Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ò Ń Dámọ̀ràn Ara Rẹ Fáwọn Ẹlòmíràn?

Ṣé Ò Ń Dámọ̀ràn Ara Rẹ Fáwọn Ẹlòmíràn?

Ṣé Ò Ń Dámọ̀ràn Ara Rẹ Fáwọn Ẹlòmíràn?

‘Ohun yòówù káwọn èèyàn máa rò nípa mi, àgunlá wọn!’ Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti la irú ọ̀rọ̀ yìí mọ́lẹ̀ rí nígbà tínú bí ọ tàbí nígbà tí nǹkan kan mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tójú ẹ bá walẹ̀ tán, ọ̀ràn náà lè máà jẹ́ kí ara rẹ lélẹ̀ mọ́. Èé ṣe? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ló bìkítà gan-an nípa ohun táwọn èèyàn ń rò nípa wa.

NÍ TÒÓTỌ́, ó yẹ ká bìkítà nípa ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wò wá. Pàápàá jù lọ, àwa Kristẹni, àwa òjíṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ti yàn, gbọ́dọ̀ bìkítà gidigidi nípa ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wò wá. Ó ṣe tán, ‘ìran àpéwò la jẹ́ fún ayé.’ (1 Kọ́ríńtì 4:9) Nínú 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4, a rí ìmọ̀ràn tó yè kooro tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni, tó kà pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”

Ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí láti dámọ̀ràn ara wa fún àwọn ẹlòmíràn? Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa gbéra wa ga tàbí ká máa fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwa la wà ńbẹ̀ tàbí kí wọ́n mọ̀ pé a mọ nǹkan ṣe? Rárá o. Ṣùgbọ́n ohun tó ń béèrè ni pé ká fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Pétérù 2:12 sọ́kàn, èyí tó wí pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé . . . kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo.” Àwọn Kristẹni máa ń dámọ̀ràn ara wọn nípa jíjẹ́ kí ìwà wọn fi irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ hàn! Ní àbárèbábọ̀, Ọlọ́run ni èyí ń mú ìyìn wá fún, kì í ṣe àwa fúnra wa. Síbẹ̀síbẹ̀, táa bá ń dámọ̀ràn ara wa fún àwọn ẹlòmíràn, ó lè jẹ́ fún àǹfààní ara wa. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yẹ̀ wò tí èyí fi lè rí bẹ́ẹ̀.

Gẹ́gẹ́ Bí Ọkọ Tàbí Aya Rere Lọ́la

Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ìgbéyàwó yẹ̀ wò. Ó jẹ́ ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, ẹni “tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:15) Bóyá ìwọ náà ń dà á rò pé lọ́jọ́ kan wàá ṣègbéyàwó. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe ń dámọ̀ràn ara rẹ tó pé o lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere? Àní, irú àpọ́n Kristẹni ọkùnrin tàbí obìnrin wo ni àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí?

Ní àwọn ilẹ̀ kan àwọn mọ̀lẹ́bí kì í fọ̀rọ̀ yìí ṣeré rárá o. Fún àpẹẹrẹ, ní Gánà, nígbà táwọn ẹni méjì bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà, àṣà wọn ni pé kí àwọn méjèèjì lọ sọ fáwọn òbí wọn. Ẹ̀wẹ̀, àwọn òbí yóò sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Àwọn ẹbi ọkùnrin yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láti mọ irú èèyàn tí obìnrin náà jẹ́ ládùúgbò. Nígbà táwọn òbí ọkùnrin náà bá rí i pé obìnrin náà lórúkọ tó dáa, wọn yóò wá sọ fáwọn ẹbí obìnrin náà pé ọmọ àwọn fẹ́ fi ọmọ wọn ṣaya. Àwọn ẹbí obìnrin náà yóò tún wádìí ọmọkùnrin náà kí wọ́n tó fọwọ́ sí ìgbéyàwó ọ̀hún. Òwe àwọn ará Gánà kan sọ pé: “Wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tó mọ ẹni tóo fẹ́ẹ́ fẹ́, kóo tó wọnú àdéhùn ìgbéyàwó.”

Ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ayé ńkọ́, níbi tí wọ́n ti yọ̀ǹda kí olúkúlùkù yan ẹni tó bá wù ú láti fẹ́? Níbẹ̀ pàápàá, ó bọ́gbọ́n mu pé kí ọkùnrin tàbí obìnrin Kristẹni kan tó dàgbà dénú wádìí bí ẹni tí òun fẹ́ẹ́ fẹ́ ti ń ṣe sí lọ́wọ́ àwọn òbí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó dàgbà dénú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ti sọ, ọ̀dọ́mọbìnrin kan lè béèrè pé: “‘Irú ènìyàn wo ni a mọ ọkùnrin yìí sí? Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ó ha ń fi ìkóra-ẹni-níjàánu hàn bí? Báwo ni ó ṣe ń hùwà sí àwọn àgbàlagbà? Irú ìdílé wo ni ó ti wá? Báwo ni ó ṣe ń bá wọn lò? Kí ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ nípa owó? Ó ha jẹ́ onímukúmu bí? Ó ha máa ń tètè bínú, tí ó sì máa ń fara ya pàápàá? Àwọn ẹrù iṣẹ́ wo ni ó ní nínú ìjọ, báwo ni ó sì ṣe ń bójú tó wọn? Mo ha lè ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un bí?’—Léfítíkù 19:32; Òwe 22:29; 31:23; Éfésù 5:3-5, 33; 1 Tímótì 5:8; 6:10; Títù 2:6, 7.” a

Bákan náà ni ọkùnrin kan yóò ṣe fẹ́ wádìí nípa Kristẹni obìnrin kan tó fẹ́ẹ́ fẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, Bóásì ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí Rúùtù, ìyẹn obìnrin tó wá fẹ́ níkẹyìn. Nígbà tí Rúùtù béèrè pé: “Báwo ni ó ti jẹ́ tí mo fi rí ojú rere lójú rẹ, tí a fi ṣàkíyèsí mi, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?” Bóásì dáhùn pé: “A ròyìn fún mi ní kíkún nípa gbogbo ohun tí o ṣe.” ( Rúùtù 2:10-12) Bẹ́ẹ̀ ni, kìí ṣe pé Bóásì pàápàá ń kíyè sí Rúùtù pé ó jẹ́ adúróṣinṣin, ẹni tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, alákitiyan obìnrin nìkan ni, àmọ́, ó tún gbọ́ ìròyìn rere nípa rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Bákan náà, ìwà rẹ yóò nípa lórí ojú tí àwọn ẹlòmíràn fi ń wò ọ́ ní ti pé bóyá o lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere. Báwo gan-an ló ṣe ń dámọ̀ràn ara rẹ fún àwọn mìíràn nínú ọ̀ràn yìí?

Gẹ́gẹ́ Bí Òṣìṣẹ́

Ibi iṣẹ́ jẹ́ àgbègbè mìíràn tí níní ìwà rere ti lè mú àǹfààní wá fún ọ. Àwọn tó ń wáṣẹ́ lè pọ̀ o. Lọ́pọ̀ ìgbà la sì máa ń lé àwọn òṣìṣẹ́ kan dànù torí pé wọ́n jẹ́ alágídí, wọ́n kìí tètè débi iṣẹ́, wọ́n sì tún jẹ́ òpùrọ́. Àwọn ilé iṣẹ́ tún lè dá àwọn òṣìṣẹ́ kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ dúró nítorí àtilè dín owónàá kù. Nígbà tí àwọn tó ń wáṣẹ́ bá ń wáṣẹ́ tuntun, wọ́n lè rí i pé àwọn ilé iṣẹ́ máa ń wádìí lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti bá ṣiṣẹ́ rí, kí wọ́n lè mọ ọwọ́ tí wọ́n fi ń múṣẹ́ wọn, ìwà wọn, àti ìrírí wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti dámọ̀ràn ara wọn lọ́nà tó dára fún àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ nípa ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n ń hù, ìmúra wọn tó máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti àwọn ànímọ́ Kristẹni tó tayọ tí wọ́n ní.

Jíjẹ́ olóòótọ́ jẹ́ ọ̀kan lára irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀—ìyẹn ni ànímọ́ tí àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń fẹ́ jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a fẹ́ máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Nínú ilé iṣẹ́ ìwakùsà kan ní Gánà, ìròyìn tó àwọn aláṣẹ létí pé àwọn kan ń ṣàfọwọ́rá. Bí wọ́n ṣe lé gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ dà nù nìyẹn o, àyàfi Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọ̀gá nídìí ẹrọ tí ń yọ́ nǹkan mọ́, nìkan ni wọn ò dá dúró. Nítorí kí ni? Àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ náà ti kíyè sí ìṣòtítọ́ rẹ̀ látìgbà tó ti ń bá wọn ṣiṣẹ́. Wọ́n sì mọ ọkùnrin yìí sí ẹni tí kì í fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré, tí kì í sì í fọwọ́ pa idà àwọn aláṣẹ lójú. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà rere tó ní, ni kò jẹ́ kíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀!

Kí làwọn nǹkan míì tí Kristẹni kan lè ṣe tó fi lè dámọ̀ràn ara rẹ̀ fún rírí iṣẹ́ ṣe? Kọ́ bóo ṣe lè jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́kíṣẹ́ táa bá fún ọ. (Òwe 22:29) Jẹ́ aláápọn, sì máa fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́. (Òwe 10:4; 13:4) Máa bọ̀wọ̀ fún ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ àtẹni tó bá tún jẹ́ ọ̀gá fún ọ níbi iṣẹ́. (Éfésù 6:5) Dídé ibi iṣẹ́ lákòókò, jíjẹ́ olóòótọ́, jíjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́, ṣíṣiṣẹ́ láṣekára jẹ́ àwọn ànímọ́ tí ó máa ń wú àwọn agbanisíṣẹ́ lórí, àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ríṣẹ́, kódà nígbà ti iṣẹ́ bá wọ́n bí ojú.

Àwọn Àǹfààní Nínú Ìjọ

Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, nísinsìnyí a nílò àwọn ọkùnrin tó dàgbà dénú láti mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. Èé ṣe? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Mú kí ibi àgọ́ rẹ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò. Kí wọ́n sì na àwọn aṣọ àgọ́ ibùgbé rẹ títóbilọ́lá.” (Aísáyà 54:2) Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ìjọ Jèhófà káàkiri àgbáyé ń gbèrú sí i.

Nítorí náà, bóo bá jẹ́ Kristẹni ọkùnrin kan, báwo lo ṣe lè dámọ̀ràn ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó tóótun láti sìn ní ipò èyíkéyìí? Gbé àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọkùnrin nì, Tímótì, yẹ̀ wò. Lúùkù ròyìn pé “àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì . . . ròyìn rẹ̀ dáadáa.” Bẹ́ẹ̀ ni, nípasẹ̀ ìwà rere rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ti dámọ̀ràn ara rẹ̀ fún àwọn èèyàn tó wà ní ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù ké sí Tímótì láti dara pọ̀ mọ́ òun nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò rẹ̀.—Ìṣe 16:1-4.

Báwo ni ọkùnrin kan lónìí ṣe lè “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” ní ọ̀nà tó tọ́, tó sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Ó dájú pé kìí ṣe nípa bíbẹ̀bẹ̀ fún ipò ṣùgbọ́n nípa mímú àwọn ànímọ́ tẹ̀mí dàgbà, ìyẹn ni àwọn ànímọ́ táa nílò láti lè gbé irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. (1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Ó tún lè fi hàn pé òun ń fẹ́ “iṣẹ́ àtàtà” nípa lílọ́wọ́ ní kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àwọn tí wọ́n dámọ̀ràn ara wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin Kristẹni tó dàgbà dénú ń nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá nínú ire àwọn ara wọn nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn. Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Nípa ṣíṣe irú àwọn nǹkan báwọ̀nyí, Kristẹni ọkùnrin kan lè fi tòótọ́tòótọ́ ‘dámọ̀ràn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.’

Ní Gbogbo Ìgbà

Dídámọ̀ràn ara wa fún àwọn ẹlòmíràn kò túmọ̀ sí pé ká máa díbọ́n tàbí ká jẹ́ “olùwu àwọn ènìyàn.” (Éfésù 6:6) Lékè gbogbo rẹ, ó túmọ̀ sí dídámọ̀ràn ara wa fún Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, nípa fífi tọkàntọkàn tẹ̀ lé òfin àti ìlànà rẹ̀. Bóo bá túbọ̀ dàgbà nípa tẹ̀mí, tóo sì fún ìbátan rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run lókun, àwọn mìíràn yóò kíyè sí i pé ọ̀nà tóo gbà ń bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ lò, ń sunwọ̀n sí i. Wọn yóò tún máa kíyè sí bóo ṣe ń lo ìfaradà àti bóo ṣe jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó, wọn yóò kíyè sí bóo ṣe ní àròjinlẹ̀ tó, àti bóo ṣe lágbára láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ tí wọ́n bá fi lé ọ lọ́wọ́ tó, àti bóo ṣe lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó. Èyí yóò jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọn óò sì túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ọ, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, èyí yóò jẹ́ kí o rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà Ọlọ́run nítorí pé o ti dámọ̀ràn ara rẹ fún àwọn ẹlòmíràn!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń fọgbọ́n wádìí nípa irú ẹni tí ọmọ wọn ọkùnrin tàbí obìnrin fẹ́ẹ́ fẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Arákùnrin kan ń dámọ̀ràn ara rẹ̀ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nípa gbígba ti àwọn ẹlòmíràn rò