Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Rere Gbà?
Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Rere Gbà?
Àwọn “iléeṣẹ́ agbaninímọ̀ràn” ti wá di iléeṣẹ́ tí ń mú àìmọye bílíọ̀nù dọ́là wọlé lọ́dọọdún báyìí o. Àwọn èèyàn ń wá ìrànlọ́wọ́. Heinz Lehmann, tó mọṣẹ́ ìlera ọpọlọ dunjú sọ pé: “[Nínú àwùjọ òde òní], ètò ẹ̀kọ́ àti àjọṣe láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ti mẹ́hẹ. Àwọn ìlànà ìsìn ò rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn ìdílé ò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ . . . , ìyẹn làwọn èèyàn ṣe ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kiri.” Òǹkọ̀wé Eric Maisel sọ pé: “Àwọn tó ti fìgbà kan yíjú sí adáhunṣe, tí wọ́n yíjú sí pásítọ̀ tàbí dókítà ìdílé wọn fún ìrànlọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro ọpọlọ, ìṣòro tẹ̀mí àti àwọn ìṣòro ara ti ń yíjú sí àwọn ìwé tí wọ́n lè kà fúnra wọn báyìí láti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro wọn.”
ẸGBẸ́ Afìṣemọ̀rònú ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti gbé ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan kalẹ̀ láti gbé ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ tí owó ń ya wọlé fún yìí yẹ̀ wò. Wọ́n sọ pé, nígbà tó jẹ́ pé “àgbàyanu àǹfààní ló wà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ara wọn àti àwọn ẹlòmíràn . . . , gbogbo àrà tí wọ́n pariwo pé àwọn lè dá àti àwọn orúkọ tí wọ́n fi ń pe ètò yìí sábà máa ń jẹ́ àsọdùn àti èyí tí ń ru ìmọ̀lára ẹni sókè ṣáá ni.” Ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé ìròyìn Toronto Star sọ pé: “Mọ bí àwọn ayédèrú ìsìn ṣe pọ̀ tó. . . . Pàtàkì jù lọ ní pé kí o ṣọ́ra fún gbogbo àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é, àwọn kásẹ́ẹ̀tì tàbí àpérò tó ń gbani ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn láàárín àkókò kúkúrú, láìsí ìsapá kankan tàbí ìkára ẹni lọ́wọ́ kò kankan.” Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ ló ń fi tinútinú fẹ́ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó níṣòro. Àmọ́, ohun tó ń bani nínú jẹ́ níbẹ̀ ni pé àwọn aríjẹ nídìí màdàrú wà tí wọ́n máa ń dánnu pé àwọn ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí kò léèyàn àti àwọn tí ìyà ń jẹ, àmọ́ tí wọn ò ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan fún wọn, tí wọn ò sì bá wọn yanjú ìṣòro wọn.
Látàrí èyí, kí ni ojúlówó orísun ìrànlọ́wọ́ táa lè gbẹ́kẹ̀ lé? Ibo la ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò nígbà gbogbo?
Orísun Ìtọ́sọ́nà Tí Kì Í Kùnà
Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, oníwàásù ará Amẹ́ríkà nì, Henry Ward Beecher, sọ pé: “Bíbélì ni ìwé atọ́nà tí Ọlọ́run fún ọ láti máa wò, kí ọkọ̀ rẹ má bàa rì, òun ni yóò sì fi ibi tí èbúté wà hàn ọ́, àti bí o ṣe máa débẹ̀ láìsí pé o forí sọ àpáta tàbí òkìtì yanrìn.” Ọkùnrin mìíràn sọ nípa Bíbélì pé: “Kò sí ẹni tó lè dàgbà kọjá Ìwé Mímọ́; bí ọdún ti ń gorí ọdún ni ìwé náà túbọ̀ ń ṣe kedere sí i, tó sì ń fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye sí i.” Èé ṣe tó fi yẹ kí o gbé orísun yìí yẹ̀ wò dáradára?
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀, ó ní: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Ọ̀dọ̀ Orísun ìyè fúnra rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, ni àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì ti pilẹ̀ ṣẹ̀. (Sáàmù 36:9) Nípa bẹ́ẹ̀, ó mọ gbogbo bí a ṣe jẹ́, gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 103:14 ṣe rán wa létí pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” Nítorí ìdí èyí, a lè wá ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Bíbélì.
Àní, Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ìlànà àti àwọn ìtọ́ni tó lè ṣe ọ́ láǹfààní nínú ipòkípò tí o bá bá ara rẹ. Ipasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọ́run ti sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni Bíbélì lè yanjú ìṣòro ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lónìí? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
Bíbélì Ń Yanjú Ìṣòro Wa . . .
Ní Bíborí Àníyàn. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé àdúrà ti gbéṣẹ́ nínú kíkojú àwọn àníyàn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣúnná owó, fífi ìbálòpọ̀ fìtínà ẹni àti sísọ̀rọ̀ gbáni lórí, tàbí ikú olólùfẹ́ kan? Gbé àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Lẹ́yìn tí Jáckie gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe fi ìbálòpọ̀ fìtínà ọmọ rẹ̀ obìnrin, ó sọ pé: “Ìmọ̀lára ẹ̀bi téèyàn máa ń ní nítorí àìlágbára láti dáàbò bo ọmọ ẹni kọjá sísọ. Mo ní láti gbógun ti ìbànújẹ́ kíkorò, ìkórìíra, àti ìbínú. Àwọn èrò wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sí ba ìgbésí ayé mi jẹ́. Mo wá nílò Jèhófà gan-an láti dáàbò bo ọkàn-àyà mi.” Lẹ́yìn tó ka Fílípì 4:6, 7 ní àkàtúnkà, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fi ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ sílò. Jackie sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo ń gbàdúrà, tí mo ń bẹ̀bẹ̀ léraléra pé kí n má lọ fi èrò òdì ba ayé ara mi jẹ́, Jèhófà sì ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, kí n sì láyọ̀. Mo rí i pé mo ní àlàáfíà nínú ara mi ní ti tòótọ́.”
Ìwọ náà lè bá ara rẹ nínú ipò tí agbára rẹ ò ká tàbí tí oò rójútùú rẹ̀, tí ìyẹn sì ń jẹ́ kí o ṣàníyàn. Tí o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nípa àdúrà gbígbà, o lè borí rẹ̀ dáadáa. Onísáàmù náà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gbà wá níyànjú pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.”—Sáàmù 37:5.
Fún Ìṣírí. Onísáàmù náà sọ gbólóhùn tó ń fi ìmọrírì hàn yìí pé: “Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ àti ibi gbígbé ògo rẹ. Dájúdájú, ẹsẹ̀ mi yóò dúró lórí ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ; inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.” (Sáàmù 26:8, 12) A gbà wá níyànjú nínú Bíbélì pé kí a máa péjọ pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà. Báwo ni ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ yìí ṣe lè yanjú ìṣòro rẹ? Kí ni àwọn ẹlòmíràn ti ṣàwárí rẹ̀?
Becky sọ pé: “Àwọn òbí mi kò sin Jèhófà, ìyẹn ni wọ́n ṣe máa ń ta kò mí nígbà tí mo bá ń gbìyànjú àtiṣe ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú sísin Ọlọ́run. Mo ní láti sapá gidigidi kí n tó lè lọ sí àwọn ìpàdé.” Becky rí i pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni òun ti rí nítorí pé ó tiraka láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Ó ní: “Àwọn ìpàdé ti fún ìgbàgbọ́ mi lókun, tí mo fi lè kojú àwọn pákáǹleke ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ìwé, bí ọmọbìnrin nínú ilé, àti ìránṣẹ́ Jèhófà. Àwọn èèyàn tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba mà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọmọléèwé o! Wọ́n bìkítà, wọ́n sì wúlò, àwọn ìjíròrò wa sì máa ń fúnni níṣìírí nígbà gbogbo. Ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n.”
Dájúdájú, nípa títẹ̀lé ìdarí Bíbélì láti máa pàdé pọ̀ déédéé, a lè rí i pé Jèhófà ń pèsè ìṣírí táa nílò. Níhìn-ín la ti máa ń rí òtítọ́ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.”—Sáàmù 46:1.
Fún Iṣẹ́ Tó Tẹ́ni Lọ́rùn Tó sì Ní Láárí. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Ṣé lóòótọ́ ni “iṣẹ́ Olúwa” ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn? Ǹjẹ́ iṣẹ́ ìsìn Kristẹni ń ṣàṣeparí ohunkóhun tó ní láárí?
Amelia ṣàlàyé bó ṣe rí lára òun pé: “Mo bá tọkọtaya kan tí wọ́n ti fẹ́ tú ká ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo tún ṣèrànwọ́ fún obìnrin kan tí wọ́n pa ọmọ rẹ̀ obìnrin nípakúpa. Ọkàn obìnrin náà gbọgbẹ́ nítorí pé kò mọ ipò tí àwọn òkú wà. Nínú ọ̀ràn méjèèjì wọ̀nyí, fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ló mú àlàáfíà àti ìrètí wá sínú ìgbésí ayé wọn. Mo ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó ga nítorí pé mo nípìn-ín nínú ríràn wọ́n lọ́wọ́.” Scott sọ pé: “Tóo bá ní àwọn ìrírí alárinrin nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, tàbí tóo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun, tàbí tóo ṣe àwọn àṣeyọrí kan nínú wíwàásù láìjẹ́ bí àṣà, ńṣe ni wàá máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣáá ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Gbogbo ìgbà tóo bá rántí rẹ̀ ní ara rẹ yóò máa yá gágá tí inú rẹ yóò sì máa dùn! Inú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni ayọ̀ tó ga jù lọ àti èyí tó ń wà pẹ́ títí ti máa ń wá.”
Ní kedere, fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò láti jẹ́ òjíṣẹ́ tó jáfáfá ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn wọ̀nyí láti ní iṣẹ́ tó tẹ́ wọn lọ́rùn, tó sì ní láárí. A ké sí ìwọ náà láti wá nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí, iṣẹ́ tí a fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà àti ìlànà Ọlọ́run, wàá sì tún ṣe ara rẹ̀ láǹfààní pẹ̀lú.—Aísáyà 48:17; Mátíù 28:19, 20.
Jíjèrè Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Láìsí àní-àní, Bíbélì ni orísun tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé fún ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ nínú ayé òde òní. Táa bá fẹ́ jàǹfààní nínú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi. A gbọ́dọ̀ máa kà á déédéé, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 4:15; Diutarónómì 11:18-21) Ọlọ́run mú un dá ọ lójú pé tí o bá fi ìmọ̀ràn rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì sílò, wàá kẹ́sẹ járí. Ó ṣèlérí pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. . . . Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì ń mú kí ìgbésí ayé tẹ́ni lọ́rùn, kó sì nítumọ̀