Rí Ìtùnú Nínú Okun Jèhófà
Rí Ìtùnú Nínú Okun Jèhófà
“Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—SÁÀMÙ 94:19.
Ọ̀RỌ̀ ìtùnú wà nínú Bíbélì fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń wá ìtùnú lójú méjèèjì. Abájọ tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé, “àìmọye ènìyàn ló ti yíjú sí Bíbélì nítorí pé wọ́n ń fẹ́ ìtùnú, ìrètí, àti ìtọ́sọ́nà nígbà ìdààmú àti nígbà tí wọn ò mọ ibi tí ọ̀ràn ilé ayé ń lọ.” Èé ṣe?
Nítorí pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ mí sí, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” Ẹni “tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Òun ni ‘Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú.’ (Róòmù 15:5) Jèhófà ti fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa pípèsè ohun tí yóò tu gbogbo wa lára. Ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Kristi Jésù, wá sórí ilẹ̀ ayé láti fún wa nírètí àti ìtùnú. Jésù kọ́ wa pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni “tí ń bá wa gbé ẹrù lójoojúmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ìgbàlà wa.” (Sáàmù 68:19) Àwọn ènìyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè fi ìgbọ́kànlé sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”—Sáàmù 16:8.
Irú ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí ń jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwa èèyàn ti pọ̀ tó. Ó wá ṣe kedere pé ó ní in lọ́kàn láti pèsè ìtùnú rẹpẹtẹ fún wa, àti láti jẹ́ kí ara tù wá ní àkókò hílàhílo, ó sì lágbára láti ṣe é. “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.” (Aísáyà 40:29) Nígbà náà, báwo la ṣe lè rí ìtùnú nínú okun Jèhófà?
Ipa Títunilára Tí Àbójútó Jèhófà Ní Lórí Wa
Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ràn ìdílé aráyé púpọ̀. Àpọ́sítélì Pétérù mú un dá àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lójú pé “Ó [Ọlọ́run] bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Jésù Kristi tẹnu mọ́ bí àwọn ènìyàn ṣe ṣeyebíye tó lójú Ọlọ́run nípa sísọ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:6, 7) A ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ tó fi ń kíyè sí kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó kéré jù lọ nípa wa. Ó mọ àwọn nǹkan tí àwa fúnra wa kò mọ̀ nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ olúkúlùkù wa.
Títẹnu mọ́ irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní yìí tu Svetlana nínú púpọ̀, ìyẹn ọ̀dọ́mọbìnrin aṣẹ́wó táa mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣaájú. Ó ti ṣe tán láti para ẹ̀ kó tó di pé ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Ó wá tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tó ràn án lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi kan, ẹni tó ní ire wa lọ́kàn. Èyí wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sún un láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà àti láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ó tún fún Svetlana ní ìgbọ́kànlé tó nílò láti lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀, kó sì gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Ohun tó sọ nísinsìnyí ni pé: “Ó dá mi lójú pé Jèhófà kò ní fi mí sílẹ̀ láé. Mo ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun táa kọ sínú 1 Pétérù 5:7. Ó wí pé: ‘Kó gbogbo àníyàn yín lé [Jèhófà], nítorí pé ó bìkítà fún yín.’”
Ìrètí Táa Gbé Ka Bíbélì Máa Ń Tuni Nínú
Ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run ń gbà pèsè ìtùnú ni nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa kọ sílẹ̀, èyí tó ní ìrètí àgbàyanu fún ọjọ́ ọ̀la nínú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Pọ́ọ̀lù mú kí ìbátan tó wà láàárín ìrètí tòótọ́ àti ìtùnú ṣe kedere, nígbà tó kọ̀wé pé: “Kí . . . Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.” (2 Tẹsalóníkà 2:16, 17) Ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè pípé, èyí tó ń fúnni láyọ̀, tí yóò wà títí láé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé wà lára “ìrètí rere” yìí.—2 Pétérù 3:13.
Irú ìrètí tó dájú, tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló mú Aísáyà 35:5, 6) Kí Laimonis lè tóótun láti wà láàyè nínú Párádísè yẹn, ó ṣe àwọn ìyípadà tó kàmàmà. Ó jáwọ́ nínú ọtí mímu, gbogbo àtúnṣe tó ń ṣe sáyé ẹ̀ yìí làwọn aládùúgbò rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì ń kíyè sí. Ní báyìí, ó ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìtùnú tí Bíbélì ń fúnni.
Laimonis lọ́kàn le, ẹni táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìyẹn ní alárùn ẹ̀gbà tó di alámupara. Nígbà tó ń ka ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, inú rẹ̀ dùn láti kọ́ nípa ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tí yóò ṣeé ṣe fún un láti ní ìlera tó jí pépé. Nínú Bíbélì, ó ka ìlérí tó fini lọ́kàn balẹ̀ nípa ìmúláradá àgbàyanu yìí pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Ipa Tí Àdúrà Ń Kó
Nígbà táwọn nǹkan kan bá mú kí ọkàn wa gbọgbẹ́, a lè rí ìtùnú nínú gbígbàdúrà sí Jèhófà. Ìyẹn lè jẹ́ kí ọkàn wa fúyẹ́. Nígbà táa bá ń gbàdúrà, a lè rí ìtùnú nípa rírántí àwọn ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Sáàmù tó gùn jù nínú Bíbélì dà bí àdúrà àtọkànwá. Ẹni tó kọ orin náà sọ pé: “Jèhófà, mo rántí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ láti àkókò tí ó lọ kánrin, mo sì rí ìtùnú fún ara mi.” (Sáàmù 119:52) Nígbà tí nǹkan bá le dójú ẹ̀, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ ọ̀ràn àìsàn, kì í sábà sí ìdáhùn kan ṣoṣo tó lè yanjú gbogbo ọ̀ràn náà. Táa bá dá a dá àwa nìkan, a lè má mọ ohun tó yẹ ká ṣe gan-an. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé nígbà táwọn bá ti ṣe gbogbo ohun táwọn lè ṣe tán, yíyíjú sí Ọlọ́run nínú àdúrà máa ń yọrí sí ìtùnú, nígbà mìíràn, ó sì máa ń yọrí sí ojútùú tí a kò retí.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Pat, ẹni tí wọ́n gbé dìgbàdìgbà lọ sí ọsibítù, rí bí àdúrà ti lè tuni nínú tó. Lẹ́yìn tí ara obìnrin náà yá, ó wí pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó yẹ kí n ṣe ni pé kí n sáà fi ìgbésí ayé mi lé e lọ́wọ́, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé e láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú. Ní gbogbo àkókò yìí, ọkàn mi balẹ̀; mo mọ̀ pé mo ní àlàáfíà Ọlọ́run táa mẹ́nu kàn nínú Fílípì orí kẹrin, ẹsẹ ìkẹfà àti ìkeje.” Ìtùnú ńlá mà làwọn ẹsẹ wọ̀nyí jẹ́ fún gbogbo wa o! Ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”
Ẹ̀mí Mímọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Olùtùnú
Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó mú un ṣe kedere sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé, òun ò ní pẹ́ fi wọ́n sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí dà wọ́n láàmú, ó sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. (Jòhánù 13:33, 36; 14:27-31) Nígbà tí Jésù mọ̀ pé wọ́n nílò ìtùnú gan-an, ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ [tàbí olùtùnú] mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.” (Jòhánù 14:16; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni Jésù ń tọ́ka sí níhìn-ín. Lára àwọn ohun mìíràn tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ni pé, ó tu àwọn àpọ́sítélì nínú nígbà àdánwò wọn, ó sì fún wọn lókun láti máa bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ.—Ìṣe 4:31.
Ó ṣeé ṣe fún Angie, tí ọkọ rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lẹ́yìn jàǹbá ọkọ̀ kan, láti borí gbogbo ìdààmú àti wàhálà tó dé bá a. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Obìnrin náà wí pé: “Láìsí ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, a ò ní lè fara da gbogbo ohun táa fara dà, ká sì jẹ́ alágbára síbẹ̀. Ní tòótọ́, agbára Jèhófà ti fara hàn nínú àìlera wa, ó sì ti jẹ́ ibi ìsádi wa nígbà ìdààmú.”
Ẹgbẹ́ Ará Tó Ń Tuni Nínú
Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn láyé yìí, bó ti wù kí kiní ọ̀hún le tó, ó yẹ kó lè rí ìtùnú nínú ẹgbẹ́ ará tó wà nínú ìjọ Jèhófà. Ẹgbẹ́ ará yìí ń pèsè ìtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí, ó sì ń ran àwọn tó ń dara 2 Kọ́ríńtì 7:5-7.
pọ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́. Níbẹ̀, èèyàn lè rí àwùjọ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹni, tó bìkítà nípa ẹni, tó sì lè tuni nínú, àwọn tí wọ́n ṣe tán láti ranni lọ́wọ́, kí wọ́n sì tuni nínú nígbà ìdààmú.—A ti kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni láti “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ẹ̀kọ́ táa gbé ka Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ ń sún wọn láti fi ìfẹ́ ará àti ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn fún ara wọn. (Róòmù 12:10; 1 Pétérù 3:8) A ń sún àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà nínú ìjọ láti jẹ́ onínúure, ẹni tí ń tuni nínú, àti aláàánú.—Éfésù 4:32.
Joe àti Rebecca, tí ọmọ wọn kú lójijì, rí irú ìtùnú bẹ́ẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni. Wọ́n wí pé: “Jèhófà àti ìjọ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ti ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àkókò tó le koko fún wa. A gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún káàdì, lẹ́tà, àti ìpè lórí tẹlifóònù. Èyí mú ká wá mọyì bí ẹgbẹ́ ará wa ti ṣeyebíye tó. Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣì ń gbò wá lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìjọ ló wá ràn wá lọ́wọ́, bí wọ́n ti ń pèsè oúnjẹ fún wa, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bá wa túnlé wa ṣe.”
Rí Ìtùnú Gbà!
Nígbà tí ẹ̀fúùfù ìdààmú bá ń fẹ́ yìì, tí òjò ìdààmú rọ̀-rọ̀-rọ̀ tí ò dá, tí wàhálà ń gorí wàhálà, Ọlọ́run ṣe tán láti pèsè ààbò tí yóò tù wá nínú. Bí ọ̀kan lára àwọn sáàmù ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń dáàbò boni nìyí: “Òun yóò fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ àfifò dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ yóò sì sá di abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀.” (Sáàmù 91:4) Àpèjúwe tí a ṣe níbí yìí lè jẹ́ ti ẹyẹ idì. Àpèjúwe náà jọ ti ẹyẹ kan tó mọ̀ pé ewu ń bọ̀, tó sáré yára fi ìyẹ́ rẹ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Lọ́nà tó tún lágbára ju ìyẹn lọ, Jèhófà jẹ́ Aláàbò tòótọ́ fún gbogbo àwọn tó bá sá di í.—Sáàmù 7:1.
Bóo bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, àwọn ànímọ́ rẹ̀, ète rẹ̀, àti agbára rẹ̀ láti pèsè ìtùnú, a ké sí ọ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ pẹ̀lú lè rí ìtùnú gbà nínú okun Jèhófà!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìrètí ọjọ́ ọ̀la táa gbé ka Bíbélì lè tuni nínú