Fífi Idà Ẹ̀mí Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́
Fífi Idà Ẹ̀mí Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́
“Ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:24.
NÍGBÀ tí ògo Ilẹ̀ Ọba Róòmù ń tàn, òun ni ìṣàkóso rẹ̀ ga lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn tó tíì ṣàkóso lágbàáyé. Ètò òfin Róòmù gbéṣẹ́ gan-an ni tó fi jẹ́ pé òun ṣì ni ìpìlẹ̀ tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gbé àkójọ òfin tiwọn kà títí di òní olónìí. Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú gbogbo àṣeyọrí tí Róòmù ṣe, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọ ogun tó ní ò lè ṣẹ́gun ọ̀tá tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ náà: ìwà ìbàjẹ́. Níkẹyìn, ìwà ìbàjẹ́ ló mú kí ìṣubú Róòmù yá kánkán.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jìyà lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ Róòmù tí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbà ti wọ̀ lẹ́wù. Ó dájú pé Fẹ́líìsì, gómìnà Róòmù tó fọ̀rọ̀ wá Pọ́ọ̀lù lẹ́nu wò mọ̀ pé kò ṣẹ̀ rárá. Síbẹ̀ Fẹ́líìsì, ọ̀kan lára àwọn gómìnà tí ìwà ìbàjẹ́ wọ̀ lẹ́wù jù lọ nígbà ayé rẹ̀, fi ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù falẹ̀, ó ń retí pé kí Pọ́ọ̀lù wá fún òun lówó kí wọ́n lè dá a nídè.—Ìṣe 24:22-26.
Kàkà tí Pọ́ọ̀lù ì bá fi fún Fẹ́líìsì ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ńṣe ló bá a sọ̀rọ̀ nípa “òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu” láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀. Fẹ́líìsì ò yí ìwà rẹ̀ padà, Pọ́ọ̀lù sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n dípò tí ì bá fi gbìyànjú àtilo àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti fi yí ohun tó bófin mu padà. Ó ń wàásù ìhìn òtítọ́ àti àìlábòsí, ó sì gbé ìgbésí ayé tó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Ó kọ̀wé sí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Irú ìdúró tó mú yẹn yàtọ̀ pátápátá sí ìwà àwọn èèyàn lákòókò náà. Pallas tó jẹ́ arákùnrin Fẹ́líìsì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lówó jù lọ láyé ìgbàanì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ṣírò sí mílíọ̀nù dọ́là lọ́nà márùnlélógójì ló tipasẹ̀ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà kó jọ. Àmọ́, gbogbo ọlà tó ní yẹn ò tó nǹkan kan táa bá fi wé àìmọye bílíọ̀nù dọ́là táwọn alákòóso tó ti kówó jẹ ní ọ̀rúndún ogún yìí ń kó pa mọ́ sínú àwọn àkáǹtì tó fara sin ní báńkì. Dájúdájú, kìkì òpè ènìyàn nìkan ló lè gbà pé àwọn ìjọba òde òní ti ṣẹ́gun ìwà ìbàjẹ́.
Níwọ̀n bí ìwà ìbàjẹ́ ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ fún àkókò tó gùn tó bẹ́ẹ̀, ṣé ó wá yẹ ká kàn gbà pé ara àbùdá ènìyàn gan-an ló wà? Àbí ohun kan wà táa lè ṣe láti kápá ìwà ìbàjẹ́?
Báwo La Ṣe Lè Kápá Ìwà Ìbàjẹ́?
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó ṣe kedere jù lọ láti kápá ìwà ìbàjẹ́ ni mímọ̀ pé ìwà ìbàjẹ́ ń ba nǹkan jẹ́, ó sì lòdì, nítorí pé àwọn apanilẹ́kún-jayé nìkan ló ń rí jẹ nínú rẹ̀. Kò sí iyèméjì pé a ti ṣe àwọn àtúnṣe kan lórí ọ̀ràn náà. James Foley, igbá kejì aṣojú ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Gbogbo wa la mọ̀ pé ohun tí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń náni kò kéré. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dojú ìjọba tó dára dé, ó máa ń pa ètò ìṣúnná owó àti ìtẹ̀síwájú lára, ó máa ń ba òwò jẹ́, gbogbo aráàlú kárí ayé ló sì ń sọ di aláìníláárí.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gba ohun tó sọ yìí. Ní December 17, 1997, àwọn orílẹ̀-èdè pàtàkì pàtàkì mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló fọwọ́ sí “àdéhùn lórí ọ̀ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,” èyí tí wọ́n ṣe láti “ní ipa tó lágbára lórí ogun tí wọ́n ń gbé ti ìwà ìbàjẹ́ kárí ayé.” Àdéhùn náà “sọ ọ́ di ìwà ọ̀daràn láti fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọni, láti ṣèlérí rẹ̀ tàbí láti fi fún òṣìṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè kan kí a lè ní àǹfààní láti ṣòwò káàkiri ayé tàbí kí àǹfààní tí a ní láti ṣòwò má bàa bọ́ lọ́wọ́ ẹni.”
Àmọ́ ṣá o, rìbá táwọn èèyàn ń san kí wọ́n lè ríṣẹ́ gbà láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wulẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba kékeré lára ìwà ìbàjẹ́ ni. Ká tó lè mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò jákèjádò ayé, ìgbésẹ̀ kejì wà tí a ní láti gbé, èyí ṣòro gan-an ju ti àkọ́kọ́ lọ: ìyẹn ni yíyí ọkàn-àyà padà, tàbí ká kúkú sọ pé, yíyí ọ̀pọ̀ ọkàn-àyà padà. Àwọn èèyàn níbi gbogbo gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìwà ìbàjẹ́. Ìgbà yẹn nìkan ni ìwà fífi èrú kó ọrọ̀ jọ tó lè kásẹ̀ nílẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni ìwé ìròyìn Newsweek fi sọ pé àwọn kan lérò pé ó yẹ kí àwọn ìjọba “fún gbogbo gbòò níṣìírí láti ní ìwà mímọ́.” Bákan náà ni Ẹgbẹ́ Afòtítọ́hùwà Kárí Ayé, ìyẹn ẹgbẹ́ kan tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́, ṣe dámọ̀ràn pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ máa “gbin ‘èso ìwà títọ́’” sí ibi iṣẹ́.
Gbígbé ogun ti ìwà ìbàjẹ́ jẹ́ ọ̀ràn ìwà híhù tó jẹ́ pé kì í ṣe kìkì òfin ṣíṣe tàbí lílo “idà” ìfìyà jẹni lábẹ́ òfin nìkan la ó fi ṣẹ́gun rẹ̀. (Róòmù 13:4, 5) A gbọ́dọ̀ gbin èso ìwà funfun àti ti ìwà títọ́ sí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn. Ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣe èyí ni pé ká lo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “idà ẹ̀mí,” ìyẹn ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Éfésù 6:17.
Bíbélì Kórìíra Ìwà Ìbàjẹ́
Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀ láti fàyè gba ìwà ìbàjẹ́? Nítorí pé ó fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, “tí kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò tàbí kí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Diutarónómì 10:17) Láfikún sí i, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù rántí ìtọ́ni tí ó ṣe pàtó tí a rí nínú Òfin Mósè, tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú tàbí kí o gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn ọlọ́gbọ́n, a sì máa fi èrú yí ọ̀rọ̀ àwọn olódodo po.” (Diutarónómì 16:19) Bákan náà ni Dáfídì Ọba mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà ìbàjẹ́, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run má ṣe ka òun mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, “tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”—Sáàmù 26:10.
Àwọn tí wọ́n ń fi tòótọ́tòótọ́ jọ́sìn Ọlọ́run tún ní ìdí mìíràn láti sá fún ìwà ìbàjẹ́. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí orílẹ̀-èdè kan dúró gbọn-in, ṣùgbọ́n olójúkòkòrò tí ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń ya á lulẹ̀.” (Òwe 29:4, New International Version) Àìṣègbè—pàápàá tó bá bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá pátápátá títí ó fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tó kéré jù lọ—ń mú kí orílẹ̀-èdè ní láárí, nígbà tó sì jẹ́ pé akúṣẹ̀ẹ́ ni ìwà ìbàjẹ́ máa ń sọ orílẹ̀-èdè dà. Ó gba àfiyèsí pé ìwé ìròyìn Newsweek là á mọ́lẹ̀ pé: “Nínú ètò kan tí olúkúlùkù ti ń wá bí òun ṣe máa rí owó tòun kó jẹ, tí wọ́n sì mọ ọ̀nà àtirí owó náà kó jẹ, ètò ọrọ̀ ajé lè forí ṣánpọ́n.”
Kódà bí ètò ọ̀rọ̀ ajé ò tiẹ̀ forí ṣánpọ́n pátápátá, ó máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àìṣègbè nígbà tí wọ́n bá rí i pé ṣe ni ìwà ìbàjẹ́ túbọ̀ ń gbalẹ̀ kan. (Sáàmù 73:3, 13) Ó tún máa ń múni dẹ́ṣẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tó fi í sí wa lọ́kàn láti nífẹ̀ẹ́ àìṣègbè. Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìwà ìbàjẹ́ tó peléke kúrò pátápátá láyé ọjọ́un. Fún àpẹẹrẹ, ó là á mọ́lẹ̀ fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù pé òun yóò fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.
Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Míkà, Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì, ẹ̀yin tí ń ṣe họ́ọ̀ sí ìdájọ́ òdodo àti ẹ̀yin tí ń ṣe ohun gbogbo tí ó tọ́ pàápàá ní wíwọ́. Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ kìkì fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń fúnni ní ìtọ́ni kìkì fún iye kan, àwọn wòlíì rẹ̀ sì ń woṣẹ́ kìkì fún owó . . . Nítorí náà, ní tìtorí yín, a ó tu Síónì bí ilẹ̀ pápá lásán-làsàn, Jerúsálẹ́mù yóò sì di òkìtì àwókù lásán-làsàn.” Ìwà ìbàjẹ́ ti ba àwùjọ Ísírẹ́lì jẹ́ pátápátá, gẹ́gẹ́ bó ṣe wá sọ Róòmù dìdàkudà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ṣe, nǹkan bí ọ̀rúndún kan lẹ́yìn tí Míkà kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílẹ̀ ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, tí ó sì di ahoro.—Míkà 3:9, 11, 12.
Bó ti wù kó rí, kò sí ẹnì kan tàbí orílẹ̀-èdè kan tó yẹ kó hu ìwà ìbàjẹ́. Ọlọ́run gba àwọn ẹni ibi níyànjú pé kí wọ́n kọ ọ̀nà wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì yí èrò inú wọn padà. (Aísáyà 55:7) Ó fẹ́ kí olúkúlùkù wa fi àìmọtara-ẹni-nìkan rọ́pò ìwọra, kí a sì fi òdodo rọ́pò ìwà ìbàjẹ́. Jèhófà rán wa létí pé: “Ẹni tí ń lu ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn òtòṣì ń yìn Ín lógo.”—Òwe 14:31.
Ṣe Àṣeyege Nínú Fífi Òtítọ́ Bíbélì Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́
Kí ló lè sún ẹnì kan láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀? Agbára kan náà yẹn ni, èyí tó sún Pọ́ọ̀lù láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Farisí padà tí ó sì di akíkanjú ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Lóde òní, òtítọ́ Ìwé Mímọ́ ṣì ń gbé ìwà àìlábòsí lárugẹ, kódà láàárín àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí jingíri sínú ìwà ìbàjẹ́ pàápàá. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
Kò pẹ́ púpọ̀ tí Alexander, tó wá láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù, parí iṣẹ́ ológun ló wá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kan tó ń ṣe iṣẹ́ bìrìbìrì, tó ń lọ́ni lọ́wọ́ gbà, tó sì máa ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. a Ó ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi ni pé kí n máa fìgbójú gbowó ààbò lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò tí wọ́n lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Gbàrà tí oníṣòwò kan bá ti fọkàn tán mi dáadáa, àwọn mìíràn nínú ẹgbẹ́ wa yóò wá lọ bá a pé àwọn máa ṣe é léṣe. Ìgbà yẹn ni mo máa ń yọjú láti yanjú ọ̀ràn náà—pẹ̀lú owó gọbọi tí oníṣòwò náà yóò san. ‘Àwọn oníbàárà’ mi á wá dúpẹ́ lọ́wọ́ mi pé mo bá wọn yanjú ìṣòro wọn, nígbà tó sì jẹ́ pé èmi gan-an ni eku ẹdá tó wà nídìí ọ̀ràn náà. Ó lè dà bí ọ̀rọ̀ kàyéfì o, àmọ́ apá tí mo fẹ́ràn nínú iṣẹ́ náà nìyẹn.
“Mo tún gbádùn owó àti ìmóríyá tí mò ń ní nípa gbígbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá ni mò ń lò, ilé tó dára ni mò ń gbé, mo sì lówó lọ́wọ́ láti ra ohunkóhun tó bá wù mí. Àwọn èèyàn ń bẹ̀rù mi gan-an ni, ìyẹn sì ń jẹ́ kí eegun mi le sí i. Mo máa ń rò pé mìmì kan ò lè mì mí, àti pé òfin ò lè mú mi. Bí ọlọ́pàá bá tiẹ̀ mú mi, ògbógi agbẹjọ́rò tó mọ báa ṣe ń yí ẹjọ́ po mọ́ adájọ́ lọ́wọ́ yóò bá mi yanjú ẹ̀, tàbí kí n fún ẹni tó wà nídìí ọ̀ràn náà ní rìbá.
“Àmọ́, kò sí ọ̀rọ̀ pé a ń fọkàn tánni láàárín àwọn tó ń gbé ìgbésí ayé ìwà ìbàjẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra mi, bó ṣe di pé kò sẹ́ni tó gba tèmi mọ́ nìyẹn. Lójijì, mo pàdánù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì mi, owó tí mo ní tán, ọ̀rẹ́ mi obìnrin tí mo ti ná jẹ̀jẹ̀rẹ̀ owó lé lórí náà fẹsẹ̀ fẹ. Kódà, wọ́n lù mí bí ẹní máa kú. Ìyípadà búburú yìí ló wá mú mi ronú gan-an nípa ète ìgbésí ayé.
“Ní oṣù díẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn, màmá mi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìwé wọn. Ọ̀rọ̀ inú Òwe 4:14, 15 mú mi ronú gan-an ni, ó ní: ‘Má wọ ipa ọ̀nà àwọn ẹni burúkú, má sì rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú. Yẹra fún un, má gbà á kọjá; yà kúrò nínú rẹ̀, kí o sì kọjá lọ.’ Àwọn àyọkà bí èyí ló wá mú un dá mi lójú pé kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn kankan nípa ọjọ́ ọ̀la fún àwọn tó ń gbé ìgbésí ayé arúfin. Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tí ó tọ́. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn tí mo sì ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run níkẹyìn. Àtìgbà yẹn ni mo ti ń gbé ìgbésí ayé aláìlábòsí.
“Ká sọ tòótọ́, gbígbé ìgbésí ayé aláìlábòsí kò jẹ́ kí n fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Àmọ́, nísinsìnyí ọkàn mi balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, ìgbésí ayé mi sì ní ìtumọ̀ gidi. Mo wá rí i pé ìgbésí ayé mi tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ rẹ̀, kò yàtọ̀ rárá sí ilé táa fitọ́ mọ, tí ìrì yóò wó láìpẹ́ láìjìnnà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ̀rí-ọkàn mi ti yigbì. Nísinsìnyí, mo dúpẹ́ pé mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo ìgbà ló máa ń gún mi ní kẹ́ṣẹ́ tí mo bá ti fẹ́ hu ìwà àbòsí kan—bó tilẹ̀ jẹ́ lórí ọ̀ràn tí ò ju kékeré lọ. Mo ń gbìyànjú àtigbé ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 37:3, tó sọ pé: ‘Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere; máa gbé ilẹ̀ ayé, kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.’”
“Ẹni Tí Ó Kórìíra Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Ni Yóò Yè”
Gẹ́gẹ́ bí Alexander ṣe wá rí i, òtítọ́ Bíbélì lè sún ẹnì kan láti borí ìwà ìbàjẹ́. Ó ṣe àtúnṣe tó bá ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Éfésù mu pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ; . . . ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin. Nítorí náà, nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá. Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:22-25, 28) Irú ìyípadà sí rere yẹn ló lè mú kí ìran ènìyàn pàápàá máa retí ọjọ́ ọ̀la tí ń fini lọ́kàn balẹ̀.
Bí a kò bá kápá rẹ̀, ìwọra àti ìwà ìbàjẹ́ lè pa ayé run, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣokùnfà ìparun Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Àmọ́, inú wa dùn pé Ẹlẹ́dàá aráyé kò pète láti fi ọwọ́ lẹ́rán láìṣe nǹkan kan sí i. Ó ti pinnu “láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Jèhófà sì ti ṣèlérí fún àwọn tó ń retí ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ìbàjẹ́ pé ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun . . . nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé’ ń bọ̀ láìpẹ́.—2 Pétérù 3:13.
Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti tẹ̀ lé ìlànà àìlábòsí lóde òní. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà mú un dá wa lójú pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, “oníwọra ènìyàn ń kó wàhálà bá ìdílé rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni yóò yè.” b (Òwe 15:27, NIV) Tí a bá kọ ìwà ìbàjẹ́ sílẹ̀ báyìí, a ń fi hàn pé ohun tó wà lọ́kàn wa là ń sọ nígbà táa bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
Báa ti ń dúró de Ìjọba yẹn láti wá gbégbèésẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ‘fún irúgbìn ní òdodo’ nípa kíkọ̀ láti fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ tàbí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀. (Hóséà 10:12) Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé àwa náà yóò jẹ́rìí sí agbára tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Idà ẹ̀mí lè ṣẹ́gun ìwà ìbàjẹ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
b Àmọ́ ṣá o, ìyàtọ̀ wà láàárín àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti owó táa fi ṣe kóríyá fúnni. Nígbà tó jẹ́ pé tìtorí àtigbẹ́bi fún aláre tàbí nítorí ká lè ṣe àwọn àbòsí mìíràn la ṣe ń fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, owó kóríyá wulẹ̀ jẹ́ láti fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ tí ẹnì kan ṣe fúnni. A ṣàlàyé èyí nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti October 1, 1986 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bíbélì, a lè mú “àkópọ̀ ìwà tuntun” dàgbà kí a sì yẹra fún ìwà ìbàjẹ́