Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Gba Ara Rẹ Àtàwọn Tí Ń Fetí Sí Ọ Là’

‘Gba Ara Rẹ Àtàwọn Tí Ń Fetí Sí Ọ Là’

‘Gba Ara Rẹ Àtàwọn Tí Ń Fetí Sí Ọ Là’

“Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. . . . Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 TÍMÓTÌ 4:16.

1, 2. Kí ló ń mú kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa bá iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà wọn nìṣó?

 NÍ ABÚLÉ kan tí ó wà ní àdádó ní àríwá ilẹ̀ Thailand, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ sọ tá-tà-tá tí wọ́n gbọ́ nínú èdè kan sáwọn ẹ̀yà kan tí ń gbé orí òkè. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni tọkọtaya náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Láhù, kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ará abúlé náà.

2 Ọkọ ṣàlàyé pé: “Ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí a ní, báa ti ń ṣiṣẹ́ láàárín àwọn èèyàn tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí, kò ṣeé fẹnu sọ. Ní ti gidi, a kà á sí pé a wà lára àwọn tí ìwé Ìṣípayá orí kẹrìnlá, ẹsẹ ìkẹfà àti ìkeje, ń ṣẹ sí lára, báa ti ń polongo làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ‘fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.’ Àwọn ìpínlẹ̀ tí ìhìn rere kò tíì dé kò pọ̀ rárá, ó sì dájú pé ibi tí a wà yìí jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Agbára káká la fi ń kárí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa.” Ó dájú pé góńgó tọkọtaya yìí kò mọ sórí gbígba ara wọn nìkan là, bí kò ṣe pé wọ́n tún fẹ́ gba àwọn tó ń fetí sí wọn là pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ǹjẹ́ kì í ṣe gbogbo wa la fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀?

“Máa Fiyè sí Ara Rẹ Nígbà Gbogbo”

3. Ká tó lè gba àwọn mìíràn là, kí làwa alára gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé, “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ,” èyí sì kan gbogbo Kristẹni. (1 Tímótì 4:16) Ní tòótọ́, ká tó lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàlà, a ní láti kọ́kọ́ fiyè sí ara wa. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nípa àkókò tí à ń gbé yìí. Jésù pèsè àmì kan tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè mọ̀ nígbà tí sáà “ìparí ètò àwọn nǹkan” yìí bá wọlé dé. Àmọ́ o, Jésù tún sọ pé a kò ní mọ àkókò pàtó tí òpin yóò dé. (Mátíù 24:3, 36) Báwo ló ṣe yẹ kí ọ̀ràn yìí rí lára wa?

4. (a) Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àkókò tó ṣẹ́ kù fún ètò yìí? (b) Èrò wo ló yẹ ká yàgò fún?

4 Olúkúlùkù wa lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń lo àkókò yòówù tó ṣẹ́ kù fún ètò yìí láti fi gba ara mi àtàwọn tó ń fetí sí mi là? Tàbí kẹ̀, ṣé ohun tí mò ń rò ni pé, “Níwọ̀n bí a ò ti mọ àkókò pàtó tí òpin máa dé, èmi ò lè máa fìyẹn gbé ara mi lẹ́mìí gbóná o jàre”?’ Ìrònú kejì yìí léwu o. Òdìkejì pátápátá ló jẹ́ sí ìyànjú tí Jésù gbà wá, pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:44) Dájúdájú, àkókò kọ́ nìyí láti dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tàbí láti wá ààbò àti ìtẹ́lọ́rùn lọ sínú ayé.—Lúùkù 21:34-36.

5. Àpẹẹrẹ wo làwọn ẹlẹ́rìí tó wà fún Jèhófà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé fi lélẹ̀?

5 Ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà fi hàn pé a ń fiyè sára wa ni nípa fífi ìṣòtítọ́ fara dà á gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ fara dà á dópin, yálà wọ́n retí kí ìdáǹdè dé lójú ẹsẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àpẹẹrẹ àwọn ẹlẹ́rìí tó wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, àwọn bíi Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù, àti Sárà, Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Wọn kò . . . rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” Wọn ò bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà àtigbé ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò dẹra nù, kí wọ́n sì wá juwọ́ sílẹ̀ fún ìwà pálapàla tó wà yí wọn ká, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi ìháragàgà wọ̀nà fún “ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà.”—Hébérù 11:13; 12:1.

6. Báwo ni èrò àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nípa ìgbàlà ṣe kan ìgbésí ayé wọn?

6 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tún rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí “àtìpó” nínú ayé yìí. (1 Pétérù 2:11) Kódà lẹ́yìn táwọn Kristẹni tòótọ́ ti la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, wọn ò wá tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ wíwàásù tàbí kí wọ́n wá ri ara wọn bọnú ayé. Wọ́n mọ̀ pé ìgbàlà ńlá ń dúró de àwọn tí ó bá ń bá ìṣòtítọ́ wọn nìṣó. Àní, títí fi di ọdún 98 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Jòhánù ṣì kọ̀wé pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17, 28.

7. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo ìfaradà lóde òní?

7 Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ti lo ìforítì nínú iṣẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fojú winá inúnibíni rírorò. Ìfaradà wọn ha ti já sásán bí? Kò tiẹ̀ lè já sásán ni, torí Jésù mú un dá wa lójú pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là,” yálà ìyẹn jẹ́ òpin ètò ògbólógbòó yìí tàbí òpin ìwàláàyè onítọ̀hún láyé tí a wà yìí. Nígbà àjíǹde, Jèhófà yóò rántí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú, yóò sì fún wọn ní èrè.—Mátíù 24:13; Hébérù 6:10.

8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ẹ̀mí ìfaradà táwọn Kristẹni ìjímìjí ní?

8 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a dúpẹ́ pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ ti ayé ọjọ́un kò du ìgbàlà ti ara wọn nìkan. Àwa tí a kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ akitiyan wọn dúpẹ́ pé wọ́n fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ tí Jésù pa láṣẹ, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Níwọ̀n ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣì ṣí sílẹ̀ fún wa, a lè fi hàn pé a moore nípa wíwàásù fáwọn ẹlòmíràn tí kò tíì gbọ́ ìhìn rere náà. Àmọ́ ṣá o, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni wíwàásù jẹ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.

‘Máa Fiyè sí Ẹ̀kọ́ Rẹ’

9. Báwo ni níní ẹ̀mí tó dáa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

9 Iṣẹ́ wa kò mọ sórí wíwàásù nìkan, ó tún wé mọ́ kíkọ́ni. Ara iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ ni pé ká máa kọ́ àwọn èèyàn láti máa pa gbogbo ohun tóun pa láṣẹ mọ́. Òtítọ́ ni pé láwọn ìpínlẹ̀ kan, ó lè dà bíi pé ìwọ̀nba kéréje làwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ̀mí pé wọn-ò-kúkú-ní-gbọ́ la fi ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ wa, a lè máà jára mọ́ bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yvette, tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ táwọn kan kà sí aláìléso, ṣàkíyèsí pé àwọn ará tó ti ibòmíràn wá sí àdúgbò yẹn ló lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí pé wọn kò ní èrò òdì yẹn. Nígbà tí Yvette pẹ̀lú wá túbọ̀ ní èrò tó dáa nípa ibẹ̀, òun náà rí àwọn èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

10. Kí ni olórí iṣẹ́ wa, gẹ́gẹ́ bí olùfi Bíbélì kọ́ni?

10 Àwọn Kristẹni kan lè máa lọ́ tìkọ̀ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn nítorí pé wọn ò gbà pé àwọn lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́. Òótọ́ kúkú ni pé a mọ nǹkan ṣe jura wa lọ. Àmọ́ kò dìgbà táa bá tó di ògbóǹkangí ká tò lè pegedé nínú fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni. Ìhìn aláìlábùlà tó wà nínú Bíbélì lágbára, Jésù sì sọ pé àwọn ẹni bí àgùntàn mọ ohùn Olùṣọ́ Àgùntàn tòótọ́ nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ. Fún ìdí yìí, iṣẹ́ wa kò ju pé ká sáà ti jẹ́ iṣẹ́ tí Jésù, Olùṣọ́ Àgùntàn àtàtà, fi rán wa láìfi bọpo bọyọ̀.—Jòhánù 10:4, 14.

11. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú ríran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́?

11 Báwo lo ṣe lè jẹ́ iṣẹ́ tí Jésù fi rán wa lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mọ ohun tí Bíbélì sọ dunjú nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ẹ ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Ìwọ alára gbọ́dọ̀ lóye kókó kan kóo tó lè fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbìyànjú láti jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbayì, àmọ́ kí ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹ̀kọ́ tètè máa ń wọrí àwọn akẹ́kọ̀ọ́, títí kan àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọ́n kéré pàápàá, bí ara bá tù wọ́n, tí olùkọ́ bá fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, tó sì lójú àánú.—Òwe 16:21.

12. Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé òye ohun tí ò ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan yé e?

12 Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, kì í ṣe pé o kàn fẹ́ máa rọ́ ìsọfúnni sí akẹ́kọ̀ọ́ lágbárí, kóun náà sì máa dáhùn gbuurugbu. Ràn án lọ́wọ́ láti lóye ohun tó ń kọ́. Bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kàwé tó, ìrírí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé, àti bó ṣe mọ Bíbélì tó, kò ní ṣàì nípa lórí bí òye ohun tí ò ń sọ ti yé e tó. Nítorí náà, o lè bí ara rẹ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ó lóye ìjẹ́pàtàkì àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú ẹ̀kọ́ yìí?’ O lè fi àwọn ìbéèrè tí kì í ṣe onídàáhùn bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé àlàyé ló máa fi dáhùn rẹ̀, wá a lẹ́nu wò. (Lúùkù 9:18-20) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan kì í fẹ́ bi olùkọ́ ní ìbéèrè kankan. Wọ́n kàn lè máa dún hẹn-hẹn, nígbà tí ohun tí a ń kọ́ wọn ò yé wọn dáadáa. Fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti máa béèrè ìbéèrè, kí ó sì sọ fún ẹ bí kókó kan ò bá yé e yékéyéké.—Máàkù 4:10; 9:32, 33.

13. Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di olùkọ́?

13 Ọ̀kan lára ète pàtàkì tí a fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni láti ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di olùkọ́. (Gálátíà 6:6) Láti ṣe èyí, nígbà tí ẹ bá ń ṣe àtúnyẹ̀wò ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, o lè ní kó ṣàlàyé kókó kan fún ẹ lọ́nà tó rọrùn, kó ṣàlàyé ọ̀hún bí ẹni pé ẹni tí ò tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn rí ló ń ṣàlàyé fún. Nígbà tó bá yá, tó ti tóótun láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, o lè ní kó jẹ́ kí ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Kò ní ṣàì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti bá ẹ ṣiṣẹ́, ìrírí tó bá sì jèrè yóò jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ máa balẹ̀ sí i, títí tí á fi lè dá jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.

Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Láti Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà

14. Kí ni olórí góńgó rẹ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, kí ni yóò sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lé e bá?

14 Góńgó pàtàkì tí olúkúlùkù Kristẹni tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ń lé ni láti ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Wàá ṣe èyí láṣeyọrí, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ nìkan, bí kò ṣe nípa àpẹẹrẹ rẹ pẹ̀lú. Kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ máa ń ní ipa lílágbára lórí ọkàn-àyà àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ìṣesí lágbára ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ, àgàgà tó bá dọ̀ràn gbígbin ẹ̀kọ́ ìwà rere àti ẹ̀mí ìtara sí akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn. Bó bá rí i pé ọ̀rọ̀ àti ìṣesí rẹ ń fi hàn pé o ní ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà, èyí lè mú kí òun náà mú irú ìbátan bẹ́ẹ̀ dàgbà.

15. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ní ète rere fún sísin Jèhófà? (b) Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú nìṣó nípa tẹ̀mí?

15 O fẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa sin Jèhófà nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kì í kàn-án ṣe pé kí ó máa sìn ín nítorí pé kò fẹ́ ṣègbé ní Amágẹ́dọ́nì. Tóo bá ń ràn án lọ́wọ́ láti ní irú ète rere bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, a jẹ́ pé àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná lo fi ń kọ́lé nìyẹn, èyí tó lè kojú ìdánwò ìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 3:10-15) Ète tó lòdì, irú bíi fífẹ́ láti máa fara wé ìwọ tàbí ẹ̀dá ènìyàn mìíràn lọ́nà àṣejù, kò ní jẹ́ kó lè ní agbára láti kọjúùjà sáwọn ìwà kan tó lòdì sí ti Kristẹni, ó sì lè máà ní ìgboyà láti ṣe ohun tó tọ́. Rántí pé o ò ní máa jẹ́ olùkọ́ rẹ̀ títí ayé. Nísinsìnyí tóo ní àǹfààní yẹn, o lè fún un níṣìírí láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí ó sì máa ṣàṣàrò nípa rẹ̀. Lọ́nà yìí, yóò máa bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ fún “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” látinú Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tóo bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.—2 Tímótì 1:13.

16. Báwo lo ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ láti máa gbàdúrà látọkànwá?

16 O tún lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípa kíkọ́ ọ láti máa gbàdúrà látọkànwá. Báwo lo ṣe lè ṣe èyí? Bóyá o lè tọ́ka rẹ̀ sí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù gbà, àti sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà àtọkànwá tó wà nínú Bíbélì, irú àwọn èyí tó wà nínú sáàmù. (Sáàmù 17, 86, 143; Mátíù 6:9, 10) Láfikún sí i, nígbà tí ẹni tóo ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá gbọ́ bóo ṣe ń gbàdúrà nígbà tẹ́ẹ bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àti tẹ́ẹ bá fẹ́ parí ìkẹ́kọ̀ọ́, á mọ bóo ṣe fẹ́ràn Jèhófà tó. Ìyẹn ló fi yẹ kí àdúrà rẹ máa fi hàn nígbà gbogbo pé o jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlẹ́tàn, àti pé o wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa tẹ̀mí, ojú ìwòye rẹ kò sì fì síbì kan.

Sísapá Láti Gba Àwọn Ọmọ Rẹ Là

17. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti má ṣe fi ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀?

17 Dájúdájú, àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa wà lára àwọn tí a fẹ́ gbà là. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ táwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bí ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n sì ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’ Àmọ́ o, àwọn kan tún wà tí òtítọ́ ò wọ̀ lọ́kàn dáadáa. (1 Pétérù 5:9; Éfésù 3:17; Kólósè 2:7) Ọ̀pọ̀ lára ọ̀dọ́ wọ̀nyí ló ti fi ọ̀nà Kristẹni sílẹ̀ nígbà tí wọ́n di ẹni tó tójúúbọ́. Bóo bá jẹ́ òbí, kí lo lè ṣe láti yẹra fún irú àtúbọ̀tán bẹ́ẹ̀? Èkíní, o lè sapá láti rí i pé ìdílé rẹ tòrò. Ìgbésí ayé ìdílé tó gbámúṣé máa ń jẹ́ kó rọrùn láti fi ojú tó dáa wo àwọn tó wà nípò àṣẹ, láti mọyì ìwà ọmọlúwàbí, àti láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Hébérù 12:9) Nípa báyìí, bí ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ bá wà nínú ìdílé, èyí lè gbin ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà sí ọmọ lọ́kàn. (Sáàmù 22:10) Ńṣe làwọn ìdílé tó wà ní ìrẹ́pọ̀ máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀—kódà bó bá di dandan káwọn òbí fi àkókò tí wọn ì bá máa fi wá ire ti ara wọn rúbọ. Lọ́nà yìí, àpẹẹrẹ tẹ́ẹ fi lélẹ̀ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ nínú ìgbésí ayé. Ẹ̀yin òbí, kì í ṣe àwọn nǹkan ti ara làwọn ọmọ yín ń fẹ́ jù lọ látọ̀dọ̀ yín, bí kò ṣe ẹ̀yin alára—àkókò yín, okun yín, àti ìfẹ́ yín. Ṣé ẹ̀ ń fún àwọn ọmọ yín ní nǹkan wọ̀nyí?

18. Irú àwọn ìbéèrè wo làwọn òbí gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti dáhùn?

18 Àwọn Kristẹni òbí ò gbọ́dọ̀ ronú pé, bó ti wù kó jẹ́, Kristẹni lọmọ àwọn náà yóò jẹ́. Daniel, tó jẹ́ alàgbà àti bàbá ọmọ márùn-ún, sọ pé: “Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò láti mú àwọn iyèméjì tí iléèwé àtàwọn ibòmíràn ń gbìn sọ́kàn àwọn ọmọ wọn kúrò. Wọ́n ní láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé lóòótọ́ là ń gbé lákòókò òpin? Ṣé òótọ́ ni pé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà? Èé ṣe tí ọmọléèwé tó ń ṣe bí ọmọlúwàbí yẹn kò fi yẹ ní bíbá rìn? Ṣé gbogbo ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ló burú ni?’” Ẹ̀yin òbí, ìdánilójú wà pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá yín, torí pé òun náà fẹ́ kó dáa fáwọn ọmọ yín.

19. Èé ṣe tó fi dáa jù lọ pé káwọn òbí fúnra wọn máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn?

19 Àwọn òbí kan lè máa ronú pé àwọn ò kúkú tóótun tó bá dọ̀ràn ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ o, kò sídìí fún ríronú bẹ́ẹ̀, nítorí pé kò tún sẹ́lòmíràn tó lè mọ àwọn ọmọ rẹẹ́ kọ́ bí ìwọ alára. (Éfésù 6:4) Kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ kóo mọ ohun náà gan-an tó wà lọ́kàn àti èrò inú wọn. Ṣé ọkàn wọn lohun tí wọ́n ń sọ ti ń wá, tàbí ọ̀rọ̀ tí ò kọjá orí ahọ́n ni? Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n gba ohun tí wọ́n ń kọ́ gbọ́? Ṣé wọ́n ka Jèhófà sí ẹni gidi? Àyàfi bó bá jẹ́ ìwọ alára ló ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ rẹ lo fi lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó ṣe kókó.—2 Tímótì 1:5.

20. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùn mọ́ni kó sì ṣàǹfààní?

20 Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín ṣe lè máa bá a lọ láìdáwọ́dúró lẹ́yìn tẹ́ẹ bá bẹ̀rẹ̀? Joseph, tó jẹ́ alàgbà àti bàbá ọmọkùnrin kékeré kan àti ọmọbìnrin kan, sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ kó rí pẹ̀lú gbogbo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùn mọ́ni, kó jẹ́ ohun tí olúkúlùkù ń fojú sọ́nà fún. Kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tàwa náà lè rí bẹ́ẹ̀, a kì í wonkoko mọ́ ọn pé iye wákàtí báyìí la gbọ́dọ̀ lò. Ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lè gba wákàtí kan, àmọ́ bó tiẹ̀ ṣe ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré la ní nígbà mìíràn, a ṣì máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ohun kan tó máa ń jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ wa jẹ́ àkókò táwọn ọmọ gbádùn jù lọ láàárín ọ̀sẹ̀ ni pé a máa ń fi àwọn ìtàn inú Iwe Itan Bibeli Mi a ṣe eré àwòkẹ́kọ̀ọ́. Bó ṣe wọ̀ wọ́n lọ́kàn tó, àti bí wọ́n ṣe lóye rẹ̀ jinlẹ̀-jinlẹ̀ tó, ṣe pàtàkì gidigidi ju iye ìpínrọ̀ táa kà lọ.”

21. Ìgbà wo làwọn òbí lè fún ọmọ wọn nítọ̀ọ́ni?

21 Ṣùgbọ́n, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kí o fi kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ mọ sí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nìkan o. (Diutarónómì 6:5-7) Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ nílẹ̀ Thailand tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Mo rántí dáadáa bí Dádì ṣe máa ń fi kẹ̀kẹ́ gbé mi dání lọ sáwọn ìpínlẹ̀ ìjọ wa tó jìnnà gan-an láti lọ wàásù. Dájúdájú, àpẹẹrẹ rere táwọn òbí wa fi lélẹ̀ àti kíkọ́ tí wọ́n kọ́ wa lábẹ́ ipòkípò ló ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu pé a óò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn ẹ̀kọ́ náà sì wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. Ṣebí èmi ọ̀hún rèé lónìí, tí mo ṣì ń ṣiṣẹ́ ní pápá tó jìnnà réré yìí!”

22. Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ bóo bá ‘ń fiyè sí ara rẹ àti sí ẹ̀kọ́ rẹ’?

22 Níjọ́ ọjọ́ kan, láìpẹ́ sígbà táa wà yìí, nígbà tákòókò rẹ̀ bá tó gẹ́ẹ́, Jésù yóò dé láti wá mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí ètò yìí. Ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì yẹn yóò wá dohun àmúpìtàn kárí ayé, ṣùgbọ́n àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà yóò máa sìn ín lọ fáàbàdà pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé níwájú wọn. Ṣé o ń retí àtiwà lára wọn, tọmọtọmọ, àti pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ? Nígbà náà, fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tímótì 4:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní, níwọ̀n bí a kò ti mọ àkókò pàtó tí ìdájọ́ Ọlọ́run yóò dé?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ‘fiyè sí ẹ̀kọ́ wa’?

• Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí ṣètò àkókò fún kíkọ́ àwọn ọmọ wọn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹ̀kọ́ máa ń dùn-ún kọ́ tí a bá ń kọ́ni lọ́nà tó gbayì tó sì jẹ́ ti ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Fífi àwọn ìtàn Bíbélì, bíi ìgbà tí Sólómọ́nì dájọ́ aṣẹ́wó méjì yẹn, ṣe eré àwòkẹ́kọ̀ọ́, máa ń jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùn mọ́ni