Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ìjiyàn Ṣì Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Wọn

Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ìjiyàn Ṣì Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Wọn

Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ìjiyàn Ṣì Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Wọn

Ṣóòótọ́ ni àwọn ìtàn tí ìwé Ìhìn rere sọ nípa ìbí Jésù Kristi?

Ṣé lóòótọ́ ló ṣe Ìwàásù Lórí Òkè?

Ṣé lóòótọ́ ni Jésù jíǹde?

Ṣé lóòótọ́ ló sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè”?—Jòhánù 14:6.

NǸKAN bí ọgọ́rin ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló ti ń ṣe atótónu lórí irú ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí níbi Àpérò Jésù, tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, láti 1985. Ọ̀nà kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni ẹgbẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí gbà dáhùn irú àwọn ìbéèrè tó wà lókè wọ̀nyí. Ńṣe làwọn alápèérò náà máa ń dìbò lórí gbogbo gbólóhùn tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé ó tẹnu Jésù jáde. Ìbò tí wọ́n bá fìwé pupa dì fi hàn pé lóòótọ́ ni Jésù sọ gbólóhùn náà. Ìbò tí wọ́n bá fìwé aláwọ̀ osùn dì túmọ̀ sí pé gbólóhùn náà fara pẹ́ ohun tí Jésù sọ. Ìbò tí wọ́n bá fìwé aláwọ̀ eérú dì fi hàn pé ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Jésù nìyẹn, ṣùgbọ́n gbólóhùn yẹn kò tẹnu rẹ̀ jáde. Ìbò tí wọ́n bá fìwé dúdú dì fi hàn pé irọ́ pátápátá ni, inú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó jáde lẹ́yìn ìgbà náà ni gbólóhùn yẹn ti wá.

Nípa títẹ̀lé ọ̀nà yìí, àwọn tó wá ṣe Àpérò Jésù ti bẹnu àtẹ́ lu gbogbo kókó mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí a gbé dìde ní ìṣáájú. Àní, ìbò dúdú ni wọ́n dì fún ìpín méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀rọ̀ táwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé ó tẹnu Jésù jáde. Wọ́n ní ìpín mẹ́rìndínlógún péré lára ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé yòókù ròyìn nípa Jésù la lè sọ pé ó jóòótọ́.

Kì í ṣòní, kì í ṣàná, ni wọ́n ti ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ìwé kan tó gbéjà ko àwọn ìwé Ìhìn Rere jáde lọ́dún 1774, ọ̀gbẹ́ni Hermann Reimarus, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àwọn èdè ará Ìlà Oòrùn ní Hamburg, Jámánì, ló kọ́kọ́ fọwọ́ kọ ìwé yìí tó ní egbèje ojú ìwé, èyí tí wọ́n wá tẹ̀ jáde lẹ́yìn ikú rẹ̀. Nínú ìwé náà, Reimarus sọ pé lọ́kàn tòun, àròkọ làwọn ìwé Ìhìn Rere. Ìdí tó fi lérò bẹ́ẹ̀ ni pé ó ṣe àwọn ìfọ́síwẹ́wẹ́ kan nípa ìlò èdè, àti pé lójú tiẹ̀, àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó ròyìn ìgbésí ayé Jésù takora. Látìgbà yẹn làwọn aṣelámèyítọ́ ti ń sọ pé kò dájú pé òótọ́ lohun tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, wọ́n sì ń tipa báyìí jẹ́ káwọn èèyàn máa kọminú nípa àwọn ìwé wọ̀nyí.

Ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí ni pé àwọn ìwé Ìhìn Rere kò yàtọ̀ sí ìtàn àtẹnudẹ́nu táwọn kan gbé jókòó nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ìbéèrè táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí tí ominú ń kọ sábà máa ń gbé dìde ni pé: Ṣé kì í ṣe pé ìgbàgbọ́ àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin mú kí wọ́n já àlùbọ́sà sí ìtàn náà? Ṣé kì í ṣe pé kí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lè gbégbá orókè ló jẹ́ kí wọ́n yí ìtàn Jésù padà, tàbí tí wọ́n fi bù mọ́ ọn kó lè dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in? Èwo lára àwọn ìtàn inú ìwé Ìhìn Rere ló ṣeé ṣe kó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀, tí kì í ṣe ìtàn àròsọ?

Àwọn èèyàn tí wọ́n tọ́ dàgbà láwùjọ táwọn èèyàn ò ti gbà pé Ọlọ́run wà, tàbí láwùjọ táwọn èèyàn ò ti ka ọ̀ràn ẹ̀sìn sí, gbà pé gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì—títí kan àwọn ìwé Ìhìn Rere—kò ju ìtàn àtẹnudẹ́nu àti ìtàn àròsọ lásán lọ. Síwájú sí i, ara àwọn èèyàn máa ń bù máṣọ nítorí àwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ látọdúnmọ́dún nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn nǹkan bí ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìfojú-ẹni-gbolẹ̀, ìyapa, àti ìwà àìnáání Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó bá ń rí irú nǹkan báwọnnì kò tiẹ̀ ní fẹ́ kọbi ara sí ìwé tí Kirisẹ́ńdọ̀mù bá pè ní mímọ́. Lójú tiwọn, ìtàn inú ìwé ẹ̀sìn àwọn alágàbàgebè wọ̀nyí kò lè yàtọ̀ sí ìtàn ìjàpá àti yánníbo.

Kí lèrò tìrẹ? Ṣé ó yẹ kóo jẹ́ kí àwọn kan tí wọ́n pera wọn lọ́mọ̀wé, tí wọ́n ń jiyàn pé ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé Ìhìn Rere kì í ṣòótọ́, wá jẹ́ kíwọ náà bẹ̀rẹ̀ sí mikàn ni? Tóo bá gbọ́ táwọn kan ń polongo pé àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ló fúnra wọn gbé ìtàn wọ̀nyẹn jókòó, ǹjẹ́ ó yẹ kóo jẹ́ kí èyí mú ẹ kọminú nípa ìwé wọn? Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìwà burúkú tó kún inú Kirisẹ́ńdọ̀mù mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí mikàn nípa àwọn ìwé Ìhìn Rere? Jọ̀wọ́ jẹ́ ká gbé àwọn òtítọ́ kan yẹ̀ wò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣé ìtàn àròsọ ló wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ni tàbí òótọ́ ọ̀rọ̀?

[Credit Line]

Jésù Ń Rìn Lórí Òkun/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwòrán ìsàlẹ̀, ojú ìwé 3 sí 5 àti 8: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúúre Freer Gallery of Art, Smithsonian Institution, Washington, D.C.