Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”

“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”

“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”

JÈHÓFÀ sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé: “Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nígbà tí onísáàmù náà, Dáfídì ń darí àfiyèsí sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ, ó kọ ọ́ lórin pé: “O [Jèhófà] ti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà mi, o ti ṣe àbẹ̀wò ní òru, o ti yọ́ mi mọ́; ìwọ yóò ṣàwárí pé èmi kò pète-pèrò ibi.”—Sáàmù 17:3.

Lóòótọ́, Jèhófà máa ń wo inú ọkàn-àyà láti mọ irú ẹni táa jẹ́ gan-an. (Òwe 17:3) Abájọ tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fi dámọ̀ràn pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Báwo la ṣe lè fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa? Ìwé Òwe orí kẹrin fún wa ní ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn.

Fetí sí Ìbáwí Baba

Orí kẹrin ìwé Òwe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà: “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ, sí ìbáwí baba, kí ẹ sì fiyè sílẹ̀, kí ẹ lè mọ òye. Nítorí ìtọ́ni rere ni ohun tí èmi yóò fi fún yín dájúdájú. Ẹ má fi òfin mi sílẹ̀.”Òwe 4:1, 2.

Ìmọ̀ràn tí wọ́n fún àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n fetí sílẹ̀ sí ìtọ́ni yíyè kooro látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn oníwà bí Ọlọ́run, àti pàápàá èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ baba wá. Ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ gbé lé e lọ́wọ́ ni pé kí ó pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí. (Diutarónómì 6:6, 7; 1 Tímótì 5:8) Láìsí irú ìtọ́nisọ́nà bẹ́ẹ̀, á mà ṣòro gan-an fún ọ̀dọ́ kan láti dàgbà dénú o! Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí ọmọ kan fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí baba rẹ̀?

Ọ̀dọ́ tí kò ní baba tó máa tọ́ ọ sọ́nà ńkọ́? Fún àpẹẹrẹ, Jason, ọmọ ọdún mọ́kànlá ti di ẹni tí kò ní baba mọ́ látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin. a Nígbà tí Kristẹni alàgbà kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni ohun tó ń kó ìdààmú bá a jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, kíá ni Jason dáhùn pé: “Ó dùn mí pé n kò ní baba. Ó máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi gan-an nígbà mìíràn.” Síbẹ̀, ìmọ̀ràn tí ń tuni nínú wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọ̀dọ́ tí wọn ò lóbìí tó máa tọ́ wọn sọ́nà. Jason àtàwọn mìíràn bíi tirẹ̀ lè wá irú ìmọ̀ràn tí bàbá ń fúnni, kí wọ́n sì rí i gbà látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni.—Jákọ́bù 1:27.

Nígbà tí Sólómọ́nì rántí ẹ̀kọ́ tí òun alára kọ́, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo jẹ́ ọmọ gidi fún baba mi, ẹni ìkẹ́ àti ọ̀kan ṣoṣo níwájú ìyá mi.” (Òwe 4:3) Ó dájú pé tìwúrí-tìwúrí ni ọba náà fi ń rántí bí a ṣe tọ́ òun dàgbà. Níwọ̀n bí Sólómọ́nì ọ̀dọ́ ti jẹ́ “ọmọ gidi” tó ń fi ìmọ̀ràn baba sọ́kàn, ó ní láti ní ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó lárinrin pẹ̀lú Dáfídì, baba rẹ̀. Ní àfikún sí i, Sólómọ́nì jẹ́ “ọ̀kan ṣoṣo,” tàbí ààyò. Ẹ wo bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí ọmọ dàgbà nínú ilé kan tí wọ́n ti lọ́yàyà, tí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí sì ṣí sílẹ̀!

Ní Ọgbọ́n àti Òye

Nígbà tí Sólómọ́nì ń rántí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí baba rẹ̀ fún un, ó sọ pé: “Baba mi a sì máa fún mi ní ìtọ́ni, a sì máa wí fún mi pé: ‘Ǹjẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ di àwọn ọ̀rọ̀ mi mú ṣinṣin. Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè. Ní ọgbọ́n, ní òye. Má gbàgbé, má sì yà kúrò nínú àwọn àsọjáde ẹnu mi. Má fi í [ọgbọ́n] sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.’”Òwe 4:4-7.

Èé ṣe tí ọgbọ́n fi jẹ́ “ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ”? Ọgbọ́n túmọ̀ sí lílo ìmọ̀ àti òye ní ọ̀nà tí yóò mú ìyọrísí rere wá. Ìmọ̀—ìyẹn dídi ojúlùmọ̀ tàbí lílóye àwọn kókó kan tí a jèrè látinú ṣíṣàkíyèsí nǹkan àti látinú àwọn ìrírí tí a ti ní tàbí nípa kíkàwé àti kíkẹ́kọ̀ọ́—ṣe kókó, bí a óò bá ní ọgbọ́n. Àmọ́ tí a kò bá ní agbára láti lò ó lọ́nà rere, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ìmọ̀ wa yóò já sí. Kì í ṣe pé ká kàn máa ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé ka Bíbélì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè déédéé nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ní láti máa gbìyànjú láti fi àwọn ohun tí a ń kọ́ nínú wọn sílò.—Mátíù 24:45.

Ó tún pọndandan láti ni òye. Láìsí òye, ǹjẹ́ a lè rí i bí àwọn kókó kọ̀ọ̀kan ṣe so mọ́ ara wọn ní ti gidi, kí a sì wá mọ bí ọ̀ràn tí a ń gbé yẹ̀ wò náà ṣe rí gan-an? Bí a kò bá ní òye, báwo la ṣe lè mọ ìdí àti ète tí àwọn nǹkan fi ṣẹlẹ̀, kí a sì wá ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìfòyemọ̀? Lóòótọ́, ká tó lè jókòó, ká ronú jinlẹ̀ kí a sì wá ṣe ìpinnu tó tọ́, a nílò òye.—Dáníẹ́lì 9:22, 23.

Sólómọ́nì ń bá sísọ ọ̀rọ̀ tí baba rẹ̀ sọ lọ, ó ní: “Gbé e [ọgbọ́n] níyì gidigidi, yóò sì gbé ọ ga. Yóò ṣe ọ́ lógo nítorí tí o gbá a mọ́ra. Yóò fún orí rẹ ní ọ̀ṣọ́ òdòdó olóòfà ẹwà; adé ẹwà ni yóò fi jíǹkí rẹ.” (Òwe 4:8, 9) Ọgbọ́n Ọlọ́run ń dáàbò bo ẹni tí ó bá gbá a mọ́ra. Ní àfikún sí i, ó tún ń fún un ní ọ̀wọ̀, ó sì ń bẹwà kún un. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipa wa láti ní ọgbọ́n.

“Di Ìbáwí Mú”

Ní títún ìtọ́ni baba rẹ̀ sọ, ọba Ísírẹ́lì náà tún sọ pé: “Gbọ́, ọmọ mi, kí o sì tẹ́wọ́ gba àwọn àsọjáde mi. Nígbà náà ni ọdún ìwàláàyè yóò di púpọ̀ fún ọ. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà ọgbọ́n pàápàá; èmi yóò mú kí o rin àwọn òpó ọ̀nà ìdúróṣánṣán. Nígbà tí o bá ń rìn, ìṣísẹ̀rìn rẹ kì yóò há; bí o bá sì ń sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.”Òwe 4:10-13.

Gẹ́gẹ́ bí ọmọ gidi sí baba rẹ̀, Sólómọ́nì ti ní láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tó ń tọ́ni sọ́nà, tó sì ń báni wí. Láìsí ìbáwí tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, báwo la ṣe lè retí pé ká tẹ̀ síwájú di ẹni tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí tàbí kí a retí pé kí ayé wa sunwọ̀n sí i? Bí a kò bá kọ́gbọ́n látinú àwọn àṣìṣe wa, tàbí tí a bá kùnà láti ṣàtúnṣe àwọn èrò òdì tí a ní, ìlọsíwájú wa nípa tẹ̀mí yóò kéré gan-an ni. Ìbáwí tí ó mọ́gbọ́n dání ń yọrí sí ìwà bí Ọlọ́run, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti “rin àwọn òpó ọ̀nà ìdúróṣánṣán.”

Irú ìbáwí mìíràn tún ń yọrí sí mímú ‘kí ọdún ìwàláàyè wa di púpọ̀.’ Lọ́nà wo? Tóò, Jésù Kristi wí pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Ǹjẹ́ kì í ṣe bíbá ara wa wí nínú ohun tó kéré ló máa mú kó rọrùn fún wa láti bá ara wa wí nínú ohun ńlá, níwọ̀n bí ó ti lè jẹ́ pé irú nǹkan ńlá wọ̀nyí ni ìgbésí ayé wa alára sinmi lé? Fún àpẹẹrẹ, kíkọ́ ojú wa láti má ṣe máa “bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i” lè gbà wá nínú ewu ṣíṣubú sínú ìwà pálapàla. (Mátíù 5:28) Ní ti gidi, bí ìlànà yìí ṣe kan ọkùnrin bẹ́ẹ̀ náà ló kan obìnrin. Tí a bá ń bá èrò inú wa wí láti “mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè,” bóyá la lè kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe.—2 Kọ́ríńtì 10:5.

Lóòótọ́, ó sábà máa ń ṣòro láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí, ó sì lè dà bí ohun tó ń káni lọ́wọ́ kò. (Hébérù 12:11) Àmọ́, ọlọgbọ́n ọba náà mú un dá wa lójú pé tí a bá di ìbáwí mú, ipa ọ̀nà tí a ń tọ̀ yóò jẹ́ kí ó rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ síwájú. Gẹ́gẹ́ bí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yíyẹ ṣe máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún sárésáré kan láti sá eré tete láìṣubú tàbí kí ó má fara pa, bẹ́ẹ̀ náà ni dídi ìbáwí mú ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a lọ lójú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè láìdúró kí a má sì kọsẹ̀. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ipa ọ̀nà tí a yàn.

Yẹra fún “Ipa Ọ̀nà Àwọn Ẹni Burúkú”

Pẹ̀lú ẹ̀mí kánjúkánjú, Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Má wọ ipa ọ̀nà àwọn ẹni burúkú, má sì rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú. Yẹra fún un, má gbà á kọjá; yà kúrò nínú rẹ̀, kí o sì kọjá lọ. Nítorí wọn kì í sùn bí kò ṣe pé wọ́n ṣe búburú, a sì ti gba oorun lójú wọn bí kò ṣe pé wọ́n mú ẹnì kan kọsẹ̀. Nítorí wọ́n ti fi oúnjẹ ìwà burúkú bọ́ ara wọn, wáìnì ìwà ipá sì ni wọ́n ń mu.”Òwe 4:14-17.

Ìwà ibi ni àwọn ẹni búburú tí Sólómọ́nì sọ pé kí a yẹra fún fi ń ṣayọ̀. Bí ẹní jẹun tán tó mumi sí i ni ìwà ibi ṣe rí lójú wọn. Wọn ò lè sùn láìjẹ́ pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà ipá. Gbogbo ìwà tí wọ́n mọ̀ ọ́n hù, ìwà ìbàjẹ́ ni! Ǹjẹ́ a wá lè sọ pé a ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà wa táa bá ń bá wọn kẹ́gbẹ́? Ẹ wo bí yóò ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti “rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú” nípa wíwo ìwà ipá tí wọ́n máa ń hù nínú ọ̀pọ̀ jù lọ eré ìdárayá òde òní! Lílàkàkà láti jẹ́ ẹni tí ó ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ kò bára mu rárá pẹ̀lú gbígba àwọn ohun tó lè sọ ọkàn wa dí èyí tí ó yigbì sínú látinú àwọn ìwà búburú tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú àwọn sinimá.

Dúró Nínú Ìmọ́lẹ̀

Sólómọ́nì ṣì ń bá a nìṣó ní lílo ipa ọ̀nà láti ṣàkàwé, ó kéde pé: “Ṣùgbọ́n ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí a sì gbìyànjú láti fi ohun tó sọ sílò nínú ìgbésí ayé wa la lè fi wé bíbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ní ìdájí. Bí ojú ọ̀run tó dúdú kirikiri tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ́lẹ̀ díẹ̀díẹ̀, tó wá ń di àwọ̀ aró, agbára káká la fi lè rí ohunkóhun. Ṣùgbọ́n bí ilẹ̀ ti túbọ̀ ń mọ́ bọ̀ díẹ̀díẹ̀, la ó túbọ̀ máa rí àwọn ohun tó wà láyìíká wa sí i. Níkẹyìn, oòrùn á wá ràn yòò, a ó sì rí gbogbo ohun tó wà láyìíká wa ní kedere. Lọ́nà kan náà, ńṣe ni òtítọ́ yóò túbọ̀ máa ṣe kedere sí wa bí a ti ń fi sùúrù àti aápọn tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Ó pọndandan láti máa fún ọkàn-àyà wa ní oúnjẹ tẹ̀mí tí a bá fẹ́ fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ kúrò nínú ìrònú èké.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìtumọ̀ tàbí ìjẹ́pàtàkì àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣe kedere sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ túbọ̀ ń ṣe kedere sí wa bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe ń tan ìmọ́lẹ̀ sórí wọn àti bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé tàbí bí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe ń mú wọn ṣẹ. Kàkà tí a ó máa fi àìnísùúrù méfò nípa ìmúṣẹ wọn, ṣe ló yẹ kí a dúró kí ‘ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i.’

Àwọn tí wọ́n wá kọ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run sílẹ̀ nípa kíkọ̀ láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ńkọ́? Sólómọ́nì sọ pé: “Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí ìṣúdùdù; wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń kọsẹ̀ lára rẹ̀ ṣáá.” (Òwe 4:19) Àwọn ẹni burúkú dà bí ẹni tó ń kọsẹ̀ nínú òkùnkùn láìmọ ohun tó ń mú òun kọsẹ̀. Kódà nígbà tó bá dà bíi pé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ń kẹ́sẹ járí nítorí ìwà àìṣòdodo wọn, fún ìgbà díẹ̀ ni àṣeyọrí wọn náà mọ. Tìtorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni onísáàmù náà ṣe kọrin pé: “Dájúdájú, orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí ìwọ gbé wọn kà. Ìwọ [Jèhófà] ti mú kí wọ́n ṣubú ní rírún wómúwómú.”—Sáàmù 73:18.

Máa Wà Lójúfò

Ọba Ísírẹ́lì náà ń bá a lọ ní sísọ pé: “Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Dẹ etí rẹ sí àwọn àsọjáde mi. Kí wọ́n má lọ kúrò ní ojú rẹ. Pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ. Nítorí ìwàláàyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó wá wọn rí àti ìlera fún gbogbo ẹran ara wọn. Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”Òwe 4:20-23.

Àpẹẹrẹ Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí bí ìmọ̀ràn náà láti fi ìṣọ́ sọ́ ọkàn-àyà ṣe níye lórí tó. Lóòótọ́, ó “jẹ́ ọmọ gidi” fún baba rẹ̀ nígbà tó wà ní èwe, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà tó tójúúbọ́. Síbẹ̀, Bíbélì ròyìn pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn [àjèjì] aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 11:4) Bí a ò bá wà lójúfò ní gbogbo ìgbà, kódà ọkàn-àyà tí ó dára jù lọ pàápàá lè di èyí tí a ré lọ láti ṣe ohun búburú. (Jeremáyà 17:9) Àwọn ìránnilétí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ jìnnà rárá sí ọkàn-àyà wa, wọ́n gbọ́dọ̀ wà ‘ní inú rẹ̀.’ Ìtọ́sọ́nà tó wà nínú ìwé Òwe orí kẹrin sì wà lára irú àwọn ìránnilétí bẹ́ẹ̀.

Ṣàyẹ̀wò Ipò Tí Ọkàn-Àyà Rẹ Wà

Ṣé à ń kẹ́sẹ járí nínú fífi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa? Báwo la ṣe lè mọ ipò tí ẹni ti inú wà? Jésù Kristi sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Ó tún sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.” (Mátíù 15:19, 20) Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa ń sọ èyí tó pọ̀ jù lọ nípa báa ṣe jẹ́ nínú lọ́hùn-ún.

Abájọ tí Sólómọ́nì fi ṣí wa létí pé: “Mú ọ̀rọ̀ wíwọ́ kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ; sì mú békebèke ètè jìnnà réré sí ara rẹ. Ní ti ojú rẹ, ọ̀kánkán tààrà ni kí ó máa wò, bẹ́ẹ̀ ni, kí ojú rẹ títàn yanran tẹjú mọ́ ọ̀kánkán gan-an ní iwájú rẹ. Mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀, ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀nà tìrẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Má tẹ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì. Mú ẹsẹ̀ rẹ kúrò nínú ohun tí ó burú.”Òwe 4:24-27.

Nítorí ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Sólómọ́nì sọ yìí, a ní láti máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa. Bí a bá fẹ́ fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà wa kí a sì mú inú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ yẹra fún jíjẹ́ ẹlẹ́nu méjì àti jíjẹ́ oníbékebèke. (Òwe 3:32) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fi tàdúràtàdúrà ronú lórí ohun tí ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa ń fi hàn pé a jẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ kí a wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà kí a lè ṣàtúnṣe àìlera èyíkéyìí tí a bá rí.—Sáàmù 139:23, 24.

Lékè gbogbo rẹ̀, ǹjẹ́ kí ‘ojú wa máa wo ọ̀kánkán gan-an ní iwájú wa.’ Ẹ jẹ́ kí a gbájú mọ́ fífi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Baba wa ọ̀run. (Kólósè 3:23) Bí o ṣe ń lépa irú ipa ọ̀nà títọ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí Jèhófà mú ọ ṣàṣeyọrí nínú “gbogbo àwọn ọ̀nà tìrẹ,” ǹjẹ́ kí òun sì bù kún ọ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn onímìísí náà láti “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an nìyẹn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Ǹjẹ́ o máa ń yẹra fún eré ìdárayá tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn àwọn tó nírìírí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìbáwí kò lè fa ọwọ́ aago rẹ sẹ́yìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ