Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òbí Lòdì sí Ẹ̀tanú Olùkọ́ Kan

Àwọn Òbí Lòdì sí Ẹ̀tanú Olùkọ́ Kan

Àwọn Òbí Lòdì sí Ẹ̀tanú Olùkọ́ Kan

Olùkọ́ kan tó ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Cassano Murge, ní Ítálì, kó àwọn bébà tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ nǹkan fún díẹ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan, ó ní kí wọ́n kó o lọọlé. Ara ilẹ̀kùn àbáwọlé ni wọ́n ṣètò pé kí wọ́n lẹ bébà yìí mọ́, ohun tí wọ́n sì kọ sára àwọn bébà náà ni: “Kátólíìkì ni wá o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ kan ilẹ̀kùn yìí.”

Àwọn kan lára òbí àwọn ọmọ náà lòdì pátápátá sí ohun tí olùkọ́ náà ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Muoviti Muoviti sọ, àwọn òbí náà sọ pé ‘fífún àwọn ọmọ ní irú ìsọfúnni yìí yóò jẹ́ kí wọ́n ṣá ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú bíi tiwọn tì tàbí kí wọ́n máa yẹra fún ẹnì kan nítorí pé ìsìn rẹ̀ “yàtọ̀.”’ Òbí kan tó kọ̀wé sí iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn náà pe bébà náà ní “èso èpò, tó jẹ yọ látinú ẹ̀mí àìmọ̀kan àti ìwà ẹ̀gọ̀.”

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí ti fi hàn, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kàn rere ló mọ ewu tó wà nínú gbígbin ẹ̀tanú sáwọn èèyàn lọ́kàn. Wọ́n sì tún bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe jákèjádò ilẹ̀ Ítálì àti gbogbo ayé. Èé ṣe tóò fi bi àwọn Ẹlẹ́rìí nípa ‘ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú wọn’? Inú wọn yóò dùn láti bá ọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, wọn ó sì ṣe é pẹ̀lú “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:15.