Ayé Tuntun Náà—Ṣé Wàá Wà Níbẹ̀?
Ayé Tuntun Náà—Ṣé Wàá Wà Níbẹ̀?
“Kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—ONÍWÀÁSÙ 3:12, 13.
1. Èé ṣe tó fi yẹ ká gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára?
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ló rò pé Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́ òǹrorò, ẹni tí kò láàánú lójú. Síbẹ̀, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí ni òtítọ́ ọ̀rọ̀ tóo lè rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. Ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà pé ó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” àti pé ó fi àwọn òbí wa àkọ́kọ́ sínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé. (1 Tímótì 1:11; Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9) Nígbà táa bá ń wá ọ̀nà àtilóye tó jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la tí Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, kò gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò kan tí yóò mú ìgbádùn pípẹ́ títí wá.
2. Kí ni àwọn nǹkan díẹ̀ tí o ń fojú sọ́nà fún?
2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a gbé mẹ́ta yẹ̀ wò lára ọ̀nà mẹ́rin tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17) Ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé gbára lé náà wà nínú Ìṣípayá orí kọkànlélógún, ẹsẹ ìkíní. Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ nípa àkókò tí Ọlọ́run Olódùmarè yóò yí àwọn ipò ayé yìí padà sí rere lọ́nà tí yóò yá kánkán. Yóò nu omijé ìbànújẹ́ nù. Kò tún ní sí pé ọjọ́ ogbó, àìsàn, tàbí jàǹbá ń mú ẹ̀mí àwọn èèyàn lọ mọ́. Ọ̀fọ̀, igbe ẹkún, àti ìrora yóò kọjá lọ. Ìrètí yìí mà kúkú múnú ẹni dùn o! Ṣùgbọ́n ṣé a lè ní ìdánilójú pé yóò dé, ipa wo sì ni ìfojúsọ́nà yẹn lè ní lórí wa nísinsìnyí?
Àwọn Ìdí Táa Fi Lè Ní Ìdánilójú
3. Èé ṣe tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la?
3 Ṣàkíyèsí bí Ìṣípayá orí kọkànlélógún, ẹsẹ ìkarùn-ún ṣe ń bá a lọ. Ó sọ ohun tí Ọlọ́run wí bó ṣe jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yẹn lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju ìpolongo òmìnira tí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lè ṣe, ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju òfin ẹ̀tọ́ èyíkéyìí táwọn èèyàn lè gbé kalẹ̀ lónìí, tàbí góńgó èyíkéyìí tí àwọn ènìyàn lè gbé kalẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. Ó jẹ́ ìpolongo kan tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tó jáde látẹnu Ẹnì kan tí Bíbélì sọ pé: “kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Lóòótọ́, o lè ronú pé kí la tún ń wá kiri, ká máa jàǹfààní ìfojúsọ́nà kíkọyọyọ yìí ló kù, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Àmọ́ kò yẹ ká parí rẹ̀ síbẹ̀ yẹn o. A ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti mọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wa.
4, 5. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo la ti gbé yẹ̀ wò tó lè fọkàn wa balẹ̀ nípa ohun tó ń bọ̀ níwájú?
4 Láti lè túbọ̀ lóye ohun tí àpilẹ̀kọ ìṣáájú sọ nípa àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú ètò tuntun bẹ́ẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sì ní ìmúṣẹ kan nígbà tí àwọn Júù padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, tí wọ́n sì padà fi ìdí ìjọsìn tòótọ́ múlẹ̀. (Ẹ́sírà 1:1-3; 2:1, 2; 3:12, 13) Àmọ́, ṣé gbogbo ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ náà nìyẹn? Ó dájú pé kì í ṣe gbogbo rẹ̀ nìyẹn! Àwọn ohun tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóò tún nímùúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò lọ́jọ́ iwájú jíjìnnà réré. Ó ṣe wá jẹ́ ibi táa parí èrò sí nìyẹn? Nítorí ohun táa kà nínú Pétérù kejì orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá àti Ìṣípayá orí kọkànlélógún, ẹsẹ ìkíní sí ìkarùn-ún ni. Àwọn àyọkà wọ̀nyẹn tọ́ka sí ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí yóò ṣe àwọn Kristẹni láǹfààní kárí ayé.
5 Gẹ́gẹ́ bí ohun táa ṣàkíyèsí rẹ̀ ṣáájú, Bíbélì lo gbólóhùn náà “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” nígbà mẹ́rin. A ti gbé mẹ́ta lára wọn yẹ̀ wò, a sì ti dórí àwọn èrò tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ní kedere, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò mú ìwà ibi àti àwọn nǹkan mìíràn tí ń fa ìjìyà kúrò, yóò sì tún bù kún ìran ènìyàn nínú ètò àwọn nǹkan tuntun rẹ̀ tó ṣèlérí.
6. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ kẹrin tó mẹ́nu kan “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
6 Ẹ jẹ́ kí a wá gbé ibi kan tó kù tí gbólóhùn náà ti jẹ yọ yẹ̀ wò, ìyẹn ni “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin, ẹsẹ ìkejìlélógún sí ìkẹrìnlélógún tó sọ pé: “‘Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí èmi yóò ṣe ti dúró níwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ yín àti orúkọ yín yóò dúró. Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì, gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọn yóò sì jáde lọ ní tòótọ́, wọn yóò sì wo òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà mi kọjá; nítorí pé kòkòrò mùkúlú tí ó wà lára wọn kì yóò kú, iná wọn ni a kì yóò sì fẹ́ pa, wọn yóò sì di ohun tí ń kóni nírìíra fún gbogbo ẹran ara.’”
7. Èé ṣe táa fi lè parí èrò sí pé Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin, ẹsẹ ìkejìlélógún sí ìkẹrìnlélógún yóò nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú?
7 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ kan láàárín àwọn Júù tí wọ́n padà sí orílẹ̀-èdè wọn, àmọ́ yóò tún ní ìmúṣẹ mìíràn. Ìyẹn yóò sì jẹ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí a bá ti kọ lẹ́tà kejì ti Pétérù àti ìwé Ìṣípayá, nítorí pé wọ́n tọ́ka sí ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun’ ti ọjọ́ iwájú. A lè máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ kíkọyọyọ tó sì pé pérépéré náà nínú ètò tuntun àwọn nǹkan. Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ipò tí a lè máa fojú sọ́nà láti gbádùn.
8, 9. (a) Lọ́nà wo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run “yóò” gbà “dúró”? (b) Kí ni ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò jọ́sìn “láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì”?
8 Ìṣípayá orí kọkànlélógún, ẹsẹ ìkẹrin fi hàn pé kò ní sí ikú mọ́. Àyọkà tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin bá ìyẹn mu wẹ́kú. A lè rí i ní ẹsẹ ìkejìlélógún pé Jèhófà mọ̀ pé ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun náà kì í ṣe èyí tí kò ní í pẹ́, tí yóò kàn wà fún ìgbà díẹ̀. Síwájú sí i, àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò wà pẹ́ títí; wọn “yóò dúró” níwájú rẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jẹ́ ìdí pàtàkì fún wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Onírúurú inúnibíni làwọn Kristẹni tí dojú kọ, àwọn agbawèrèmẹ́sìn pàápàá ti gbìyànjú láti pa wọ́n rẹ́. (Jòhánù 16:2; Ìṣe 8:1) Síbẹ̀, àwọn tó jẹ́ alágbára lára àwọn ọ̀tá àwọn ènìyàn Ọlọ́run pàápàá, ìyẹn àwọn èèyàn bíi Nero Olú Ọba Róòmù àti Adolf Hitler, kò lè pa àwọn adúróṣinṣin ènìyàn Ọlọ́run, tí wọ́n ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ rẹ́. Jèhófà tí pa ìjọ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́, a sì lè ní ìdánilójú pé ó lè mú un dúró títí láé.
9 Bákan náà làwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí apá kan ilẹ̀ ayé tuntun, ìyẹn ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ nínú ayé tuntun náà, yóò máa wà títí nítorí pé Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ni wọ́n ń jọ́sìn lọ́nà tó mọ́ gaara. Ìyẹn ò ní jẹ́ ìjọsìn tí a ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí ní ìdákúrekú. Òfin Ọlọ́run tí a tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè fún àwọn ìjọsìn kan lóṣooṣù, ìyẹn nígbà tí òṣùpá tuntun bá yọ, àwọn kan sì jẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí ni wọ́n ń ṣe ní ọjọ́ sábáàtì. (Léfítíkù 24:5-9; Númérì 10:10; 28:9, 10; 2 Kíróníkà 2:4) Nítorí náà, Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin, ẹsẹ ìkẹtàlélógún tọ́ka sí jíjọ́sìn Ọlọ́run déédéé, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti lóṣooṣù. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò lè sí àwọn tí ò gbà pé Ọlọ́run wà tàbí àwọn tí ń fi ẹ̀sìn jẹni lójèé láàárín wọn. “Gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú” Jèhófà.
10. Èé ṣe tó fi lè dá ọ lójú pé ilẹ̀ ayé tuntun náà kò ní di èyí tí àwọn ẹni ibi bà jẹ́ láìsí àtúnṣe?
10 Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin ẹsẹ ìkẹrìnlélógún mú un dá wa lójú pé àlàáfíà àti òdodo inú ilẹ̀ ayé tuntun náà kò ní wà nínú ewu. Àwọn ẹni ibi ò ní bà á jẹ́. Rántí pé Pétérù kejì orí kẹta ẹsẹ ìkeje sọ pé ohun tó wà níwájú wa ni “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò di ẹni àwátì. Kò sí ewu kankan tí yóò bá àwọn aláìṣẹ̀, ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ogun tí ènìyàn ń jà, níbi tí àwọn aráàlú tí ogun ń pa ti ń pọ̀ ju àwọn jagunjagun tó ń kú lójú ogun lọ. Atóbilọ́lá Adájọ́ náà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ òun yóò jẹ́ ọjọ́ ti a óò pa àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run run.
11. Kí ni Aísáyà fi hàn pé yóò jẹ́ ọjọ́ ọ̀la ẹnikẹ́ni tó bá lòdì sí Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀?
11 Àwọn olódodo tó bá là á já yóò rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Ẹsẹ ìkẹrìnlélógún sọ tẹ́lẹ̀ pé “òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà” Jèhófà “kọjá” ni yóò jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ rẹ̀. Èdè àpèjúwe tí Aísáyà lò lè dàbí ohun tó múni gbọ̀n rìrì. Síbẹ̀, ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìtàn àtijọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro. Ẹ̀yìn ògiri Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ni ibi tí wọ́n máa ń da ìdọ̀tí sí wà, ìgbà kọ̀ọ̀kan sì wà tí wọ́n máa ń ju òkú àwọn ọ̀daràn síbẹ̀, ìyẹn àwọn táa dá lẹ́jọ́ pé wọn ò yẹ lẹ́ni táa ń sin lọ́nà yíyẹ. a Kì í sì í pẹ́ tí àwọn kòkòrò mùkúlú àti iná tó wà níbẹ̀ fi ń yanjú àwọn ìdọ̀tí àti àwọn òkú wọ̀nyẹn. Ó ṣe kedere pé àwòrán tí Aísáyà fojú inú rí yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́tẹ̀ yìí o, ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn tó ń fojú pa ìlànà rẹ̀ rẹ́ yóò jẹ́ àṣekágbá.
Ohun Tó Ti Ṣèlérí
12. Kí ni àwọn nǹkan mìíràn tí Aísáyà tún sọ nípa bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nínú ayé tuntun náà?
12 Ìṣípayá orí kọkànlélógún, sọ díẹ̀ fún wa lára àwọn nǹkan tí kò ní sí mọ́ nínú ètò tuntun tó ń bọ̀. Àmọ́, kí ni yóò wà nígbà náà? Báwo ni ìgbésí ayé yóò ṣe rí? Ǹjẹ́ a lè rí ìsọfúnni èyíkéyìí tó ṣeé fọkàn tán? Bẹ́ẹ̀ ni. ẹsẹ ìkẹrinAísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe àwọn ipò tí a óò gbádùn tí a bá rí ojú rere Jèhófà láti wà láàyè nígbà tó bá dá àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wọ̀nyí níkẹyìn. Àwọn tí a bá fún láǹfààní láti máa gbé títí láé nínú ilẹ̀ ayé tuntun náà kò ní darúgbó, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní kú. Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ogún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Kì yóò sí ọmọ ẹnu ọmú kan níbẹ̀ tí ọjọ́ rẹ̀ kéré níye, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí àgbàlagbà kan tí ọjọ́ rẹ̀ kò kún; nítorí pé ẹnì kan yóò kú ní ọmọdékùnrin lásán-làsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún; àti ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.”
13. Báwo ní Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ogún ṣe mú un dá wa lójú pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò gbé láìséwu?
13 Nígbà tí èyí kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ lórí àwọn ènìyàn Aísáyà, ó túmọ̀ sí pé a dáàbò bo àwọn ọmọ ọwọ́ tó wà ní ilẹ̀ náà. Kò sí ọ̀tá kankan tó ń wọlé láti kó àwọn ọmọ ẹnu ọmú tàbí láti dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin légbodò bí àwọn ará Bábílónì ti ṣe nígbà kan. (2 Kíróníkà 36:17, 20) Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, ọkàn àwọn ènìyàn yóò balẹ̀, ewu kankan kò ní wu wọ́n, wọn ó sì máa gbádùn ìgbésí ayé wọn. Bí ẹnì kan bá wá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, kò ní sí ìyọ̀ǹda fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti máa gbé lókè eèpẹ̀. Ọlọ́run yóò mú un kúrò ni. Tí ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá ti wá pé ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ńkọ́? Táa bá fi wéra pẹ̀lú wíwà láàyè títí láé, “ọmọdékùnrin lásán-làsàn” ló jẹ́ nígbà tó kú yẹn.—1 Tímótì 1:19, 20; 2 Tímótì 2:16-19.
14, 15. Látàrí ohun tó wà nínú Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkọkànlélógún àti ìkejìlélógún, ìgbòkègbodò amóríyá wo lo lè máa retí?
14 Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí bí a óò ṣe mú ẹnì kan tó mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ kúrò, Aísáyà ṣàpèjúwe irú ìgbésí ayé tí yóò gbilẹ̀ nínú ayé tuntun náà. Gbìyànjú láti wo ara rẹ̀ nínú ipò yẹn. Ohun tó ṣeé ṣe kóo kọ́kọ́ fojú inú rí ni àwọn ohun tóo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ. Aísáyà sọ̀rọ̀ lórí ìyẹn nínú ẹsẹ ìkọkànlélógún àti ìkejìlélógún pe: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”
15 Ká ní o kò tíì mọ báa ṣe ń kọ́lé tàbí báa ṣe ń dáko, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ń dúró dè ọ́. Àmọ́ ṣá o, ṣé wàá ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ tó dáńgájíá, tó lè jẹ́ àwọn aládùúgbò tí inú wọn yóò dún láti ràn ọ́ lọ́wọ́? Aísáyà ò sọ bóyá ilé rẹ yóò ní fèrèsé ńlá tí a taṣọ sí, kí o lè máa gbádùn atẹ́gùn tó tuni lára, kò sì sọ bóyá fèrèsé onídígí ni yóò ní, èyí tóo lè máa tibẹ̀ rí bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí padà. Báwo ni wàá ṣe fẹ́ kí òrùlé ilé rẹ rí ná, ṣé wàá fẹ́ kó dami sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ni? Àbí nítorí bí ojú ọjọ́ àgbègbè náà ṣe rí, wàá fẹ́ kí òrùlé ilé rẹ tẹ́ pẹrẹsẹ—bíi ti ọ̀kan lára àwọn ilé tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé—òrùlé tí ìwọ àti ìdílé rẹ lè jókòó sórí rẹ̀ láti jẹ oúnjẹ aládùn, kí ẹ sì ní ìjíròrò tó gbámúṣé?—Diutarónómì 22:8; Nehemáyà 8:16.
16. Èé ṣe tóo fi lè retí pé kí ayé tuntun náà fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn tí kò lópin?
16 Dípò tí wàá fi máa ronú nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn nǹkan ó ṣe rí gan-an, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ láti mọ̀ ni pé wàá ní ilé tìrẹ. Yóò jẹ́ tìẹ gan-an—kò ní rí bíi tòde òní tó jẹ́ pé o lè forí ṣe, fọrùn ṣe kóo lè kọ́lé, ṣùgbọ́n kí ẹlòmíràn wá máa gbádùn rẹ̀. Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta ẹsẹ ìkọkànlélógún tún sọ pé wàá gbin nǹkan wàá sì jẹ èso rẹ̀. Ní kedere, ìyẹn ṣàkópọ̀ bí ipò nǹkan yóò ṣe rí ní gbogbo gbòò. Wàá jadùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ìyẹn ni pé ìwọ ni wàá jèrè gbogbo làálàá rẹ. Wàá lè ṣèyẹn fún àkókò gígùn gan-an—“bí ọjọ́ igi.” Ẹ ò ri pé ìyẹn bá àpèjúwe yẹn mu wẹ́kú pé “ohun gbogbo di tuntun”!—Sáàmù 92:12-14.
17. Ìlérí wo ni yóò fún àwọn òbí níṣìírí jù lọ?
17 Bóo bá jẹ́ òbí, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yóò wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an ni: “Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu; nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà, àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn. Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ti tòótọ́ pé, kí wọ́n tó pè, èmi fúnra mi yóò dáhùn; bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi fúnra mi yóò gbọ́.” (Aísáyà 65:23, 24) Ǹjẹ́ o mọ bí ìrora tó wà nínú ‘bíbí ọmọ fún ìyọlẹ́nu’ ti pọ̀ tó? Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ pọndandan pé ká to àwọn ìṣòro tí àwọn ọmọ lè ní tó lè mú ìyọlẹ́nu bá àwọn òbí àti àwọn ẹlòmíràn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Nípa tìyẹn, gbogbo wa la ti rí àwọn òbí tí iṣẹ́ wọn, àwọn ìgbòkègbodò mìíràn, tàbí ìgbádùn gbà lọ́kàn débi pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni wọ́n ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ohun tó yàtọ̀ kan yóò wà, Jèhófà mú un dá wa lójú pé òun óò gbọ́, òun ó sì bá wa yanjú ìṣòro wa, kódà òun yóò máa retí wọn.
18. Èé ṣe tóo fi lè retí àtigbádùn àwọn ẹranko nínú ayé tuntun?
18 Bóo ṣe ń ronú nípa àwọn ohun tóo máa gbádùn nínú ayé tuntun, wá fojú inú wo ohun tí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “‘Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn pàápàá yóò máa jùmọ̀ jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù; àti ní ti ejò, oúnjẹ rẹ̀ yóò jẹ́ ekuru. Wọn kì yóò ṣe ìpalára kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi,’ ni Jèhófà wí.” (Aísáyà 65:25) Àwọn ayàwòrán ti gbìyànjú àtiya àwòrán yẹn, àmọ́ èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwòrán lásán tí ayàwòrán kan tó ti kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ lè ronú rẹ̀ kó sì yà. Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ gan-an lèyí. Àlàáfíà yóò gbilẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn, bákan náà la ó sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹranko. Ọ̀pọ̀ onímọ̀ nípa ohun alààyè àti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹranko ló ń lo ọdún tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹranko díẹ̀, tàbí ọ̀wọ́ ẹranko kan péré tàbí irú ẹranko kan ní pàtó. Ìyàtọ̀ pátápátá yóò wà, ronú nípa ẹ̀kọ́ tí wàá lè kọ́ nígbà tí àwọn ẹranko ò bá bẹ̀rù àwọn èèyàn mọ́. Ìgbà yẹn ni wàá lè fọwọ́ gbé ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá tín-tìn-tín tó jẹ́ pé inú igbó tàbí aginjù ni wọ́n ń gbé—dájúdájú, wàá lè wò wọ́n láwòfín, wàá lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, wàá sì lè gbádùn wọn. (Jóòbù 12:7-9) Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìfòyà, kò ní sí ewu látọ̀dọ̀ ènìyàn tàbí ẹranko. Jèhófà sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi.” Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti yàtọ̀ pátápátá tó sí ohun tí a ń rí, tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lóde òní!
19, 20. Èé ṣe tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn lóde òní?
19 Gẹ́gẹ́ báa ṣe sọ ọ́ lẹ́ẹ̀kan, pẹ̀lú gbogbo ariwo táwọn èèyàn ń pa nípa ẹgbẹ̀rúndún tuntun, kò ṣeé ṣe fún wọn láti sọ bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí ní pàtó. Ìyẹn ló mú kí ìbànújẹ́ dorí ọ̀pọ̀ èèyàn kodò, tí ọkàn wọn pòrúurùu, tílé ayé wá sú wọn pátápátá. Peter Emberley, ọ̀gá àgbà kan ní Yunifásítì kan ní Kánádà, kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ [àwọn àgbàlagbà] ló jẹ́ pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ni wọ́n ń bi ara wọn léèrè pé kí làwọ́n wálé ayé fún. Ta ni mí? Kí ni mò ń forí ṣe, fọrùn ṣe fún gan-an? Ogún wo ni mò ń fi sílẹ̀ fún àwọn ìran tó ń bọ̀? Nígbà tí wọ́n ṣì wà lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún sí àádọ́ta, bí wọ́n ti ń sá sọ́tùn-ún, ni wọ́n ń sá sósì, láti ṣáà lè rí i pé ìgbésí ayé wọn gún régé, kó sì nítumọ̀.”
20 O lè lóye ìdí tí ọ̀ràn fí rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Wọ́n lè máa wá ọ̀nà àtigbádùn ìgbésí ayé nípa ṣíṣe àwọn nǹkan tí ara wọn ń fẹ́ tàbí àwọn eré ìtura tó ń mára yá gágá. Síbẹ̀, wọn ò mọ ohun tí ọjọ́ iwájú ní nípamọ́ fún wọn, nípa bẹ́ẹ̀ ìgbésí ayé lè má jọ wọ́n lójú mọ́, ó lè má rọgbọ fún wọn, tàbí kí ó má tilẹ̀ ní ìtumọ̀ tó ṣe gúnmọ́ sí wọn. Wàyí o, wáá fí ìyẹn wé ojú tí o fi ń wo ìgbésí ayé, látàrí ohun táa ti gbé yẹ̀ wò. O mọ̀ pé nínú ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí, a ó láǹfààní àtiwò káàkiri kí a sì sọ látọkàn wá pé, ‘Ní ti tòótọ́, Ọlọ́run ti sọ ohun gbogbo di tuntun!’ Ẹ wo bí a ó ṣe gbádùn ìyẹn tó!
21. Kí ni kókó tó bára mu táa rí nínú Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti Aísáyà orí kọkànlá, ẹsẹ ìkẹsàn-án?
21 Kì í ṣe ìwà ọ̀kánjúà láti máa fojú inú wò ó pé a óò gbé nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. Ó ń pè wá, ó tiẹ̀ ń rọ̀ wá pàápàá láti wá jọ́sìn òun ní òtítọ́ báyìí, kí a lè tóótun láti wà láàyè nígbà tí ‘wọn ò ní ṣe ìpalára kankan, tí wọn ò sì ní fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.’ (Aísáyà 65:25) Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Aísáyà ti kọ́kọ́ sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, àti pé ó tún fi ohun kan táa nílò láti rí ìgbádùn tòótọ́ nínú ayé tuntun náà kún un? Aísáyà orí kọkànlá, ẹsẹ ìkẹsàn-án sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”
22. Kí ni gbígbé tí a gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin yẹ̀ wò nínú Bíbélì gbọ́dọ̀ fún ìpinnu wa lókun láti ṣe?
22 “Ìmọ̀ Jèhófà.” Nígbà tí Ọlọ́run bá sọ ohun gbogbo di tuntun, àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé yóò ní ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀ àti nípa ìfẹ́ rẹ̀. Ìyẹn yóò wé mọ́ ohun tó pọ̀ gan-an ju kíkọ́ ẹ̀kọ́ lára ẹranko lọ. Yóò ní í ṣe pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mí sí. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan táa ti rí nígbà táa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó mẹ́nu kan “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1) Abájọ tó fi yẹ kóo máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ ìyẹn wà lára àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ? Tí kò bá sí níbẹ̀, àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe tó fi lè jẹ́ pé ojoojúmọ́ ní wàá máa ka díẹ̀ lára ohun tí Ọlọ́run sọ? Wàá rí i pé yàtọ̀ sí pé o ń fojú sọ́nà fún gbígbádùn ayé tuntun kan, wàá rí ìgbádùn tó túbọ̀ pọ̀ sí i nísinsìnyí, àní gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti rí i.—Sáàmù 1:1, 2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé náà, Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 906, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Èé ṣe táa fi lè parí èrò sí pé àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 66:22-24 jẹ́ ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
• Kí ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ń fojú sọ́nà láti rí lára àwọn nǹkan táa mẹ́nu kàn nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 66:22-24 àti Aísáyà 65:20-25?
• Kí ni àwọn ìdí tóo ní tóo fi lè fọkàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Aísáyà, Pétérù, àti Jòhánù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”