À Ń Fẹ́ Ìtùnú Gan-An Ni!
À Ń Fẹ́ Ìtùnú Gan-An Ni!
“Sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.”—ONÍWÀÁSÙ 4:1.
ṢÉ Ò ń fẹ́ ìtùnú? Ǹjẹ́ ò ń yán hànhàn fún ìtùnú tó lè mú ẹ borí ipò tó mú kó dà bíi pé gbogbo ìrètí rẹ ti já sófo? Ṣé ò ń fẹ́ ìtùnú díẹ̀ tó sáà lè mú ayé rẹ dùn, ayé kan tí ìyà tí ò ṣeé fẹ́nu sọ àti àwọn ohun ìbànújẹ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ ti sọ di báṣubàṣu?
Nígbà kọ̀ọ̀kan, a máa ń fẹ́ ìtùnú àti ìṣírí. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan lojú ẹni ń rí nílé ayé yìí tó ń bani nínú jẹ́. Gbogbo wa là ń fẹ́ ká ràdọ̀ bò wá, ká fìfẹ́ hàn sí wa, ká gbá wa mọ́ra. Àwọn kan lára wa ti darúgbó, èyí ò sì múnú wọn dùn. Àwọn míì sì ń kárí sọ nítorí pé ìgbésí ayé ò rí bí wọ́n ṣe rò pé yóò rí. Àwọn mìíràn sì rèé, ìròyìn tí wọ́n gbọ́ láti ilé ìṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ti mì wọ́n jìgìjìgì.
Láfikún sí i, táa bá gbé e sọ́tùn-ún, gbé e sósì, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ni yóò jiyàn pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ò mú ká túbọ̀ nílò ìtùnú àti ìrètí. Ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí nìkan ṣoṣo, àwọn tó bógun lọ lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù. a Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló fi ìdílé wọn sínú ọ̀fọ̀, tí àwọn ìdílé wọ̀nyí sì wá nílò ìtùnú lójú méjèèjì, ìyẹn àwọn màmá àti baba wọn, àwọn arábìnrin àti arákùnrin wọn, àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn. Lónìí, àwọn tí kò ní gá, tí kò ní go, lé ní bílíọ̀nù kan. Ìlàjì àwọn olùgbé ayé ni ò rówó gbàtọ́jú lọ́sibítù, tí wọn ò sì rí kọ́bọ̀ ra oògùn. Nígboro àwọn ìlú ńláńlá táa ti sọ dìdàkudà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ táwọn òbí wọn sá fi sílẹ̀, ló ń rìn gbéregbère kiri, ọ̀pọ̀ lára wọn ti di ajoògùnyó, wọ́n sì ti gbaṣẹ́ aṣẹ́wó. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ogun ti lé nílùú ló ń jẹ palaba ìyà nínú àwọn ibùdó tó jẹ́ pé ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ ò dáa rárá.
Àmọ́ ṣá o, bó ti wu kí iye náà pọ̀ tó, ìyẹn ò ní ká mọ bí ìdààmú àti ìpọ́njú tó dé bá àwọn èèyàn náà ti tó. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa Svetlana, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó wá láti ilẹ̀ àwọn Balkan, tó jẹ́ pé wọ́n b Ó sọ pé, “nítorí àtirówó ná, àwọn òbí mi á rán mi jáde pé kí n lọ tọrọ báárà tàbí kí n lọ jalè. Ìgbésí ayé ìdílé wa bà jẹ́ débi pé àwọn ìbátan mi bẹ̀rẹ̀ sí bá mi sùn. Nígbà tó yá, mo ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbáwo, màmá mi, tí mò ń kó owó náà fún sọ pé, bí iṣẹ́ yẹn bá fi lè bọ́ lọ́wọ́ mi, òun á para òun. Gbogbo èyí ló wá sọ mí di aṣẹ́wó. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá péré sì ni mí nígbà yẹn o. Kò pẹ́ púpọ̀, mo lóyún, mo sì ṣẹ́ ẹ. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ẹní bá rí mi á rò pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni mí.”
tálákà ju èkúté ṣọ́ọ̀ṣì lọ nílé wọn.Laimonis, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó wá láti Latvia, sọ bó ṣe fẹ́ ìtùnú tó àti àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i, tó mú kó máa kárí sọ. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni nígbà tí ìjàǹbá ọkọ̀ sọ ọ́ dí ẹni tí ìbàdí rẹ̀ sísàlẹ̀ rọ pátápátá. Ayé sú u dé góńgó, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí mutí àmuyíràá. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, kò jéèyàn mọ́, ó ti di òkú ọ̀mùtí alárùn ẹ̀gbà tílé ayé ti sú. Ibo ló ti wá lè rí ìtùnú?
Tàbí kóo ronú nípa Angie. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ inú ọpọlọ fún ọkọ rẹ̀, èyí ló kọ́kọ́ sọ ọ́ di ẹni tí apa kan ara rẹ̀ rọ. Lẹ́yìn èyí, lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tó kẹ́yìn, jàǹbá ọkọ̀ kan ṣẹlẹ̀ sí i, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tíyàwó rẹ̀ wọnú yàrá ìtọ́jú pàjáwìrì, tó rí ọkọ rẹ̀ tó ti sùn lọ gbári nítorí orí tó fi pa, ó mọ̀ pé wàhálà ló ń bọ̀ yẹn. Nǹkan ò lè rọrùn fún òun àti ìdílé rẹ̀. Báwo ni yóò ṣe rí ìtìlẹyìn àti ìṣírí?
Ní ti Pat, ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní ìgbà ọ̀gìn-nìtìn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, gbogbo nǹkan ń lọ déédéé. Àmọ́ ṣá o, kò lè rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní ọjọ́ mẹ́ta tó tẹ̀ lé e. Ọkọ rẹ̀ ṣàlàyé fún un pé nígbà tí àyà dùn ún títí, ni ọkàn-àyà rẹ̀ bá kọṣẹ́. Ọkàn-àyà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lù kì-kì-kì, kíkankíkan, lójijì, ni kò bá ṣiṣẹ́ mọ́. Ni kò bá lè mí mọ́. Pat sọ pé: “Mo kú tán díẹ̀ ló kù.” Lọ́nà kan ṣá, ó yè é. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìgbà tó fi wà ní ọsibítù, ó ní: “Ọ̀pọ̀ jáǹtírẹrẹ àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe fún mi bà mí lẹ́rù, pàápàá jù lọ nígbà tí wọ́n fẹ́ gbìyànjú láti mú kí ọkàn-àyà mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kó sì tún dáwọ́ dúró, bó ti ṣe lọ́jọ́sí.” Kí ló lè fún un ní ìtùnú àti ìtura tó ń fẹ́ ní àkókò líle koko yìí?
Joe àti Rebecca pàdánù ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún mọ́kàndínlógún nínú jàǹbá ọkọ̀. Wọ́n wí pé: “Àjálù báyìí kò dé bá wa rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà àtijọ́, a ti bá àwọn ẹlòmíràn kẹ́dùn nígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wọ́n, àmọ́ kò bà wá lọ́kàn jẹ́ tó báyìí rí.” Kí ló wá lè mú irú “ẹ̀dùn ọkàn” bẹ́ẹ̀ kúrò—ẹ̀dùn ọkàn ikú ẹnì kan tí èèyàn fẹ́ràn gan-an?
Gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn, ti rí ìtùnú àti ìtura tó kọyọyọ. Tóo bá fẹ́ mọ bíwọ náà ṣe lè jàǹfààní láti orísun yẹn, jọ̀wọ́ máa kàwé yìí nìṣó.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kò sẹ́ni tó mọye àwọn sójà àti àwọn aráàlú tó ti kú ní pàtó. Fún àpẹẹrẹ, ìwé 1998 Facts About the American Wars sọ nípa Ogun Àgbáyé Kejì nìkan pé: “Ọ̀pọ̀ orísun ìsọfúnni ló sọ pé àpapọ̀ iye àwọn tó kú sí Ogun Àgbáyé Kejì (àtisójà àti aráàlú) jẹ́ àádọ́ta mílíọ̀nù, ṣùgbọ́n àwọn tó fara balẹ̀ ṣèwádìí náà gbà pé wọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ—àní, wọ́n tó ìlọ́po méjì iye yẹn.”
b A ti pa orúkọ náà dà.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ/J. K. ISAAC LÓ YA FỌ́TÒ YÌÍ
FỌ́TỌ̀ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ 146150, TÍ O. MONSEN YÀ