Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Èmi Yóò Rìn Yí Ká Pẹpẹ Rẹ, Jèhófà”

“Èmi Yóò Rìn Yí Ká Pẹpẹ Rẹ, Jèhófà”

“Èmi Yóò Rìn Yí Ká Pẹpẹ Rẹ, Jèhófà”

“ÈMI yóò wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, èmi yóò rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà.” (Sáàmù 26:6) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Dáfídì Ọba ìgbàanì fi kéde ìfọkànsìn rẹ̀ sí Jèhófà. Àmọ́ o, kí ló fà á tí yóò fi “rìn yí ká” pẹpẹ Jèhófà, lọ́nà wo sì ni?

Dáfídì gbà pé ibùdó ìjọsìn Jèhófà ni àgọ́ ìjọsìn tí a fi bàbà bo pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀, èyí tó wà ní Gíbéónì, ní ìhà àríwá Jerúsálẹ́mù ní àkókò ìṣàkóso rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 3:4) Nǹkan bí mítà méjì níbùú lóròó péré ni pẹpẹ náà, ó kéré gan-an sí arabarìbì pẹpẹ tí wọn óò kọ́ sí àgbàlá tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. a Síbẹ̀, ńṣe ni inú Dáfídì máa ń dùn ṣìnkìn sí àgọ́ ìjọsìn náà àti pẹpẹ rẹ̀, tí ó jẹ́ ibùdó ìjọsìn mímọ́ gaara ní Ísírẹ́lì.—Sáàmù 26:8.

Àwọn ọrẹ ẹbọ sísun, àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n máa ń rú lórí pẹpẹ náà, Ọjọ́ Ètùtù tó ń wáyé lọ́dọọdún sì jẹ́ àkókò rírú àwọn ẹbọ nítorí orílẹ̀-èdè náà. Pẹpẹ náà àti àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú lórí rẹ̀ ní ìtumọ̀ fún àwọn Kristẹni lónìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé pẹpẹ náà túmọ̀ sí ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Ó tipasẹ̀ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba ẹbọ kan tí ó ṣe rẹ́gí fún ìràpadà ìran ènìyàn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ ‘ìfẹ́’ tí a sọ náà, a ti sọ wá di mímọ́ nípasẹ̀ ìfirúbọ ara Jésù Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.”—Hébérù 10:5-10.

Nígbà tí àwọn àlùfáà bá fẹ́ rúbọ lórí pẹpẹ náà, àṣà wọn ni pé kí wọ́n fi omi wẹ ọwọ́ wọn láti wẹ ara wọn mọ́. Abájọ nígbà náà tí Dáfídì Ọba fi wẹ ọwọ́ rẹ̀ “ní àìlẹ́ṣẹ̀” kó tó di pé ó ‘ń rìn yí ká pẹpẹ náà.’ Ó gbégbèésẹ̀ “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà àti pẹ̀lú ìdúróṣánṣán.” (1 Àwọn Ọba 9:4) Ká ní kò wẹ ọwọ́ rẹ̀ lọ́nà yìí ni, ìjọsìn rẹ̀—‘rírìn tó ń rìn yí ká pẹpẹ náà’—ì bá máà ní ìtẹ́wọ́gbà. Àmọ́ ṣá o, Dáfídì kì í ṣe ọmọ Léfì, kò sì láǹfààní àtiṣe iṣẹ́ àlùfáà lórí pẹpẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba ni, síbẹ̀ a ò gbà á láyè láti wọ inú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn pàápàá. Síbẹ̀síbẹ̀, níwọ̀n bí òun ti jẹ́ ọmọ Ìsírẹ́lì olóòótọ́, ó ṣègbọràn sí òfin Mósè, ó sì ń mú àwọn ọrẹ rẹ̀ wá fún ìrúbọ lórí pẹpẹ déédéé. Ó rìn yí pẹpẹ náà ká ní ti pé ìjọsìn mímọ́ gaara ló gbé gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ kà.

Ǹjẹ́ àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwa náà lè wẹ ọwọ́ wa ní àìlẹ́ṣẹ̀, kí a sì máa rìn yí ká pẹpẹ Ọlọ́run, tí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù, tí a jẹ́ ‘ọlọ́wọ́ mímọ́ àti ẹni tí ó mọ́ ní ọkàn-àyà,’ tí a sì ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà.—Sáàmù 24:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nǹkan bíi mítà mẹ́sàn-án níbùú lóròó ni pẹpẹ yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pẹpẹ náà dúró fún ìfẹ́ Jèhófà, èyí tí ó tipasẹ̀ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba ẹbọ kan tí ó ṣe rẹ́gí fún ìràpadà ìran ènìyàn