Èé Ṣe Tí Ìwà Ìbàjẹ́ Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
Èé Ṣe Tí Ìwà Ìbàjẹ́ Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
“Kí o má gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn tí ó ríran kedere, ó sì lè fi èrú yí ọ̀rọ̀ àwọn olódodo po.”—Ẹ́kísódù 23:8.
NÍ Ẹ̀Ẹ́DÉGBÈJÌDÍNLÓGÚN [3,500] ọdún sẹ́yìn, òfin Mósè ka gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ léèwọ̀. Àwọn òfin tó ka ìwà ìbàjẹ́ léèwọ̀ sì ti pọ̀ rẹpẹtẹ láti àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá títí di ìsinsìnyí. Síbẹ̀síbẹ̀, òfin ṣíṣe kò tíì ṣàṣeyọrí kankan láti dá ìwà ìbàjẹ́ dúró. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ló ń tọwọ́ dọ́wọ́ lójoojúmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn ló sì ń fara gbá àwọn àbájáde rẹ̀.
Ìwà ìbàjẹ́ ti gbilẹ̀ gan-an ni, ó sì ti gogò débi pé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tí ikán ń jẹlé ni ìwà ìbàjẹ́ rọra ń jẹ ìpìlẹ̀ tó gbé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ró. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, èèyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dami síwájú kó tó lè tẹlẹ̀ tútù. Ìgbà táa bá fún ẹni tó yẹ lábẹ̀tẹ́lẹ̀ tán la tó lè yege nínú ìdánwò táa bá ṣe, ìgbà náà la tó lè rí ìwé ìwakọ̀ gbà, táa lè ríṣẹ́ gbà tàbí ká jàre nílé ẹjọ́. Arnaud Montebourg, amòfin kan nílùú Paris, kédàárò pé: “Ìwà ìbàjẹ́ dà bí ohun kan tó ń ba àyíká jẹ́ jù lọ, tó sì ń ba àwọn èèyàn nínú jẹ́.”
Nínú iṣẹ́ ajé lọ̀ràn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ti wọ́pọ̀ jù lọ. Àwọn ilé iṣẹ́ kan wà tó jẹ́ pé ìdá mẹ́ta gbogbo èrè tí wọ́n bá jẹ ni wọ́n fi ń san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn lọ́gàálọ́gàá tó jẹ́ jẹgúdújẹrá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, The Economist, ti sọ, ìpín mẹ́wàá nínú bílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n dọ́là tí wọ́n ń ná lọ́dọọdún nínú owó tí wọ́n fi ń ṣòwò ohun ìjà ogun kárí ayé ni wọ́n fi ń san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn tó máa di oníbàárà wọn lọ́la. Bí ìwà ìbàjẹ́ yìí ṣe ń peléke sí i náà ni àbájáde rẹ̀ ń di wàhálà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Láàárín ẹ̀wádún tó kọjá, “lílo ẹsẹ̀” nínú ìṣòwò—ìyẹn ètò ìṣòwò tó díbàjẹ́ débi pé kìkì àwọn díẹ̀ tó mọ̀ọ̀yàn ló ń jàǹfààní rẹ̀—la gbọ́ pé ó ti ba ètò ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè kan jẹ́ pátápátá.
Ní kedere, àwọn tí ìwà ìbàjẹ́ àti bó ṣe ń ba ètò ìṣúnná owó jẹ́ ń fìyà jẹ jù lọ ni àwọn òtòṣì—ìyẹn làwọn tí wọn ò tiẹ̀ jẹun kánú débi tí wọ́n á fún ẹnikẹ́ni lábẹ̀tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Economist ti sọ láìfi bọpobọyọ̀ pé, “ìwà ìbàjẹ́ wulẹ̀ jẹ́ apá kan lára àwọn ohun tó ń fa ìnira ni.” Ǹjẹ́ irú ìnira yìí tiẹ̀ ṣeé ṣẹ́pá, àbí ìwà ìbàjẹ́ ò ṣeé yẹra fún ni? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó ń ṣokùnfà ìwà ìbàjẹ́ gan-an.
Kí Ni Àwọn Ohun Tó Ń Fa Ìwà Ìbàjẹ́?
Èé ṣe táwọn èèyàn fi yàn láti jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ dípò tí wọn ì bá fi jẹ́ olóòótọ́? Fún àwọn kan, ó lè jẹ́ híhu ìwà ìbàjẹ́ lọ̀nà tó rọrùn jù lọ fún wọn—tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé òun lọ̀nà kan ṣoṣo—tí wọ́n fi lè rí ohun tí wọ́n ń fẹ́. Nígbà mìíràn, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ ọ̀nà láti fi bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà ní wọ́ọ́rọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ tó kíyè sí i pé àwọn òṣèlú, àwọn ọlọ́pàá, àtàwọn adájọ́ ti gbójú fo ìwà ìbàjẹ́ dá tàbí pé àwọn fúnra wọn pàápàá ń hù ú níwà, ló wulẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
Bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe ń peléke sí i, àwọn èèyàn ò wá ní kà á sí nǹkan bàbàrà mọ́ títí tó fi máa di àṣà Oníwàásù 8:11.
láwùjọ. Àwọn tí owó oṣù wọn kéré gan-an wá rí i pé kò sí ọgbọ́n mìíràn táwọn lè dá ju ìyẹn lọ. Wọ́n ní láti gba rìbá kí wọ́n tó lè gbọ́ bùkátà ara wọn. Nígbà táwọn tó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí àwọn tó ń fúnni lábẹ̀tẹ́lẹ̀ torí àtirí nǹkan tí wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí gbà bá ń lọ láìjìyà, ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ló máa fẹ́ sọ pé ohun tí wọ́n ń ṣe ò dáa. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.”—Àwọn ipá lílágbára méjì tó ń jẹ́ kí ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ sí i ni: ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra. Nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan, àwọn oníwà ìbàjẹ́ kì í ka ìyà tí ìwà ìbàjẹ́ wọn ń fà fún àwọn ẹlòmíràn sí ohun tó burú, wọ́n sì máa ń dá gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láre nítorí ìjẹ tí wọ́n ń rí níbẹ̀. Bí àwọn nǹkan tí wọ́n ń rí kó jẹ níbẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i ni àwọn tó ń hu ìwà ìbàjẹ́ náà túbọ̀ ń di oníwọra sí i. Sólómọ́nì tún sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) Lóòótọ́, ìwọra lè sọni dolówó, àmọ́, kò sí bí ò ṣe ní múni gbójú fo ìwà ìbàjẹ́ àti ohun tí kò bófin mu dá.
Kókó mìíràn tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá ni ipa tí alákòóso ayé yìí tí kò ṣeé fojú rí ń kó, ìyẹn ni ẹni tí Bíbélì pè ní Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:9) Tokuntokun ni Sátánì fi ń gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tóbi jù lọ nínú àkọsílẹ̀ ni èyí tí Sátánì fi lọ Kristi. ‘Gbogbo ìjọba ayé ni èmi yóò fi fún ọ bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’—Mátíù 4:8, 9.
Àmọ́ ṣá o, Jésù kì í ṣe oníwà ìbàjẹ́, ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti má ṣe hùwà ìbàjẹ́. Ṣé àwọn ẹ̀kọ́ Kristi lè jẹ́ irin iṣẹ́ tó gbéṣẹ́ láti fi ṣẹ́pá ìwà ìbàjẹ́ lónìí? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò fọ́ ìbéèrè yìí sí wẹ́wẹ́.