Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run!

Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run!

Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run!

“A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú.”—2 PÉTÉRÙ 1:19.

1, 2. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ́kọ́ kọ sílẹ̀ pàá, kí sì ni ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó gbé dìde?

 JÈHÓFÀ ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ́kọ́ kọ sílẹ̀ pàá. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sọ fún ejò náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7, 14, 15) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ní láti kọjá kó tó di pé a lóye àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ní kíkún.

2 Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn fún ìran ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ojúlówó ìrètí. Ìwé Mímọ́ wá fi Sátánì Èṣù hàn gẹ́gẹ́ bí “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” níkẹyìn. (Ìṣípayá 12:9) Àmọ́, ta ni yóò wá jẹ́ Irú Ọmọ Ọlọ́run tí a ṣèlérí náà?

Wíwá Irú Ọmọ Náà Kiri

3. Báwo ni Ébẹ́lì ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́?

3 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí baba rẹ̀, Ébẹ́lì olùbẹ̀rù Ọlọ́run lo ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ náà. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì mọ̀ pé a ní láti da ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ kí a tó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Nítorí náà, ìgbàgbọ́ sún un láti rú ẹbọ kan tó fi ẹran rú, Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà á. (Jẹ́nẹ́sísì 4:2-4) Síbẹ̀, mímọ irú ẹni tí Irú Ọmọ náà jẹ́ ṣì jẹ́ àdììtú.

4. Ìlérí wo ni Ọlọ́run fún Ábúráhámù, kí ló sì fi hàn nípa Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà?

4 Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún lẹ́yìn ọjọ́ Ébẹ́lì, Jèhófà fún baba ńlá náà, Ábúráhámù ní ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ yìí pé: “Èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run . . . Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ náà kò yọ Ábúráhámù sílẹ̀. Wọ́n fi hàn pé ìlà ìdílé Ábúráhámù ni Irú-Ọmọ náà tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ sọ àwọn iṣẹ́ Èṣù di asán yóò gbà wá. (1 Jòhánù 3:8) “Nítorí ìlérí Ọlọ́run, [Ábúráhámù] kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́,” bákan náà ni àwọn yòókù tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé kò mikàn, ìyẹn àwọn tí “kò rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.” (Róòmù 4:20, 21; Hébérù 11:39) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n di ìgbàgbọ́ wọn nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run mú.

5. Ta ní ìlérí Ọlọ́run nípa Irú-Ọmọ náà ṣẹ sí lára, èé sì ti ṣe tóo fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà hàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn ìlérí náà ni a sọ fún Ábúráhámù àti fún irú-ọmọ rẹ̀. Kò sọ pé: ‘Àti fún àwọn irú-ọmọ,’ gẹ́gẹ́ bí nínú ọ̀ràn ti ọ̀pọ̀ irúfẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí nínú ọ̀ràn ẹnì kan: ‘Àti fún irú-ọmọ rẹ,’ tí í ṣe Kristi.” (Gálátíà 3:16) Kì í ṣe gbogbo àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ló jẹ́ Irú-Ọmọ tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún ara wọn. A ò lo àwọn àtọmọdọ́mọ Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ tí Kétúrà bí fún un láti bù kún ìran ènìyàn. Irú-Ọmọ ìbùkún yìí wá nípasẹ̀ Ísákì ọmọ rẹ̀ àti Jékọ́bù ọmọ-ọmọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12; 25:23, 31-34; 27:18-29, 37; 28:14) Jékọ́bù fi hàn pé “àwọn ènìyàn” yóò ṣègbọràn sí Ṣílò ti ẹ̀yà Júdà, àmọ́ nígbà tó yá, a wá fi hàn pàtó pé ìlà ìran Dáfídì ni Irú-Ọmọ náà yóò ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10; 2 Sámúẹ́lì 7:12-16) Àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní retí ẹnì kan tí yóò dé gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, tàbí Kristi. (Jòhánù 7:41, 42) Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run nípa Irú-Ọmọ náà wá ṣẹ sí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi lára.

Mèsáyà Náà Fara Hàn!

6. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká lóye àsọtẹ́lẹ̀ nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà? (b) Ìgbà wo ni Jésù “pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò” báwo ló sì ṣe ṣe é?

6 Wòlíì Dáníẹ́lì kọ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan nípa Mèsáyà. Ní ọdún kìíní Dáríúsì ará Mídíà, ó mọ̀ pé ìdahoro Jerúsálẹ́mù fún àádọ́rin ọdún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. (Jeremáyà 29:10; Dáníẹ́lì 9:1-4) Nígbà tí Dáníẹ́lì sì ń gbàdúrà lọ́wọ́, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì dé, ó sì ṣí i payá pé ‘àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a ti pinnu láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò.’ Láàárín àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà ni wọn óò ké Mèsáyà kúrò. “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún” bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Atasásítà Kìíní Ọba Páṣíà ‘rán ọ̀rọ̀ jáde láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́.’ (Dáníẹ́lì 9:20-27; Moffatt; Nehemáyà 2:1-8) Mèsáyà náà yóò dé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta. Ọ̀rìnlé-ní-rínwó ọdún ó lé mẹ́ta [483] wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa títí dé ọdún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jésù ṣe batisí, tí Ọlọ́run sì fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, tàbí Kristi. (Lúùkù 3:21, 22) Jésù “pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò” nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. (Máàkù 10:45) Ìdí tó lágbára láti ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run mà lèyí o! a

7. Lo Ìwé Mímọ́ láti tọ́ka sí bí Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣẹ.

7 Ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti dá Mèsáyà náà mọ̀. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni àwọn òǹkọ̀wé tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì darí rẹ̀ sí Jésù ní tààràtà. Fún àpẹẹrẹ: Wúńdíá kan bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Aísáyà 7:14; Míkà 5:2; Mátíù 1:18-23; Lúùkù 2:4-11) A pè é jáde ní Íjíbítì, wọ́n sì pa àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ́yìn ìbí rẹ̀. (Jeremáyà 31:15; Hóséà 11:1; Mátíù 2:13-18) Jésù ru àwọn àìsàn wa. (Aísáyà 53:4; Mátíù 8:16, 17) Bí a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù. (Sekaráyà 9:9; Jòhánù 12:12-15) Ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ní ìmúṣẹ lẹ́yìn tí wọ́n kan Jésù mọ́gi, tí àwọn ọmọ ogun pín aṣọ rẹ̀ láàárín ara wọn, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Sáàmù 22:18; Jòhánù 19:23, 24) Àní bí wọn ò ṣe ṣẹ́ àwọn egungun Jésù, tí wọ́n sì fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ tún jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀. (Sáàmù 34:20; Sekaráyà 12:10; Jòhánù 19:33-37) Ìwọ̀nba àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí tọ́ka rẹ̀ sí Jésù nìwọ̀nyí. b

Ẹ Kókìkí Mèsáyà Ọba!

8. Ta ni Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí keje, ẹsẹ ìkẹsàn-án sí ìkẹrìnlá ṣe ní ìmúṣẹ?

8 Ní ọdún kìíní Bẹliṣásárì ọba Bábílónì, Jèhófà jẹ́ kí wòlíì rẹ̀ Dáníẹ́lì lá àlá kan, ó sì tún rí àwọn ìran tó kàmàmà. Wòlíì náà kọ́kọ́ rí ẹranko mẹ́rin tó tóbi fàkìàfakia. Áńgẹ́lì Ọlọ́run pè wọ́n ní “ọba mẹ́rin,” tí ó fi hàn pé wọ́n ń ṣàpẹẹrẹ ìtòtẹ̀léra àwọn agbára ayé. (Dáníẹ́lì 7:1-8, 17) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Dáníẹ́lì wá rí Jèhófà, “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” tó gúnwà lọ́nà ológo. Ó dá àwọn ẹranko náà lẹ́jọ́ ẹ̀bi, ó gba ìṣàkóso kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sì pa ẹranko kẹrin run. Agbára ìṣàkóso fún àkókò tí ó lọ kánrin, lórí “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè,” ni a gbé wọ “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn.” (Dáníẹ́lì 7:9-14) Àgbàyanu àsọtẹ́lẹ̀ mà lèyí o, tó ń tọ́ka sí gígùn tí “Ọmọ ènìyàn,” Jésù Kristi, gorí ìtẹ́ ní ọ̀run ní ọdún 1914!—Mátíù 16:13.

9, 10. (a) Kí ni ohun tí onírúurú ẹ̀yà ara ère inú àlá náà tọ́ka sí? (b) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìmúṣẹ Dáníẹ́lì orí kejì, ẹsẹ ìkẹrìn-lé-lógójì?

9 Dáníẹ́lì mọ̀ pé Ọlọ́run ń “mú àwọn ọba kúrò, ó sì ń fi àwọn ọba jẹ.” (Dáníẹ́lì 2:21) Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, “Olùṣí àwọn àṣírí payá,” wòlíì náà sọ ìtumọ̀ ère arabarìbì inú àlá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì. Onírúurú ẹ̀yà ara rẹ̀ tọ́ka sí ìdìde àti ìṣubú àwọn agbára ayé bí Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù. Ọlọ́run tún lo Dáníẹ́lì láti la àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́sẹẹsẹ títí dé ìgbà tiwa àti ré kọjá ìgbà tiwa.—Dáníẹ́lì 2:24-30.

10 Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin ní 1914, Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ ọ̀run kalẹ̀ lábẹ́ Kristi. (Lúùkù 21:24; Ìṣípayá 12:1-5) Nípa agbára àtọ̀runwá ni a fi gé “òkúta” Ìjọba Mèsáyà jáde láti ara “òkè ńlá” ipò ọba aláṣẹ àgbáyé ti Ọlọ́run. Nígbà Amágẹ́dọ́nì, òkúta yẹn yóò kọlu ère náà, yóò sì lọ̀ ọ́ lúúlúú. Gẹ́gẹ́ bí ìjọba táa lè fi wé òkè ńlá kan tó nípa lórí “gbogbo ilẹ̀ ayé,” Ìjọba Mèsáyà náà yóò dúró títi láé.—Dáníẹ́lì 2:35, 45; Ìṣípayá 16:14, 16. c

11. Ìyípadà ológo Jésù jẹ́ rírí kí ni ṣáájú, ipa wo sì ni ìran yẹn ní lórí Pétérù?

11 Bí Jésù ti ní ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ lọ́kàn, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:28) Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lọ sí orí òkè ńlá kan tó ga fíofío níbi tí a ti yí i padà di ológo níwájú wọn. Bí àwọsánmà mímọ́lẹ̀ yòò ṣe ṣíji bo àwọn àpọ́sítélì náà, Ọlọ́run kéde pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mátíù 17:1-9; Máàkù 9:1-9) Ìran àríṣáájú yìí mà ga o nípa ògo Ìjọba Kristi! Abájọ tí Pétérù fi tọ́ka sí ìran dídányanran yẹn pé: “Nítorí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú.”—2 Pétérù 1:16-19. d

12. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì ní àkókò yìí láti fi ìgbàgbọ́ táa ni nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run hàn?

12 Ó dájú pé kì í ṣe kìkì àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù nìkan ni “ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀” náà ní nínú, àmọ́ ó tún ní ọ̀rọ̀ Jésù nínú pé òun yóò wá “pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Mátíù 24:30) Ìyípadà ológo náà jẹ́rìí sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ ológo Kristi nínú agbára Ìjọba. Láìpẹ́, ìṣípayá rẹ̀ nínú ògo yóò mú ìparun bá àwọn aláìgbàgbọ́, yóò sì mú ìbùkún wá fún àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́. (2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ikẹyìn” nìwọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1-5, 16, 17; Mátíù 24:3-14) Gẹ́gẹ́ bí Olórí Amúdàájọ́ṣẹ ti Jèhófà, Máíkẹ́lì, ẹni tí í ṣe Jésù Kristi, ti dúró ní sẹpẹ́ láti mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan búburú yìí ní ìgbà “ìpọ́njú ńlá.” (Mátíù 24:21; Dáníẹ́lì 12:1) Láìsí àní-àní, àkókò nìyí láti fi hàn gbangba pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tóo Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Yingin

13. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí ìgbàgbọ́ wa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ má sì yingin?

13 Dájúdájú, inú wa dùn gan-an ni nígbà tí a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣé ìgbàgbọ́ táa ní láti ìgbà yẹn ti dín kù ni àbí ìfẹ́ wa ti di tútù? Kí a má ṣe dà bí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù láé, àwọn tí wọ́n ‘fi ìfẹ́ tí wọ́n ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.’ (Ìṣípayá 2:1-4) Bó ti wù kí àkókò tí a fi sin Jèhófà gùn tó, a lè pàdánù, àyàfi táa bá ‘ń wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́’ kí a lè to ìṣúra pa mọ́ sí ọ̀run. (Mátíù 6:19-21, 31-33) Fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nínípìn-ín nínú àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, àti fífi tìtaratìtara lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò wíwàásù Ìjọba náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọmọ rẹ̀, àti Ìwé Mímọ́. (Sáàmù 119:105; Máàkù 13:10; Hébérù 10:24, 25) Èyí, ẹ̀wẹ̀, kì yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yingin.—Sáàmù 106:12.

14. Báwo la ṣe san èrè fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà?

14 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ṣe ní ìmúṣẹ láyé ọjọ́un, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tó sọ nípa ọjọ́ iwájú. Fún àpẹẹrẹ, wíwàníhìn-ín Kristi nínú ògo Ìjọba rẹ̀ ti dòótọ́ báyìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣe olóòótọ́ dójú ikú sì ti rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ìlérí náà pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jẹ nínú igi ìyè, èyí tí ń bẹ nínú párádísè Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 2:7, 10; 1 Tẹsalóníkà 4:14-17) Jésù fún àwọn aṣẹ́gun wọ̀nyí ní àǹfààní “láti jẹ nínú igi ìyè,” tó wà nínú “párádísè Ọlọ́run” lókè ọ̀run. Lẹ́yìn àjíǹde wọn àti nípasẹ̀ Jésù Kristi, wọn yóò nípìn-ín nínú àìkú àti àìdíbàjẹ́ tí Jèhófà, “Ọba ayérayé, tí kò lè díbàjẹ́, tí a kò lè rí, Ọlọ́run kan ṣoṣo náà,” fi jíǹkí wọn. (1 Tímótì 1:17; 1 Kọ́ríńtì 15:50-54; 2 Tímótì 1:10) Ẹ wo bí èyí ṣe jẹ́ èrè kíkọyọyọ tó fún ìfẹ́ tí iná rẹ̀ kì í kú tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ wọn tí kò mì nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀!

15. Inú àwọn wo ni ìpìlẹ̀ “ilẹ̀ ayé tuntun” fìdí sọlẹ̀ sí, àwọn wo sì ni alábàákẹ́gbẹ́ wọn?

15 Kété lẹ́yìn tí àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ti kú jíǹde sínú “párádísè Ọlọ́run” ti ọ̀run ni àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó wà lórí ilẹ̀ ayé gba ìdáǹdè kúrò lábẹ́ “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 14:8, Gálátíà 6:16) Inú wọn ni ìpìlẹ̀ “ilẹ̀ ayé tuntun fìdí sọlẹ̀ sí.” (Ìṣípayá 21:1) Nípa bẹ́ẹ̀, a bí “ilẹ̀ kan,” a sì kọ́ ọ di párádísè tẹ̀mí tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ jákèjádò ayé lónìí. (Aísáyà 66:8) Ibẹ̀ sì ni ògìdìgbó àwọn ẹni bí àgùntàn tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí ń wọ́ tìrítìrí sí báyìí, “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.”—Aísáyà 2:2-4; Sekaráyà 8:23; Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9.

A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọjọ́ Ọ̀la Ìran Ènìyàn Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run

16. Kí ni ìrètí àwọn tó ń fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró?

16 Kí ni ìrètí àwọn tó ń fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró? Àwọn pẹ̀lú ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, ìrètí wọn sì ni pé kí wọ́n wọ inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:39-43) Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa mu lára “odò omi ìyè kan” tí ń múni wà láàyè, wọn ó sì rí ìmúláradà látinú “ewé àwọn igi” tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. (Ìṣípayá 22:1, 2) Bí o bá ní irú àgbàyanu ìrètí bẹ́ẹ̀, yóò dára kí o máa bá a nìṣó láti fí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí Jèhófà, kí o sì ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ kí o wà lára àwọn tí yóò ní ìdùnnú aláìlẹ́gbẹ́ ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.

17. Àwọn ìbùkún wo ni ìgbésí ayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò ní nínú?

17 Kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ kọjá ohun tí àwa ẹ̀dá aláìpé lè ṣàlàyé, àmọ́ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ti fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn ìbùkún tó wà nípamọ́ fún ìran ènìyàn onígbọràn. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso láìsí alátakò, tí a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run, kò ní sí eléwu ènìyàn mọ́—rárá, kò tiẹ̀ ní sí ẹranko abèṣe pàápàá—tí yóò ‘ṣe ìpalára èyíkéyìí tàbí tí yóò fa ìparun èyíkéyìí.’ (Aísáyà 11:9; Mátíù 6:9, 10) Àwọn ọlọ́kàn tútù yóò jogún ilẹ̀ ayé, “wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Kò ní sí àwùjọ ènìyàn tí kò rí oúnjẹ jẹ mọ́, nítorí pé “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Kò ní sí dída omijé ìbànújẹ́ lójú mọ́. Àìsàn yóò ti lọ, ikú pàápàá kò ní sí mọ́. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4) Fojú inú wò ó ná—kò sí àwọn dókítà mọ́, kò sí egbòogi, kò sí ilé ìwòsàn tàbí ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn aláìsàn ọpọlọ, kò sí ìsìnkú mọ́. Ìrètí kíkàmàmà mà lèyí o!

18. (a) Kí ni a mú dá Dáníẹ́lì lójú? (b) Kí ni yóò jẹ́ “ìpín” Dáníẹ́lì?

18 Kódà isà òkú tí aráyé ń sin àwọn èèyàn sí yóò ṣófo nígbà tí ikú bá pòórá, tí àjíǹde yóò sì bẹ̀rẹ̀. Jóòbù ọkùnrin olódodo nì ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 14:14, 15) Bákan náà ni wòlíì Dáníẹ́lì, nítorí pé áńgẹ́lì Jèhófà fún un ní ìdánilójú onítùnú náà pé: “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin; ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Dáníẹ́lì fi tòótọ́tòótọ́ sin Ọlọ́run títí dé òpin ìgbésí ayé rẹ̀. Ó ń sinmi nínú ikú báyìí, àmọ́ yóò “dìde” nígbà “àjíǹde àwọn olódodo” nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Lúùkù 14:14) Kí ni yóò wá jẹ́ “ìpín” Dáníẹ́lì? Tóò, nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì bá ní ìmúṣẹ nínú Párádísè, ó fi hàn pé gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà ni yóò ní àyè tiwọn, kódà a óò pín ilẹ̀ náà létòlétò àti lọ́nà títọ́. (Ìsíkíẹ́lì 47:13–48:35) Nítorí náà, Dáníẹ́lì yóò ní àyè kan nínú Párádísè, àmọ́ ìpín tí yóò kàn án kò ní jẹ́ ilẹ̀ nìkan. Yóò kan àyè rẹ̀ nínú ète Jèhófà pẹ̀lú.

19. Kí ló yẹ ní ṣíṣe ká tó lè gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé?

19 Ìwọ náà àti ìpín tìrẹ ńkọ́? Tóo bá ní ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní láti jẹ́ pé o ń yán hànhàn láti wà láàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. O tiẹ̀ lè máa fojú inú wo ara rẹ̀ níbẹ̀, tí o ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún rẹ̀, tí o ń bójú tó ilẹ̀ ayé, tí o sì ń fi tayọ̀tayọ̀ kí àwọn òkú káàbọ̀. Ó ṣe tán, Párádísè la ṣẹ̀dá aráyé láti máa gbé. Ọlọ́run dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti máa gbé nínú irú ibi bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9) Ó sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn onígbọràn máa gbé inú Párádísè títí láé. Ṣé wàá ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kí o lè wà lára ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí yóò máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀? O lè wà níbẹ̀ tóo bá ní ìfẹ́ tòótọ́ sí Baba wa ọ̀run, Jèhófà, tí o sì ní ìgbàgbọ́ tó dúró ṣinṣin nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo orí kọkànlá ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! àti “Àádọ́rin Ọ̀sẹ̀” inú Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Wo “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” ojú ìwé 343 sí 344, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́, ta sì ni Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà?

• Kí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíi mélòó kan nípa Mèsáyà tó ṣẹ sí Jésù lára?

• Báwo ní Dáníẹ́lì orí kejì, ẹsẹ ìkẹrìnlélógójì àti ìkarùnlélógójì yóò ṣe ní ìmúṣẹ?

• Irú ọjọ́ ọ̀la wo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run tọ́ka sí fún ìran ènìyàn onígbọràn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ṣé o ní ìrètí láti wà láàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé?