò yìí mú káwọn Ẹlẹ́rìí tó gbọ́ nípa ìpànìyàn yìí gbọ̀nrìrì, wọ́n dúró gbọn-in láìbẹ̀rù, wọ́n sì ń bá ìgbòkègbodò Kristẹni wọn lọ. Ìjọ kékeré àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó wà nítòsí ibi tí wọ́n ti pa Bernard, ròyìn gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa á pé: “Lóṣù yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ọjọ́ ò dáa, tí Sátánì sì gbé ọ̀pọ̀ òkè ìṣòro kò wá, ńṣe ni iṣẹ́ wa ń tẹ̀ síwájú. Iye wákàtí táa lò ní pápá lọ sókè látorí irínwó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [429] dórí ẹgbẹ̀rin dín márùndínlógójì [765]. . . . Nígbà tí arákùnrin kan ń wàásù, ó pàdé ọkùnrin kan tí ìwàásù rẹ̀ wọ̀ lọ́kàn gan-an. Ọkùnrin náà béèrè bóyá ẹ̀sìn yìí ni ọkùnrin tí wọ́n yìnbọn pa yẹn ń ṣe. Nígbà tó gbọ́ pé ẹ̀sìn yẹn ni, ọkùnrin náà kígbe pé: ‘Ọkùnrin mẹ́ta ni, ìgbàgbọ́ rẹ̀ mà lágbára o! Akọni nínú ìgbàgbọ́ ni o jàre!’”

Jèhófà Ò Jẹ́ Gbàgbé Wọn

Ní May 1945, wọ́n ṣẹ́gun àwọn Násì, wọ́n sì lé wọn kúrò ní Netherlands. Láìka gbogbo inúnibíni àìdabọ̀ tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ogun sí, iye àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sókè látorí ọgọ́rùn-ún mélòó kan dórí iye tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì. Nígbà tí òpìtàn nì, Ọ̀jọ̀gbọ́n de Jong, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nígbà ogun, ó sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ wọn, tí wọ́n sì ń dá wọn lóró.”

Ìdí rèé táwọn aláṣẹ ayé kan fi rántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí ìgboyà tí wọ́n ní láti kojú ìjọba Násì. Ṣùgbọ́n, ohun tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn ni pé Jèhófà àti Jésù ò jẹ́ gbàgbé gudugudu méje táwọn Ẹlẹ́rìí ìgbà ogun wọ̀nyí ṣe. (Hébérù 6:10) Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Jésù Kristi tó ti sún mọ́lé yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí tó dúró gbọn-in láìbẹ̀rù, tó fi ẹ̀mí wọn jin iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ni a óò gbé dìde látinú ibojì ìrántí, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà láti wà láàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé!—Jòhánù 5:28, 29.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Jacob van Bennekom

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀rọ̀ inú ìwé ìròyìn táa gé, tó sọ̀rọ̀ nípa òfin tí wọ́n fi de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Lápá ọ̀tún: Bernard Luimes; nísàlẹ̀: Albertus Bos (lápá òsì) àti Antonie Rehmeijer; nísàlẹ̀: ẹ̀ka iléeṣẹ́ Society ní Heemstede