Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ ọ́ Tẹ́lẹ̀

Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ ọ́ Tẹ́lẹ̀

Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ ọ́ Tẹ́lẹ̀

“Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: . . . ‘Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’”—ÌṢÍPAYÁ 21:5.

1, 2. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi tọ̀nà nípa bí wọ́n ṣe ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣàyẹ̀wò ohun tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

 ǸJẸ́ o ti sọ ọ́ jáde tàbí kí o ronú nípa rẹ̀ rí pé, ‘Ta ló mọ̀la?’ O lè wá lóye ìdí tí àwọn èèyàn fi máa ń lọ́ tìkọ̀ láti méfò ohun tí ọjọ́ ọ̀la yóò mú wá tàbí ìdí tí wọn kì í fi í fọkàn tán àwọn tó ń kù gìrì sọ pé àwọn mọ ohun tó ń bọ̀ níwájú. Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ tóótun rárá láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó péye nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láwọn oṣù tàbí àwọn ọdún tó ń bọ̀.

2 Ìwé ìròyìn Forbes ASAP ya odindi ẹ̀dà kan sọ́tọ̀ fún àkókò. Inú rẹ̀ ni Robert Cringely, tó ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbàfiyèsí jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, ti kọ̀wé pé: “Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àkókò máa já gbogbo wa kulẹ̀ ni, àmọ́ kò sí ẹni tí àkókò ń fìyà jẹ tó àwọn alásọtẹ́lẹ̀. Ọ̀rọ̀ lórí ká máa méfò nípa ọjọ́ ọ̀la jẹ́ ìgbòkègbodò kan táa ti sábà ń kùnà nínú rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. . . . Síbẹ̀, àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ògbógi kò yéé sọ àsọtẹ́lẹ̀.”

3, 4. (a) Irú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára wo ni àwọn kan ní nípa ẹgbẹ̀rúndún tuntun yìí? (b) Ìrètí tí kò bára dé wo làwọn mìíràn ní nípa ọjọ́ ọ̀la?

3 O ti lè ṣàkíyèsí pé pípè tí wọ́n ń pe ọ̀pọ̀ àfiyèsí sórí ẹgbẹ̀rúndún tuntun náà lè jẹ́ kó dà bí ẹni pé àwọn èèyàn tó ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la ti ń pọ̀ sí i. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó kọjá, ìwé ìròyìn Maclean sọ pé: “Ọdún 2000 lè wulẹ̀ jẹ́ ọdún mìíràn lórí kàlẹ́ńdà ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Kánádà, àmọ́ ó lè wá ṣeé ṣe kó bọ́ sí ìbẹ̀rẹ̀ tuntun lóòótọ́.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Chris Dewdney ti Yunifásítì York sọ ìdí tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, ó ní: “Ẹgbẹ̀rúndún tuntun yìí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sọ pé ó dìgbà fún ọ̀rúndún tó burú jáì.”

4 Ǹjẹ́ ìyẹn ò dún bí àlá tí ò lè ṣẹ? Ní Kánádà, ìpín méjìlélógún péré lára àwọn tó dáhùn sí ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu-wò tí wọ́n ṣe ló “gbà gbọ́ pé ọdún 2000 yóò mú ìbẹ̀rẹ̀ tuntun bá ayé.” Àní, nǹkan bí ìdajì wọn “ló ń retí ìforígbárí mìíràn”—ogun àgbáyé—láàárín àádọ́ta ọdún. Ní kedere, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló ń wò ó pé ẹgbẹ̀rúndún tuntun kò lè yanjú àwọn ìṣòro wa, kí ó sì sọ ohun gbogbo di tuntun. Alàgbà Michael Atiyah, tó jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún Ẹgbẹ́ Aláyélúwà ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kọ̀wé pé: “Bí nǹkan ṣe ń yí padà lemọ́lemọ́ . . . túmọ̀ sí pé ọ̀rúndún kọkànlélógún yóò mú àwọn ìpèníjà pípabanbarì bá gbogbo ọ̀làjú wa. Ìṣòro iye ènìyàn tó ń pọ̀ sí i, àìtó ohun ìgbọ́bùkátà, ìbàyíkájẹ́, àti ipò òṣì tó gbòde kan ti ń bá wa fínra, nǹkan wọ̀nyí sì ń fẹ́ àbójútó láìfọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá.”

5. Ibo la ti lè rí ìsọfúnni tó ṣeé gbọ́kàn lé nípa ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

5 O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Níwọ̀n bí ènìyàn ò ti lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ́ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ǹjẹ́ kò yẹ ká kúkú gbàgbé nípa ọjọ́ ọ̀la?’ “Rárá!” ni ìdáhùn rẹ̀. Lóòótọ́, èèyàn ò lè sọ bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí ní ti gidi, ṣùgbọ́n kò yẹ ká wá ronú pé kò sẹ́ni tó mọ̀ nípa rẹ̀. Tóò, ta wá ni ó lè sọ nípa ọjọ́ ọ̀la, kí sì ni ìdí tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára? O lè rí àwọn ìdáhùn tí yóò tẹ́ ọ lọ́rùn nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ṣe gúnmọ́. A kọ wọ́n sínú ìwé tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní, táwọn èèyàn sì ń kà jù lọ, tó sì tún jẹ́ ìwé tí àwọn èèyàn ń ṣì lóye gan-an tí wọn ò sì kà sí rárá—ìwé náà ni Bíbélì. Ohunkóhun tóo lè rò nípa Bíbélì, bó tí wù kóo mọ̀ ọ́n dáradára tó, yóò ṣe ọ́ láǹfààní láti gbé àwọn àyọkà ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rin tó ṣe kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò. Wọ́n dìídì sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la alárinrin. Ní àfikún sí i, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ṣe kókó wọ̀nyí ṣàlàyé bí ọjọ́ ọ̀la rẹ àti ti àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe lè rí.

6, 7. Ìgbà wo ni Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ báwo sì ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ní ìmúṣẹ tó yani lẹ́nu?

6 Èkíní wà nínú ìwé Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta. Kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí kà á, fojú inú wo àyíká ọ̀rọ̀ náà—ìgbà tí a kọ ọ̀rọ̀ yìí, àti ohun tó fà á táa fi kọ ọ́. Wòlíì Ọlọ́run nì, Aísáyà, ẹni tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, gbé ayé ní ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà tí ìjọba Júdà wá sópin. Òpin náà dé nígbà tí Jèhófà mú ààbò rẹ̀ kúrò lórí àwọn Júù aláìṣòótọ́, tó jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ti Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.—2 Kíróníkà 36:15-21.

7 Láti mú kí ìtàn tó yí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ká túbọ̀ ṣe kedere, rántí pé Ọlọ́run ṣamọ̀nà Aísáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ orúkọ ará Páṣíà náà, Kírúsì, tí a kò tíì bí nígbà náà, tó sì jẹ́ pé òun ló wá ṣẹ́gun Bábílónì níkẹyìn. (Aísáyà 45:1) Kírúsì ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Júù láti padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lọ́nà yíyanilẹ́nu, Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìpadàbọ̀ yẹn, gẹ́gẹ́ bí a ti kà á nínú orí karùnlélọ́gọ́ta. Ó darí àfiyèsí sórí ipò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbádùn ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn.

8. Ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ wo ni Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, gbólóhùn wo ló sì gbàfiyèsí gan-an?

8 A kà á nínú Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàdínlógún sí ìkọkàndínlógún pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun tí ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà. Ó sì dájú pé èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Jerúsálẹ́mù, èmi yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú àwọn ènìyàn mi; a kì yóò sì gbọ́ ìró ẹkún tàbí ìró igbe arò mọ́ nínú rẹ̀.” Dájúdájú, Aísáyà ṣàpèjúwe àwọn ipò tó dára gan-an ju èyí tí àwọn Júù wà ní Bábílónì. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìdùnnú àti ayọ̀. Wàyí o, wá wo gbólóhùn yẹn, “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” Èyí ni àkọ́kọ́ nínú ìgbà mẹ́rin tí gbólóhùn yẹn ti fara hàn nínú Bíbélì, àwọn àyọkà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí sì lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa ní tààràtà, kódà ó lè sọ bí yóò ṣe rí.

9. Báwo ní ìmúṣẹ Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta ẹsẹ ìkẹtàdínlógún sí ìkọkàndínlógún ṣe kan àwọn Júù ìgbàanì?

9 Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ pàá tí Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàdínlógún sí ìkọkàndínlógún ní dá lórí àwọn Júù ìgbàanì, àwọn tó jẹ́ pé bí Aísáyà ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ gan-an ni wọ́n ṣe padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, níbi tí wọn ti padà fi ìdí ìjọsìn mímọ́ gaara múlẹ̀. (Ẹ́sírà 1:1-4; 3:1-4) Kò sí àní-àní pé orí pílánẹ́ẹ̀tì kan náà ni ilẹ̀ ìbílẹ̀ tí wọ́n padà sí wà, kì í ṣe ibòmíràn lágbàáyé. Irú òye yẹn lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tí Aísáyà ní lọ́kàn nípa ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun. Kò sídìí fún míméfò, bí àwọn kan ti ń ṣe, nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Nostradamus tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tàbí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tí àwọn èèyàn ń sọ. Bíbélì fúnra rẹ̀ jẹ́ ká lóye ohun tí Aísáyà ní lọ́kàn.

10. Báwo ló ṣe yẹ ká lóye “ilẹ̀ ayé” tuntun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀?

10 Nínú Bíbélì, “ilẹ̀ ayé” kì í fi gbogbo ìgbà tọ́ka sí àgbáyé wa. Fún àpẹẹrẹ, Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní sọ ní ṣangiliti pé: ‘Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ilẹ̀ ayé.’ A mọ̀ pé pílánẹ́ẹ̀tì wa—ilẹ̀ lásán àti agbami òkun tó lọ salalu—kò lè kọrin. Àwọn èèyàn ló ń kọrin. Dájúdájú, àwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé ni Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní ń tọ́ka sí. a Àmọ́, Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta ẹsẹ ìkẹtàdínlógún tún mẹ́nu kan “ọ̀run tuntun.” Tí “ilẹ̀ ayé” bá dúró fún àwùjọ tuntun ti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ àwọn Júù, kí wá ni “ọ̀run tuntun”?

11. Kí ni gbólóhùn náà, “ọ̀run tuntun,” ń tọ́ka sí?

11 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Cyclopædia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, tí M’Clintock àti Strong ṣe, sọ pé: “Níbikíbi tí wọ́n bá ti mẹ́nu kan ọ̀run nínú ìran inú àsọtẹ́lẹ̀ kan, ọ̀run máa ń túmọ̀ sí . . . gbogbo àgbájọ àwọn alákòóso . . . ìyẹn àwọn tó ní àwọn ọmọ abẹ́ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ṣe wà lókè, tó sì ń ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí.” Ní ti àpapọ̀ gbólóhùn náà, “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,” ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopædia náà ṣàlàyé pé ‘nínú èdè àsọtẹ́lẹ̀, gbólóhùn náà túmọ̀ sí ètò ìṣèlú kan tí àwọn èèyàn ti di onírúurú ipò mú. Ọ̀run ló ni ipò ọba aláṣẹ; ilẹ̀ ayé ni ọmọ abẹ́, ìyẹn àwọn ẹni tí àwọn lọ́gàálọ́gàá ń ṣàkóso.’

12. Báwo ni àwọn Júù ìgbàanì ṣe nírìírí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”?

12 Nígbà tí àwọn Júù padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, ohun kan táa lè pè ní ètò àwọn nǹkan tuntun tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n ní ẹgbẹ́ alákòóso tuntun. Serubábélì, tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba ni gómìnà wọn, Jóṣúà sì ni àlùfáà àgbà wọn. (Hágáì 1:1, 12; 2:21; Sekaráyà 6:11) Ìwọ̀nyí ló para pọ̀ jẹ́ “ọ̀run tuntun.” Lórí kí ni? “Ọ̀run tuntun” náà ṣàkóso lé “ilẹ̀ ayé tuntun” lórí, ìyẹn ni àwùjọ àwọn ènìyàn tí a sọ di mímọ́, tí wọ́n padà wá sí ilẹ̀ wọn kí wọ́n lè tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́ fún ìjọsìn Jèhófà. Nítorí náà, ní ti gidi, ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà nínú ìmúṣẹ tó kan àwọn Júù lákòókò yẹn.

13, 14. (a) Ibòmíràn wo ni gbólóhùn náà “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ti jẹ yọ, tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò? (b) Èé ṣe tí àsọtẹ́lẹ̀ Pétérù fi gbà wá lọ́kàn gan-an lákòókò táa wà yìí?

13 Kíyè sára kí o má lọ gbàgbé kókó ọ̀rọ̀ tí à ń sọ gan-an. Èyí kì í ṣe pé a kàn ń gbìyànjú láti fi òye orí wa gbé ìtumọ̀ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé a kàn ń yẹ ìtàn ayé àtijọ́ wò gààràgà. O lè rí ohun tí a ń wí yìí tóo bá lọ wo ibòmíràn tí gbólóhùn náà “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tún ti fara hàn. Tóo bá ṣí Pétérù kejì orí kẹta, wàá rí gbólóhùn yìí níbẹ̀, wàá sì rí i pé ó kan ọjọ́ ọ̀la wa.

14 Ó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún tí àwọn Júù ti padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn kí àpọ́sítélì Pétérù tó kọ lẹ́tà rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù, ṣe ni Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi “Olúwa” tí a mẹ́nu kàn nínú Pétérù kejì orí kẹta, ẹsẹ kejì. Ní ẹsẹ ìkẹrin, Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “wíwàníhìn-ín” tí Jésù “ṣèlérí,” ìyẹn ló wá jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ náà bá òde òní mu gan-an. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni Jésù ti wà níhìn-ín ní ti pé ó ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. (Ìṣípayá 6:1-8; 11:15, 18) Èyí tún wá ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀, lójú ìwòye ohun mìíràn tí Pétérù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú orí yìí.

15. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Pétérù sọ nípa “ọ̀run tuntun” ṣe ń ní ìmúṣẹ?

15Pétérù kejì, orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá, a kà á pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” Ó ṣeé ṣe kí o ti mọ̀ pé Jésù tó wà lọ́run ni Alákòóso pàtàkì nínú “ọ̀run tuntun.” (Lúùkù 1:32, 33) Síbẹ̀, àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn fi hàn pé kò ní dá nìkan ṣàkóso. Jésù ṣèlérí pé àyè yóò wà lọ́run fáwọn àpọ́sítélì àti àwọn mìíràn bíi tiwọn. Nínú ìwé Hébérù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní “alábàápín ìpè ti ọ̀run.” Jésù sì sọ pé ẹgbẹ́ yìí yóò jókòó sórí àwọn ìtẹ́ pẹ̀lú òun ní ọ̀run. (Hébérù 3:1; Mátíù 19:28; Lúùkù 22:28-30; Jòhánù 14:2, 3) Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé àwọn mìíràn yóò bá Jésù ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ara ọ̀run tuntun. Kí ni Pétérù wá ní lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé tuntun”?

16. “Ilẹ̀ ayé tuntun” wo ló ti wà nísinsìnyí?

16 Gẹ́gẹ́ bíi ti ìmúṣẹ ìgbàanì—ìyẹn pípadà tí àwọn Júù padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn—ìmúṣẹ Pétérù kejì orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí tí ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso ọ̀run tuntun náà. O lè rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí, tí wọ́n ń fínnúfíndọ̀ fi ara wọn sábẹ́ irú ìṣàkóso bẹ́ẹ̀. Wọ́n ń jàǹfààní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wọ́n sì ń sapá láti máa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. (Aísáyà 54:13) Àwọn wọ̀nyí ló para pọ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ “ilẹ̀ ayé tuntun,” ní ti pé wọ́n jẹ́ àwùjọ kan kárí ayé tó wá látinú gbogbo ilẹ̀, èdè, àti ẹ̀yà, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní fífi ara wọn sábẹ́ Ọba tí ń jọba náà, Jésù Kristi. Kókó pàtàkì kan ni pé, ìwọ náà mà lè jẹ́ ọ̀kan lára wọn!—Míkà 4:1-4.

17, 18. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Pétérù kejì, orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá fi jẹ́ ìdí fún wa láti máa wò ó pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára?

17 Má rò pé ibi tí gbogbo rẹ̀ pin sí nìyí o, kóo má rò pé a ò ní ìjìnlẹ̀ òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ọjọ́ ọ̀la. Àní, bóo bá ṣe ń ṣàyẹ̀wò àyíká ọ̀rọ̀ inú Pétérù kejì, orí kẹta lo máa rí i pé àwọn àmì ìyípadà ńlá ń bẹ níwájú. Ní ẹsẹ ìkarùn-ún àti ìkẹfà, Pétérù kọ̀wé nípa Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ìyẹn Àkúnya Omi tó fòpin sí ayé búburú ìgbàanì. Ní ẹsẹ ìkeje, Pétérù mẹ́nu kàn án pé “àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí,” ìyẹn àwọn tó ń ṣàkóso àtàwọn àwùjọ ènìyàn lápapọ̀, la fi pa mọ́ de “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Èyí wá jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe àgbáyé tí ó ṣeé fojú rí ni gbólóhùn náà, “àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí” tọ́ka sí, bí kò ṣe àwọn ènìyàn àti ìṣàkóso wọn.

18 Pétérù wá ṣàlàyé lẹ́yìn náà pé ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ yóò mú ìfọ̀mọ́ tónítóní wá, láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tó mẹ́nu kàn ní ẹsẹ ìkẹtàlá. Kíyè sí ìparí ẹsẹ yẹn—“nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” Ǹjẹ́ ìyẹn ò fi hàn pé àwọn ìyípadà pàtàkì kan tí yóò kóre dé yóò ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ kò mú kí a máa fojú sọ́nà fún àwọn ohun tó jẹ́ tuntun ní ti tòótọ́, àkókò kan tí àwọn ènìyàn yóò túbọ̀ gbádùn ìwàláàyè ju tòde òní lọ? Bó bá jẹ́ pé bóo ṣe rí i nìyẹn, a jẹ́ pé o ti ní ìjìnlẹ̀ òye ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nìyẹn, ìjìnlẹ̀ òye tó jẹ́ pé ìwọ̀nba kéréje ènìyàn ló ní in.

19. Kí ló fà á tí ìwé Ìṣípayá fi tọ́ka sí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tí ń bọ̀?

19 Àmọ́, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú. A ti wo ibi tí gbólóhùn náà “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ti fara hàn nínú Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta àti ibòmíràn tó tún ti fara hàn ní Pétérù kejì orí kẹta. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká yíjú sí Ìṣípayá orí kọkànlélógún, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára ibòmíràn tí gbólóhùn yìí ti fara hàn nínú Bíbélì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, lílóye bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wáyé yóò ṣèrànwọ́. Ní orí méjì ṣáájú rẹ̀, ní Ìṣípayá orí kọkàndínlógún, a rí i pé wọ́n fi ohun ìṣàpẹẹrẹ tó ṣe kedere ṣàpèjúwe ogun kan—àmọ́ kì í ṣe ogun tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn ń jà o. “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” wà lápá kan. Ó ṣeé ṣe kóo mọ̀ pé Jésù Kristi ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 1:1, 14) Ó wà lọ́run, ìran yìí sì ṣàpèjúwe bó ṣe wà níbẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ti ọ̀run. Ta ni wọ́n wá ń bá jà? Orí náà mẹ́nu kan “àwọn ọba,” “àwọn ọ̀gágun,” àti onírúurú ènìyàn, àti “àwọn ẹni kékeré àti àwọn ẹni ńlá.” Ogun yìí ní í ṣe pẹ̀lú dídé ọjọ́ Jèhófà, pípa ìwà ibi run. (2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Bó ṣe ń tẹ̀ síwájú, Ìṣípayá orí ogún bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣàpèjúwe ìmúkúrò “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì.” Èyí ló wá sún wa dórí gbígbé ìwé Ìṣípayá orí kọkànlélógún yẹ̀ wò.

20. Kí ni ìyípadà pàtàkì tí Ìṣípayá orí kọkànlélógún ẹsẹ ìkíní fi hàn pé ó wà lọ́jọ́ iwájú?

20 Àpọ́sítélì Jòhánù bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ amúniláyọ̀ wọ̀nyí, ó ní: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ, òkun kò sì sí mọ́.” Lójú ohun tí a ti rí nínú Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta àti Pétérù kejì orí kẹta, a lè ní ìdánilójú pé èyí kò túmọ̀ sí pé a ó fi ohun mìíràn rọ́pò àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé wa, pẹ̀lú agbami òkun tó wà nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn orí tó ṣáájú ti fi hàn, àwọn ènìyàn burúkú àti ìṣàkóso wọn, títí kan alákòóso tí a kò lè fojú rí náà, Sátánì la óò mú kúrò. Dájúdájú, ìlérí ètò àwọn nǹkan tuntun tó kan àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé la ṣe níhìn-ín.

21, 22. Àwọn ìbùkún wo ni Jòhánù mú dá wa lójú, kí sì ni nínu omijé nù túmọ̀ sí?

21 Èyí dá wa lójú, báa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu yìí. Apá ìparí ẹsẹ ìkẹta sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú aráyé, tí yóò darí àfiyèsí rẹ̀ tí ń ṣeni láǹfààní sí àwọn ènìyàn tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 43:7) Jòhánù tún ń tẹ̀ síwájú ní ẹsẹ ìkẹrin àti ìkarùn-ún pé: “[Jèhófà] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí mà wúni lórí o!

22 Sinmẹ̀dọ̀ ná, kí o finú ro ohun tí Bíbélì ń sọ tẹ́lẹ̀ yìí. ‘Ọlọ́run yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.’ Ìyẹn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ omijé tó ń fọ ìdọ̀tí kúrò ní ọmọlójú wa tó jẹ́ ẹlẹgẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè jẹ́ omijé ayọ̀. Ó tì o, omijé tí Ọlọ́run yóò nù kúrò ni èyí tí ìyà, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀, ìpalára, àti ìjẹ̀rora máa ń fà. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú? Tóò, ìlérí kíkàmàmà tí Ọlọ́run ṣe yìí so nínu omijé pọ̀ mọ́ ‘ikú, ọ̀fọ̀, igbe ẹkún, àti ìrora tí kò ní sí mọ́.’—Jòhánù 11:35.

23. Òpin àwọn ipò wo ni àpọ́sítélì Jòhánù mú dá wa lójú?

23 Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pé àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ẹ̀gbà, àrùn ọkàn-àyà, àti ikú pàápàá la ó ti mú kúrò? Ta ni nínú wa tí àrùn, jàǹbá, tàbí ìjábá kò tíì pa èèyàn rẹ̀ kan rí? Ọlọ́run ṣèlérí níhìn-ín pé ikú kì yóò sí mọ́, tí ó fi hàn pé àwọn ọmọ tó ṣeé ṣe káa bí nígbà yẹn kò ní dàgbà di arúgbó—kí ikú sì wá pa wọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún túmọ̀ sí pé kò ní sí àrùn ọdẹ orí tí ń bọ́jọ́ ogbó rìn, àrùn tí ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, oyún ìju, àrùn glaucoma, tàbí àfòta pàápàá—tó sábà máa ń ṣe àwọn arúgbó.

24. Báwo ni ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun’ yóò ṣe jẹ́ ìbùkún, kí sì ni a ṣì máa gbé yẹ̀ wò?

24 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, wàá gbà pé ọ̀fọ̀ àti igbe ẹkún yóò dín kù nígbà táa bá ti mú ikú, ọjọ́ ogbó, àti àìsàn kúrò. Síbẹ̀, báwo wá ni ọ̀rọ̀ nípa ipò òṣì, híhùwà àìdáa sọ́mọdé, àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà nítorí ibi téèyàn ti wá tàbí nítorí àwọ̀ ara? Tí irú àwọn nǹkan wọ̀nyí—tó gbòde kan lóde òní—bá ń bá a lọ, a jẹ́ pé a ò ní bọ́ lọ́wọ́ ọ̀fọ̀ àti igbe ẹkún nìyẹn. Nítorí náà, ìgbésí ayé tí a óò gbé lábẹ́ “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” kì í ṣe èyí tí àwọn ohun tó ń fa ìbànújẹ́ lónìí yóò bà jẹ́. Ìyípadà ńlá mà lèyí o! Síbẹ̀síbẹ̀, mẹ́ta péré la tíì gbé yẹ̀ wò lára ibi mẹ́rin tí gbólóhùn náà “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ti fara hàn nínú Bíbélì. Ó ṣì ku ọ̀kan tó so pọ̀ mọ́ ohun táa ti gbé yẹ̀ wò, tó sì tún tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà fún àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ láti ‘sọ ohun gbogbo di tuntun’ ṣẹ, àti bí yóò ṣe mú un ṣẹ. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àti ohun tó lè túmọ̀ sí fún ayọ̀ wa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

aThe New English Bible ṣe tú Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní ni pé: “Ẹ kọrin sí OLÚWA, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.” The Contemporary English Version kà pé: “Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí, ẹ kọrin ìyìn sí OLÚWA.” Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òye náà pé “ilẹ̀ ayé tuntun” tí Aísáyà ń tọ́ka sí ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè wọn.

Kí Lo Rántí?

• Àwọn ibi mẹ́ta wo ni Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”?

• Báwo ni àwọn Júù ìgbàanì ṣe nípìn-ín nínú ìmúṣẹ “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”?

• Kí ni ìmúṣẹ táa lóye nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” bí Pétérù ṣe sọ ọ́?

• Báwo ni Ìṣípayá orí kọkànlélógún ṣe tọ́ka wa sí ọjọ́ ọ̀la alárinrin?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bí Jèhófà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gan-an, Kírúsì ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Júù láti padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa