Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Igi Ólífì Gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nínú Ilé Ọlọ́run

Igi Ólífì Gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nínú Ilé Ọlọ́run

Igi Ólífì Gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nínú Ilé Ọlọ́run

NÍ ILẸ̀ Ísírẹ́lì, igi kan wà níbẹ̀ tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ lè sọ pé kò ṣeé pa run. Kódà táa bá gé e lulẹ̀, kíá ni kùkùté rẹ̀ á tún bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ̀mùnú. Nígbà tí olóko bá sì kóre èso rẹ̀, ó máa ń rí òróró púpọ̀ fún látinú rẹ̀, òróró tí wọ́n lè fi ṣoúnjẹ, tí wọ́n lè fi tan iná, tó tún wúlò fún ìmọ́tótó ara, tí wọ́n sì ń lò gẹ́gẹ́ bí èròjà ìṣaralóge.

Gẹ́gẹ́ bí àkàwé ìgbàanì kan tó wà nínú Bíbélì, nínú ìwé Onídàájọ́, ti wí, “nígbà kan rí, àwọn igi lọ fòróró yan ọba lórí ara wọn.” Èwo lára igi igbó ni wọ́n yàn láàyò? Èwo ni ì bá tún jẹ́, bí kì í báá ṣe igi ólífì, eléso wọ̀ǹtìwọnti, tí ẹ̀mí rẹ̀ yi.—Onídàájọ́ 9:8.

Ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dégbèjìdínlógún [3,500] ọdún sẹ́yìn, wòlíì náà Mósè pe Ísírẹ́lì ní ‘ilẹ̀ tí ó dára, ilẹ̀ ólífì.’ (Diutarónómì 8:7, 8) Àní, di báa ti ń wí yìí, àwọn oko ólífì ṣì wà káàkiri, láti ẹsẹ̀ Òkè Hámónì níhà àríwá títí dé ẹ̀yìn odi ìlú Bíá-Ṣébà níhà gúúsù. Wọ́n ṣì ń bẹwà kún Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì tí ń bẹ létíkun, àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Samáríà, àtàwọn àfonífojì ẹlẹ́tù lójú ní Gálílì.

Àwọn tó kọ Bíbélì sábà máa ń lo igi ólífì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àwọn ẹ̀yà ara igi yìí ṣàpèjúwe àánú Ọlọ́run, ìlérí àjíǹde, àti ìdílé aláyọ̀. Wíwo igi ólífì láwòfín yóò jẹ́ ká lóye nǹkan wọ̀nyí tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀, yóò sì jẹ́ ká túbọ̀ mọyì igi àrà ọ̀tọ̀ yìí tí òun pẹ̀lú ìyókù ìṣẹ̀dá jùmọ̀ ń yin Ẹlẹ́dàá rẹ̀ lógo.—Sáàmù 148:7, 9.

Igi Tó Rọ́kú Nigi Ólífì

Igi ólífì kì í sábà jọni lójú nígbà téèyàn bá kọ́kọ́ rí i. Kì í ga kan ọ̀run bí àwọn igi kédárì gàgàrà tó wà ní Lẹ́bánónì. Pákó rẹ̀ kò ṣe iyebíye tó pákó júnípà, ìtànná rẹ̀ kò sì ní àwọ̀ mèremère bí ìtànná igi álímọ́ńdì. (Orin Sólómọ́nì 1:17; Ámósì 2:9) Inú ilẹ̀ ni apá tó ṣe pàtàkì jù lọ lára igi ólífì wà—níbi tójú ò dé. Àwọn gbòǹgbò rẹ̀ atẹ́rẹrẹ, tó lè tàn dé mítà mẹ́fà lábẹ́ ilẹ̀, kí ó sì tún lọ sílẹ̀ dòò jù bẹ́ẹ̀ lọ, ló ń jẹ́ kí igi náà so tìrìgàngàn, kí ó sì rọ́kú.

Irú àwọn gbòǹgbò bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ káwọn igi ólífì tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olókùúta kú nígbà ọ̀dá, nígbà tí ọ̀gbẹlẹ̀ bá ti pa àwọn igi tí ń bẹ láfonífojì nísàlẹ̀. Gbòǹgbò rẹ̀ máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti máa sèso ólífì rẹ̀ nìṣó fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, kódà nígbà tí igi rẹ̀ ti gbẹ pátápátá, tó ti rí bí igi ìdáná. Gbogbo ohun tí igi tí ara rẹ̀ gbàyà yìí nílò ni àyè láti tẹ́ rẹrẹ, àti ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ amọ̀, èyí tí afẹ́fẹ́ lè ráyè wọ̀, àti ibi tí kò ti ní sí èpò tàbí àwọn ewéko mìíràn táwọn kòkòrò aṣèparun lè sá pa mọ́ sínú rẹ̀. Bó bá lè rí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ wọ̀nyí tó ń fẹ́, igi kan ṣoṣo lè pèsè òróró tó tó lítà mẹ́tàdínlọ́gọ́ta lọ́dún kan.

Láìsí àní-àní, òróró oníyebíye tó ń tara èso ólífì wá ló sọ igi yìí di ààyò fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn fìtílà olówùú, tó ń lo epo ólífì, ló máa ń fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ nínú ilé wọn. (Léfítíkù 24:2) Kòṣeémánìí lòróró ólífì fẹ́ní bá fẹ́ ṣoúnjẹ. Ó ń dáàbò bo awọ ara kúrò lọ́wọ́ oòrùn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń fi òróró yìí ṣe ọṣẹ. Ọkà, wáìnì, àti ólífì ni lájorí irè ilẹ̀ náà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé tí igi ólífì ò bá so dáadáa, wàhálà so nìyẹn fún ìdílé Ísírẹ́lì.—Diutarónómì 7:13; Hábákúkù 3:17.

Àmọ́ o, òróró ólífì kì í wọ́n wọn. Mósè pe Ilẹ̀ Ìlérí ní ‘ilẹ̀ ólífì,’ bóyá nítorí pé ólífì nigi tí wọ́n ń gbìn jù lọ lágbègbè yẹn. Onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, H. B. Tristram, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, pe ólífì ní “igi tó wọ́pọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè náà.” Nítorí ìníyelórí òróró ólífì àti bó ṣe pọ̀ tó, wọ́n tilẹ̀ máa ń ná an gẹ́gẹ́ bí owó jákèjádò àgbègbè Mẹditaréníà. Àní Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa gbèsè kan tí wọ́n ṣírò pé ó jẹ́ “ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n báàfù òróró ólífì.”—Lúùkù 16:5, 6.

“Bí Àwọn Àgélọ́ Igi Ólífì”

Ó sì ṣe wẹ́kú pé igi ólífì tó wúlò gan-an yìí dúró fún ìbùkún àtọ̀runwá. Kí lèrè ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run? Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Aya rẹ yóò dà bí àjàrà tí ń so èso ní ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ilé rẹ. Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn àgélọ́ igi ólífì yí tábìlì rẹ ká.” (Sáàmù 128:3) Kí ni “àgélọ́ igi ólífì” wọ̀nyí, kí sì ni ìdí tí onísáàmù fi fi wọ́n wé ọmọ?

Igi ólífì tún yàtọ̀ ní ti pé ó máa ń yọ ọ̀mùnú láti ìdí igi rẹ̀. a Tó bá di pé igi yìí ti lọ́jọ́ lórí gan-an, tí kò sì lè so bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, àwọn aroko lè jẹ́ kí àwọn ẹ̀ka kéékèèké, tàbí ọ̀mùnú tuntun mélòó kan dàgbà di ńlá títí tí wọ́n fi máa di apá kan igi náà. Tó bá yá, igi àkọ́kọ́ yẹn á wá ní igi gbọ̀ngbọ̀nrọ̀n mẹ́tà tàbí mẹ́rin tó yí i ká, bí ìgbà táwọn ọmọ yí tábìlì ká. Gbòǹgbò kan náà ló gbé tọmọ-tìyá ró, wọ́n sì jọ ń so àsokún, àsogbó èso ólífì ni.

Ànímọ́ yìí tí igi ólífì ní, ṣe wẹ́kú pẹ̀lú bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣe lè dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, bóyá torí gbòǹgbò tẹ̀mí tó dúró sán-ún táwọn òbí wọ́n ní. Bí àwọn ọmọ wọ̀nyí ti ń dàgbà, àwọn náà á bẹ̀rẹ̀ sí so èso, wọ́n á sì máa ti àwọn òbí wọn lẹ́yìn, àwọn òbí tí inú wọn ń dùn pé ọmọ àwọn ń sin Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn.—Òwe 15:20.

“Ìrètí Wà fún Igi Pàápàá”

Inú bàbá àgbàlagbà tó ń sin Jèhófà máa ń dùn sáwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn ọmọ yìí kan náà máa ń ṣọ̀fọ̀ nígbà tí bàbá wọn bá ‘lọ sí ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé’ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (1 Àwọn Ọba 2:2) Kí irú ọ̀fọ̀ ìdílé bẹ́ẹ̀ má bàa gbò wá jù, Bíbélì mú un dá wa lójú pé àjíǹde wà.—Jòhánù 5:28, 29; 11:25.

Jóòbù, tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ púpọ̀, mọ̀ pé ọjọ́ ayé wa kúrú gan-an ni. Ó fi wé ìtànná tí kì í pẹ́ rọ. (Jóòbù 1:2; 14:1, 2) Jóòbù yán hànhàn fún ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àjàbọ́ kúrò nínú ìroragógó rẹ̀, ó sì wo sàréè gẹ́gẹ́ bí ibi ìlùmọ́ tó ṣeé lọ ní àlọbọ̀. Jóòbù béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Ó wá dáhùn láìmikàn pé: “Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé. Ìwọ [Jèhófà] yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 14:13-15.

Àpèjúwe wo ni Jóòbù lò láti fi hàn pé ó dá òun lójú pé Ọlọ́run yóò pe òun jáde látinú sàréè? Àpèjúwe igi kan ló lò, bó sì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé igi ólífì ló ń sọ̀rọ̀ bá. Jóòbù sọ pé: “Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù.” (Jóòbù 14:7) Wọ́n lè gé igi ólífì lulẹ̀, ṣùgbọ́n ìyẹn ò ní kó kú. Àfi bí wọ́n bá hú u tigbòǹgbò-tigbòǹgbò nìkan ló fi lè kú. Bí nǹkan kan ò bá ṣe àwọn gbòǹgbò rẹ̀, igi náà á tún gbéra sọ lákọ̀tun ni.

Kódà bí ọ̀dá bá dá lọ títí, tó sì mú kí ògbólógbòó igi ólífì gbẹ dénú, síbẹ̀síbẹ̀, igi gbígbẹ yẹn ṣì lè sọ jí. “Bí gbòǹgbò rẹ̀ bá di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú nínú ekuru, nígbà tí ó bá gbọ́ ìtasánsán omi, yóò hù, yóò sì mú ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun wá dájúdájú.” (Jóòbù 14:8, 9) Ilẹ̀ gbígbẹ, tó jẹ́ eléruku ni Jóòbù ń gbé, bóyá ó sì ti ṣàkíyèsí ọ̀pọ̀ ògbólógbòó kùkùté igi ólífì tó jọ pé wọ́n ti gbẹ dà nù, tó jọ pé wọ́n ti kú fin-ínfin-ín. Àmọ́ nígbà tójò bá dé, ṣe ni irú “òkú” igi bẹ́ẹ̀ á tún sọ jí, tí ọ̀mùnú á tún yọ láti ara gbòǹgbò rẹ̀, àfi bí ẹni pé “ọ̀gbìn tuntun” ni. Rírọ́kú tí igi yìí rọ́kú, ló jẹ́ kí ará Tunisia kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa iṣẹ́ ọ̀gbìn sọ pé: “Èèyàn lè sọ pé igi ólífì kì í kú.”

Gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ kan yóò ti máa fi tọkàntara wọ̀nà fún ìgbà tí àwọn igi ólífì rẹ̀ yóò sọ jí, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ń fẹ́ gidigidi láti jí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ dìde. Ó ń wọ̀nà fún àkókò tí àwọn olóòótọ́ bí Ábúráhámù àti Sárà, Ísákì àti Rèbékà, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn yóò padà wà láàyè. (Mátíù 22:31, 32) Ẹ wo bí yóò ti lárinrin tó láti kí àwọn òkú káàbọ̀, kí a sì rí wọ́n bí wọ́n ti ń gbádùn ìgbésí ayé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i!

Igi Ólífì Ìṣàpẹẹrẹ

Ọlọ́run fi àánú rẹ̀ hàn ní ti pé kò ṣe ojúsàájú, àti ní ti pé ó ti ṣètò àjíǹde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi igi ólífì ṣàpèjúwe bí àánú Jèhófà ṣe nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn, láìka ibi tí wọ́n ti wá tàbí ipò tí wọ́n wà sí. Tipẹ́tipẹ́ làwọn Júù ti ń yangàn pé àwọn làyànfẹ́ Ọlọ́run, ‘àwọn lọmọ Ábúráhámù.’—Jòhánù 8:33; Lúùkù 3:8.

Pé a bí ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí ọmọ orílẹ̀-èdè Júù kò túmọ̀ sí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kó rí ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n o, Júù ni gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn tí Jésù kọ́kọ́ ní, wọ́n sì ní àǹfààní jíjẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ táa ṣèlérí fún Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Gálátíà 3:29) Pọ́ọ̀lù fi àwọn Júù ọmọ ẹ̀yìn yìí wé àwọn ẹ̀ka igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ.

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù àbínibí ló kọ Jésù, èyí ni kò jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti jẹ́ mẹ́ńbà “agbo kékeré,” tàbí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nígbà táǹfààní yẹn yọ. (Lúùkù 12:32; Gálátíà 6:16) Nítorí èyí, wọ́n dà bí ẹ̀ka ólífì ìṣàpẹẹrẹ táa gé dà nù. Àwọn wo ló máa rọ́pò wọn? Lọ́dún 36 Sànmánì Tiwa, a yan àwọn Kèfèrí láti di ara irú ọmọ Ábúráhámù. Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà lọ́ àwọn ẹ̀ka ólífì ti ìgbẹ́ sára igi ólífì inú ọgbà. Àwọn tí yóò para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù táa ṣèlérí yóò ní àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè nínú. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí lè wá di “alájọpín nínú gbòǹgbò ọ̀rá ólífì náà.”—Róòmù 11:17.

Lójú àgbẹ̀ kan, lílọ́ ẹ̀ka ólífì ti ìgbẹ́ sára igi ólífì inú ọgbà kò ṣeé ronú kàn, ó sì “lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Róòmù 11:24) Ìwé The Land and the Book ṣàlàyé pé: “Lọ́ èyí tó dáa sára ti ìgbẹ́, yóò sì borí ti ìgbẹ́, gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Lárúbáwá, ṣùgbọ́n béèyàn bá ṣe é ní àtoríkòdì, kò ní bímọ re.” Ìyẹn ló fi jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni nígbà tí Jèhófà “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 10:44-48; 15:14) Èyí ló wá jẹ́ àmì tó ṣe kedere pé Ọlọ́run ò gbára lé orílẹ̀-èdè èyíkéyìí kí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tó lè kẹ́sẹ járí. Nítorí pé “ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:35.

Pọ́ọ̀lù sọ pé níwọ̀n bí a ti gé “àwọn ẹ̀ka” igi ólífì, ìyẹn, àwọn Júù aláìṣòótọ́, sọnù, ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá fi ẹ̀mí ìgbéraga àti àìgbọràn kọ ojú rere Jèhófà sílẹ̀. (Róòmù 11:19, 20) Èyí fi hàn gbangba pé a ò gbọ́dọ̀ fojú kéré inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.—2 Kọ́ríńtì 6:1.

Fífi Òróró Para

Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí ìlò òróró ólífì, ní ti gidi àti lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Láyé ọjọ́un, wọ́n máa ‘ń fi òróró tu’ ojú ọgbẹ́ àti ara bíbó kí ó lè tètè sàn. (Aísáyà 1:6) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù ṣe fi hàn, ọkùnrin ará Samáríà náà tó jẹ́ aládùúgbò rere fòróró ólífì àti wáìnì pa ojú ọgbẹ́ ọkùnrin tó ṣalábàápàdé lójú ọ̀nà Jẹ́ríkò.—Lúùkù 10:34.

Títa òróró síra ẹni lórí ń mórí yá gágá, ó sì ń tuni lára. (Sáàmù 141:5) Nígbà táwọn Kristẹni alàgbà bá sì ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ àìsàn tẹ̀mí, wọ́n lè ‘fi òróró pa orí mẹ́ńbà ìjọ ní orúkọ Jèhófà.’ (Jákọ́bù 5:14) Ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ látinú Ìwé Mímọ́ táwọn alàgbà fi fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí àti àdúrà àtọkànwá tí wọ́n gbà sí i lórí la fi wé òróró ólífì tí ń tuni lára. Ohun kan tó gbàfiyèsí rèé pé, nígbà míì, àkànlò èdè táwọn Hébérù ń lò fún ẹni rere ni “ojúlówó òróró ólífì.”

“Igi Ólífì Gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nínú Ilé Ọlọ́run”

Lójú gbogbo ohun táa ti sọ lókè yìí, kò yani lẹ́nu pé a lè fi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wé igi ólífì. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì láti jẹ́ “igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run.” (Sáàmù 52:8) Gẹ́gẹ́ bí igi ólífì ti máa ń yí ilé àwọn ìdílé Ísírẹ́lì ká, bẹ́ẹ̀ náà ni Dáfídì fẹ́ láti sún mọ́ Jèhófà, kí ó sì máa sèso fún ìyìn Ọlọ́run.—Sáàmù 52:9.

Nígbà tí ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà, ńṣe ló dà bí “igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, tí ó rẹwà nínú èso àti ní ìrísí.” (Jeremáyà 11:15, 16) Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn Júdà pàdánù àǹfààní yẹn nígbà tí ‘wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì wá ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.’—Jeremáyà 11:10.

Táa bá fẹ́ jẹ́ igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, a ní láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, kí a sì múra tán láti gba ìbáwí tó fi “ń tọ́” wa, kí a bàa lè túbọ̀ máa sèso tó yẹ Kristẹni. (Hébérù 12:5, 6) Ní àfikún sí i, gan-an gẹ́gẹ́ bí igi ólífì gidi ti nílò àwọn gbòǹgbò tó tẹ́ rẹrẹ kí ó má bàa kú nígbà ọ̀gbẹlẹ̀, ó pọndandan pé kí àwa náà fún gbòǹgbò wa nípa tẹ̀mí lókun, kí a lè fàyà rán ìdánwò àti inúnibíni.—Mátíù 13:21; Kólósè 2:6, 7.

Igi ólífì ṣàpèjúwe Kristẹni olóòótọ́ gan-an ni, ẹni tí ayé ò kà sí, ṣùgbọ́n tó gbayì lójú Ọlọ́run. Bírú ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kú nínú ètò yìí, yóò tún wà láàyè nínú ayé tuntun tó ń bọ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:9; 2 Pétérù 3:13.

Igi ólífì tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ lè sọ pé kò ṣeé pa run, tó ń so láti ọdún dé ọdún, rán wa létí ìlérí Ọlọ́run, pé: “Bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:22) Ìlérí táa sọ tẹ́lẹ̀ yẹn yóò nímùúṣẹ nínú ayé tuntun Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọdọọdún ni wọ́n sábà máa ń rẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀mùnú tó bá yọ, kí wọ́n má bàa gba gbogbo agbára tó wà lára igi náà tán.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Igi ólífì kan tó ti gbẹ pátápátá, táa rí nílùú Jávea, Ẹkùn Ilẹ̀ Alicante, lórílẹ̀-èdè Sípéènì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Oko ólífì ní Ẹkùn Ilẹ̀ Granada, lórílẹ̀-èdè Sípéènì

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 26]

Igi ólífì àtayébáyé lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 26]

Bíbélì mẹ́nu kan lílọ́ àwọn ẹ̀ka sára igi ólífì

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn ẹ̀ka àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ló yí ògbólógbòó igi ólífì yìí ká