Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń wo Àwọn Oníwà Ipá Lo Fi Ń wò Wọ́n?

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń wo Àwọn Oníwà Ipá Lo Fi Ń wò Wọ́n?

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń wo Àwọn Oníwà Ipá Lo Fi Ń wò Wọ́n?

Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń gba ti àwọn alágbára ọkùnrin, tí wọ́n sì máa ń bọlá fún wọn, ìyẹn àwọn ọkùnrin tó taagun, tí wọ́n sì jẹ́ onígboyà. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni akọni tó wà nínú ìtàn àròsọ àwọn Gíríìsì ìgbàanì, tí wọ́n ń pè ní Hérákù, tàbí tí àwọn ará Róòmù mọ̀ sí Hákúlésì.

AKỌNI tó ju akọni lọ ní Hérákù, ó sì lókìkí gan-an, òun ni jagunjagun tó lágbára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ, ẹbọra ni. Súúsì, ọlọ́run Gíríìkì ni baba rẹ̀, Alcmene tó jẹ́ ènìyàn sì ni ìyá rẹ̀. Ìwà akin rẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ látìgbà tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. Nígbà tí abo-ọlọ́run kan tó ń jowú rẹ̀ rán ejò ńlá méjì láti lọ pa á, ńṣe ní Hérákù lọ́ wọn lọ́rùn pa. Nígbà tó dàgbà tán, ó ja ọ̀pọ̀ ogun, ó ṣẹ́gun àwọn abàmì ẹ̀dá, ó sì bá ikú jà láti gba ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan là. Ó tún pa àwọn ìlú ńlá run, ó fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀, ó ju ọmọdékùnrin kan sísàlẹ̀ látorí ilé gogoro kan, ó sì pa ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hérákù kì í ṣe ènìyàn gidi, látọjọ́ tó ti pẹ́ gan-an ni wọ́n ti máa ń dárúkọ rẹ̀ nínú àwọn ìtàn ìgbàanì tí àwọn Gíríìkì mọ̀ bí ẹní mowó. Àwọn ará Róòmù a máa sìn ín bí ọlọ́run kan; àwọn oníṣòwò àtàwọn arìnrìn-àjò a sì máa gbàdúrà sí i fún aásìkí àti ààbò kúrò nínú ewu. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni àwọn ìtàn nípa ìwà akin rẹ̀ ti ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra.

Bí Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Ǹjẹ́ ìtàn nípa Hérákù àti àwọn akọni mìíràn nínú ìtàn tiẹ̀ ní ìpìlẹ̀ tó jẹ́ òótọ́? Lọ́nà kan, ó ṣeé ṣe. Bíbélì sọ nípa àkókò kan, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, nígbà tí “àwọn ọlọ́run” àti “àwọn ẹbọra” wà lórí ilẹ̀ ayé lóòótọ́.

Nígbà tí Mósè ń ṣàpèjúwe sànmánì yẹn, ó kọ̀wé pé: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ ní iye lórí ilẹ̀, tí a sì ń bí àwọn ọmọbìnrin fún wọn, nígbà náà ni àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2.

“Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” wọ̀nyẹn kì í ṣe ènìyàn; àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ni wọ́n. (Fi wé Jóòbù 1:6; 2:1; 38:4, 7.) Júúdà tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì náà sọ pé àwọn áńgẹ́lì kan ‘kò dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì.’ (Júúdà 6) Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, wọ́n fi ibi tí a yàn wọ́n sí nínú ètò Ọlọ́run ti òkè ọ̀run sílẹ̀ nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa bá àwọn arẹwà ọmọbìnrin ènìyàn gbé orí ilẹ̀ ayé. Júúdà fi kún un pé àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí dà bí àwọn ènìyàn Sódómù àti Gòmórà tí wọ́n ‘ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù, tí wọ́n sì jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá.’—Júúdà 7.

Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyí ṣe. Àmọ́ ṣá, àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ìgbàanì tí wọ́n ń sọ ní Gíríìsì àti láwọn ibòmíràn fúnni ní àwòrán kan tó ṣàpèjúwe onírúurú ọlọ́run àti abo-ọlọ́run tí wọ́n ń rìn káàkiri láàárín àwọn èèyàn, yálà lójúkojú tàbí nínú ẹ̀mí. Bí wọ́n bá ti gbé ara ènìyàn wọ̀ tán, àrímáleèlọ ni ẹwà wọn. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń sùn, wọ́n sì ń ní ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín ara wọn àti pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ẹni mímọ́ àti aláìlèkú ni wọ́n fi ń wò wọ́n, síbẹ̀, wọ́n parọ́, wọ́n tanni jẹ, wọ́n ṣaáwọ̀, wọ́n sì jà, wọ́n súnni dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì fipá báni lò pọ̀. Irú ìtàn àròsọ bẹ́ẹ̀ kò ṣàì jẹ mọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ṣáájú Ìkún Omi tí a mẹ́nu kàn nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì inú Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè ti bù mọ́ ìtàn náà, kí wọ́n sì lọ́ ọ po.

Àwọn Alágbára Ńlá Ìgbà Láéláé, Àwọn Ọkùnrin Olókìkí

Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn tí wọ́n gbára wọ̀ náà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin, àwọn obìnrin ọ̀hún sì bí àwọn ọmọ. Abàmì làwọn ọmọ wọ̀nyí o. Néfílímù ni wọ́n, apá kan ènìyàn àti apá kan áńgẹ́lì. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Àwọn Néfílímù sì wà ní ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ wọnnì, àti lẹ́yìn ìyẹn pẹ̀lú, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, tí wọ́n sì bí ọmọkùnrin fún wọn, àwọn ni alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé, àwọn ọkùnrin olókìkí.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:4.

Ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù nì “Néfílímù” túmọ̀ sí ní ṣangiliti ni “abiniṣubú,” àwọn tó ń bi àwọn mìíràn ṣubú, tàbí tí wọ́n ń jẹ́ kí ẹlòmíràn ṣubú, nípa ìwà ipá wọn. Abájọ tí àkọsílẹ̀ Bíbélì náà fi kún un pé: “Ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Àwọn ẹbọra inú ìtàn àròsọ, àwọn bíi Hérákù àti Gílígáméṣì, akọni ará Bábílónì nì, jọ Néfílímù gan-an ni.

Ṣàkíyèsí pé a pe Néfílímù ní “àwọn alágbára ńlá” àti “àwọn ọkùnrin olókìkí.” Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí Nóà, ọkùnrin olódodo, tó gbé ayé ní àkókò kan náà, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn Néfílímù kò nífẹ̀ẹ́ sí kíkókìkí Jèhófà rárá. Òkìkí, ògo, àti ìyìn tiwọn fúnra wọn ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Nípasẹ̀ ìwà agbára tí wọ́n ń hù, tó dájú pé ó ní ìwà ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú, wọ́n rí òkìkí tí wọ́n ń wá látọ̀dọ̀ ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó yí wọn ká. Àwọn ni akọni tó ju akọni lọ nígbà ayé wọn—àwọn èèyàn bẹ̀rù wọn, wọ́n bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n sì dà bí ẹni tí kò ṣeé ṣẹ́gun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Néfílímù àti àwọn baba wọn tó jẹ́ áńgẹ́lì tó fi ipò wọn sílẹ̀ ti lè di olókìkí lójú àwọn tí wọ́n jọ ń gbáyé nígbà yẹn, ó dájú pé wọn ò lókìkí kankan lójú Ọlọ́run. Ìgbésí ayé ìríra ni wọ́n ń gbé. Nítorí ìdí yìí, Ọlọ́run gbégbèésẹ̀ lòdì sí àwọn áńgẹ́lì alábùkù wọ̀nyí. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kò fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n, nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì, ó jù wọ́n sínú àwọn kòtò òkùnkùn biribiri láti fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́; kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 2:4, 5.

Nígbà Ìkún Omi, àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà bọ́ ẹran ara sílẹ̀, wọ́n sì fìtìjú padà sí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Ọlọ́run wá fìyà jẹ wọ́n nípa ṣíṣàìgbà wọ́n láyè láti gbé ara ènìyàn wọ̀ mọ́. Gbogbo àwọn Néfílímù wọ̀nyẹn, ìyẹn àwọn àràmàǹdà ọmọ tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn bí, ló pa run. Nóà àti ìdílé rẹ̀ kéréje nìkan ló la Àkúnya Omi náà já.

Àwọn Olókìkí Lóde Òní

Àwọn ọlọ́run àtàwọn ẹbọra ò sí lórí ilẹ̀ ayé mọ́ lóde òní. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwà ipá gbòde kan. Àwọn olókìkí òde òní ni wọ́n ń gbóríyìn fún nínú àwọn ìwé, sinimá, tẹlifíṣọ̀n, àti orin. Wọn ò jẹ́ ronú láé nípa bí wọn ó ṣe yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì síni, bí wọn ó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, bí wọn ó ṣe máa wá àlàáfíà, bí wọn ó ṣe máa dárí jini, tàbí bí wọn ó ṣe máa yẹra fún ìwà ipá. (Mátíù 5:39, 44; Róòmù 12:17; Éfésù 4:32; 1 Pétérù 3:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń kan sáárá sí àwọn alágbára òde òní nítorí okun tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe mọ ìjàá jà, tí wọ́n lè ránró, àti bí wọ́n ṣe lè fi ìwà ipá ńlá gbẹ̀san ìwà ipá kékeré. a

Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú àwọn bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ayé Nóà kò tíì yí padà. Inú Jèhófà ò dùn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá rárá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo itú tí wọ́n ń pa kì í jọ ọ́ lójú. Onísáàmù náà kọrin pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.

Agbára Kan Tí Ó Yàtọ̀

Ẹnì kan tí ó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn alágbára oníwà ipá ni ọkùnrin tí ó lókìkí jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí, Jésù Kristi, ẹni àlàáfíà. Nígbà tó wà láyé, kò hu “ìwà ipá kankan.” (Aísáyà 53:9) Idà bíi mélòó kan wà lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ wá mú un nínú ọgbà Gẹtisémánì. (Lúùkù 22:38, 47-51) Wọn lè ti gbéjà kò wọ́n kí wọ́n má bàá jẹ́ kí a fi í lé àwọn Júù lọ́wọ́.—Jòhánù 18:36.

Àní, àpọ́sítélì Pétérù tiẹ̀ fa idà rẹ̀ yọ láti gbèjà Jésù, àmọ́ Jésù wí fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:51, 52) Dájúdájú, ìwà ipá máa ń bí ìwà ipá ni, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn ìran ènìyàn ti fi hàn léraléra. Yàtọ̀ sí àǹfààní tí Jésù ní láti fi ohun ìjà gbèjà ara rẹ̀, ó tún ní ọ̀nà mìíràn tó lè lò. Ohun tó sọ fún Pétérù tẹ̀ lé e ni pé: “Ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí?”—Mátíù 26:53.

Dípò tí Jésù ì bá fi hu ìwà ipá tàbí kó sọ pé kí àwọn áńgẹ́lì wá dáàbò bo òun, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àwọn to pa á. Èé ṣe? Ìdí kan ni pé ó mọ̀ pé àkókò tí Baba òun ọ̀run yóò mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé kò tíì tó. Kàkà kí Jésù yanjú ọ̀ràn náà fúnra rẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

Èyí kì í ṣọ̀ràn àìlágbára, ṣùgbọ́n okun inú gidi ló lò. Jésù fi ìgbàgbọ́ tó lágbára hàn pé Jèhófà yóò tún àwọn nǹkan ṣe ní àkókò Rẹ̀ àti lọ́nà tó wù ú. Nítorí pé Jésù ṣègbọràn, ó di ẹni tí a gbé ga dé ipò kan tí ó lókìkí tí ó sì jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ nìkan ṣoṣo ló ga jù ú lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa Jésù pé: “Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yìí gan-an pẹ̀lú ni Ọlọ́run fi gbé e sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílípì 2:8-11.

Ọlọ́run Ṣèlérí Láti Fòpin sí Ìwà Ipá

Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń mú ìgbésí ayé wọn bá àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù mu. Wọn kì í kan sáárá sí àwọn olókìkí àti oníwà ipá tó wà nínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fara wé wọn. Wọ́n mọ̀ pé tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, àfẹ́kù á dé bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ títí láé, ìyẹn sì dájú pé yóò rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Nóà.

Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn. Òun sì ni ipò Ọba Aláṣẹ tọ́ sí. (Ìṣípayá 4:11) Tí ẹ̀dá ènìyàn kan tó jẹ́ adájọ́ bá ní ọlá àṣẹ láti dá ẹjọ́, Ọlọ́run ní ọlá àṣẹ tó ju ìyẹn lọ pàápàá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀wọ̀ tí ó ní fún àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, títí kan ìfẹ́ tó ní sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sún un láti fòpin sí gbogbo ìwà ibi àti àwọn tó ń fi ṣe ìwà hù.—Mátíù 13:41, 42; Lúùkù 17:26-30.

Èyí yóò ṣamọ̀nà sí àlàáfíà pípẹ́ títí lórí ilẹ̀ ayé, àlàáfíà tí a gbé ka orí àìṣègbè àti òdodo. Èyí la sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó nípa Jésù Kristi pé: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.”—Aísáyà 9:6, 7.

Abájọ nígbà náà tí àwọn Kristẹni fi ní láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn onímìísí tó ti wà látọjọ́ tó ti pẹ́, pé: “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”—Òwe 3:31, 32.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn tó máa ń hu ìwà ipá nínú àwọn eré orí fídíò àti nínú àwọn sinimá àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sábà máa ń fi àwọn ìwà ibi wọ̀nyí hàn, ìwà ipá tí wọ́n ń gbé yọ sì burú ré kọjá ààlà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

ÀWỌN ALÁGBÁRA ÒDE ÒNÍ LÀWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń KAN SÁÁRÁ SÍ NÍTORÍ OKUN WỌN ÀTI NÍTORÍ AGBÁRA TÍ WỌ́N NÍ LÁTI FI ÌWÀ IPÁ ŃLÁ GBẸ̀SAN ÌWÀ IPÁ KÉKERÉ

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Alinari/Art Resource, NY