Pípẹja Ènìyàn Níbi Òkun Aegean
Pípẹja Ènìyàn Níbi Òkun Aegean
ÒKUN Aegean ló lọ salalu níhà ìlà oòrùn Mẹditaréníà, ilẹ̀ Gíríìsì tó lọ gbalasa sì wà ní àríwá àti ìwọ̀ oòrùn rẹ̀, erékùṣù Kírétè wà ní gúúsù, Turkey sì wà ní ìlà oòrùn. Erékùṣù ńlá àti kékeré pọ̀ ní Òkun Aegean, ibẹ̀ sì ni ọ̀làjú ti tàn dé ibi púpọ̀ láyé ọjọ́un. Gátagàta àti págunpàgun táwọn erékùṣù yìí wà, táwọn ilé funfun kéékèèké tó wà nínú wọn sì rọra ń tàn yanranyanran nínú ìmọ́lẹ̀ oòrùn, ló mú kí akéwì kan fi wọ́n wé “àwọn òkúta tó rí bí ẹṣin onígọ̀gọ̀ yàùyàù.”
Abájọ tí àwọn erékùṣù yìí fi wá di ọ̀kan lára àwọn ibi tó gbayì jù lọ lágbàáyé táwọn èèyàn ti lọ ń gbafẹ́! Ìwà ọmọlúwàbí tọkùnrin tobìnrin tí wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi táa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí túbọ̀ wá gbé ẹwà ibẹ̀ yọ. Wọn kì í ṣojú ayé rárá, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlejò, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í wo aago aláago ṣiṣẹ́, ká sòótọ́ àwọn èèyàn yẹn túbọ̀ fi kún iyì àgbègbè náà.
Iṣẹ́ ẹja pípa nínú omi Òkun Aegean lọ̀pọ̀ àwọn olùgbé erékùṣù yẹn fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Àmọ́ o, oríṣi “ẹja pípa” pàtàkì mìíràn tún ti ń mú àbájáde yanturu wá ní àgbègbè yẹn. “Àwọn apẹja ènìyàn” ni, àwọn oníwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n ń la àwọn erékùṣù Aegean kọjá, tí wọ́n ń sọ àwọn ènìyàn di Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 4:18, 19; Lúùkù 5:10.
Ní nǹkan bí ọ̀rúndún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn, làwọn Kristẹni oníwàásù ṣèbẹ̀wò sí àwọn erékùṣù Aegean. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń padà bọ̀ láti ẹnu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, ó tẹsẹ̀ dúró díẹ̀ ní àwọn erékùṣù Lẹ́sífọ́sì, Kíósì, Sámósì, Kọ́sì, àti Ródésì. Pọ́ọ̀lù tó máa ń wàásù láìṣàárẹ̀, ti gbọ́dọ̀ wàásù fún àwọn kan lára àwọn olùgbé erékùṣù náà. (Ìṣe 20:14,15, 24; 21:1, 2) Lẹ́yìn tó ti ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì ní Róòmù, ó jọ pé ó lọ sí Kírétè, ó sì tún kó wọnú ìgbòkègbodò Kristẹni níbẹ̀. Bó ti kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún kìíní parí, àpọ́sítélì Jòhánù di ìgbèkùn ní erékùṣù Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Báwo làwọn olùpòkìkí ìhìn rere tọjọ́ òní ṣe ń ṣe sí láwọn erékùṣù wọ̀nyí?
Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Mérè Wá
Wíwàásù ní ọ̀wọ́ àwọn erékùṣù wọ̀nyí ṣòro, ó sì ń muni lómi. Ó ń béèrè fún ìsapá gidi àti ìfara-ẹni-rúbọ. Àwọn kan lára àwọn erékùṣù náà jìnnà púpọ̀ síra wọn. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọkọ̀ ojú omi tàbí ti òfuruufú máa ń dé àwọn ibì kan, nígbà tí kò tiẹ̀ sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ láwọn ibòmíì, pàápàá tó bá jẹ́ ìgbà òtútù. Tó bá tún wá lọ jẹ́ ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle meltemia láti àríwá bá ń fẹ́ ni, òkun lè máa ru gùdù. Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àwọn abúlé tó wà ní ọ̀pọ̀ lára àwọn erékùṣù náà ò sí lójú kan, kò sì rọrùn láti débẹ̀ nítorí pé àwọn ọ̀nà eléruku tí wọn ò dọ̀dà sí kì í ṣeé gbà kọjá. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké nìkan ló lè dé àwọn abúlé kan.
Fún àpẹẹrẹ, wo erékùṣù Ìkáríà. Kò ṣeé ṣe fún àwọn akéde mọ́kànlá tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba náà nínú ìjọ kékeré tó wà níbẹ̀ láti kárí gbogbo abúlé tó wà ní erékùṣù náà àti àwọn kéékèèké tó wà nítòsí. Fún ìdí yìí, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin láti Sámósì máa ń wá wàásù fún àwọn ènìyàn Ìkáríà,
àti bákan náà fún àwọn tó wà ní àwọn erékùṣù Fọ́nóì, Pátímọ́sì, àti Lípísọ́sì. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà iṣẹ́ ìwàásù ọlọ́jọ́ méjì, àwọn Ẹlẹ́rìí náà fi àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650] ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, àti ìwé ńlá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ń sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì sóde! Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn láti pàdé àwọn èèyàn tí ò tiẹ̀ gbọ́ nǹkan kan rí nípa Jèhófà, ṣe ni wọ́n tún ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n máà tíì lọ, kí wọ́n jọ̀wọ́ túbọ̀ kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì. Obìnrin kan tiẹ̀ sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé: “A gbọ́ pé ẹ ti ń lọ báyìí o. Àmọ́ mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti béèrè nínú Bíbélì. Ta ni yóò wá ràn mí lọ́wọ́?” Arábìnrin Kristẹni náà ṣèlérí láti tún kàn sí i nípa lílo tẹlifóònù, ó mà ṣe bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan o.Nígbà tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan bẹ Ìkáríà wò, ó ṣètò láti kárí gbogbo erékùṣù yẹn pátá ní òpin ọ̀sẹ̀ kan. Ó ní kí àwọn akéde Ìjọba bí ọgbọ̀n láti Sámósì wá kún àwọn lọ́wọ́. Àwọn ará tó tibòmíràn wá wọ̀nyí ló sanwó oorun ọjọ́ méjì tí wọ́n sùn ní òtẹ́ẹ̀lì kan, àwọn náà ló sì sanwó àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ arinkòtò-ringegele tí wọ́n háyà. Odindi ọjọ́ méjì lòjò ńlá kan fi rọ̀, ó sì jọ pé ojú ọjọ́ kò ní fi bẹ́ẹ̀ dáa lópin ọ̀sẹ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n àwọn ará ò jẹ́ kí èyí ṣèdíwọ́ fún wọn, ọ̀rọ̀ Oníwàásù 11:4 wá sọ́kàn wọn: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ojú ọjọ́ sunwọ̀n sí i díẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n sì ti jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n mú wá jákèjádò erékùṣù yẹn, làwọn ará tó padà sílé pẹ̀lú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.
Àwọn akéde mẹ́rìndínlógún tó ń gbé ní erékùṣù Áńdúrósì sapá gidigidi láti kárí gbogbo erékùṣù yẹn pátá. Nígbà tí àwọn arákùnrin méjì kan dé abúlé kan tó wà ládàádó, wọ́n pinnu pé àwọn yóò wàásù fún gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀. Wọ́n bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú ilé wọn, lójúu pópó, àti ní oko. Wọ́n tilẹ̀ tún dé àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n sì fìwé fún wọn níbẹ̀. Ọkàn wọn ti balẹ̀ pé gbogbo àwọn ará abúlé náà làwọ́n ti kàn sí, ni wọ́n bá fẹ́ máa lọ. Bí wọ́n ṣe ń kúrò lójúde ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí àlùfáà ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì tó ń bọ̀. Wọ́n rí i pé àwọn ò tíì jẹ́rìí fún un, ni wọ́n bá fi ìwé kékeré kan lọ̀ ọ́, ó sì fìdùnnú gbà á. Ìgbà yẹn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dá wọn lójú pé wọn ò fo ẹnikẹ́ni dá nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn!
Erékùṣù Gáfúdò (tàbí Káúdà) kékeré tó wà nísàlẹ̀ igun Kírétè, tó jẹ́ pé kìkì èèyàn méjìdínlógójì péré ló ń gbébẹ̀, ni a kà sí ibi tó jẹ́ ìpẹ̀kun Yúróòpù níhà gúúsù. (Ìṣe 27:16) Alábòójútó arìnrìn-àjò kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú tọkọtaya mìíràn, lọ fi ọjọ́ mẹ́ta wàásù níbẹ̀. Kí wọ́n lè dín ìnáwó kù, inú àgọ́ ni wọ́n ń sùn. Wọ́n mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn olùgbé ibẹ̀ pátá, inú àwọn ará náà sì dùn pé àwọn ènìyàn ibẹ̀ kò ní ẹ̀tanú. Wọn ò tíì gbọ́ nǹkan kan rí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ì báà jẹ́ nǹkan dáadáa tàbí búburú. Àwọn ènìyàn àdúgbò náà, títí kan àlùfáà ibẹ̀, gba ìwé ńlá mọ́kàndínlógún àti ìwé pẹlẹbẹ mẹ́tàlá. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ń padà lọ sí Kírétè nínú ọkọ̀ kékeré kan, bẹ́ẹ̀ ni òkun bẹ̀rẹ̀ sí ru gùdù, tí ìyẹn sì fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Wọ́n sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a dé ilé láàyè, ṣùgbọ́n a tún yìn ín lógo pé ó jẹ́ kí a lè bọlá fún orúkọ rẹ̀ ní ibí yìí tó jẹ́ ìpẹ̀kun Yúróòpù níhà gúúsù.”
Erékùṣù Pátímọ́sì ni àpọ́sítélì Jòhánù ti kọ ìwé Ìṣípayá, èyí tó kẹ́yìn Bíbélì. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ wà ní Pátímọ́sì. Àwọn arákùnrin láti Sámósì fara balẹ̀ ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní erékùṣù yẹn. Wọ́n mọ̀ pé àwọn lè pàdé àtakò gbígbóná nítorí pé odi agbára ni erékùṣù náà jẹ́ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì. Obìnrin kan ké sí àwọn arábìnrin méjì tó ń sọ ìhìn rere wọlé. Lọkọ obìnrin náà bá tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé kí àwọn arábìnrin náà sọ ẹni tó ní kí wọ́n wá sí ilé àwọn fóun. Nígbà tí wọ́n ṣàlàyé pé
gbogbo ilé pátá làwọ́n ń bẹ̀ wò, ló bá tún béèrè pé: “Ṣé ó dẹ̀ dá yín lójú pé aládùúgbò kan kọ́ ló rán yín wá síbí?” Ìyàwó rẹ̀, tó jẹ́ pé òun ní tiẹ̀ ti mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí ó wà ní Zaire, ló wá ṣàlàyé lẹ́yìn náà fún àwọn arábìnrin yẹn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn. Ó wí pé: “Ṣe ni mo ń gbàdúrà sí Jèhófà, bí mo ti ń ṣe ní gbogbo ọjọ́, pé kó rán àwọn Ẹlẹ́rìí ẹ̀ sí erékùṣù yìí. Ẹ̀rín lọkọ mi fi mí rín. Nígbà tí mo rí yín lẹ́nu ọ̀nà, ẹnu yà mí àti ọkọ mi pàápàá. Ìdí nìyẹn tó fi ń bi yín ṣáá nípa ẹni tó rán yín sí ilé wa.” Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin náà. Wọ́n ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lórí tẹlifóònù fún oṣù mẹ́wàá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìnáwó ńlá ni èyí kó arábìnrin náà àti obìnrin olùfìfẹ́hàn yìí sí. A ti batisí rẹ̀, òun nìkan sì ni Ẹlẹ́rìí tó wà ní erékùṣù yẹn níbi tí àpọ́sítélì Jòhánù dá wà ní ẹgbàá dín ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.“Pípẹja” Láwọn Èbúté
Ní gbogbo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń rìnrìn afẹ́ máa ń dúró ní èbúté púpọ̀ tó wà ní àwọn erékùṣù Aegean, tí wọ́n ń kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó ń ṣe fàájì wá síbẹ̀. Nípa báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti bá àwọn ènìyàn láti onírúurú ilẹ̀ àti èdè sọ̀rọ̀. Àwọn ìjọ ní ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ lóríṣiríṣi èdè, tí àwọn akéde sì ń fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìròyìn fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́. Àwọn ọkọ̀ òkun aláfẹ́ kan máa ń wá sí èbúté kan náà yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí tó ń fún àwọn ará ní àǹfààní títayọ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò, kódà kí wọ́n tún ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn agbo òṣìṣẹ́ ọkọ̀ wọnnì.
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1996, arábìnrin kan tó jẹ́ oníwàásù alákòókò kíkún ní Ródésì jẹ́rìí fún ọ̀dọ́kùnrin ará Jàmáíkà kan tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun tó ń ṣèbẹ̀wò sí èbúté yẹn ní gbogbo ọjọ́ Friday. Wọ́n ké sí ọkùnrin náà pé kó wá sí àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a ó ṣe ní erékùṣù náà ní Friday tó tẹ̀ lé e. Pẹ̀lú Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà náà ràn án lọ́wọ́ láti lóye àwọn kan lára àwọn òtítọ́ Bíbélì táa ṣàlàyé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn ní àpéjọpọ̀ yẹn wọ ọkùnrin yìí lọ́kàn gidigidi. Ní ọjọ́ Friday tó tẹ̀ lé e, ó ké sí àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì wá sínú ọkọ̀ òkun náà. Àwọn aṣáájú ọ̀nà yìí kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spanish dání pẹ̀lú wọn. Kò pé wákàtí kan rárá tí àpò òde ẹ̀rí wọn fi di òfìfo! Ní gbogbo ọjọ́ Friday ni ọ̀dọ́ ará Jàmáíkà náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí tí ó fi di òpin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Bó ti di
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó tẹ̀ lé e ló bá tún dé, tó sì ṣe tán láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Àmọ́ o, lọ́tẹ̀ yìí, ó pinnu láti yí iṣẹ́ rẹ̀ padà kí ó bàa lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bó tún ṣe lọ nìyẹn o. Inú àwọn ará ní Ródésì mà dùn o, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣe batisí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1998!Mímú Àwọn “Ẹja” Tó Ń Ṣí Wá
Àwọn èèyàn mọ Òkun Aegean bí ẹní mowó fún ọ̀pọ̀ yanturu ẹja tó máa ń ṣí wá sínú ẹ̀, ní kékeré wọn àti àwọn tó tóbi gidi gan-an, bí wọ́n bá ti ń kọjá nínú omi òkun yìí, inú àwọ̀n àwọn ọ̀jáfáfá apẹja ni wọn ń parí ìrìn àjò wọn sí. Lọ́nà kan náà, àwọn oníwàásù Ìjọba náà ń rí ọ̀pọ̀ tó ní àyà ìgbàṣe láàárín àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣí wá sí Gíríìsì láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Yúróòpù.
Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni Rezi nígbà tó kọ́kọ́ kà nípa Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ìyẹn jẹ́ nígbà tó wà ní Albania. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà lòun àti ìdílé ẹ̀ ṣí wá sí erékùṣù Ródésì. Lọ́jọ́ kan, Rezi gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti rí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ibùgbé òun tuntun. Lọ́jọ́ kejì ni bàbá ẹ̀ bá kó ìwé ìròyìn gbígbajúmọ̀ wọ̀nyẹn, Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, wálé, èyí sì dùn mọ́ Rezi nínú gidigidi. Rezi pàdé arábìnrin tí bàbá ẹ̀ gba àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí lọ́wọ́ ẹ̀, láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Nígbà míì, ó tiẹ̀ máa ń ní kí wọ́n bá òun kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mẹta láàárín ọjọ́ kan! Lẹ́yìn oṣù méjì, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, nígbà tó sì di March 1998, a batisí rẹ̀ ní ẹni ọdún mẹ́rìnlá. Lọ́jọ́ yẹn gangan ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ló forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Arákùnrin kan ní erékùṣù Kọ́sì ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn kan láti Rọ́ṣíà. Nígbà tó bi wọ́n léèrè bí wọ́n bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó máa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ tọkọtaya ará Armenia kan—Leonidas àti Ophelia aya rẹ̀—ní abúlé kan tó wà ní nǹkan bí ogún ibùsọ̀ síbẹ̀. Ẹnu kọ̀ròyìn lọ́jọ́ táà ń wí yìí. Ṣe ni tọkọtaya ará Armenia náà lọ gbé odindi àpò kan wá tó kún fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Armenia àti Rọ́ṣíà, tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde! Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn sì ti tẹ̀ síwájú débi dídi akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ṣùgbọ́n nítorí rúkèrúdò ìlú àti ìṣòro ọrọ̀ ajé, wọ́n ní láti fi ìlú ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀. Gbàrà tí wọ́n dé sí Kọ́sì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìyá Leonidas àti àbúrò rẹ̀ obìnrin, tí wọ́n ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, bí Ẹlẹ́rìí náà ṣe ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun mẹ́ta láti darí nìyẹn—ìkan pẹ̀lú Ophelia, ìkan pẹ̀lú Leonidas, àti ìkan pẹ̀lú ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin. Èyí ń béèrè fún gígun alùpùpù ní àlọ àti àbọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ fún ọgbọ̀n kìlómítà. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Leonidas àti aya rẹ̀ ṣe batisí. Èrè ńlá mà lèyí o, nítorí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àwọn ará ládùúgbò wọ̀nyí!
Jèhófà Ló Ń Mú Un Dàgbà
Ìbùkún Jèhófà hàn gbangba lórí ìsapá aláìṣàárẹ̀ àwọn olùpòkìkí ìjọba aláapọn wọ̀nyí tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ní àwọn erékùṣù Aegean yẹn. Ìjọ mẹ́rìnlélógójì àti àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló wà níbẹ̀ báyìí. Mẹ́tàdínlógún ló ń lo èdè òkèèrè lára àwọn àwùjọ náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Ní àfikún sí i, àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe mẹ́tàlá ló túbọ̀ ń sapá gidigidi láti lè bá èèyàn púpọ̀ sí i sọ̀rọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyẹn tó wà ládàádó.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni Òkun Aegean ti jẹ́ ibùdó ìdàgbàsókè fún àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ọrọ̀ ajé. Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ó ti wá di ibi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ yíjú sí. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, gẹ́gẹ́ bí “àwọn apẹja ènìyàn,” àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ti rí àwọn aláìlábòsí ọkàn tí wọ́n ń hára gàgà láti yin Jèhófà ní àwọn erékùṣù wọ̀nyí. Gbogbo wọn lápapọ̀, ti dáhùn padà lọ́nà kíkọyọyọ sí ìkésíni alásọtẹ́lẹ̀ náà: “Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà, kí wọ́n sì sọ ìyìn rẹ̀ jáde àní ní àwọn erékùṣù.”—Aísáyà 42:12.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 22]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Aegean
GÍRÍÌSÌ
Lẹ́sífọ́sì
Kíósì
Sámósì
Ìkáríà
Fọ́nọ́ì
Pátímọ́sì
Kọ́sì
Ródésì
Kírétè
TURKEY
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Erékùṣù Lẹ́sífọ́sì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Erékùṣù Pátímọ́sì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Erékùṣù Kírétè