Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Lójú Jèhófà
Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Lójú Jèhófà
Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì rí lẹ́tà tó tẹ̀ le yìí gbà:
“Ọmọdékùnrin ọlọ́dún méje ni mí. Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni mo ṣì wà. Mò ń fi owó yìí tí mo rí nígbà tí mo ta àkùkọ mi tí mò ń sìn ránṣẹ́. Ẹgbẹ̀rún méjìlá Métíkà owó ilẹ̀ Mòsáńbíìkì [dọ́là kan owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà] ni mo tà á. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ kí ọmọ adìẹ tí màá kọ́kọ́ sìn láyé mi dàgbà di àkùkọ ńlá. Màá fẹ́ ká lo ẹ̀bùn mi fún iṣẹ́ Ìjọba Jèhófà.
“Àfikún àlàyé: Baba mi ló bá mi kọ̀wé yìí.”
Lójú àwọn kan, kìkì àwọn tó jẹ ṣẹ́ kù nìkan ló lè lẹ́mìí ọ̀làwọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà táa bá ka àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa opó tó sọ “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” sínú àpótí ìṣúra, a lè wá mọyì ẹ̀ pé kìí ṣe bí nǹkan ṣe pọ̀ tó la fi ń sọ pé èèyàn lẹ́mìí ọ̀làwọ́, bí kò ṣe kéèyàn nítẹ̀sí ọkàn-àyà tó tọ́.—Lúùkù 21:1-4.
Bó ti wù kẹ́bùn kan ó kéré tó, Jèhófà máa ń mọrírì rẹ̀, tó bá ti tinú ọkàn tí ìfẹ́ sún ṣiṣẹ́ wá. Wọ̀ǹtì-wọnti ló sì máa ń bù kún àwọn tó bá ṣàfarawé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ rẹ̀ nípa lílo àkókò, okun, tàbí ohun ìní wọn nípa tara nítorí Ìjọba rẹ̀.—Mátíù 6:33; Hébérù 6:10.