Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀tọ̀ Lohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà “Kristẹni” Wá Túmọ̀ sí Ní Báyìí?

Ṣé Ọ̀tọ̀ Lohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà “Kristẹni” Wá Túmọ̀ sí Ní Báyìí?

Ṣé Ọ̀tọ̀ Lohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà “Kristẹni” Wá Túmọ̀ sí Ní Báyìí?

KÍ NI jíjẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí? Báwo lo ṣe máa dáhùn? Ìbéèrè yìí gan-an ni wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bíi mélòó kan tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, díẹ̀ lára ìdáhùn wọn sì nìyí:

“Títẹ̀lé Jésù ká sì máa ṣe bíi tirẹ̀.”

“Jíjẹ́ ẹni rere, ká sì tún lawọ́.”

“Ká gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà.”

“Ká máa lọ sí Máàsì, ká máa ka Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà, ká sì máa gba Ara Olúwa.”

“Èmi ò gbà pé ó dìgbà tóo bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kóo tó di Kristẹni.”

Kódà onírúurú ìtumọ̀ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ló wà nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè. Àní ọ̀nà mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìwé kan gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “Kristẹni,” látorí “gbígba Jésù Kristi gbọ́ tàbí jíjẹ́ ẹlẹ́sìn Jésù Kristi” dórí “jíjẹ́ ọmọlúwàbí tàbí ẹni àyẹ́sí láwùjọ.” Abájọ tó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣàlàyé ohun tí jíjẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí.

Àṣà Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́

Lóde òní, láàárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni—kódà láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń lo àga ìwàásù kan náà—èèyàn lè rí bí èrò wọn ṣe yàtọ̀ síra pátápátá lórí àwọn irú kókó bíi jíjẹ́ tí Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí, ẹ̀kọ́ nípa ẹfolúṣọ̀n, ipa tí ṣọ́ọ̀ṣì ń kó nínú ọ̀ràn ìṣèlú, àti sísọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ ẹni fún àwọn ẹlòmíràn. Ọ̀rọ̀ nípa ìwà rere, lórí irú àwọn àkòrí bíi ìṣẹ́yún, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, àti àwọn ẹni méjì tó ń gbé pa pọ̀ láìṣe ìgbéyàwó, sábà máa ń fa àríyànjiyàn rẹpẹtẹ. Ayé ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ la wà yìí.

Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Christian Century sọ pé, lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kan dìbò láti fọwọ́ sí ẹ̀tọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì kan ní “láti yan alàgbà kan tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ sínú ìgbìmọ̀ alákòóso rẹ̀.” Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tiẹ̀ ti gbé èròǹgbà kan kalẹ̀ pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù kì í ṣe ohun tó pọndandan fún ìgbàlà. Ìròyìn kan láti inú ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà gbà gbọ́ pé àwọn Júù, àwọn Mùsùlùmí, àtàwọn mìíràn “lè lọ sí ọ̀run [bíi tí àwọn Kristẹni].”

Tóo bá lè ṣe é, ìwọ fojú inú wo ẹnì kan tó jẹ́ olólùfẹ́ ètò ọrọ̀ ajé àjùmọ̀ní tó wá ń ṣe alágbàwí ìṣòwò bòńbàtà tàbí olóṣèlú ìjọba tiwa-n-tiwa tó wá ń gbé ìjọba aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ lárugẹ tàbí olùdáàbòbò àyíká tó wá ń gbárùkù ti pípa igbó run. Ǹjẹ́ o ò ní sọ pé “irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ṣojúlówó olólùfẹ́ ètò ọrọ̀ ajé àjùmọ̀ní, tàbí òṣèlú gidi tàbí ojúlówó olùdáàbòbò àyíká?”—wàá sì tọ̀nà tóo bá sọ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ nígbà tóo bá wo onírúurú èrò tí àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lóde òní ní, wàá rí àwọn ìgbàgbọ́ tó yàtọ̀ síra pátápátá tó sì sábà máa ń lòdì sí ohun tí Jésù Kristi, Olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni fi kọ́ni. Kí ni ìyẹn ń sọ nípa irú ẹ̀sìn Kristẹni tiwọn?—1 Kọ́ríńtì 1:10.

Ó ti pẹ́ tí àwọn ènìyàn ti ń làkàkà láti yí ẹ̀kọ́ Kristẹni padà kí ó lè bá ojú ìwòye ìgbàlódé mu, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i. Ojú wo ní Ọlọ́run àti Jésù Kristi fi ń wo irú ìyípadà bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá ìlànà Kristi mu lè fọwọ́ sọ̀yà pé Kristẹni làwọn? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.