Di Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Mú Gírígírí
Di Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Mú Gírígírí
“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—ÒWE 3:5, 6.
1. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, báwo ni ìmọ̀ ènìyàn ti pọ̀ tó láyé táa wà yìí?
NÍ LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ìwé ìròyìn ló ń jáde lójoojúmọ́ jákèjádò ayé. Lọ́dọọdún, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ìwé tuntun làwọn èèyàn ń tẹ̀ jáde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan. Àwọn kan sì fojú bù ú pé, nígbà tó di March 1998, nǹkan bí ọ̀rìnlélúgba ó dín márùn-ún [275] mílíọ̀nù ibùdó ìsọfúnni làwọn èèyàn ti ṣí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Iye yìí fi hàn pé ogún mílíọ̀nù ibùdó ìsọfúnni làwọn èèyàn ń ṣí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lóṣooṣù. Níbi tọ́mọ aráyé ti rìn jìnnà dé báyìí, ṣàṣà ni ìsọfúnni téèyàn lè máa wá tí kò ní rí. Èyí láǹfààní nínú lóòótọ́, àmọ́ o, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni yìí tún ní àkóbá tó ń ṣe.
2. Kí làwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ látinú níní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni lọ́wọ́?
2 Àwọn èèyàn kan ti wà báyìí, tó jẹ́ pé wọn ò níṣẹ́ méjì ju pé kí wọ́n máa wá ìsọfúnni tuntun kiri lọ, wọ́n ti di elétí ọfẹ tó ń fimú fínlẹ̀ kiri, tí wọ́n pa iṣẹ́ gidi tó yẹ ní ṣíṣe tì. Àwọn míì, tó jẹ́ pé tá-tà-tá ni wọ́n mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ kan téèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ dunjú, ti ka ara wọn sí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Pẹ̀lú tá-tà-tá tí wọ́n mọ̀ yìí, wọ́n ń ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe kókó, tó lè kó bá àwọn fúnra wọn tàbí àwọn ẹlòmíì. Kò mọ síbẹ̀ o, àìmọye ìgbà ló tún máa ń jẹ́ pé irọ́ funfun báláú, tàbí irọ́ díẹ̀ òótọ́ díẹ̀ ni ìsọfúnni tí wọ́n kó jọ. Bó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, kì í sábàá sí béèyàn ṣe lè mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ irú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni bẹ́ẹ̀.
3. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì ṣe nípa lílépa ọgbọ́n orí ènìyàn?
3 Ó ti pẹ́ tọ́mọ aráyé ti nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ojú-mìí-tó. Tipẹ́tipẹ́, láti ìgbà ayé Sólómọ́nì Ọba ni ìkìlọ̀ ti ń dún pé ewu ń bẹ nínú fífi àkókò gidi ṣòfò nídìí wíwá ìsọfúnni tí kò wúlò tàbí ìsọfúnni tó tiẹ̀ lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́ kiri. Ọba náà sọ pé: “Gba ìkìlọ̀: Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.” (Oníwàásù 12:12) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’ Nítorí ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:20, 21) Láìsí àní-àní, àwọn Kristẹni òde òní gbọ́dọ̀ yàgò fáwọn èròǹgbà tó lè kó wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́.
4. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà táa lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀?
4 Ó tún yẹ káwọn èèyàn Jèhófà kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 3:5, 6, tó kà pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà wé mọ́ kíkọ èròǹgbà èyíkéyìí tó bá ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yálà ó wá látinú ìrònú tiwa tàbí látọ̀dọ̀ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Kí a lè dáàbò bo ipò tẹ̀mí wa, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ agbára ìwòye wa, ká lè dá ìsọfúnni tó lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́ mọ̀, ká sì yàgò fún un. (Hébérù 5:14) Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára orísun irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀.
Ayé Kan Tó Wà Lábẹ́ Agbára Sátánì
5. Kí ni orísun àwọn èròǹgbà burúkú, ta ló sì wà nídìí ẹ̀?
5 Àwọn àjọ ayé tí kò tan mọ́ ẹ̀sìn ni orísun àwọn èròǹgbà burúkú tó pọ̀ lọ jàra. (1 Kọ́ríńtì 3:19) Jésù Kristi gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 17:15) Ẹ̀bẹ̀ Jésù pé kí Ọlọ́run máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun kúrò lọ́wọ́ “ẹni burúkú náà” fi hàn pé ó mọ itú tí Sátánì ń pa nínú ayé. Jíjẹ́ táa jẹ́ Kristẹni kò sì túmọ̀ sí pé a ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo agbára burúkú táyé yìí ń sà. Jòhánù kọ̀wé pé: “A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Àgàgà ní apá ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ohun táa lè retí ni pé kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ fi ìsọfúnni burúkú kún inú ayé.
6. Báwo ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo eré ìnàjú ṣe lè sọ wá dẹni tó gbàgbàkugbà?
6 A tún lè retí pé káwọn kan lára ìsọfúnni burúkú wọ̀nyí dà bí ìsọfúnni tó dáa. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo eré ìnàjú, gẹ́gẹ́ bí a ti ń rí i nínú àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, sinimá, orin, àti ìwé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ńṣe làwọn eré ìnàjú kan túbọ̀ ń gbé ìwàkíwà lárugẹ, àwọn bí ìṣekúṣe, ìwà ipá, àti ìjoògùnyó. Nígbà táwọn òǹwòran bá kọ́kọ́ rí eré ìnàjú kan tí ìwà ìbàjẹ́ inú rẹ̀ gogò, ṣe ni ara wọn máa ń bù máṣọ. Àmọ́ tó bá wá dohun tí wọ́n ń rí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, wọn ò ní kà á sí nǹkan bàbàrà mọ́. Àmọ́ láyéláyé, a ò gbọ́dọ̀ ka eré ìnàjú tó ń gbé èròǹgbà burúkú lárugẹ sóhun táa ń rí yọ̀, tàbí ká kà á sí ohun tí kò lè pani lára.—Sáàmù 119:37.
7. Irú ọgbọ́n ènìyàn wo ló lè mú ká máa ṣiyèméjì nípa Bíbélì?
7 Ẹ jẹ́ ká sún síwájú kẹ́rẹ́, ká ṣàyẹ̀wò orísun míì táwọn ìsọfúnni burúkú ti ń wá—èyíinì ni òbìtìbitì èròǹgbà tó wà nínú ìwé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí ń jiyàn pé ọ̀rọ̀ Bíbélì kì í ṣòótọ́. (Fi wé Jákọ́bù 3:15.) Lemọ́lemọ́ làwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé tó gbajúmọ̀ máa ń gbé ọ̀rọ̀ wọn jáde, èyí sì lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa Bíbélì. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń dìídì fi àwọn ìméfò tí kò lórí tí kò nídìí jin agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́sẹ̀. Irú ewu yẹn wà nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, gẹ́gẹ́ bó ti hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó kà pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.
Àwọn Ọ̀tá Òtítọ́
8, 9. Báwo ni ìpẹ̀yìndà ṣe ń ṣẹlẹ̀ lónìí?
8 Àwọn apẹ̀yìndà tún lè jin ipò tẹ̀mí wa lẹ́sẹ̀ o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpẹ̀yìndà yóò dìde láàárín àwọn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni. (Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:3) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìmúṣẹ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, nígbà tí ìpẹ̀yìndà ńlá kan dìde tó wá bí Kirisẹ́ńdọ̀mù. Òótọ́ ni pé lónìí, ìpẹ̀yìndà ńlá kankan ò sí láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, àwọn díẹ̀ ti kúrò lágbo wa, àwọn kan lára wọn sì ti pinnu pé àforí-àfọrùn àwọn gbọ́dọ̀ ba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́ ṣáá ni, nípa gbígbékèé yíde àti nípa yíyí irọ́ mọ́ òótọ́. Àwọn díẹ̀ kan tiẹ̀ ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn àwùjọ míì láti pawọ́ pọ̀ kọjúùjà sí ìjọsìn mímọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń gbè sẹ́yìn Sátànì, apẹ̀yìndà àkọ́kọ́ pàá.
9 Àwọn apẹ̀yìndà kan ti túbọ̀ múra sí lílo onírúurú ọ̀nà ìtàtaré ìsọfúnni fáyé gbọ́, títí kan Íńtánẹ́ẹ̀tì, láti fi tan ìsọfúnni èké kálẹ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nígbà tí àwọn olóòótọ́ ọkàn bá ń ṣe ìwádìí nípa àwọn ohun táa gbà gbọ́, wọ́n lè ṣàdédé já lu ìgbékèéyíde apẹ̀yìndà. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan pàápàá ti kan irú ìsọfúnni burúkú yìí kuu. Ìyẹn nìkan kọ́ o, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn apẹ̀yìndà máa ń kópa nínú àwọn ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí rédíò. Kí ló bọ́gbọ́n mu láti ṣe nínú irú ipò yìí?
10. Kí lohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe nípa ìgbékèéyíde apẹ̀yìndà?
10 Àpọ́sítélì Jòhánù là á mọ́lẹ̀ pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ gba àwọn apẹ̀yìndà sínú ilé wọn. Ó kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i. Nítorí ẹni tí ó bá kí i jẹ́ alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.” (2 Jòhánù 10, 11) Yíyàgò pátápátá fáwọn alátakò wọ̀nyí yóò dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìrònú wọn tó ti díbàjẹ́. Ewu gidi wà nínú jíjẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ apẹ̀yìndà máa gba àwọn ọ̀nà ìsọfúnni òde òní dé ọ̀dọ̀ wa, nítorí kò yàtọ̀ sígbà tí a gba apẹ̀yìndà náà fúnra rẹ̀ sínú ilé wa. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ojú-mìí-tó sún wa kàgbákò o!—Òwe 22:3.
Nínú Ìjọ
11, 12. (a) Kí ni orísun kan tí àwọn èròǹgbà burúkú ti ń wá nínú ìjọ ọ̀rúndún kìíní? (b) Báwo làwọn Kristẹni kan ṣe kùnà láti fọwọ́ dan-indan-in mú àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run?
11 Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò orísun míì táwọn èròǹgbà burúkú ti ń wá. Ète àtikọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èké lè máà wá sọ́kàn Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, àmọ́ ó lè ti di àṣà rẹ̀ láti máa sọ̀rọ̀ láìronú. (Òwe 12:18) Nítorí jíjẹ́ táa jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń fi ahọ́n wa dẹ́ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Òwe 10:19; Jákọ́bù 3:8) Ó jọ pé nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn kan wà nínú ìjọ tí kò kó ahọ́n wọn níjàánu, tí wọ́n sì ń jìjà ọ̀rọ̀. (1 Tímótì 2:8) Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé èrò tiwọn ti jọ wọ́n lójú jù, èyí sì sún wọn dédìí fífọwọ́ pa idà àṣẹ Pọ́ọ̀lù lójú. (2 Kọ́ríńtì 10:10-12) Àwọn nǹkan tí kò tó nǹkan ni irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ máa ń sọ dìjà.
12 Nígbà míì, àwọn èdè àìyédè wọ̀nyí lè wá di “awuyewuye lílenípá lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan,” tó wá dá wàhálà ńlá sílẹ̀ nínú ìjọ. (1 Tímótì 6:5; Gálátíà 5:15) Àwọn adárúgúdù-sílẹ̀ wọ̀nyí ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí, nígbà tó kọ̀wé pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń fi ẹ̀kọ́ mìíràn kọ́ni, tí kò sì fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera, tí ó jẹ́ ti Olúwa wa Jésù Kristi, tàbí ẹ̀kọ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run, ó ń wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, láìlóye ohunkóhun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olókùnrùn ní èrò orí lórí bíbéèrè ìbéèrè àti fífa ọ̀rọ̀. Láti inú nǹkan wọ̀nyí ni ìlara ti ń jáde wá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, ọ̀rọ̀ èébú, ìfura burúkú.”—1 Tímótì 6:3, 4.
13. Kí ni ìṣarasíhùwà ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní?
13 Inú wa dùn pé nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni ló jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ọwọ́ wọ́n dí lẹ́nu iṣẹ́ bíbójútó “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn,” wọ́n sì pa ara wọn mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé,” láìfi àkókò ṣòfò nídìí ìjiyàn òfìfo. (Jákọ́bù 1:27) Wọ́n yẹra fún “ẹgbẹ́ búburú” nínú ìjọ Kristẹni pàápàá, láti lè dáàbò bo ipò tẹ̀mí wọn.—1 Kọ́ríńtì 15:33; 2 Tímótì 2:20, 21.
14. Bá ò bá ṣọ́ra, báwo ni ìfèròwérò lásán ṣe lè wá di ìjiyàn tó ń dá họ́ùhọ́ù sílẹ̀?
14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ipò táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìpínrọ̀ kọkànlá kò wọ́pọ̀ nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní. Ṣùgbọ́n, ó yẹ ká gbà pé irú ìjiyàn òfìfo bẹ́ẹ̀ lè wáyé dáadáa. A ò kúkú sọ pé ó burú láti jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tàbí láti fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan kan tí a kò tíì ṣí payá nísinsìnyí nípa ayé tuntun tí a ṣèlérí. Kò sì sóhun tó burú nínú fífèròwérò nípa àwọn ọ̀ràn ara ẹni, irú bí ọ̀ràn aṣọ àti ìmúra tàbí irú eré ìnàjú téèyàn fẹ́. Àmọ́ o, táa bá wá sọ pé ohun táa sọ labẹ́ gé, táa sì fárígá nígbà táwọn èèyàn ò bá fara mọ́ èrò tiwa, àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké wọ̀nyí lè pín ìjọ níyà. Nǹkan tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kékeré, ọ̀rọ̀ eré la pè é níbẹ̀rẹ̀ lè wá dá họ́ùhọ́ù sílẹ̀.
Títọ́jú Ohun Táa Fi Síkàáwọ́ Wa
15. Àkóbá wo ni “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” lè ṣe fún wa nípa tẹ̀mí, kí sì ni ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ fún wa?
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àsọjáde onímìísí sọ ní pàtó pé ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1) Ọ̀rọ̀ la gbọ́ yìí o, àwọn èròǹgbà burúkú lè ṣe àkóbá gidi. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi pàrọwà fún Tímótì, ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà, pé: “Ìwọ Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’ Nítorí ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 6:20, 21.
16, 17. Kí ni Ọlọ́run fi síkàáwọ́ wa, báwo ló sì ṣe yẹ ká dáàbò bò ó?
16 Báwo ni ìkìlọ̀ onífẹ̀ẹ́ yìí ṣe lè ṣe wá láǹfààní lóde òní? A fi nǹkan kan síkàáwọ́ Tímótì—nǹkan iyebíye tí ó ní láti tọ́jú, kí ó sì dáàbò bò ni. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù. Ohun ìtọ́júpamọ́ àtàtà yìí ni kí o ṣọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú wa.” (2 Tímótì 1:13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni, lára ohun tó wà níkàáwọ́ Tímótì ni “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” “ẹ̀kọ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run.” (1 Tímótì 6:3) Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn Kristẹni lónìí ti gbára dì láti dáàbò bo ìgbàgbọ́ wọn àti àpapọ̀ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà níkàáwọ́ wọn.
17 Títọ́jú ohun tó wà níkàáwọ́ wọn yìí wé mọ́ àwọn nǹkan bíi sísọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire dàṣà àti àdúrà gbígbà láìdábọ̀, wọn ò sì ní gbàgbé ṣíṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10; Róòmù 12:11-17) Pọ́ọ̀lù tún gbà wá níyànjú síwájú sí i, pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù. Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́, tí ìwọ sì ṣe ìpolongo àtàtà ní gbangba níwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí.” (1 Tímótì 6:11, 12) Lílò tí Pọ́ọ̀lù lo àwọn gbólóhùn bíi “ja ìjà àtàtà” àti “dì . . . mú gírígírí,” mú un ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ fi taratara àti tinútinú gbéjà ko àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí.
Ìfòyemọ̀ Ṣe Kókó
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni nínú ojú táa fi ń wo ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ayé?
18 Àmọ́, nínú ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, ìfòyemọ̀ ṣe kókó o. (Òwe 2:11; Fílípì 1:9) Fún àpẹẹrẹ, kò ní bọ́gbọ́n mu láti ṣàìfọkàn tán gbogbo ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ayé. (Fílípì 4:5; Jákọ́bù 3:17) Kì í ṣe gbogbo èròǹgbà ẹ̀dá ló tako Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù tọ́ka sí i pé ó yẹ káwọn tó bá ń ṣàìsàn lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn tó tóótun—bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tayé ni iṣẹ́ ìṣègùn. (Lúùkù 5:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìṣègùn ò fi bẹ́ẹ̀ múná dóko nígbà ayé Jésù, táa bá fi wé tòde òní, síbẹ̀ Jésù gbà pé kò ṣàìsí àǹfààní nínú ìrànlọ́wọ́ oníṣègùn. Àwọn Kristẹni lóde òní wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ayé, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń yẹra fún èyíkéyìí tó lè ṣàkóbá fún wọn nípa tẹ̀mí.
19, 20. (a) Báwo làwọn alàgbà ṣe ń fi ìfòyemọ̀ gbégbèésẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó sọ ọ̀rọ̀ àìnírònú? (b) Ìgbésẹ̀ wo ni ìjọ máa ń gbé lòdì sáwọn tó bá ń bá a lọ láti máa gbé ẹ̀kọ́ èké lárugẹ?
19 Ó tún ṣe pàtàkì káwọn alàgbà lo ìfòyemọ̀ nígbà tí wọ́n bá ké sí wọn láti wá ṣèrànwọ́ fáwọn tó sọ ọ̀rọ̀ àìnírònú. (2 Tímótì 2:7) Nígbà míì, àwọn ará ìjọ lè kó wọnú awuyewuye lórí ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan, tàbí kí wọ́n máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Láti pa ìṣọ̀kan ìjọ mọ́, ó yẹ káwọn alàgbà tètè wá nǹkan ṣe sírú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún yẹ kí wọ́n yẹra fún níní in lọ́kàn pé èrò burúkú ló wà lọ́kàn àwọn ará, kí wọ́n má sì tìtorí ìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí fojú apẹ̀yìndà wò wọ́n láìdúró gbẹ́jọ́.
20 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé irú ẹ̀mí tó yẹ ká fi ṣèrànwọ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” (Gálátíà 6:1) Nígbà tí Júúdà ń sọ̀rọ̀ ní pàtó nípa àwọn Kristẹni tí iyèméjì ń jà gùdù lọ́kàn wọn, ó kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn fún àwọn kan tí wọ́n ní iyèméjì; ẹ gbà wọ́n là nípa jíjá wọn gbà kúrò nínú iná.” (Júúdà 22, 23) Ṣùgbọ́n o, bí ẹnì kan bá wá rin kinkin mọ́ gbígbé ẹ̀kọ́ èké lárugẹ lẹ́yìn táwọn alàgbà ti kìlọ̀ fún un léraléra, dandan ni káwọn alàgbà gbé ìgbésẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ.—1 Tímótì 1:20; Títù 3:10, 11.
Fífi Àwọn Ohun Tó Yẹ fún Ìyìn Kún Èrò Inú Wa
21, 22. Ó yẹ ká ṣe àṣàyàn nípa kí ni, kí ló sì yẹ ká fi kún èrò inú wa?
21 Ìjọ Kristẹni kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú tí ń “tàn kálẹ̀ bí egbò kíkẹ̀.” (2 Tímótì 2:16, 17; Títù 3:9) Wọ́n gbọ́dọ̀ kórìíra irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ì báà jẹ́ “ọgbọ́n” ayé tí ń ṣini lọ́nà, ì báà jẹ́ ìgbékèéyíde àwọn apẹ̀yìndà, tàbí ọ̀rọ̀ aláìnírònú tẹ́nì kan sọ nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ tó mọ́yán lórí láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tuntun lè ṣeni láǹfààní, síbẹ̀, wíwá fìn-ín ìdí kókò lè gbé wa dédìí àwọn èròǹgbà tó lè ṣàkóbá fún wa. Kì í kúkú ṣe pé a ò mọ àwọn ète ọkàn Sátánì. (2 Kọ́ríńtì 2:11) A mọ̀ pé ó ń forí-fọrùn ṣe láti lè pín ọkàn wa níyà kí a bàa lè dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run.
22 Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ àtàtà, ẹ jẹ́ ká di ẹ̀kọ́ Ọlọ́run mú gírígírí. (1 Tímótì 4:6) Ẹ jẹ́ ká fi ọgbọ́n lo àkókò wa nípa ṣíṣe àṣàyàn irú ìsọfúnni táa ń gbà sínú ọkàn wa. Báa bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á ṣòro kí ìgbékèéyíde Sátánì tó lè gbò wá. Àní, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní ríronú nípa “ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn.” Báa bá ń fi irú nǹkan wọ̀nyí kún èrò inú àti ọkàn-àyà wa, Ọlọ́run àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú wa.—Fílípì 4:8, 9.
Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́?
• Báwo ni ọgbọ́n ayé ṣe lè ṣàkóbá fún ipò tẹ̀mí wa?
• Kí la lè ṣe láti dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ ìsọfúnni burúkú àwọn apẹ̀yìndà?
• Irú ọ̀rọ̀ wo ló yẹ ká yàgò fún nínú ìjọ?
• Báwo la ṣe ń fi hàn pé a wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì gẹ́gẹ́ bí Kristẹni nínú ayé tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni wà yìí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé tó gbajúmọ̀ ló lòdì sáwọn ìlànà Kristẹni táa ń tẹ̀ lé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni lè fèròwérò láìfi òòté lé ohun tí wọ́n bá sọ