Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbé Ìgbàgbọ́ Ró ní Íńdíà

Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbé Ìgbàgbọ́ Ró ní Íńdíà

Àwa Ni Irú Àwọn Ẹni Tó Nígbàgbọ́

Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbé Ìgbàgbọ́ Ró ní Íńdíà

LÁTI àwọn orí Òkè Himalaya àwòṣífìlà, tí yìnyín bò níhà àríwá, títí dé etí Òkun Íńdíà tí ń hó gùdù níhà gúúsù, Íńdíà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́kàn-ò-jọ̀kan, ní ti bí ilẹ̀ ibẹ̀ ṣe rí àti ní ti ọ̀ràn ẹ̀sìn. Lára gbogbo àwọn èèyàn ibẹ̀, tó lé ní bílíọ̀nù kan, nǹkan bí ìpín mẹ́tàlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, ìpín mọ́kànlá jẹ́ Mùsùlùmí, àwọn yòókù sì jẹ́ àpapọ̀ Kristẹni aláfẹnujẹ́, àtàwọn ẹlẹ́sìn Sikh, Búdà àti Jain. Kálukú ló lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe kókó nínú ìgbésí ayé àwọn ará Íńdíà.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Íńdíà, tí iye wọ́n ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún àti igba lọ, ń gbé níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn nípa tẹ̀mí tí ń bẹ káàkiri ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Íńdíà kà á sí àǹfààní láti ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ tó lágbára ró nínú Bíbélì Mímọ́, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:16, 17) Gbọ́ bí ìdílé kan nílùú Chennai ní gúúsù Íńdíà ṣe wá mọ òtítọ́ Bíbélì.

Kí ìdílé yìí tó gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, alákitiyan ni wọ́n nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́mìímẹ́mìí inú Ìjọ Kátólíìkì, àwọn tó sọ pé wọ́n máa ń ríran, wọ́n máa ń fèdè fọ̀, àti pé wọ́n máa ń ṣèwòsàn. Abẹnugan ni wọ́n nínú ìjọ àti ládùúgbò, àwọn èèyàn tilẹ̀ máa ń pe àwọn kan nínú ìdílé yẹn ní “swami,” tó túmọ̀ sí “olúwa.” Àmọ́ lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí kan bẹ ìdílé náà wò, ó sì fi hàn wọ́n nínú Bíbélì pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, òun kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe gbà gbọ́. Ẹlẹ́rìí náà tún fi hàn wọ́n pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run àti pé ète Jèhófà fún ilẹ̀ ayé ni láti sọ ọ́ di párádísè ẹlẹ́wà.—Sáàmù 83:18; Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16.

Nítorí tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ràn ohun tí wọ́n gbọ́, àwọn mẹ́ńbà ìdílé yìí gbà pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa báwọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ni àwọn tí wọ́n jọ mọra ní ṣọ́ọ̀ṣì bá bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀, ìdílé yìí pinnu pé àwọn óò máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ. Bí ìmọ̀ wọn ti ń pọ̀ sí i, tí ìgbàgbọ́ wọn sì ń lágbára sí i, wọ́n jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn èké. Lónìí, mẹ́ta lára mẹ́ńbà ìdílé yìí ló ti di Ẹlẹ́rìí onítara, tó ti ṣe batisí, ìyá wọ́n sì máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà táyè ẹ̀ bá yọ.

Ìgbàgbọ́ Láti Borí Àìlera Ara

Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Sunder Lal, tó ń gbé lábúlé kan lágbègbè Punjab, nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ńláǹlà kí ó lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì. (Mátíù 24:14) Ìdí èkíní ni pé, kò nígbàgbọ́ nínú jíjọ́sìn ọ̀pọ̀ ọlọ́run mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ìdílé rẹ̀ gbà gbọ́ nìyí, ó sì ti fi abúlé rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Èkejì, Sunder Lal kò lẹ́sẹ̀.

Kó tó di ọdún 1992, àwọn ohun kan náà ṣáá ni Sunder Lal máa ń fi ojoojúmọ́ ayé ṣe. Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ oníṣègùn kan ni, ó sì ń dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ̀ nínú bíbọ onírúurú òòṣà lábẹ́ ìdarí àwòrò tiwọn. Àmọ́ lóru ọjọ́ kan, ó ṣubú nígbà tó ń sọdá ojú irin. Ni rélùwéè bá gé ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì láti itan sísàlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yè é, síbẹ̀, ó ro ara rẹ̀ pin. Gẹ́gẹ́ báa ti lè retí, ìrònú dorí Sunder Lal kodò, ó tilẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí ara ẹ̀. Àwọn ẹbí gbárùkù tì í, ṣùgbọ́n ayé ti sú u.

Nígbà náà ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bẹ Sunder Lal wò, tó sì fi hàn án látinú Bíbélì pé Ọlọ́run ti ṣèlérí láti sọ ayé di párádísè tó gbámúṣé àti pé gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀ ni yóò fún ní ìlera pípé. Sunder Lal gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọdún kan gbáko ló fi gbájú mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Wọ́n ké sí i pé kó wá sáwọn ìpàdé Kristẹni, níkẹyìn ó bá wọn lọ, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ló gbé e sẹ́yìn kẹ̀kẹ́ débẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹ̀lú ìroragógó ló fi débẹ̀, èrè ńlá ló yọrí sí. Ohun tó ti kọ́ nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tó rí, bó ṣe ń rí àwọn míì tó gba ìlérí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ ní tòótọ́, tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Sunder Lal bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà fún àwọn aládùúgbò rẹ̀, a sì batisí rẹ̀ lọ́dún 1995. Nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ńṣe ló máa ń fìdí wọ́ kiri láti ilé dé ilé lábúlé rẹ̀, bó kúkú ṣe ń lọ kiri tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ báyìí o, ó ti rí ẹ̀bùn kan gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí—ẹ̀bùn kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n dìídì ṣe láti máa fọwọ́ “wà.” Ọpẹ́lọpẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta yìí, kò retí kí wọ́n máa gbé òun kiri mọ́, ó ti lè dá rin ìrìn àjò kìlómítà méjìlá lọ sáwọn ìpàdé báyìí. Nígbà míì, ó máa ń gun kẹ̀kẹ́ yìí nígbà òjò wẹliwẹli; nígbà míì, ó máa ń gùn ún nígbà tí ìdíwọ̀n ooru bá ga tó mẹ́tàlélógójì lórí òṣùwọ̀n Celsius.

Ní àfikún sí lílọ sáwọn ìpàdé, Sunder Lal ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tó ń fẹ́ láti gbé ìgbàgbọ́ tó lágbára ró nínú Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Kódà, méje lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti ṣèrìbọmi báyìí, yàtọ̀ sí àwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ pé òun ló kọ́kọ́ kàn sí wọn ṣùgbọ́n táwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Àmọ́ ní ti àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé lè gbé ìgbàgbọ́ tó lágbára ró nínú wọn. (Ìṣe 13:48) Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ tún ń múni yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú ìrètí ọjọ́ ọ̀la alárinrin—ohun kan tí àwọn púpọ̀ sí i ní Íńdíà ti gbà gbọ́ báyìí.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

AFGANISTAN

PAKISTAN

NEPAL

BHUTAN

CHINA

BANGLADESH

MYANMAR

LAOS

THAILAND

VIETNAM

CAMBODIA

SRI LANKA

ÍŃDÍÀ

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.