Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà

Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà

Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà

Ìlú Sòwẹ́tò, Ní Gúúsù Áfíríkà Ni Welsh Àti Elthea Ti Ṣègbéyàwó Wọn Lọ́dún 1985. Lóòrèkóòrè, Àwọn Àti Zinzi, Ọmọbìnrin Wọn, Máa Ń wo Fọ́tò Ìgbéyàwó Wọn, Tí Wọ́n á Sì Bẹ̀rẹ̀ Sí Rántí Ọjọ́ Ayọ̀ Yẹn. Zinzi Máa Ń fẹ́ Mọ Ẹni Tí Àwọn Àlejò Tó Wá Síbi Ìgbéyàwó Náà Jẹ́, Inú Rẹ̀ Sì Máa Ń dùn Yàtọ̀ Nígbà Tó Bá Rí Fọ́tò Màmá Rẹ̀ Tó Múra Rèǹtèrente.

AYẸYẸ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé ìgbéyàwó tí wọ́n sọ nínú gbọ̀ngàn ìlú Sòwẹ́tò. Lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni akọrin fi ohùn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run. Lẹ́yìn èyí, làwọn àlejò wá ń jẹun, bí orin atunilára ti Ìjọba Ọlọ́run ti ń dún lábẹ́lẹ̀. Kò sí ọtí, kò sórin àgbọ́fọwọ́dití tàbí ijó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn àlejò ń gbádùn ìfararora, tí wọ́n ń kí tọkọtaya náà kú àṣeyẹ. Gbogbo ètò náà pátá kò ju wákàtí mẹ́ta lọ. Raymond, tí í ṣe Kristẹni alàgbà, rántí pé: “Ńṣe ni inú mi máa ń dùn nígbàkigbà tí mo bá rántí ayẹyẹ ìgbéyàwó yẹn.”

Nígbà tí Welsh àti Elthea ṣe ìgbéyàwó, wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society tó wà lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà. Ayẹyẹ ìgbéyàwó tó mọ níwọ̀n lapá wọ́n ká. Àwọn Kristẹni kan ti yàn láti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀, kí wọ́n lọ wá iṣẹ́ owó ṣe, kí wọ́n lè filé pọntí, fọ̀nà rokà lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Ṣùgbọ́n Welsh àti Elthea kò kábàámọ̀ rárá pé wọ́n pinnu láti ṣe ìgbéyàwó tó mọ níwọ̀n, nítorí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti máa sin Ọlọ́run nìṣó gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, kó tó di pé wọ́n bí Zinzi.

Àmọ́ tí àwọn méjì tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà bá yàn láti lo orin ayé, kí ijó sì ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ńkọ́? Bí wọ́n bá pinnu láti pèsè wáìnì tàbí àwọn ọtí míì ńkọ́? Bí agbára wọn bá gbé e láti ṣe ìgbéyàwó ayé-gbọ́-ọ̀run-mọ̀ ńkọ́? Báwo ni wọ́n ṣe lè rí i dájú pé àṣeyẹ náà yóò jẹ́ èyí tó mìrìngìndìn, tó sì yẹ àwọn olùjọsìn Ọlọ́run? Irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí gbèrò o, torí Bíbélì pàṣẹ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

Yíyẹra fún Àríyá Aláriwo

Ṣàṣà lọjọ́ ìgbéyàwó tí kì í ṣọjọ́ ayọ̀. Ṣùgbọ́n téèyàn ò bá ṣọ́ra, àṣejù lè wọ̀ ọ́, kí ó sì wá di àríyá tí kò ṣeé ṣàkóso. Níbi ọ̀pọ̀ ayẹyẹ ìgbéyàwó tí kì í ṣe ti Ẹlẹ́rìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ tí ń tàbùkù sí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sábà máa ń mutí débi tí wọ́n á fi yó kẹ́ri. Ó mà ṣe o, irú èyí ti ṣẹlẹ̀ níbi àwọn ìgbéyàwó kan tó jẹ́ ti Kristẹni pàápàá.

Bíbélì kìlọ̀ pé “aláriwo líle ni ọtí tí ń pani.” (Òwe 20:1) Bí ọtí bá lè sọ ẹnì kan ṣoṣo di aláriwo, ronú itú tí ọtí lè pa láàárín èrò rẹpẹtẹ, tó mu ún lámujù! Láìsí àní-àní, irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ kì í pẹ́ di ibi “mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí,” tó wà lára àwọn nǹkan tí Bíbélì pè ní “iṣẹ́ ti ara.” Irú àṣàkaṣà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwà dà tóótun láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run.—Gálátíà 5:19-21.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “àríyá aláriwo” ni wọ́n lò láti fi ṣàpèjúwe àwọn ọ̀dọ́ tó ti mutí, tí wọ́n ń pariwo kiri ìgboro, tí wọ́n ń kọrin, tí wọ́n ń lù, tí wọ́n sì ń jó. Bí ọtí bá ya yẹ̀yẹ́ níbi ìgbéyàwó, tí orin ń dún lákọlákọ, táwọn èèyàn sì ń jó ijó ewèlè, àfàìmọ̀ ni àṣeyẹ náà ò ní di àríyá aláriwo. Nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, àwọn aláìmọ̀kan lè ṣubú wẹ́rẹ́ sínú ìdẹwò, kí wọ́n sì lọ́wọ́ sáwọn iṣẹ́ ti ara míì, bí “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, . . . [tàbí kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ fún] ìrufùfù ìbínú.” Kí la lè ṣe kírú iṣẹ́ ti ara bẹ́ẹ̀ má ba ayọ̀ ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni jẹ́? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó kan yẹ̀ wò.

Ìgbéyàwó Kan Tí Jésù Lọ

Wọ́n pe Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ síbi ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì. Wọ́n gbà láti lọ síbi ayẹyẹ ọ̀hún, kódà Jésù fi kún ayọ̀ ayẹyẹ náà. Ìgbà tí wáìnì ò tó, ó pèsè wáìnì àtàtà tó pọ̀ lọ́nà ìyanu. Láìsí àní-àní, wáìnì tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn ìgbéyàwó náà wúlò fún ọkọ ìyàwó tó moore náà àti ìdílé rẹ̀ fún sáà kan.—Jòhánù 2:3-11.

A lè rí ẹ̀kọ́ mélòó kan kọ́ nínú ìgbéyàwó tí Jésù lọ yìí. Èkínní, mo-gbọ́-mo-yà kọ́ ló gbé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débi àsè ìgbéyàwó yẹn. Bíbélì sọ pàtó pé wọ́n ké sí wọn wá síbẹ̀ ni. (Jòhánù 2:1, 2) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nínú àkàwé méjì tí Jésù ṣe nípa àsè ìgbéyàwó, léraléra ló sọ pé ṣe ni wọ́n ké sí àwọn àlejò tó wá síbẹ̀.—Mátíù 22:2-4, 8, 9; Lúùkù 14:8-10.

Ní àwọn ilẹ̀ kan, àṣà wọn ni pé káwọn ará àdúgbò gbà pé àwọn ò gbọ́dọ̀ ṣàìsí níbi àsè ìgbéyàwó kan, yálà wọ́n pè wọ́n tàbí wọn ò pè wọ́n. Àmọ́ èyí lè fa àpò àwọn onínàáwó gbẹ. Àwọn àfẹ́sọ́nà tó fẹ́ ṣègbéyàwó, tí wọn ò sì lówó rẹpẹtẹ lọ́wọ́, lè lọ tọrùn bọ gbèsè láti lè rí i pé àwọn èrò tí kò lóǹkà tó wá síbi ìgbéyàwó náà, jẹ àjẹtẹ́rùn, wọ́n sì mu àmutẹ́rùn. Nítorí náà, bí àwọn Kristẹni méjèèjì tó fẹ́ ṣègbéyàwó bá pinnu pé iye àwọn èèyàn báyìí làwọn fẹ́ kó wá síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu, kò yẹ káwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọn ò pè bínú, kò sì yẹ kí wọ́n yọjú síbẹ̀. Ọkùnrin kan tó ṣègbéyàwó ní Cape Town, ní Gúúsù Áfíríkà, rántí pé igba èèyàn lòun pè síbi ìgbéyàwó òun. Àmọ́, ẹgbẹ̀ta ló rọ́ dé, oúnjẹ ò sì kárí. Lára mo-gbọ́-mo-yà náà làwọn àlejò tó kún inú bọ́ọ̀sì kan, tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n kàn wá mọ̀lú Cape Town ní ìparí ọ̀sẹ̀ tí ìgbéyàwó yẹn bọ́ sí. Ẹni tó ń fi ìlú han àwọn èrò inú bọ́ọ̀sì náà ló kàn tan díẹ̀ mọ́ ìyàwó, ó sì gbà pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti kó gbogbo èrò náà wá, láìtilẹ̀ fi tó ìyàwó tàbí ọkọ̀ ìyàwó létí!

Àfi táwọn onínàáwó bá sọ pé gbogbo ayé làwọn pè wá síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu wọn, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù kò ní lọ síbi àsè ìgbéyàwó tí wọn ò pè é sí, láti lọ jókòó ti oúnjẹ àti ohun mímu tí wọ́n pèsè sílẹ̀ de àwọn tí wọ́n pè. Àwọn tó bá ń ṣe bí ẹni pé káwọn ó lọ, láìjẹ́ pé a pè wọ́n, lè bi ara wọn léèrè pé, ‘Bí mo bá lọ síbi àsè ìgbéyàwó yìí, ǹjẹ́ kò ní fi hàn pé mi ò nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó? Ǹjẹ́ mi ò ní dá kún wàhálà wọn báyìí, kí n sì wá di bàsèjẹ́?’ Dípò bíbínú nítorí pé wọn ò pè é, Kristẹni tí òye yé lè fi tìfẹ́tìfẹ́ fi ìkíni a-báa-yín-yọ̀ ránṣẹ́ sí tọkọtaya náà, kí ó sì tọrọ ìbùkún Jèhófà sórí wọn. Ó tiẹ̀ lè ronú nípa bí òun ó ṣe ran tọkọtaya náà lọ́wọ́ nípa fífi ẹ̀bùn ránṣẹ́ láti lè fi kún ayọ̀ ọjọ́ ìgbéyàwó wọn.—Oníwàásù 7:9; Éfésù 4:28.

Ojúṣe Ta Ni?

Láwọn ibì kan ní Áfíríkà, àṣà wọn ni pé káwọn àgbà ìdílé ṣètò ayẹyẹ ìgbéyàwó. Àwọn àfẹ́sọ́nà lè mọrírì èyí, nítorí á jẹ́ kí ẹrù ìnáwó fúyẹ́ lọ́rùn wọn. Wọ́n tún lè gbà pé kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dá àwọn lẹ́bi ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀. Àmọ́, kí àwọn àfẹ́sọ́nà tó tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí tó lọ́kàn rere, ó yẹ káwọn náà rí i dájú pé àwọn ẹbí gbà láti bá àwọn fẹ́ ohun tí àwọn fẹ́.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, tó “sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run,” kò sí ẹ̀rí kankan pé ó tìtorí ìyẹn sọ ara rẹ̀ di baba ètò, tó wá ń pàṣẹ bí nǹkan ṣe ń lọ níbi ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà. (Jòhánù 6:41) Kàkà bẹ́ẹ̀, àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé ẹlòmíì ni wọ́n fi ṣe “olùdarí àsè.” (Jòhánù 2:8) Ẹ̀wẹ̀, olùdarí yìí ní láti jíhìn fún ọkọ ìyàwó, tí í ṣe olórí ìdílé tuntun náà.—Jòhánù 2:9, 10.

Àwọn ẹbí tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ wọ olórí tí Ọlọ́run yàn fún ìdílé tuntun náà. (Kólósè 3:18-20) Òun ló máa dáhùn fún ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó rẹ̀. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, ó yẹ kí ọkọ ìyàwó gba tàwọn ẹlòmíì rò, bó bá sì ṣeé ṣe, ó yẹ kó fàyè gba ohun tí ìyàwó rẹ̀ fẹ́, ohun táwọn òbí òun alára fẹ́, àtohun táwọn àna rẹ̀ fẹ́. Àmọ́ o, báwọn ẹbí bá takú pé ètò táwọn ṣe ni wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé, tí èyí sì lòdì sí ìfẹ́ inú àwọn àfẹ́sọ́nà náà, nígbà náà, àwọn àfẹ́sọ́nà náà lè kọ ìrànlọ́wọ́ wọn láìfi ṣe tìjà, kí wọ́n sì rọra ṣe ìgbéyàwó náà níwọ̀n tí agbára wọ́n mọ. Lọ́nà yìí, nǹkan kan ò ní ṣẹlẹ̀ tí yóò ba tọkọtaya náà lọ́kàn jẹ́ lẹ́yìnwá ọ̀la. Fún àpẹẹrẹ, níbi ìgbéyàwó Kristẹni kan ní Áfíríkà, ìbátan wọn kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tí wọ́n fi ṣe olùdarí ètò, ta ọtí sílẹ̀ láti fi júbà àwọn babańlá!

Nígbà míì, tọkọtaya á ti lọ fún ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì kí ayẹyẹ ìgbéyàwó tó parí. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọkọ ìyàwó ní láti ṣètò àwọn tó tóótun, tó máa rí sí i pé gbogbo nǹkan ń lọ níbàámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì, àti pé ayẹyẹ náà parí lásìkò.

Ìwéwèé Àfẹ̀sọ̀ṣe àti Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Ó jọ pé oúnjẹ tó gbámúṣé pọ̀ níbi ìgbéyàwó tí Jésù lọ, nítorí Bíbélì pè é ní àsè ìgbéyàwó. Gẹ́gẹ́ báa ti sọ níṣàájú, wáìnì pẹ̀lú pọ̀ níbẹ̀. Láìsí àní-àní, orin tó bétí mu àti ijó tó bójú mu wà níbẹ̀, nítorí pé nǹkan wọ̀nyí kì í wọ́n níbi pọ̀pọ̀ṣìnṣìn àwọn Júù. Jésù fi èyí hàn nínú àkàwé olókìkí náà nípa ọmọ onínàákúnàá. Bàbá olówó inú ìtàn náà láyọ̀ gan-an pé ọmọ òun tó ti ronú pìwà dà padà wálé, ó sì sọ pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a jẹun, kí a sì gbádùn ara wa.” Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí, ayẹyẹ náà ní “orin àwọn òṣèré àti ijó” nínú.—Lúùkù 15:23, 25.

Àmọ́ o, ẹ jẹ́ ká kíyè sí i pé Bíbélì kò sọ pàtó pé orin àti ijó wáyé níbi ìgbéyàwó ti Kánà. Bíbélì ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ kan ijó rárá ní gbogbo ibi tó ti sọ̀rọ̀ ayẹyẹ ìgbéyàwó. Ó jọ pé àyàbá lọ̀ràn ijó jíjó jẹ́ níbi ìgbéyàwó àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a kọ Bíbélì, kì í sì í sí lára ètò tí wọ́n dìídì ṣe. Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan kan kọ́ nínú èyí?

Ní Áfíríkà, wọ́n máa ń kó àwọn ẹ̀rọ sitẹrió amìjìnjìn wá síbi àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni kan. Orin náà lè ròkè lálá débi pé ńṣe làwọn tó wà níkàlẹ̀ gbọ́dọ̀ máa pariwo sókè kí wọ́n tó lè gbọ́ ara wọn. Nígbà míì, àwọn èèyàn kì í róúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n wọ́n á ríjó jó, àní kí wọ́n tilẹ̀ jó àjótàkìtì pàápàá. Dípò kí ó jẹ́ àsè ìgbéyàwó, àwọn èèyàn lè wá fi ibẹ̀ pagbo ijó. Kò tán síbẹ̀ o, orin tí ń dún lákọlákọ máa ń ké sí àwọn kàràǹbàní ẹ̀dá, àtàwọn àjèjì tó máa fẹsẹ̀ palẹ̀ wá síbẹ̀, láìjẹ́ pé a pè wọ́n.

Níwọ̀n bí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ayẹyẹ ìgbéyàwó kò ti fi orin àtijó sípò pàtàkì, ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí jẹ́ atọ́nà fáwọn àfẹ́sọ́nà tó ń múra àtiṣe ìgbéyàwó tí yóò bọlá fún Jèhófà? Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n ń múra ìgbéyàwó bíi mélòó kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní apá gúúsú Áfíríkà, ṣe làwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tó jẹ́ ara ọmọ ìyàwó lọ ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nídìí kíkọ́ bí wọ́n ṣe ń gbẹ́sẹ̀ ijó ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọ̀pọ̀ oṣù ni wọ́n fi ń lo àkókò dà nù sórí èyí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó yẹ kí Kristẹni ‘ra àkókò padà’ fún “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” àwọn nǹkan bí, iṣẹ́ ìjíhìnrere, ìdákẹ́kọ̀ọ́, àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni.—Éfésù 5:16; Fílípì 1:10.

Táa bá tibi ìwọ̀n wáìnì tí Jésù pèsè wò ó, ó jọ pé ayẹyẹ ńlá ni ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà, ó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ dájú pé kì í ṣe ayẹyẹ aláriwo, àwọn àlejò kò sì mutí yó, bó ṣe máa ń rí níbi ìgbéyàwó àwọn Júù kan. (Jòhánù 2:10) Báwo lèyí ṣe dá wa lójú? Ohun tó mú un dá wa lójú ni pé Jésù Kristi Olúwa wà níbẹ̀. Láàárín gbogbo ẹ̀dá, Jésù ni ó máa jẹ́ ẹni tó ń kíyè sára jù lọ láti ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run nípa ẹgbẹ́ búburú, èyí tó sọ pé: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri.”—Òwe 23:20.

Fún ìdí yìí, bí àwọn àfẹ́sọ́nà kan bá pinnu láti pèsè wáìnì tàbí àwọn ọtí míì nígbà ìgbéyàwó wọn, wọ́n ní láti ṣètò pé kí àwọn tó tóótun bójú tó o dáadáa. Bí wọ́n bá sì fẹ́ lo orin, kí wọ́n ṣe àṣàyàn orin tó mọ́yán lórí, kí wọ́n sì fi ẹni tó tóótun sídìí ẹ̀ láti rí i dájú pé kò pariwo jù. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àlejò gbapò àṣẹ, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé orinkórin sí i, tàbí kó wá yí ìró rẹ̀ sókè burúkú-burúkú. Bí ijó jíjó yóò bá wà, kí ó jẹ́ lọ́nà tó gbayì tó gbẹ̀yẹ, tó sì mọ níwọ̀n. Báwọn ìbátan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí àwọn Kristẹni tí kò dàgbà dénú bá bẹ̀rẹ̀ sí jó ijó aṣa tàbí ijó tó lè ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, á pọndandan kí ọkọ ìyàwó sọ pé kí wọ́n fi orin míì sí i, tàbí kó fọgbọ́n sọ pé kí wọ́n dáwọ́ ijó dúró. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ayẹyẹ ìgbéyàwó yẹn lè wá di ibi rúkèrúdò, èyí sì lè mú àwọn kan kọsẹ̀.—Róòmù 14:21.

Nítorí ewu tó sábà máa ń bá àwọn ijó àti orin aláriwo kan rìn lóde òní, àti ewu tó wà nínú kí ọtí máa ṣàn bí omi òjò, ọ̀pọ̀ Kristẹni ọkọ ìyàwó ló ti pinnu pé àwọn ò ní lo nǹkan wọ̀nyí nígbà ìgbéyàwó àwọn. Wọ́n ti bẹnu àtẹ́ lu àwọn kan nítorí èyí, àmọ́ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yẹ ní gbígbóríyìn fún, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní láti yàgò fún ohunkóhun tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Ọlọ́run. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọkọ ìyàwó kan ti ṣètò orin tó bétí mu, àti àkókò fún ijó jíjó, àti pé kí ọtí wà níwọ̀nba. Èyí ó wù ó jẹ́, ọkọ ìyàwó ló máa dáhùn fún ohun tó bá fàyè gbà níbi ìgbéyàwó rẹ̀.

Ní Áfíríkà, àwọn kan tí kò dàgbà dénú máa ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni tó gbayì, wọ́n ní kò yàtọ̀ sígbà téèyàn lọ síbi ìsìnkú. Bó ti wù kó rí, èrò wọn pọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Òótọ́ ni pé àwọn iṣẹ́ ti ara tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ lè mórí yá gágá fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n tójú bá wálẹ̀ tán, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí i nà án ní pàṣán, ó sì máa ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. (Róòmù 2:24) Ní òdìkejì pátápátá sí èyí, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀. (Gálátíà 5:22) Nígbà tí ọ̀pọ̀ tọkọtaya Kristẹni bá rántí ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, ṣe ni inú wọ́n máa ń dùn ṣìnkìn, nítorí wọ́n mọ̀ pé àṣeyẹ tó mìrìngìndìn ni, kì í ṣe “okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 6:3.

Welsh àti Elthea ṣì rántí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wúni lórí táwọn ìbátan wọn aláìgbàgbọ́ tó wá síbi ìgbéyàwó wọn sọ. Ọ̀kan sọ pé: “Àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó aláriwo tí wọ́n ń ṣe láyé ìsinyìí ti sú wa. Ó dáa gan-an láti lọ sírú ìgbéyàwó tó gbámúṣé báyẹn, tó yàtọ̀ sáwọn èyí téèyàn ti ń lọ.”

Lékè gbogbo rẹ̀, àwọn ìgbéyàwó Kristẹni tó mìrìngìndìn, tó sì gbayì, ń bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń FẸ́ ÀBÓJÚTÓ NÍBI ÀSÈ ÌGBÉYÀWÓ

• Bẹ́ẹ bá ṣètò kí ìbátan tí kì í ṣe onígbàgbọ́ sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ ẹ ti rí i dájú pé kò ní mú àṣà kan wá tó lòdì sí ti Kristẹni?

• Bẹ́ẹ bá fẹ́ lo orin, ṣé ẹ ti ṣàṣàyàn kìkì àwọn orin tó yẹ?

• Ṣé orin náà ò ní lọ sókè jù?

• Bẹ́ẹ bá fàyè gba ijó jíjó, ṣé wọ́n á jó o lọ́nà tó gbayì?

• Ṣé ọtí tẹ́ẹ fẹ́ lò kò ní pọ̀ jù?

• Ṣé àwọn tó tóótun ló máa ṣètò bí ẹ ó ṣe pín in?

• Ṣé ẹ ti ṣètò kí àsè ìgbéyàwó náà parí lásìkò tó bọ́gbọ́n mu?

• Ṣé àwọn tó tóótun máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti rí i dájú pé gbogbo nǹkan lọ létòlétò títí dé ìparí?