Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Borí Ìtìjú

Ó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Borí Ìtìjú

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Borí Ìtìjú

GẸ́GẸ́ BÍ RUTH L. ULRICH ṢE SỌ Ọ́

Ó dùn mí wọnú eegun, ni mo bá bú sẹ́kún gbẹ̀ẹ́ lójúde àlùfáà. Ńṣe ni ẹ̀sùn èké ń pe ẹ̀sùn èké rán níṣẹ́ bí àlùfáà náà ti tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀, tó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹ̀sùn èké kan Charles T. Russell, tí í ṣe ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Bible and Tract Society. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí èmi ọmọbìnrin pínníṣín nígbà yẹn, ṣe ń ṣe irú àwọn àbẹ̀wò yẹn sọ́dọ̀ àwọn èèyàn.

ÌDÍLÉ tí kò fọ̀ràn ẹ̀sìn ṣeré rárá la bí mi sí lábúlé kan ní Ìpínlẹ̀ Nebraska, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1910. Ìdílé wa máa ń ka Bíbélì pa pọ̀ láràárọ̀ àti lálaalẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Bàbá mi ló ń bójú tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ti Ìjọ Mẹ́tọ́díìsì ní ìlú kékeré Winside, tí kò ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́fà lọ sóko wa. A ní kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan tó nílé lórí, táa taṣọ bo àwọn ojú fèrèsé rẹ̀, ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní tòjò-tẹ̀rùn, a kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ láràárọ̀ Sunday.

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bíi ọmọ ọdún mẹ́jọ, àrùn rọpárọsẹ̀ kọlu àbúrò mi ọkùnrin, màmá mi sì gbé e lọ sílé ìtọ́jú kan ní Ìpínlẹ̀ Iowa. Pẹ̀lú gbogbo ìsásókè sá sódò màmá mi, àbúrò mi kú sí ilé ìtọ́jú yẹn. Àmọ́ o, kí màmá mi tó padà wálé láti Ìpínlẹ̀ Iowa, ó pàdé ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn lorúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn. Ọ̀rọ̀ pọ̀ tí wọ́n jọ sọ, màmá mi tiẹ̀ bá obìnrin náà lọ sáwọn ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìgbà tí màmá mi padà dé, ìdìpọ̀ mélòó kan ìwé Studies in the Scriptures, tí Watch Tower Society tẹ̀, ló kó bọ̀. Kò pẹ́ tó dá a lójú pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń fi òtítọ́ kọ́ni, àti pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn àti ìdálóró ayérayé fún àwọn olubi.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Àmọ́ ṣe ni Bàbá tutọ́ sókè tó fojú gbà á, tó ní kì í ṣojú òun ni Màmá á ti máa lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń mú èmi àti Clarence, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, dání lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣùgbọ́n nígbà tí Bàbá kò bá sí nílé, Màmá máa ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwa ọmọ láǹfààní dáadáa láti fi ẹ̀kọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wé ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wa.

Èmi àti Clarence kì í pa ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi tó máa ń wáyé ní ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, ẹ̀gbọ́n mi sì máa ń bi obìnrin to ń kọ́ wa láwọn ìbéèrè tí kì í lèé dáhùn. Nígbà táa bá délé, àá sọ fún màmá wa, èyí sì máa ń yọrí sáwọn ìjíròrò gígùn lórí kókó wọ̀nyí. Níkẹyìn, mo pa ṣọ́ọ̀ṣì tì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú màmá mi, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí Clarence náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé.

Bíborí Ìtìjú

Ní September 1922, èmi àti màmá mi lọ sí ìpàdé àgbègbè mánigbàgbé táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú Cedar Point, Ohio. Mo ṣì ń wò ó báyìí, bí wọ́n ṣe ṣí àkọlé gàdàgbà yẹn, nígbà tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn, fi ọ̀rọ̀ tó wà lára àkọlé náà rọ àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbàásàn-án [18,000] tó wà níjokòó, pé: “Ẹ Fọnrere Ọba náà àti Ìjọba Rẹ̀.” Orí mi wú, mo sì rí i pé ó jẹ́ kánjúkánjú láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 6:9, 10; 24:14.

Nígbà àwọn ìpàdé àgbègbè táa ṣe látọdún 1922 sí 1928, a ṣe ọ̀wọ́ àwọn ìpinnu kan, wọ́n sì kọ ìsọfúnni tó wà nínú ìpinnu wọ̀nyí sínú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dà wọn fáwọn èèyàn jákèjádò ayé. Èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́, agùntáṣọọ́lò ni mí—wọ́n sì máa ń pè mí ni ajá ọdẹ—ẹsẹ̀ mi yá bí nǹkan míì, bí mo ti ń lọ láti ilé dé ilé tí mo ń pín àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí. Mo gbádùn iṣẹ́ yìí gan-an. Àmọ́ o, bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ojúlé dé ojúlé, bíbá wọn sọ̀rọ̀ lójúkojú nípa Ìjọba Ọlọ́run, máa ń ni mí lára gan-an.

Ẹ wò ó, ojú máa ń tì mí débi pé ẹ̀rù máa ń bà mí gan-an nígbà tí Màmá bá ké sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí wá sílé wa lọ́dọọdún. Ńṣe ni mo máa ń sá wọ yàrá mi lọ, tí màá sì jókòó pa síbẹ̀. Nígbà kan, màmá mi fẹ́ kí gbogbo ẹbí jọ ya fọ́tò, ó sì ní kí n jáde wá. Níwọ̀n bí n kò ti fẹ́ dara pọ̀ mọ́ wọn, ṣe ni mo figbe bọnu bó ṣe ń wọ́ mi tuurutu jáde kúrò nínú yàrá mi.

Àmọ́, ó wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan, tí mo ní òní lòní ń jẹ́, tí mo sì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú àpò. Léraléra ni mo ń sọ pé, “Mi ò lè ṣe é,” ṣùgbọ́n tó bá yá, màá tún sọ fún ara mi pé, “Mo fẹ́, mo kọ̀, màá ṣe é.” Níkẹyìn, bí mo ṣe lọ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nìyẹn. Lẹ́yìn náà, inú mi dùn gan-an pé mo lo ìgboyà, mo sì lọ. Kì í ṣe iṣẹ́ tí mo lọ ṣe gan-an ló fún mi láyọ̀ jù lọ, bí kò ṣe nítorí pé mo lọ mo bọ̀ mi ò bọmọ jẹ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo ṣalábàápàdé àlùfáà tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ pé ẹkún ni mo sun kúrò nílé ẹ̀. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láti ojúlé dé ojúlé, ayọ̀ mi sì kún. Nígbà tó wá di ọdún 1925 ni mo fàmì ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo fi owó tí mo jogún látọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n ìyá mi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní ọdún 1930, èmi àti aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi kan tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n yàn fún wa. Clarence náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nígbà yẹn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, èyíinì ni orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York.

Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn òbí wa pínyà, nítorí náà èmi àti Màmá ra ọkọ̀ àfiṣelé kan, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà pọ̀. Àkókò yẹn ni Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé bẹ̀rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Bíbá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó wá le koko bí ojú ẹja, ṣùgbọ́n àwa náà pinnu pé ohun tó bá gbà la máa fún un, a ò ní jáwọ́. A máa ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gba adìyẹ, ẹyin, àtàwọn èso inú ọgbà, kódà a fi ń gba àwọn nǹkan bíi ògbólógbòó bátìrì àti àlòkù tánganran. Ńṣe la máa ń ta àwọn nǹkan táa mẹ́nu kàn gbẹ̀yìn yìí, tí a ó sì fowó rẹ̀ ra epo sọ́kọ̀, tàbí ká fi gbọ́ àwọn bùkátà míì. Mo tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi gírísì pa ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń pààrọ̀ epo inú ẹ́ńjìnnì, láti lè dín ìnáwó kù. Jèhófà kò gbàgbé ìlérí rẹ̀, a rí i pé ó ṣí ọ̀nà ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀ tó jẹ́ ká borí àwọn òkè ìṣòro wa.—Mátíù 6:33.

Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Yá

Lọ́dún 1946, mo rí ìkésíni gbà pé kí n wá sí kíláàsì keje ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, tó wà nítòsí South Lansing, New York. Nígbà yẹn, èmi àti Màmá ti jọ ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, síbẹ̀ kò fẹ́ di igi wọ́rọ́kọ́ tí í daná rú, tó máa dènà àǹfààní tí mo ní láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Nítorí náà, ó fún mi níṣìírí láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní náà láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege, èmi àti Martha Hess, tó wá láti ìlú Peoria, ní Ìpínlẹ̀ Illinois, ni wọ́n pín pa pọ̀. Wọ́n yan àwa, àtàwọn arábìnrin méjì míì, sílùú Cleveland, ní Ìpínlẹ̀ Ohio, fún ọdún kan táa fi ń dúró de iṣẹ́ tí wọ́n máa yàn fún wa lókè òkun.

Iṣẹ́ yẹn dé ní 1947. Wọ́n yan èmi àti Martha sí Hawaii. Níwọ̀n bí ó ti rọrùn láti gba ìwé àṣẹ fún wíwọ erékùṣù wọ̀nyí, màmá mi wá ń gbé nítòsí wa nílùú Honolulu. Àìlera rẹ̀ túbọ̀ ń le sí i, nítorí náà, ní àfikún sí ṣíṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, mo tún ń tọ́jú màmá mi. Mo tọ́jú ẹ̀ títí ó fi filẹ̀ ṣaṣọ bora ní Hawaii lọ́dún 1956, lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin. Nígbà táa délẹ̀ yìí, nǹkan bíi àádóje Ẹlẹ́rìí ló wà ní Hawaii, àmọ́ nígbà yẹn tí màmá mi kú, wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún, wọn ò sì nílò míṣọ́nnárì mọ́.

Nígbà náà ni èmi àti Martha gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Watch Tower Society pé ká kọjá sí Japan. Ohun tó kọ́kọ́ kó ìrònú bá wa ni pé bóyá la ó fi lè kọ́ èdè Japan mọ́ níbi tọ́jọ́ orí wa dé yìí. Ẹni ọdún méjìdínláàádọ́ta ni mí nígbà yẹn, ọdún mẹ́rin péré sì ni mo fi ju Martha lọ. Àmọ́ a fi gbogbo rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, a sì gbà láti lọ.

Kété lẹ́yìn ìpàdé àgbáyé táa ṣe ní Yankee Stadium àti Polo Grounds ní New York City, a wọkọ̀ òkun, ó di ìlú Tokyo. Ìjì líle ló kí wa káàbọ̀ sí èbúté Yokohama, níbi tí Don àti Mabel Haslett, Lloyd àti Melba Barry, àtàwọn míṣọ́nnárì míì, ti wá pàdé wa. Nígbà yẹn, kìkì ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [1,124] Ẹlẹ́rìí ló wà ní Japan.

Ojú ẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Japan, táa sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ojúlé dé ojúlé. A fi ábídí èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Japan táa fẹ́ sọ, a ó sì kà á jáde. Onílé á wá fèsì pé, “Yoroshii desu” tàbí, “Kekko desu,” tí wọ́n sọ pé ó túmọ̀ sí, “Ó dáa” tàbí, “Kò burú.” Ṣùgbọ́n a kì í sábàá mọ̀ bóyá onílé fìfẹ́ hàn ni o, tàbí kò fìfẹ́ hàn, torí pé ọ̀rọ̀ kan náà yẹn lẹni tí ò fẹ́ gbọ́ máa sọ. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn sinmi lé ohùn tí wọ́n bá fi sọ ọ́ tàbí ojú onítọ̀hún. Ó gbà wá lákòókò ká tó mọ èwo lèwo.

Àwọn Ìrírí Tó Múnú Mi Dùn

Pẹ̀lú ìwọ̀nba tá-tà-tá tí mo gbọ́ nínú èdè yẹn, lọ́jọ́ kan mo gbéra ó di ilé elérò púpọ̀ tí Iléeṣẹ́ Mitsubishi kọ́, mo sì pàdé obìnrin kan níbẹ̀ tó jẹ́ ẹni ogún ọdún. Ìmọ̀ Bíbélì tètè wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1966. Ọdún kan lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn tó di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ó ṣì wà lẹ́nu rẹ̀ títí dòní. Ó sábà máa ń jẹ́ ìwúrí fún mi láti rí bó ṣe lo àkókò àti okun rẹ̀ láti ìgbà èwe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Dídúró ṣinṣin fún òtítọ́ Bíbélì jẹ́ ìpèníjà ńlá, àgàgà fáwọn tó ń gbé láwùjọ tí kì í ṣe tàwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni. Síbẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ti kojú ìpèníjà yìí, àwọn kan tí mo ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì wà lára wọn. Wọ́n ti wó àwọn ibi ìrúbọ tí wọ́n fi owó ribiribi kọ́, tí wọ́n ń lò nínú ẹ̀sìn Búdà àtàwọn pẹpẹ ẹlẹ́sìn Ṣintó tí kì í wọ́n nínú ilé àwọn ará Japan. Níwọ̀n bí àwọn ẹbí ti lè gbà á sódì, kí wọ́n ka irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí àìbọ̀wọ̀ fáwọn baba ńlá tó ti kú, ó gba ìgboyà fáwọn ẹni tuntun láti ṣe èyí. Ìgbésẹ̀ onígboyà wọn máa ń ránni létí àwọn Kristẹni ìjímìjí tó kó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn èké dà nù.—Ìṣe 19:18-20.

Mo rántí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, tí í ṣe ìyàwó ilé, tó ń wéwèé láti ṣí kúrò nílùú Tokyo tòun ti ìdílé rẹ̀. Ó fẹ́ kó lọ sílé tuntun tí kò ní nǹkan kan tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà. Nítorí náà, ó bá ọkọ rẹ̀ sọ ọ́, ọkọ rẹ sì fọwọ́ sí i. Obìnrin náà fi tayọ̀tayọ̀ sọ fún mi nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ó wá rántí pé òun di ọ̀wọ́nlọ́wọ̀n-ọ́n àwo òdòdó kan, tí a fi mábìlì ṣe, èyí tí ó rà nítorí tí wọ́n sọ pé á jẹ́ kí ilé tùbà kó tùṣẹ, mẹ́rù. Àmọ́ ominú ń kọ ọ́ pé àfàìmọ̀ kí àwo náà má tan mọ́ ìjọsìn èké, bó ṣe fi òòlù fọ́ ọ nìyẹn, tó sì kó o dà nù.

Rírí obìnrin yìí àtàwọn míì tí wọ́n fínnúfíndọ̀ kó àwọn nǹkan tó gbówó lórí tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn èké dà nù, tí wọ́n sì fi tìgboyà-tìgboyà bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, jẹ́ ìrírí alárinrin, tó sì ń mú inú mi dùn. Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà déédéé pé mo ti gbádùn ohun tó lé ní ogójì ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní Japan.

“Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu” Lóde Òní

Nígbà tí mo bá wẹ̀yìn wò, tí mo ronú lórí ohun tó ju àádọ́rin ọdún tí mo ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, lójú tèmi iṣẹ́ ìyanu òde òní ni wọ́n jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ onítìjú, mi ò lè ronú láé pé mo lè lo gbogbo ìgbésí ayé mi nínú lílọ máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba kan táwọn èèyàn púpọ̀ jù lọ kò fẹ́ gbọ́ nípa rẹ̀ rárá. Kì í tiẹ̀ ṣe pé mo ṣe ìyẹn nìkan ni, àmọ́ mo tún ti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn míì, bí wọn ò bá tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún pàápàá, tí wọ́n ti ṣe ohun kan náà. Wọ́n sì ti ṣe é lọ́nà tó gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún kan tó wà ní Japan nígbà tí mo débẹ̀ lọ́dún 1958 ti lé ní ọ̀kẹ́ mọ́kànlá ó lé lẹ́gbàá [222,000] lónìí!

Nígbà tí èmi àti Martha kọ́kọ́ dé Japan, ẹ̀ka iléeṣẹ́ nílùú Tokyo ni wọ́n fi wá wọ̀ sí. Ní 1963, wọ́n kọ́ ilé tuntun kan tó jẹ́ alájà mẹ́fà sórí ilẹ̀ yẹn, ibẹ̀ la sì ń gbé látìgbà yẹn. Ní November 1963, a wà lára ẹni mẹ́tàlélọ́gọ́jọ [163] tó gbọ́ àsọyé ìyàsímímọ́ látẹnu Lloyd Barry, alábòójútó ẹ̀ka wa. Nígbà yẹn, iye àwa Ẹlẹ́rìí tó wà ní Japan ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta.

Ohun ìdùnnú ló jẹ́ láti rí i bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ti gbèrú lọ́nà tó bù yààrì, tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000] lọ́dún 1972 nígbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ẹ̀ka tuntun tó fẹ̀, táa kọ́ sílùú Numazu. Ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ọdún 1982, àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà tó wà ní Japan ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́rin [68,000], a sì wá kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó tún tóbi sí i sílùú Ebina, tó jẹ́ nǹkan bíi ọgọ́rin kìlómítà sí Tokyo.

Láàárín àkókò yìí la tún ilé ẹ̀ka ti tẹ́lẹ̀, tó wà ní àárín gbùngbùn Tokyo ṣe. Nígbà tó yá, ó wá di ilé àwọn míṣọ́nnárì tó lé ní ogún, àwọn tó ti sìn ní Japan fún ogójì tàbí àádọ́ta ọdún, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, títí kan èmi náà àti Martha Hess, táa ti jọ ń bára wa bọ̀ tipẹ́. Dókítà kan àti aya rẹ̀, tó jẹ́ nọ́ọ̀sì, wà lára àwọn táa jọ ń gbélé wa. Àwọn ló ń tọ́jú wa, tí wọ́n ń ṣaájò wa. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nọ́ọ̀sì míì tún pẹ̀lú wọn, àwọn Kristẹni arábìnrin sì máa ń wá lójoojúmọ́ láti wá ran àwọn nọ́ọ̀sì lọ́wọ́. Àwọn méjì tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì nílùú Ebina máa ń wá gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn láti wá gbọ́ oúnjẹ fún wa, àti láti wá gbá ilé wa mọ́ tónítóní. Ká sòótọ́, oore Jèhófà pọ̀ lórí wa.—Sáàmù 34:8, 10.

Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì lóṣù November tó kọjá, ìyẹn ọdún mẹ́rìndínlógójì lẹ́yìn ìyàsímímọ́ ilé tí ọ̀pọ̀ àwa míṣọ́nnárì ọlọ́jọ́ pípẹ́ ń gbé báyìí. Ní November 13, 1999, mo wà lára iye àwọn tó lé ní 4,486, ní àfikún sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ọlọ́jọ́ pípẹ́ láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlógójì, tó pésẹ̀ síbi ìyàsímímọ́ àwọn ìmúgbòòrò táa ṣe sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society tó wà ní Ebina, Japan. Ní báyìí, nǹkan bíi ẹgbẹ̀ta ó lé láàádọ́ta [650] ni mẹ́ńbà ìdílé ẹ̀ka yẹn.

Jèhófà, ọ̀ránmọ-níṣẹ́-fàyàtì-í, ti fún mi lókun jálẹ̀jálẹ̀ ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin ọdún láti ìgbà tí mo fìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ ìhìn Bíbélì láti ilé dé ilé. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìtìjú mi. Ó dá mi lójú hán-ún pé Jèhófà lè lo ẹnikẹ́ni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, kódà àwọn tó máa ń tijú gan-an bíi tèmi. Ẹ sì wo bí ayé mi ti dáa, tó sì dùn tó, bí mo ti ń bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àti màmá mi àti Clarence, nígbà tó wá bẹ̀ wá wò láti Bẹ́tẹ́lì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn ọmọ kíláàsì wa, tí wọ́n ń kàwé lórí koríko tútù yọ̀yọ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nítòsí ìlú South Lansing, New York

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Apá òsì: Èmi, Martha Hess, àti màmá mi, ní Hawaii

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Apá ọ̀tún: Àwọn táa jọ ń gbé ilé míṣọ́nnárì ní Tokyo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Nísàlẹ̀: Èmi àti Martha Hess, táa ti jọ ń bára wa bọ̀ tipẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

A ṣe ìyàsímímọ́ ìmúgbòòrò ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Ebina ní November ọdún tó kọjá