Ìgbésí Ayé Ìdílé Aláyọ̀ Ń Jẹ́ Káwọn Ẹlòmíì Sún Mọ́ Ọlọ́run
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìgbésí Ayé Ìdílé Aláyọ̀ Ń Jẹ́ Káwọn Ẹlòmíì Sún Mọ́ Ọlọ́run
JÈHÓFÀ fi ọgbọ́n ńlá àti ìfòyemọ̀ jíǹkí Jósẹ́fù. (Ìṣe 7:10) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìjìnlẹ̀ òye Jósẹ́fù “dára ní ojú Fáráò àti ní ojú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 41:37.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lọ̀rọ̀ rí lóde òní, Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìfòyemọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ látinú Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ yìí ń so èso rere bí wọ́n ti ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táa gbé ka Bíbélì. Ìwà rere wọn máa ‘ń dára lójú àwọn tó bá kíyè sí i,’ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e láti Zimbabwe ti fi hàn.
• Obìnrin kan wà tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé àdúgbò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí, síbẹ̀ ìwà wọn wù ú, pàápàá jù lọ ìṣesí wọn nínú ilé. Ó ṣàkíyèsí pé ìbágbé tọkọtaya náà wọ̀ gan-an àti pé àwọn ọmọ wọn jẹ́ elétí ọmọ. Ó tún jọ ọ́ lójú gan-an pé ọkọ náà nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ púpọ̀.
Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ láwọn ibì kan ní Áfíríkà ni pé bí ọkọ bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ṣe ni aya ọ̀hún lọ ṣoògùn láti fi “fà á lójú mọ́ra.” Ìyẹn ló jẹ́ kí obìnrin yìí tọ aya Ẹlẹ́rìí náà lọ, tó sì bi í pé: “Jọ̀ọ́, ṣé o lè fún mi ní oògùn ìfẹ́ tóo fún ọkọ rẹ jẹ, kí ọkọ tèmi náà lè nífẹ̀ẹ́ mi bí ọkọ tìrẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ?” Ẹlẹ́rìí náà dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni o, màá mú un wá fún ẹ lọ́sàn-án ọ̀la.”
Nígbà tó dọjọ́ kejì, arábìnrin yẹn mú “oògùn” náà lọ bá aládùúgbò rẹ̀ yìí. Kí ni “oògùn” ọ̀hún? Bíbélì ni, pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Lẹ́yìn jíjíròrò látinú ìwé Ìmọ̀ lórí kókó náà “Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá fún Ọlọ́run Ró,” ó sọ fún obìnrin náà pé: “‘Oògùn’ témi àtọkọ mi fi ‘ń fa ojú ara wa mọ́ra’ nìyí, ìdí sì nìyẹn táa fi nífẹ̀ẹ́ ara wa tó báyẹn.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, obìnrin náà sì tẹ̀ síwájú kíákíá dé ipò fífàmì ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi.
• Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì táa yàn sí ìjọ kékeré kan nítòsí ààlà ìlà oòrùn mọ́ àríwá Zimbabwe àti Mòsáńbíìkì kò jáde iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko. Kí ló dé? Nítorí pé àwọn èèyàn ń wọlé wá gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn ni. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà náà ṣàlàyé bó ṣe jẹ́, ó ní: “A máa ń rin kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lọ bá olùfìfẹ́hàn kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ibẹ̀ ṣòroó dé. A ní láti rìn nínú ẹrẹ̀, a tún ní láti sọdá àwọn odò tó kún dẹ́nu, tó mù wá dé ọrùn. Ṣe la máa ń kó aṣọ àti bàtà wa lérí gba inú odò kọjá, kí a tó padà wá múra nígbà táa bá sọdá tán.
“Ìtara wa jẹ́ ìwúrí ńláǹlà fáwọn aládùúgbò olùfìfẹ́hàn náà. Ara àwọn tó ṣàkíyèsí èyí ni aṣáájú ètò ẹ̀sìn kan ládùúgbò náà. Ó sọ fáwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé: ‘Ṣé ẹ̀yin náà ò fẹ́ jẹ́ onítara bíi tàwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyẹn ni?’ Ní ọjọ́ kejì, ọ̀pọ̀ lára ọmọ ìjọ rẹ̀ rọ́ wá sílé wa láti wá mọ̀dí táa fi ń forí-fọrùn ṣe. Kò tán síbẹ̀ o, títí di ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ńṣe làlejò ń wọ́ nílé wa, débi pé a ò ráyè gbọ́ oúnjẹ táa fẹ́ jẹ!”
Aṣáájú ẹ̀sìn náà alára wà lára àwọn tó wá sílé àwọn aṣáájú ọ̀nà náà láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ọ̀hún. Ẹ fojú inú wo bí inú àwọn aṣáájú ọ̀nà náà ti dùn tó nígbà tó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!